ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 73 ojú ìwé 172-ojú ìwé 173 ìpínrọ̀ 2
  • Jòhánù Múra Àwọn Èèyàn Sílẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jòhánù Múra Àwọn Èèyàn Sílẹ̀
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Òun Ni Ẹni Tí A Rán Ṣáájú Messia Náà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Jòhánù Arinibọmi Ṣètò Ọ̀nà Sílẹ̀
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Jésù Di Mèsáyà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Johanu Pa Ọ̀nà Mọ́
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 73 ojú ìwé 172-ojú ìwé 173 ìpínrọ̀ 2
Jòhánù Arinibọmi ń kọ́ àwọn èèyàn létí Odò Jọ́dánì

Ẹ̀KỌ́ 73

Jòhánù Múra Àwọn Èèyàn Sílẹ̀

Jòhánù ọmọ Sekaráyà àti Èlísábẹ́tì di wòlíì Ọlọ́run nígbà tó dàgbà. Jèhófà lo Jòhánù láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Mèsáyà ń bọ̀. Àmọ́, dípò kí Jòhánù máa kọ́ àwọn èèyàn nínú sínágọ́gù tàbí nínú ìlú, inú aginjù ló ti ń kọ́ wọn. Àwọn èèyàn wá láti Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jòhánù. Ó kọ́ wọn pé tí wọ́n bá fẹ́ mú inú Ọlọ́run dùn, wọ́n gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú ohun búburú. Ọ̀rọ̀ tí Jòhánù bá wọn sọ mú kí ọ̀pọ̀ lára wọn ronú pìwà dà, Jòhánù sì ṣèrìbọmi fún wọn nínú Odò Jọ́dánì.

Jòhánù kì í ṣe olówó. Asọ tí wọ́n fi irun ràkúnmí ṣe ló máa ń wọ̀, kòkòrò kan tí wọ́n ń pè ní eéṣú àti oyin ìgàn ló sì máa ń jẹ. Àwọn èèyàn máa ń wò ó pé, irú èèyàn wo lèyí? Kódà, àwọn Farisí àtàwọn Sadusí tí wọ́n jẹ́ agbéraga wá sọ́dọ̀ ẹ̀. Jòhánù wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ gbọ́dọ̀ yíwà yín pa dà. Ẹ má rò pé èèyàn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni yín torí ẹ sọ pé ọmọ Ábúráhámù ni yín. Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ọmọ Ọlọ́run ni yín.’

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń wá sọ́dọ̀ Jòhánù, wọ́n á sì bi í pé: ‘Kí la máa ṣe kínú Ọlọ́run lè dùn sí wa?’ Jòhánù máa ń sọ fún wọn pé: ‘Kí ẹni tó ní aṣọ méjì fún ẹni tí kò ní rárá ní aṣọ kan.’ Ṣé o mọ ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó fẹ́ káwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ mọ̀ pé tí wọ́n bá fẹ́ mú inú Ọlọ́run dùn, wọ́n gbọ́dọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn míì.

Jòhánù sọ fáwọn agbowó orí pé: ‘Ẹ má ṣe rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ.’ Ó tún sọ fáwọn sójà pé: ‘Ẹ má ṣe gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, kẹ́ ẹ sì máa sọ òtítọ́.’

Àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì náà wá bá Jòhánù, wọ́n sì bi í pé: ‘Ta ni ẹ́? Torí pé gbogbo èèyàn ló fẹ́ mọ̀ ẹ́.’ Jòhánù wá sọ fún wọn pé: ‘Èmi ni ohùn ẹni tó ń ké jáde ní aginjù pé, ẹ mú kí ọ̀nà Jèhófà tọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí wòlíì Àìsáyà ti sọ tẹ́lẹ̀.’

Inú àwọn èèyàn ń dùn sí ohun tí Jòhánù ń kọ́ wọn. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì ń ronú pé òun gangan ni Mèsáyà. Àmọ́, ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹnì kan ń bọ̀ tó tóbi jù mí lọ, mi ò sì lè tú okùn bàtà ẹ̀. Èmi ń bátisí pẹ̀lú omi, àmọ́ ẹni yẹn máa bátisí yín pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́.’

“Ọkùnrin yìí wá gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí, kó lè jẹ́rìí nípa ìmọ́lẹ̀ náà, kí onírúurú èèyàn lè gbà gbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.”​—Jòhánù 1:7

Ìbéèrè: Kí nìdí tí Jèhófà fi rán Jòhánù sáwọn èèyàn? Kí làwọn èèyàn ṣe lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Jòhánù?

Mátíù 3:1-11; Máàkù 1:1-8; Lúùkù 3:1-18; Jòhánù 1:19-28; Àìsáyà 40:3

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́