ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • gt orí 11
  • Johanu Pa Ọ̀nà Mọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Johanu Pa Ọ̀nà Mọ́
  • Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jòhánù Arinibọmi Ṣètò Ọ̀nà Sílẹ̀
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Òun Ni Ẹni Tí A Rán Ṣáájú Messia Náà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Jòhánù Múra Àwọn Èèyàn Sílẹ̀
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Jésù Di Mèsáyà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
gt orí 11

Orí 11

Johanu Pa Ọ̀nà Mọ́

ỌDUN 17 ti kọja lọ lati ìgbà ti Jesu jẹ́ ọmọ ọdun 12 ti o nbeere ibeere lọwọ awọn olukọ ninu tẹmpili. O jẹ́ ni ìgbà ìrúwé 29 C.E., ó sì dabi ẹni pe, gbogbo eniyan ni o nsọrọ nipa mọ̀lẹ́bí Jesu naa Johanu, ẹni ti o nwaasu ni gbogbo ìgbèríkó ti o yí Odò Jọdani ká.

Johanu nitootọ jẹ́ ọkunrin kan ti o fanimọra, ni ìrísí ati ni ọ̀rọ̀ sísọ. Aṣọ rẹ̀ jẹ́ ti ẹran ràkúnmí, o sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ounjẹ rẹ̀ ni kòkòrò eéṣú ati oyin ìgàn. Kí sì ni ihin iṣẹ́ rẹ̀? “Ẹ ronupiwada, nitori ijọba ọrun kù sí dẹ̀dẹ̀.”

Ihin iṣẹ yii ru awọn olùgbọ́ rẹ̀ soke. Ọpọlọpọ ni wọn mọ aini wọn lati ronupiwada, eyiini ni, lati yí iṣarasi huwa wọn pada kí wọn sì kọ ipa ọna igbesi-aye wọn atẹhinwa silẹ bi ohun tí a kò fẹ́. Nitori naa lati gbogbo agbegbe ipinlẹ ti o yi Jọdani ká, ani lati Jerusalẹmu paapaa, awọn eniyan jade tọ Johanu wá ni ògìdìgbó, oun sì nbaptisi wọn, ó sì ńrì wọn bọ inú omi Jọdani. Eeṣe?

Johanu nbaptisi awọn eniyan gẹgẹ bi ami, tabi ìmọ̀jẹ́wọ́, ironupiwada atọkanwa wọn fun awọn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọn ti dá lodisi Ofin majẹmu Ọlọrun. Nipa bayii, nigba ti awọn Farisi ati awọn Sadusi kan jade wá sí Jọdani, Johanu dẹbi fun wọn. “Ẹyin ọmọ paramọ́lẹ̀,” ni oun wí. “Ẹ so eso ti o yẹ fun ironupiwada. Ki ẹ má sì ṣe rò ninu araayin, wipe, awa ní Aburahamu ni baba. Ki emi wi fun yin, Ọlọrun lè yọ ọmọ jade lati inu okuta wọnyi wá fun Aburahamu. Ati nisinsinyi pẹlu, a ti fi àáké lé gbongbo igi naa; nitori naa gbogbo igi tí kò bá so eso rere, a o ké e lulẹ, a o sì wọ́ ọ ju sinu iná.”

Nitori gbogbo afiyesi ti Johanu nri gbà, awọn Juu rán awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi sí i. Awọn wọnyi beere pe: “Ta ni iwọ nṣe?”

“Emi kii ṣe Kristi naa,” ni Johanu jẹ́wọ́.

“Ta ni iwọ nṣe?” ni wọn wadii. “Elija ni ọ bí?”

“Bẹẹkọ,” ni oun dahun.

“Iwọ ni wolii naa bí?”

“Bẹẹkọ!”

Nitori naa wọn tẹpẹlẹ mọ́ ọn pe: “Ta ni iwọ nṣe? ki awa ki o lè fi èsì fun awọn ti o rán wa. Ki ni o wí niti araàrẹ?”

Johanu ṣalaye pe: “Emi ni ohùn ẹni ti nkigbe ni ijù, Ẹ ṣe é kí ọna Oluwa [“Jehofa,” NW] tọ́, gẹgẹ bi wolii Aisaya ti wi.”

“Eeṣe ti iwọ fi nbaptisi,” ni wọn fẹ́ lati mọ̀, “bi iwọ kii baa ṣe Kristi naa, tabi Elija, tabi wolii naa?”

“Emi nfi omi baptisi,” ni oun dahun. “Ẹnikan duro laaarin yin, ẹni tí ẹyin kò mọ̀, oun naa ni ẹni ti o nbọ lẹhin mi.”

Johanu npa ọ̀nà mọ́ nipa mimu ki ọkan awọn eniyan naa wà ni ipo ti o tọ́ lati tẹwọgba Mesaya naa, ti yoo di Ọba. Nipa Ẹni yii, Johanu wipe: “Ẹnikan ti o pọ̀ ju mi lọ nbọ lẹhin mi, bàtà ẹni ti emi kò tó gbé.” Koda Johanu sọ niti gidi pe: “Ẹni ti o nbọ lẹhin mi, o pọ̀ ju mi lọ, nitori o wà ṣiwaju mi.”

Nipa bayii, ihin iṣẹ Johanu, “ijọba ọrun kù sí dẹ̀dẹ̀,” ṣiṣẹ gẹgẹ bi ìfitónileti tẹlẹ ni gbangba pe, iṣẹ-ojiṣẹ Ọba ti Jehofa yàn, Jesu Kristi, ti fẹ bẹ̀rẹ̀. Johanu 1:6-8, 15-28; Matiu 3:1-12; Luuku 3:1-18; Iṣe 19:4.

▪ Iru ọkunrin wo ni Johanu jẹ́?

▪ Eeṣe ti Johanu fi baptisi awọn eniyan?

▪ Eeṣe ti Johanu fi lè wipe Ijọba naa ti sunmọle?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́