Ẹ̀KỌ́ 74
Jésù Di Mèsáyà
Jòhánù ti ń wàásù fáwọn èèyàn pé: ‘Ẹnì kan tó tóbi jù mí lọ ń bọ̀.’ Nígbà tí Jésù pé ọmọ ọgbọ̀n (30) ọdún, ó wá sí Odò Jọ́dánì, níbi tí Jòhánù ti ń ṣèrìbọmi fáwọn èèyàn. Jésù fẹ́ kí Jòhánù ṣèrìbọmi fún òun, àmọ́ Jòhánù sọ pé: ‘Ìwọ ló yẹ kó o ṣèrìbọmi fún mi, kì í ṣe èmi ló yẹ kí n ṣèrìbọmi fún ẹ.’ Jésù wá sọ fún Jòhánù pé: ‘Jèhófà fẹ́ kó o ṣèrìbọmi fún mi.’ Torí náà, àwọn méjèèjì lọ sínú Odò Jọ́dánì, Jòhánù sì ri Jésù bọ inú omi náà pátápátá.
Lẹ́yìn tí Jésù jáde kúrò nínú omi, ó gbàdúrà sí Jèhófà. Bí Jésù ṣe ń gbàdúrà lọ́wọ́, ọ̀run ṣí sílẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tó dà bí ẹyẹ àdàbà sì bà lé Jésù. Jèhófà wá sọ̀rọ̀ látọ̀run pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.”
Nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run bà lé Jésù, Jésù di Kristi tàbí Mèsáyà. Àkókò wá tó báyìí fún Jésù láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí Jèhófà rán an pé kó wá ṣe láyé.
Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló lọ sí aginjù, ó sì lo ogójì (40) ọjọ́ níbẹ̀. Nígbà tó kúrò ní aginjù, ó lọ sọ́dọ̀ Jòhánù. Bí Jòhánù ṣe rí Jésù lọ́ọ̀ọ́kán, ó sọ pé: ‘Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run ló ń bọ̀ yìí, òun ló sì máa kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.’ Ohun tí Jòhánù sọ yìí jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà. Àmọ́, ṣé o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù nígbà tó wà ní aginjù? Jẹ́ ká wò ó.
“Ohùn kan sì dún láti ọ̀run pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, àyànfẹ́; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.’”—Máàkù 1:11