ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 11 ojú ìwé 30-ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 14
  • Jòhánù Arinibọmi Ṣètò Ọ̀nà Sílẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jòhánù Arinibọmi Ṣètò Ọ̀nà Sílẹ̀
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Johanu Pa Ọ̀nà Mọ́
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Òun Ni Ẹni Tí A Rán Ṣáájú Messia Náà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Jòhánù Múra Àwọn Èèyàn Sílẹ̀
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Jésù Di Mèsáyà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 11 ojú ìwé 30-ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 14
Jòhánù Arinibọmi ń wàásù ìrònúpìwàdà

ORÍ 11

Jòhánù Arinibọmi Ṣètò Ọ̀nà Sílẹ̀

MÁTÍÙ 3:1-12 MÁÀKÙ 1:1-8 LÚÙKÙ 3:1-18 JÒHÁNÙ 1:6-8, 15-28

  • JÒHÁNÙ Ń WÀÁSÙ, Ó SÌ Ń RINI BỌMI

  • Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN LÓ ṢÈRÌBỌMI, ÀMỌ́ KÌ Í ṢE GBOGBO WỌN

Nígbà ìrúwé ọdún 29 S.K., ìyẹn nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínlógún (17) lẹ́yìn tí Jésù lọ sínú tẹ́ńpìlì lọ́mọ ọdún méjìlá (12), tó sì ń bi àwọn olùkọ́ ní ìbéèrè. Àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa mọ̀lẹ́bí Jésù kan tó ń jẹ́ Jòhánù. Ìdí ni pé Jòhánù ń wàásù ní gbogbo ìgbèríko tó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn Odò Jọ́dánì.

Ìrísí Jòhánù àti ọ̀rọ̀ ẹnu ẹ̀ wúni lórí gan-an. Irun ràkúnmí ni wọ́n fi ṣe aṣọ tó ń wọ̀, ó sì máa ń de bẹ́líìtì tí wọ́n fi awọ ṣe. Oríṣi tata kan tí wọ́n ń pè ní eésú àti oyin ìgàn ló máa ń jẹ. Ohun tó ń wàásù fáwọn èèyàn ni pé: “Ẹ ronú pìwà dà, torí Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.”—Mátíù 3:2.

Ọ̀rọ̀ Jòhánù máa ń wú àwọn tó ń fetí sí i lórí. Ọ̀pọ̀ nínú wọn sì rí i pé ó yẹ káwọn ronú pìwà dà, ìyẹn ni pé, kí wọ́n yí ìwà àti ìṣe wọn pa dà, kí wọ́n sì yẹra fáwọn ohun tí ò dáa tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀. “Jerúsálẹ́mù àti gbogbo Jùdíà àti gbogbo ìgbèríko tó yí Jọ́dánì ká” làwọn èèyàn ti ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀. (Mátíù 3:5) Ọ̀pọ̀ àwọn tó wá bá Jòhánù ló ronú pìwà dà. Jòhánù á wá rì wọ́n bọmi nínú Odò Jọ́dánì. Kí nìdí tó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?

Àwọn Júù tó ronú pìwà dà wá bá Jòhánù kó lè rì wọ́n bọmi

Ó ń ri àwọn èèyàn bọmi láti fi hàn pé wọ́n ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn lórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá lòdì sí Òfin Mósè. (Ìṣe 19:4) Àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ló ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Nígbà tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan, ìyẹn àwọn Farisí àtàwọn Sadusí wá bá a, Jòhánù pè wọ́n ní “ọmọ paramọ́lẹ̀.” Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ so èso tó yẹ ìrònúpìwàdà. Ẹ má ṣe dá ara yín lójú, kí ẹ sì sọ fún ara yín pé, ‘A ní Ábúráhámù ní baba.’ Torí mò ń sọ fún yín pé Ọlọ́run lè gbé àwọn ọmọ dìde fún Ábúráhámù látinú àwọn òkúta yìí. Àáké ti wà níbi gbòǹgbò àwọn igi báyìí. Torí náà, gbogbo igi tí kò bá so èso tó dáa la máa gé lulẹ̀, tí a sì máa jù sínú iná.”—Mátíù 3:7-10.

Nígbà táwọn kan rí i pé òkìkí Jòhánù ń kàn, pé ìwàásù rẹ̀ gbàfiyèsí, ó sì tún ń ri ọ̀pọ̀ èèyàn bọmi, wọ́n rán àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì pé kí wọ́n lọ bi í pé: “Ta ni ọ́?”

Jòhánù sọ fún wọn pé: “Èmi kọ́ ni Kristi.”

Wọ́n tún bi í pé: “Ta wá ni ọ́? Ṣé ìwọ ni Èlíjà?”

Ó dáhùn pé: “Èmi kọ́.”

Ni wọ́n bá tún béèrè pé: “Ṣé ìwọ ni Wòlíì náà?” ìyẹn, Wòlíì ńlá tí Mósè sọ pé ó máa wá.—Diutarónómì 18:15, 18.

Jòhánù fèsì pé: “Rárá!”

Síbẹ̀, wọn ò fi í lọ́rùn sílẹ̀, wọ́n ní: “Ta ni ọ́? Sọ fún wa ká lè mọ ohun tí a máa sọ fún àwọn tó rán wa níṣẹ́. Kí lo sọ nípa ara rẹ?” Jòhánù sọ pé: “Èmi ni ohùn ẹni tó ń ké nínú aginjù pé, ‘Ẹ mú ọ̀nà Jèhófà tọ́,’ bí wòlíì Àìsáyà ṣe sọ.”—Jòhánù 1:19-23.

Wọ́n wá bi í pé: “Kí ló dé tí o fi ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn èèyàn tí kì í bá ṣe ìwọ ni Kristi tàbí Èlíjà tàbí Wòlíì náà?” Ó wá dá wọn lóhùn pé: “Omi ni mo fi ń batisí. Ẹnì kan wà láàárín yín tí ẹ kò mọ̀, ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi.”—Jòhánù 1:25-27.

Jòhánù gbà pé òun ń ṣètò ọ̀nà ní ti pé òun ń múra ọkàn àwọn èèyàn sílẹ̀ fún Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí, tó sì máa di Ọba. Jòhánù sọ nípa Mèsáyà náà pé: “Ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi lágbára jù mí lọ, ẹni tí mi ò tó bọ́ bàtà rẹ̀.” (Mátíù 3:11) Kódà, Jòhánù sọ pé: “Ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi ti lọ níwájú mi, torí ó ti wà ṣáájú mi.”—Jòhánù 1:15.

Torí náà, ó ṣe kedere pé bí Jòhánù ṣe ń kéde fáwọn èèyàn pé kí wọ́n “ronú pìwà dà, torí Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé” bọ́ sákòókò gan-an. (Mátíù 3:2) Ṣe ló ń jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé Jésù Kristi, Ọba tí Jèhófà yàn, máa tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀.

  • Irú èèyàn wo ni Jòhánù, kí ló sì ń ṣe?

  • Kí nìdí tí Jòhánù fi ń ri àwọn èèyàn bọmi?

  • Kí ni Jòhánù ń wàásù fáwọn èèyàn, kí sì nìdí tí ìkéde náà fi bọ́ sákòókò?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́