Ọsẹ Naa Ti Ó Yí Ayé Pada
“Olubukun ni ẹni ti ń bọ̀ ni orukọ Jehofa!”—MATIU 21:9, NW.
1. Awujọ meji yiyatọ gédégédé wo ni awọn iṣẹlẹ ti o ṣẹlẹ ni August ti o kọja nipa le lori?
“ỌJỌ MẸTA ONÍRORAGÓGÓ TÍ Ó MI AYÉ TÌTÌ.” Ní August 1991, àkọlé iwaju iwe irohin bi iru eyi tẹnumọ otitọ naa pe ayé ni a lè gbé sọ sinu idarudapọ ńlá laaarin awọn ọjọ diẹ. Nitootọ, awọn ọjọ ti o kẹhin oṣu August kun fun awọn iṣẹlẹ fifanilọkan mọra julọ kii ṣe kiki fun ayé ṣugbọn fun awujọ kan pẹlu ti Jesu sọ nipa rẹ̀ pe: “Wọn kii ṣe ti ayé.” Awujọ yii ni a mọ lonii si awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.—Johanu 17:14.
2, 3. (a) Bawo ni a ṣe tẹnumọ ominira ni Zagreb laika ewu ogun si? (b) Bawo ni a ṣe san ẹ̀san rere fun igbagbọ ni Odessa?
2 Apejọpọ agbaye akọkọ ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí a tíì wewee fun Yugoslavia rí ni a ti ṣeto fun August 16 si 18. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, yoo tun jẹ́ apejọpọ titobi akọkọ ti awọn eniyan Jehofa laaarin orilẹ-ede ti ń bẹ ní bèbè ogun abẹ́lé. Awọn Ẹlẹ́rìí adugbo, papọ pẹlu awọn oluyọnda ara-ẹni lati awọn ilẹ ti o sunmọ tosi, ti ṣiṣẹ kára fun oṣu meji ni fifun pápá iṣere bọọlu àfẹsẹ̀gbá ti HAŠK Građanski ni Zagreb ni atunṣe patapata kan. Ó mọ́ tónítóní, ọgangan ti ó yẹ fun Apejọpọ “Awọn Olùfẹ́ Ominira ti Ọlọrun.” Ẹgbẹẹgbẹrun awọn ayanṣaṣoju jakejado orilẹ-ede, ti o ni 600 lati United States ninu wewee lati wà nibẹ. Bi ewu ogun abẹ́lé ti rọ̀dẹ̀dẹ̀, ọrọ naa lọ yika pe: “Awọn ará America kò ni wá rara.” Ṣugbọn wọn wá, papọ pẹlu awọn ayanṣaṣoju lati ọpọlọpọ awọn ilẹ miiran. Awọn 10,000 eniyan ti yoo wá ni a ti fojusọna fun, ṣugbọn 14,684 wà ninu pápá iṣere naa ni ọjọ ti o kẹhin! Gbogbo wọn ni a bukun fun jìngbìnnì nitori pe wọn kò ‘kọ ipejọpọ araawọn silẹ.’—Heberu 10:25.
3 Laaarin ọjọ mẹta ti o tẹle apejọpọ ni Zagreb, ifipa gbajọba kan ti kò kẹ́sẹjárí ni a ṣe ni Soviet Union. Ni akoko naa, awọn olùfẹ́ ominira ti Ọlọrun ń ṣe imurasilẹ ikẹhin fun apejọpọ wọn ni Odessa ni Ukraine. A ha lè ṣe apejọpọ naa bi? Pẹlu igbagbọ lilagbara awọn ará ṣe atunṣe ti o kẹhin lati pari títún pápá iṣere naa ṣe patapata, awọn ayanṣaṣoju sì ń baa lọ lati maa dé. Gẹgẹ bi ẹni pe o jẹ́ iṣẹ iyanu, ifipa gbajọba naa pari. Apejọpọ ti o gbadun mọni kan ni a ṣe ni August 24, 25, pẹlu 12,115 awọn eniyan ti wọn wá tí 1,943—ti o jẹ́ ipin 16 ninu ọgọrun-un gongo awọn eniyan ti wọn wa—sì jẹ́ awọn ti a bamtisi! Awọn Ẹlẹ́rìí titun wọnyi, papọ pẹlu awọn olupawatitọ mọ alakooko pipẹ, yọ̀ pe wọn ti wá si apejọpọ yẹn pẹlu igbọkanle kikun ninu Jehofa.—Owe 3:5, 6.
4. Apẹẹrẹ ti Jesu fi lélẹ̀ wo ni Awọn Ẹlẹ́rìí ni Ila-oorun Europe ti ń tẹle?
4 Awọn Ẹlẹ́rìí oluṣotitọ wọnyi ń tẹle apẹẹrẹ tí Awofiṣapẹẹrẹ wa, Jesu Kristi fi lélẹ̀. Oun kò ṣainaani lilọ si awọn ayẹyẹ tí Jehofa palaṣẹ, ani nigba ti awọn Juu ń wá ọna lati pa á paapaa. Bi o ti wa si Jerusalẹmu, fun Ajọ-Irekọja rẹ̀ ti o kẹhin, awọn wọnyi ń duro kaakiri ninu tẹmpili, ni bibeere pe: “Ẹyin ti rò ó si? Pe ki yoo wá si ajọ?” (Johanu 11:56) Ṣugbọn ó wá! Eyi mura ọna silẹ fun ọsẹ ti a dé òtéńté rẹ̀ ninu iyipada ti ó dé bá itolẹsẹẹsẹ idagbasoke ninu ìtàn eniyan. Kò a yẹ ki a ṣatunyẹwo diẹ ninu awọn iṣẹlẹ pataki ọsẹ yẹn nisinsinyi—Nisan 8 si 14 ni ori kalẹnda awọn Juu bi?
Nisan 8
5. Ki ni Jesu mọ̀ ninu irin-ajo rẹ̀ lọ si Bẹtani ni Nisan 8, 33 C.E.?
5 Ni ọjọ yii Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ dé sí Bẹtani. Nihin-in, Jesu yoo sun oorun ọjọ mẹfa ni ile ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n Lasaru, ẹni ti oun jí dide kuro ninu oku lẹnu aipẹ yii. Bẹtani sunmọ Jerusalẹmu. Níkọ̀kọ̀, Jesu ti sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tẹlẹ pe: “Ẹ wò ó! Awa ń lọ si Jerusalẹmu, a o sì fi Ọmọkunrin eniyan lé awọn olori alufaa ati awọn akọwe lọwọ, wọn yoo sì dá a lẹbi iku, wọn yoo sì fi í lé ọwọ awọn eniyan awọn orilẹ-ede lati fi ṣe yẹyẹ ati lati nà án ni pàṣán ati lati kàn án mọgi, ati ni ọjọ kẹta a o jí i dide.” (Matiu 20:18, 19, NW) Jesu mọ lẹkun-unrẹrẹ pe oun gbọdọ doju kọ awọn àdánwò onirora nisinsinyi. Bi o ti wu ki o ri, bi akoko idanwo titobi julọ yẹn ti ń sunmọ, ó lo gbogbo isapa lati fi tifẹtifẹ ṣiṣẹsin awọn arakunrin rẹ̀. Njẹ ki awa maa ni “ẹmi ironu ero-ori yii . . . ti o wà ninu Kristi Jesu pẹlu” nigba gbogbo.—Filipi 2:1-5; 1 Johanu 3:16, NW.
Nisan 9
6. Ni alẹ́ Nisan 9, ki ni Maria ṣe, kí sì ni ohun ti Jesu sọ fun Judasi?
6 Lẹhin ti oorun ti wọ̀, bi Nisan 9 ti bẹrẹ, Jesu gbadun ounjẹ kan ni ile Simoni adẹ́tẹ̀ tẹlẹri naa. Nihin-in ni Maria arabinrin Lasaru ti tú ororo olóòórùn didun olowo gọbọi si ori ati ẹsẹ Jesu ti o sì fi irẹlẹ nu ẹsẹ Rẹ̀ gbẹ pẹlu irun rẹ̀. Nigba ti Judasi lodi si i, Jesu sọ pe: “Ẹ jọwọ rẹ̀, o ṣe e silẹ de ọjọ sisinku mi.” Ni gbígbọ́ pe ọpọlọpọ awọn Juu ń lọ si Bẹtani ti wọn sì ń ní igbagbọ ninu Jesu, awọn olori alufaa di rìkíṣí lati pa oun ati Lasaru.—Johanu 12:1-7.
7. Ni owurọ Nisan 9, bawo ni a ṣe bọla fun orukọ Jehofa, ki sì ni Jesu sọtẹlẹ?
7 Ni kutukutu owurọ, Jesu gbera irin ajo lọ si Jerusalẹmu. Ogunlọgọ jade lọ lati pade rẹ̀, ni fífi imọ-ọpẹ sọ́tùn-ún-sósì ati ni pipariwo pe: “Gbanila, awa bẹ̀ ọ́ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀! Olubukun ni ẹni ti o wá ni orukọ Jehofa, ani ọba Isirẹli!” Jesu mu asọtẹlẹ Sekaraya 9:9 ṣẹ nigba naa nipa gigun kẹtẹkẹtẹ kan lọ sinu ilu naa. Bi o ti sunmọ Jerusalẹmu, o sunkun lé e lori, ni sisọtẹlẹ pe awọn ara Roomu yoo yí i ká pẹlu awọn igi ṣóńṣó ti wọn yoo sì pa á run patapata—asọtẹlẹ kan ti yoo ni imuṣẹ apafiyesi ni ọdun 37 lẹhin naa. (Eyi tun jẹ́ ami ibi ọjọ iwaju fun Kristẹndọmu, ti o ti di apẹhinda lọna kan naa bii ti Jerusalẹmu igbaani.) Oluṣakoso awọn Juu kò fẹ́ Jesu gẹgẹ bi ọba wọn. Pẹlu ibinu ni wọn ké jade pe: “Wò ó! Ayé ti wọ́ tọ̀ ọ́ lẹhin.”—Johanu 12:13, 19, NW.
Nisan 10
8. Ni Nisan 10, bawo ni Jesu ṣe fi ọ̀wọ̀ jijinlẹ han fun ile adura Jehofa, ki ni o sì tẹle e?
8 Jesu lẹẹkan sii bẹ tẹmpili wò. Fun igba keji, o lé awọn oniṣowo oniwọra ati awọn onipaṣipaarọ owo jade. Ẹmi òwò-ṣíṣe—“ifẹ owo”—kò gbọdọ gbapò ninu ile adura Jehofa! (1 Timoti 6:9, 10) Jesu ni yoo kú laipẹ. Ó sọrọ nipa gbigbin irugbin lati ṣakawe eyi. Irugbin ti a gbìn ní ipilẹṣẹ naa kú, ṣugbọn ó hù lati mú pòròpórò ti ń so ọkà yanturu jade. Bakan naa, iku Jesu yoo yọrisi ìyè ainipẹkun fun ọpọlọpọ eniyan ti wọn lo igbagbọ ninu rẹ̀. Bi idaamu ti báa ni rironu nipa iku rẹ̀ ti o sunmọ, Jesu gbadura pe orukọ Baba oun yoo tipa bẹẹ di eyi ti a yin logo. Ni idahun pada, ohùn Ọlọrun bú jade bi àrá lati ọrun fun gbogbo awọn ti o wà nibẹ lati gbọ pe: “Emi ti ṣe e logo ná, emi yoo sì tun ṣe e logo.”—Johanu 12:27, 28.
Nisan 11—Ọjọ Igbokegbodo Kan
9. (a) Ni ibẹrẹ ọjọ ni Nisan 11, bawo ni Jesu ṣe lo awọn àkàwé ni didẹbi fun awọn Juu apẹhinda? (b) Ni ìlà pẹlu owe Jesu, awọn wo ni wọn ti kùnà anfaani titobilọla?
9 Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẹẹkan sii fi Bẹtani silẹ fun ọjọ kan ti ó kún fun igbokegbodo. Jesu lo awọn apejuwe mẹta lati fi idi ti a fi dẹbi fun awọn eniyan Juu apẹhinda han. Ó ti fi igi ọ̀pọ̀tọ́ kan ti kò léso bú, ipo gbigbẹ rẹ̀ nisinsinyi duro fun orilẹ-ede Juu alainigbagbọ, ati alaimeso jade. Ni wíwọ inu tẹmpili, o ṣapejuwe bi awọn alaiyẹ olutọju ọgbà àjàrà ọ̀gá kan nikẹhin ṣe pa ani ọmọkunrin ati ajogun ọga naa—ti ń fi aworan aiduroṣinṣin awọn Juu nipa ohun afunniṣọ wọn lati ọdọ Jehofa hàn, eyi ti yoo dé otente rẹ̀ nipa pipa ti wọn yoo pa Jesu. Ó ṣapejuwe ayẹyẹ igbeyawo kan tí a ṣeto lati ọwọ ọba kan—Jehofa—ti awọn alejo rẹ̀ ti o késí (awọn Juu) fi imọtara-ẹni-nikan ṣe gááfárà lati maṣe wá sibẹ. Fun idi yii, ikesini naa lọ sọdọ awọn ará ita—awọn Keferi—ti diẹ ninu wọn dahun pada. Ṣugbọn ọkunrin kan ti a rí ti kò ni ẹwu igbeyawo ni a gbesọ sita. Ó duro fun awọn ayédèrú Kristẹni ti Kristẹndọmu. Ọpọlọpọ awọn Juu ni ọjọ Jesu ni a késí “ṣugbọn diẹ ni a yàn” lati wà lara 144,000 awọn ẹni ti a fi èdídí dí ti wọn jogun Ijọba ti ọrun.—Matiu 22:14; Iṣipaya 7:4.
10-12. (a) Eeṣe ti Jesu fi fi ọrọ na awọn awujọ alufaa Juu ni patiyẹ, ẹnu àtẹ́ ìbáwí riroro wo ni o sì bù lu awọn alagabagebe wọnni? (b) Bawo ni a ṣe mu idajọ ṣẹ lẹhin-ọ-rẹhin lori awọn eniyan Juu alagabagebe?
10 Awujọ alufaa Juu alagabagebe wá akoko kan lati mú Jesu, ṣugbọn ó dahun diẹ ninu awọn ibeere ẹ̀tàn wọn ó sì dà wọn láàmú niwaju awọn eniyan. Óò, nǹkan mà ni awọn Juu onisin aláìṣòótọ́ wọnni o! Ẹ wo bi Jesu ti fi ọrọ nà wọn ni patiyẹ laifọrọsabẹ ahọ́n sọ tó! Wọn nífẹ̀ẹ́ sí ipo ọla, ẹwu gbàgẹ̀rẹ̀ ti ń finihan, ati orukọ oyè ńláńlá, iru bii “Rábì” ati “Baba,” ni ìbámu pẹlu ọpọlọpọ awujọ alufaa ni ọjọ wa. Jesu sọ ilana naa: “Ẹnikẹni ti o ba sì gbé araarẹ ga, ni a o rẹ̀ silẹ; ẹnikẹni ti o bá sì rẹ araarẹ silẹ ni a o gbé ga.”—Matiu 23:12.
11 Jesu bu ẹnu àtẹ́ lu awọn aṣaaju onisin wọnyẹn lọna rírorò. Ni igba meje ni o ké jade pe: “Ègbé ni fun yin,” ni pípè wọn ni afọju amọna ati agabagebe. Ati nigba kọọkan ó funni ni idi fun idalẹbi naa. Wọn ń dí ọna ti o lọ si Ijọba awọn ọrun. Nigba ti wọn bá dẹ ìkẹ́kùn mú alawọṣe kan, oun a di ẹni ti a fi sabẹ idajọ Gẹhẹna ni ipele meji, ó ṣeeṣe ki o ti wà ni ìlà fun iparun nitori ẹṣẹ wiwuwo tabi ìgbawèrèmẹ́sìn ti iṣaaju. “Ẹyin alaimoye ati afọju,” ni Jesu polongo, nitori awọn Farisi kó afiyesi jọ sori wura inu tẹmpili dipo pipa ijọsin mimọgaara nibẹ mọ́. Wọn ṣá idajọ ododo, aanu, ati iṣotitọ tì bi wọn ti ń san idamẹwaa ewéko míńtì, ewéko dílì, ati ewéko kúmínì wiwọniloju naa, ṣugbọn wọn ṣainaani awọn ọran Ofin ti o wuwo. Iwẹnumọ ti isin kò lè mu ẹgbin inu wọn lọhun-un kuro—kiki ọkan-aya ti a wẹ̀mọ́ nipasẹ igbagbọ ninu ẹbọ Jesu ti ń sunmọ nikan ni o lè ṣaṣepari iyẹn. Agabagebe inu lọhun-un ati ailofin wọn kò dá ẹhin ode “iboji funfun” eyikeyii láre.—Matiu 23:13-29.
12 Bẹẹni, ègbè nitootọ ni fun awọn Farisi, “awọn ọmọ awọn ẹni ti o pa awọn wolii” igba laelae nitootọ! Ejo, ọmọ paramọlẹ ni wọn, ti a ti kadara fun Gẹhẹna, nitori wọn yoo pa kii ṣe kiki Jesu nikan ṣugbọn awọn wọnni ti ó rán jade pẹlu. Eyi ni idajọ ti a o muṣẹ “sori iran yii.” Ni imuṣẹ, Jerusalẹmu ni a parun patapata ni ọdun 37 lẹhin naa.—Matiu 23:30-36.
13. Awọn ọrọ Jesu lori awọn ọrẹ inu tẹmpili ni a gbeyọ ninu awọn ipo wo lonii?
13 Ki o tó fi tẹmpili silẹ, Jesu sọrọ oríyìn nipa opó alaini kan ti o sọ owo-ẹyọ wẹ́wẹ́ meji—“gbogbo ohun ti o ní” sinu apoti iṣura. Iyatọ patapata nitootọ si awọn ọlọ́rọ̀ oniwọra, ti wọn ń sọ iwọnba ọrẹ gbà-má-pòóó-rọ́wọ́ọ̀-mi sinu rẹ̀! Bii ti opó alaini yẹn, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lonii ń fi tinutinu fi akoko, okun, ati owó níná rubọ ki wọn bàa lè ṣetilẹhin ki wọn sì mu iṣẹ Ijọba kari ayé gbooro sii. Ẹ wo bi wọn ti yatọ tó si awọn ajihinrere ori tẹlifiṣọn oniwa palapala wọnni ti wọn ń rẹ́run awọn agutan wọn ti wọn sì ń kọ́ ilẹ-ọba ti ọrọ̀ àdáni!—Luuku 20:45–21:4.
Bi Nisan 11 Ti Ń Lọ Sopin
14. Ibanujẹ wo ni Jesu fihan, bawo sì ni ó ṣe dahun iwadii siwaju sii tí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ṣe?
14 Jesu sọkún lé Jerusalẹmu ati awọn eniyan rẹ̀ lori ó sì polongo pe: “Ẹyin ki yoo rí mi mọ́ lọnakọna lati isinsinyi lọ titi ẹyin yoo fi wi pe, ‘Olubukun ni ẹni naa ti ń bọ ni orukọ Jehofa!’” (Matiu 23:37-39, NW) Lẹhin naa, nigba ti wọn jokoo lori Oke Olifi, awọn ọmọ-ẹhin timọtimọ Jesu beere nipa eyi, ati ni idahun Jesu sapejuwe ami ti yoo sami si wiwanihin-in rẹ̀ ninu agbara Ijọba ati opin eto igbekalẹ awọn nǹkan buburu ti Satani.—Matiu 24:1–25:46; Maaku 13:1-37; Luuku 21:5-36.
15. Ami wo ni Jesu fi funni nipa wiwanihin-in rẹ̀ fun idajọ, lati ìgbà wo sì ni a ti ń mu un ṣẹ?
15 Ni titọka si idajọ Jehofa ti a o muṣẹ laipẹ sori tẹmpili naa, Jesu fihan pe eyi duro fun awọn iṣẹlẹ ajalu ibi ọjọ-ọla ni ipari gbogbo eto igbekalẹ awọn nǹkan. Akoko yẹn ti wiwanihin-in rẹ̀ ni a o sami si nipa ibẹsilẹ ogun ni iwọn ti kò ni afiwe, ati bakan naa nipa ìyàn, ìsẹ̀lẹ̀, ati ajakalẹ arun, papọ pẹlu iwa ainifẹẹ ati iwa ailofin. Ẹ wo bi eyi ti jẹ́ ootọ tó nipa ayé ọrundun lọna ogun wa lati 1914!
16, 17. Awọn idagbasoke wo ninu ayé ni Jesu ṣapejuwe, bawo sì ni awọn Kristẹni ṣe nilati huwa pada si asọtẹlẹ naa?
16 Otente ni a o dé ninu “ipọnju ńlá . . . iru eyi ti kò sí lati igba ibẹrẹ ọjọ ìwà di isinsinyi, bẹẹkọ, iru rẹ̀ ki yoo sì sí.” Niwọn bi eyi yoo ti jẹ́ eyi ti ń ṣeparun bii ti Ikun-omi ọjọ Noa, Jesu kilọ lodi si fifi ara ẹni fun awọn ilepa ayé. “Nitori naa ẹ maa ṣọna; nitori ẹyin kò mọ wakati ti Oluwa yin yoo dé.” Ẹ wo bi a ṣe lè layọ tó pe Ọga naa ti yan “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” ẹni ami ororo sipo lati kéde ikilọ jade ati lati pese ounjẹ tẹmi yanturu fun ọjọ wiwanihin-in rẹ̀ yii!—Matiu 24:21, 42, 45-47, NW.
17 Ni ọrundun 20 wa, a ti ri “lori ilẹ ayé idaamu fun awọn orilẹ-ede . . . àyà awọn eniyan yoo ma já fun ibẹru, ati fun ireti nǹkan wọnni ti ń bọ̀ sori ayé.” Ṣugbọn Jesu sọ fun wa pe: “Nigba ti nǹkan wọnyi bá bẹrẹ sii ṣẹ, njẹ ki ẹ wo oke, ki ẹ sì gbe ori yin soke; nitori idande yin kù si dẹ̀dẹ̀.” Ó sì kilọ fun wa pe: “Ẹ maa kiyesara yin, ki ọkan yin ki o maṣe kun fun wọbia, ati fun ọti amupara, ati fun aniyan ayé yii, ti ọjọ naa yoo sì fi dé bá yin lojiji bi ikẹkun.” Kiki nipa wíwà lójúfò ni a lè duro ni ẹni itẹwọgba niwaju Jesu, “Ọmọ-eniyan,” ni igba wiwanihin-in rẹ̀.—Luuku 21:25-28, 34-36.
18. Iṣiri wo ni a lè rí fayọ lati inu àkàwé Jesu nipa awọn wundia mẹwaa ati awọn talẹnti?
18 Ni pipari ifitonileti akọkọ rẹ̀ gẹgẹ bi alaṣẹ nipa awọn iṣẹlẹ ode oni, Jesu funni ni awọn àkàwé mẹta. Akọkọ, ninu owe awọn wundia mẹwaa, o tun tẹnumọ aini naa lati “maa ṣọna.” Lẹhin naa, ninu àkàwé ti awọn ẹrú ati talẹnti, ó fi bi a ṣe san ẹ̀san rere fun jíjẹ́ alaapọn han nipa ikesini naa lati ‘wọle sinu ayọ Oluwa naa.’ Awọn Kristẹni ẹni ami ororo, tí awọn owe wọnyi jẹ́ apẹẹrẹ iṣaaju fun, ati bakan naa awọn agutan miiran lè rí iṣiri pupọ gbà lati inu awọn ọrọ apejuwe wọnyi.—Matiu 25:1-30.
19, 20. Ibatan gbigbadunmọni ti ode oni wo ni a gbéyọ ninu àkàwé Jesu nipa awọn agutan ati ewurẹ?
19 Àkàwé kẹta tọka si wiwanihin-in Jesu ninu agbara Ijọba lẹhin ti o ti dé lati jokoo lori ìtẹ́ ogo rẹ̀ ti ọrun. Ó jẹ́ akoko kan fun dídá awọn orilẹ-ede lẹjọ ati fun yiya awọn eniyan ori ilẹ-aye sọtọ si awujọ meji, ọ̀kan jẹ́ ti awọn ẹni bi agutan ati ekeji, awọn eniyan alaigbọran bi ewurẹ. Awọn agutan sa ipá afikun lati fi araawọn han ni alatilẹhin awọn arakunrin Ọba naa—awọn aṣẹku ẹni ami ororo lori ilẹ-aye ni akoko opin ayé yii. Awọn agutan wọnyi ni a san ẹ̀san rere fun pẹlu ìyè, nigba ti o jẹ́ pe awọn ewurẹ alainimọriri lọ kuro sinu iparun ainipẹkun.—Matiu 25:31-46.
20 Iru ibatan agbayanu wo ni a ri laaarin awọn agutan miiran ati awọn arakunrin Ọba naa ni ipari eto igbekalẹ awọn nǹkan yii! Bi o tilẹ jẹ pe awọn aṣẹku ẹni ami ororo fàyà rán ẹrù iṣẹ naa ni ibẹrẹ wiwanihin-in Ọba naa, araadọta-ọkẹ onitara awọn agutan miiran nisinsinyi jẹ́ ipin 99.8 ninu ọgọrun-un ti awọn iranṣẹ Ọlọrun lori ilẹ-aye. (Johanu 10:16) Awọn pẹlu sì ti fi araawọn han ni ẹni ti o muratan lati farada ‘ebi, oungbẹ, ìhòhò, aisan, ati ẹwọn’ gẹgẹ bi alabaakẹgbẹ awọn ẹni ami ororo ti ń pa iwatitọ mọ́.a
Nisan 12
21. Ki ni o ń tẹsiwaju ni Nisan 12, bawo sì ni?
21 Rikiṣi lati pa Jesu ti ń tẹsiwaju. Judasi bẹ awọn olori alufaa wo ninu tẹmpili, ni gbígbà lati fi Jesu han fun 30 ẹyọ owo fadaka. Ani eyi ni a ti sọtẹlẹ paapaa.—Sekaraya 11:12.
Nisan 13
22. Imurasilẹ wo ni a ṣe ni Nisan 13?
22 Jesu, ẹni ti o ti wà ni Bẹtani, boya fun adura ati ironujinlẹ, rán awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si Jerusalẹmu lati wá “ọkunrin kan bayii” lọ. Ninu ile ọkunrin yii, ninu yara oke ńlá kan, wọn ṣeto Ajọ-Irekọja silẹ. (Matiu 26:17-19) Gẹgẹ bi oòrùn ti ń wọ̀ ni Nisan 13, Jesu darapọ mọ wọn nibẹ fun ayẹyẹ ti o kun fun iṣẹlẹ fifanimọra julọ ninu gbogbo ìtàn. Ki ni o duro sẹpẹ́ nisinsinyi ní Nisan 14? Ọrọ-ẹkọ wa ti o tẹle e yoo sọ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọrọ ẹkọ ti o tẹle e gbọdọ ràn wa lọwọ lati mọriri ibatan timọtimọ ti o wà laaarin agbo kekere ẹni ami ororo ati awọn agutan miiran siwaju sii.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Ṣe Àkópọ̀?
◻ Aájò alejo ati ikini kaabọ wo ni awọn kan fifun Jesu laaarin Nisan 8 titi de 10?
◻ Bawo ni Jesu ṣe tudii aṣiiri awujọ alufaa alagabagebe ni Nisan 11?
◻ Asọtẹlẹ ńlá wo ni Jesu fifunni, bawo ni a sì ṣe ń mú un ṣẹ lonii?
◻ Bawo ni awọn iṣẹlẹ ṣe sún lọ siha otente kan ni Nisan 12 ati 13?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Jesu gboriyin fun opó alaini ti o fi awọn owo-ẹyọ wẹwẹ meji—gbogbo ohun ti o ni tọrẹ