ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 3/15 ojú ìwé 28-31
  • Justin—Ọlọgbọn Imọ-Ọran, Agbeja Igbagbọ, ati Ajẹriiku

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Justin—Ọlọgbọn Imọ-Ọran, Agbeja Igbagbọ, ati Ajẹriiku
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibẹrẹ Igbesi-Aye ati Idalẹkọọ
  • Wíwo Awọn Iwe Rẹ̀ Kínníkínní
  • Iku Rẹ̀
  • Ẹ̀kọ́ Èké Kan Ló Ń Fa Òmíràn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Apa 3—Awọn Agbeja Igbagbọ Ha fi Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan Kọni bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àwọn Agbèjà Ìgbàgbọ́—Ṣé Ajàfẹ́sìn Kristẹni Ni Wọ́n Ni àbí Onímọ̀ Ọgbọ́n Orí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Mo Bá Ní Àìsàn tí Mò Ń Bá Fínra? (Apá 3)
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 3/15 ojú ìwé 28-31

Justin—Ọlọgbọn Imọ-Ọran, Agbeja Igbagbọ, ati Ajẹriiku

“A BEERE pe ki awọn ẹ̀sùn ti a fi kan awọn Kristẹni di eyi ti a wádìíwò, ati pe, bi iwọnyi bá jẹ́ otitọ, ki a fiya jẹ wọn gẹgẹ bi o ti tọ́ si wọn, . . . Ṣugbọn bi ẹnikẹni kò bá lè fẹ̀bi ohun kan kàn wá, idajọ rere kà á léèwọ̀ fun ọ, lati ṣe ipalara fun awọn ọkunrin alailẹbi, nititori àgbọ́sọ buburu kan . . . Nitori bi iwọ kò bá ṣe ohun ti o bá idajọ ododo mu, nigba ti iwọ ti mọ otitọ, iwọ yoo wà niwaju Ọlọrun laini àwíjàre.”

Pẹlu awọn ọrọ wọnyi, Justin Martyr, ẹni ti o jẹwọ pe oun jẹ́ Kristẹni kan ni ọrundun keji C.E., fọranlọ olu-ọba Roomu Antoninus Pius. Justin beere fun iṣayẹwo onidaajọ kan ti a fi otitọ-ọkan ṣe sinu igbesi-aye ati igbagbọ awọn Kristẹni. Ibeere fun idajọ ododo yii wá lati ọdọ ọkunrin ti o ni ipilẹ igbesi-aye didara kan ati ọgbọn imọ-ọran.

Ibẹrẹ Igbesi-Aye ati Idalẹkọọ

Justin jẹ́ Keferi kan, ti a bi ni nǹkan bii 110 C.E. ni Samaria ni ilu Flavia Neapolis, Nablus ode-oni. Ó pe araarẹ̀ ni ará Samaria, bi o tilẹ jẹ pe ó ṣeeṣe ki baba ati babanla rẹ̀ jẹ́ ara Roomu tabi Giriiki. Títọ́ ti a tọ́ ọ dagba ninu aṣa oloriṣa, papọ pẹlu oungbẹ fun otitọ, ṣamọna si ikẹkọọ alaapọn ti imọ-ọran. Bi kò ti nitẹẹlọrun ninu iwakiri rẹ̀ laaarin awọn Stoic (Aláìmadùn), Peripatetic (awọn ọmọlẹhin Aristotle), ati awọn Atẹ̀lé Ẹkọ Pythagoras, ó lepa awọn ero Plato.

Ninu ọ̀kan lara awọn iwe rẹ̀, Justin sọrọ nipa ifẹ ọkàn rẹ̀ lati bá awọn ọlọgbọn imọ-ọran sọrọ ó sì wi pe: “Mo fi araami lélẹ̀ fun Stoic kan bayii; lẹhin ti mo sì ti lo akoko pupọ pẹlu rẹ̀, nigba ti emi kò ì tíì gba ìmọ̀ eyikeyii nipa Ọlọrun siwaju sii (nitori oun funraarẹ kò mọn ọn), . . . Mo fi í silẹ mo sì mú araami lọ sọdọ ẹlomiran.”—Dialogue of Justin, Philosopher and Martyr, With Trypho, a Jew.

Lẹhin naa Justin lọ sọdọ Peripatetic kan ẹni ti o nifẹẹ si owó ju otitọ lọ. “Ọkunrin yii, lẹhin ti o ti gbà mi fun iwọnba ọjọ diẹ akọkọ,” ni Justin sọ, “sọ fun mi pe ki n san owo, ki ijumọṣe paṣipaarọ ironu wa má baà jẹ́ alailere. Oun, pẹlu ni mo patì, fun idi yii, emi kò gbà á gbọ pe ó jẹ́ onimọ-ọran kankan rara.”

Bi o ti ni iharagaga lati tẹ́tísí “onimọ-ọran ayanlaayo” naa, Justin “wá sọdọ Atẹ̀lé Ẹkọ Pythagoras kan, ẹni ti o lokiki gan-an—ọkunrin kan ti o ronu pupọ nipa ọgbọn araarẹ.” Justin sọ pe: “Nigba ti mo ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu rẹ̀, ti mo muratan lati di olùgbọ́ ati ọmọ-ẹhin rẹ̀, ó sọ pe, ‘Ki ni ó kàn? Iwọ ha mọ nipa orin kíkọ, imọ ijinlẹ sánmà, ati ẹkọ iṣiro geometry bi? Iwọ ha reti lati loye eyikeyii ninu awọn ohun wọnni [ti Ọlọrun] eyi ti o ṣamọna si igbesi-aye alayọ kan, bi a kò bá tii sọ [iwọnyi] fun ọ ṣaaju’? . . . Ó lé mi lọ nigba ti mo jẹwọ aimọkan mi fun un.”

Bi o tilẹ jẹ pe ó rẹwẹsi, Justin ń baa lọ lati maa wá otitọ kiri nipa yiyiju si Awọn Ẹlẹkọọ Plato ti wọn lokiki. Ó sọ pe: “Kete lẹhin iyẹn ni mo bẹrẹ sii lo ọpọ julọ ninu akoko mi bi mo ti lè ṣe tó pẹlu ẹnikan ti ó ṣẹṣẹ wá si ilu wa—ọkunrin ọlọgbọn kan, ti o di ipo giga mú laaarin awọn Ẹlẹkọọ Plato,—mo sì tẹsiwaju, mo sì tubọ ń ṣe daradara sii lojoojumọ . . . , debi pe laipẹ pupọ mo lero pe mo ti di ọlọgbọn; iru iyẹn sì ni iwa wèrè mi” ni Justin pari ero sí.

Wíwá otitọ kiri Justin nipa lilọ sọdọ awọn onimọ-ọran ti já sí asán. Ṣugbọn nigba ti o ń ronu ni etikun, ó pade Kristẹni agbalagba kan, “ọkunrin arugbo kan bayii, ti kii ṣe alainilaari ni irisi, ti ń fi iwa pẹlẹ ati ọ̀wọ̀ han.” Ijumọsọrọpọ ti o tẹle e dari afiyesi rẹ̀ si awọn ẹkọ ipilẹ Bibeli ti o kó afiyesi jọ sori aini naa fun imọ pipeye ti Ọlọrun.—Roomu 10:2, 3.

Kristẹni ti a kò darukọ rẹ̀ naa sọ fun Justin pe: “Awọn ọkunrin kan wà, tipẹtipẹ ṣaaju akoko yii, ti wọn pẹ́ sẹhin ju awọn wọnni ti wọn jẹ́ awọn ọlọgbọn imọ-ọran ti a kàsí, wọn jẹ́ olododo ati ayanfẹ fun Ọlọrun, ẹni ti o . . . sọ awọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti yoo ṣẹlẹ̀ ṣaaju, ti wọn sì ń ṣẹlẹ̀ nisinsinyi. A pè wọn ni wolii. Awọn wọnyi nikan ni wọn rí ti wọn sì kede otitọ fun awọn eniyan, . . . bi a ti fi Ẹmi Mímọ́ kún wọn.” Ni mímú ifẹ Justin múná siwaju sii, Kristẹni naa sọ pe: “Awọn iwe wọn ṣì wà, ẹni ti o bá sì kà wọn ni a ń ràn lọwọ gidigidi ninu ìmọ̀ rẹ̀ nipa ibẹrẹ ati opin awọn nǹkan.” (Matiu 5:6; Iṣe 3:18) Gẹgẹ bi oniwarere ẹlẹmii ọ̀rẹ́ naa ti rọ̀ ọ́, Justin fi taapọntaapọn ṣayẹwo Iwe Mímọ́ ó sì jọ bi ẹni pe o ti jere iwọn imọriri fun wọn ati fun asọtẹlẹ Bibeli, gẹgẹ bi a ti rí i ninu awọn iwe rẹ̀.

Wíwo Awọn Iwe Rẹ̀ Kínníkínní

Justin ni a wú lori pẹlu aibẹru awọn Kristẹni ni oju iku. Ó tun mọriri awọn ẹkọ tootọ ti Iwe Mímọ́ lede Heberu. Lati ti awọn koko ọrọ rẹ̀ ninu Dialogue With Trypho lẹhin, Justin ṣayọlo lati inu Jẹnẹsisi, Ẹkisodu, Lefitiku, Deutaronomi, 2 Samuẹli, 1 Ọba, Saamu, Aisaya, Jeremaya, Esekiẹli, Daniẹli, Hosea, Joẹli, Amosi, Jona, Mika, Sekaraya, ati Malaki, ati awọn Ihinrere bakan naa. Imọriri rẹ̀ fun awọn iwe Bibeli wọnyi ni a rí ninu paṣipaarọ ero ti o ṣe pẹlu Trypho, ninu eyi ti Justin sọrọ lori isin awọn Juu ti o gbagbọ ninu Mesaya.

A rohin rẹ̀ pe Justin jẹ́ ajihinrere kan, ti ń polongo ihinrere ni gbogbo akoko. O ṣeeṣe, ki o rìnrìn-ajo jìnnà. Diẹ lara akoko rẹ̀ ni ó lò ni Efesu, ó sì jọ bii pe ó gbé ni Roomu fun sáà akoko gigun kan.

Iṣẹ iwe kíkọ Justin ní awọn ọrọ ìgbèjà ti ó kọ fun ìgbèjà isin Kristẹni ninu. Ninu iwe rẹ̀ First Apology, ó wá ọna lati lé òkùnkùn dudu ti imọ-ọran oloriṣa lọ nipasẹ imọlẹ lati inu Iwe Mímọ́. Ó kede pe ọgbọn awọn onimọ-ọran jẹ́ èké kò sì nitumọ ni ifiwera pẹlu awọn ọrọ alagbara ti Kristi. (Fiwe Kolose 2:8.) Justin bẹbẹ fun awọn Kristẹni ti a ṣainaani naa awọn ti oun ka araarẹ mọ́. Lẹhin iyilọkan pada rẹ̀, ó ń baa lọ lati wọ ẹwu onimọ-ọran, ni wiwi pe oun ti dé ori ọgbọn imọ-ọran tootọ kanṣoṣo.

Nitori tí wọn kọ̀ lati jọsin awọn ọlọrun oloriṣa, awọn Kristẹni ọrundun keji ni a kàsí alaigbọlọrungbọ. “Awa kii ṣe alaigbọlọrungbọ,” ni Justin sọ ni ìgbèjà pada, “ni jijọsin Ẹlẹdaa agbaye gẹgẹ bi a ti ń ṣe . . . Ẹni ti o kọ wa ní awọn nǹkan wọnyi ni Jesu Kristi . . . Oun ni Ọmọkunrin Ọlọrun tootọ naa.” Niti ibọriṣa, Justin sọ pe: “Wọn ṣe oun ti wọn pe ni ọlọrun kan; eyi ti awa kà si kii ṣe alaibọgbọnmu nikan, ṣugbọn ó tun jẹ́ ìwọ̀sí sí Ọlọrun . . . Iru iwa omugọ wo ni iyẹn! pe ki a sọ pe awọn eniyan ẹlẹṣẹ nilati ṣe ẹ̀dà ki wọn sì ṣe ọlọrun fun ijọsin yin.”—Aisaya 44:14-20.

Pẹlu ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ awọn itọka si Iwe Mímọ́ Kristẹni lede Giriiki, Justin sọrọ nipa igbagbọ rẹ̀ ninu ajinde, iwarere Kristẹni, bamtisimu, asọtẹlẹ Bibeli (ni pataki nipa Kristi), ati awọn ẹkọ Jesu. Niti Jesu, Justin ṣayọlo Aisaya, ni wiwi pe: “Ijọba naa yoo wà lori ejika [Kristi].” Justin fikun un pe: “Bi a ba ń wá ijọba eniyan kan kaakiri, a nilati sẹ́ Kristi wa pẹlu.” Ó jiroro awọn adanwo ati iṣẹ aigbọdọmaṣe awọn Kristẹni, pípa iṣẹ-isin titọna yẹn mọ si Ọlọrun beere fun jijẹ oluṣe ifẹ-inu Rẹ̀, ó sì sọ siwaju sii pe “awọn eniyan ni Oun nilati rán sinu gbogbo orilẹ-ede lati kede awọn nǹkan wọnyi.”

Iwe The Second Apology of Justin (ti a gbagbọ pe o wulẹ jẹ́ biba a lọ pẹlu ti akọkọ) ni a kọ sí mẹmba Ajọ Igbimọ Giga Julọ Roomu. Justin rọ awọn ara Roomu nipa sisọ iriri awọn Kristẹni, ti a ṣe inunibini sí lẹhin wíwá sinu ìmọ̀ pipeye nipa Jesu Kristi. Itayọlọla iwarere awọn ẹkọ Jesu, ti a fihan ninu iwa awọn Kristẹni ara ilu, dabi alaijamọ nǹkankan fun awọn alaṣẹ Roomu. Kaka bẹẹ, wiwulẹ jẹwọ jíjẹ́ ọmọ-ẹhin lè ni abajade aṣekupani. Nipa olukọni ni awọn ẹkọ Kristẹni tẹlẹri kan, Justin fa ọrọ ẹnikan ti a pe ni Lucius yọ, ẹni ti o beere pe: “Eeṣe ti o fi fiya jẹ ọkunrin yii, kii ṣe gẹgẹ bi panṣaga, tabi alágbèrè, tabi apaniyan, tabi ole, tabi ọlọṣa, tabi nitori ẹbi ẹsẹ iwa ipa eyikeyii rara, ṣugbọn nitori ti o wulẹ jẹwọ pe a pe oun pẹlu orukọ Kristẹni?”

Iwọn ẹtanu lodisi awọn ti wọn sọ pe awọn jẹ́ Kristẹni ní akoko yẹn ni a fihan nipa gbolohun ọrọ Justin pe: “Nitori naa, emi pẹlu, reti lati di ẹni ti a di rikiṣi mọ ti a sì so mọ òpó-igi, lati ọwọ awọn wọnni ti mo ti darukọ, tabi boya lati ọwọ Crescens, olufẹ oríyìn ati ìfọ́nnu yẹn, nitori ọkunrin naa ti o jẹrii ni gbangba lodisi wa ninu awọn ọran ti oun kò loye daradara kò yẹ fun orukọ onimọ-ọran, ni wiwi pe awọn Kristẹni jẹ́ alaigbọlọrungbọ ati alailẹmii-isin, ti o sì ń ṣe bẹẹ lati jere ojurere awujọ awọn eniyankeniyan ti a tanjẹ, ati lati wù wọn. Nitori bi ó bá kọ lù wá laijẹ pe ó ti ka awọn ẹkọ Kristi, ó ti dibajẹ patapata gbáà, ó sì buru ju aláìmọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà lọ, ti wọn sábà maa ń sá sẹhin ninu jijiroro tabi jijẹrii èké nipa awọn ọran ti wọn kò loye.”

Iku Rẹ̀

Boya lati ọwọ Crescens tabi awọn Cynic miiran, Justin ni wọn rojọ́ rẹ̀ fun alaṣẹ Roomu gẹgẹ bi asojú nǹkan dé a sì dẹbi iku fun un. Ni nǹkan bii 165 C.E., a bẹ́ ẹ lori ni Roomu ó si di “ajẹriiku” (ti o tumọsi “ẹlẹrii”). Fun idi yii, a pè é ni Justin Martyr.

Ọna ikọwe Justin lè ṣalaini ẹwà ati ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́ ti awọn ọkunrin ọmọwe miiran ni ọjọ rẹ̀, ṣugbọn itara rẹ̀ fun otitọ ati ododo jẹ́ ojulowo lọna ti o han gbangba. Dé iwọn ti o gbé ni ibamu pẹlu Iwe-Mimọ ati awọn ẹkọ Jesu ni a kò lè sọ pẹlu idaniloju. Sibẹ, awọn iwe Justin ni a kàsí fun nini ọ̀rọ̀ ìtàn ati ọpọlọpọ itọka ti o bá Iwe-Mímọ́ mu ninu. Wọn pese ijinlẹ oye sinu igbesi-aye ati iriri awọn ti wọn jẹwọ jíjẹ́ Kristẹni ni ọrundun keji.

Eyi ti o yẹ fun afiyesi ni awọn isapa Justin lati fi aiṣedajọ ododo ati inunibini ti a dari lodi si awọn Kristẹni han awọn olu-ọba. Kíkọ̀ ti o kọ isin abọriṣa ati ọgbọn imọ-ọran fun ìmọ̀ pipeye ti Ọrọ Ọlọrun rán wa leti pe ni Anteni apọsiteli Pọọlu sọrọ si awọn ọmọran Epicurean ati Stoic nipa Ọlọrun tootọ naa ati Jesu Kristi ti a ti ji dide.—Iṣe 17:18-34.

Justin funraarẹ ni ìmọ̀ diẹ nipa ajinde awọn oku ni akoko Ẹgbẹrun ọdun. Ireti ajinde tootọ ti Bibeli si ti jẹ́ afungbagbọ lokun tó! Ó ti mú awọn Kristẹni duro loju awọn inunibini o si ti mu ki o ṣeeṣe fun wọn lati farada adanwo titobi, ani titi dé iku paapaa.—Johanu 5:28, 29; 1 Kọrinti 15:16-19; Iṣipaya 2:10; 20:4, 12, 13; 21:2-4.

Wayi o, nigba naa, Justin wá otitọ kiri ó sì ṣá ọgbọn imọ-ọran Giriiki tì. Gẹgẹ bi agbèjà igbagbọ kan, ó gbèjà awọn ẹkọ ati àṣà awọn ti wọn pe araawọn ni Kristẹni. Ati fun jijẹwọ isin Kristẹni funraarẹ, ó niriiri iku ajẹriiku. Eyi ti o yẹ fun akiyesi ni pataki ni imọriri Justin fun otitọ ati ijẹrii onigboya ni oju inunibini, nitori awọn animọ wọnyi ni a rí ninu igbesi-aye awọn ojulowo ọmọlẹhin Jesu ode oni.—Owe 2:4-6; Johanu 10:1-4; Iṣe 4:29; 3 Johanu 4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́