ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 4/1 ojú ìwé 24-30
  • Apa 3—Awọn Agbeja Igbagbọ Ha fi Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan Kọni bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Apa 3—Awọn Agbeja Igbagbọ Ha fi Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan Kọni bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ọmọkunrin Jẹ́ Ọmọ-Abẹ́”
  • Ṣiṣagbeyọ Ẹ̀kọ́ Ọrundun Kìn-ín-ní
  • Ohun Ti Justin Martyr Fi Kọni
  • Ohun Ti Clement Fi Kọni
  • Ẹ̀kọ́-Ìsìn Tertullian
  • Kò Sí Mẹtalọkan
  • Awọn ìtọ́ka:
  • Apa Keji—Awọn Onkọwe Lẹhin Akoko Awọn Apọsiteli Ha Fi Ẹkọ Mẹtalọkan Kọni Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ẹ̀kọ́ Bibeli Ní Kedere Ha Ni Bí?
    Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?
  • Apa Kì-ín-ní—Jesu ati Awọn Ọmọ-ẹhin Rẹ̀ Ha Fi Ẹkọ Mẹtalọkan Kọni Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Apa 4—Nigba Wo Ati Bawo ni Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan Ṣe Gbèrú?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 4/1 ojú ìwé 24-30

Ṣọọṣi Ijimiji Ba Kọni Pe Olọrun Jẹ́ Mẹtalọkan Bi?

Apa 3—Awọn Agbeja Igbagbọ Ha fi Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan Kọni bi?

Ninu awọn itẹjade rẹ̀ ti November 1, 1991, ati February 1, 1992, Ilé-Ìṣọ́nà fihan pe ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan ni a kò fi kọni nipasẹ Jesu tabi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tabi Awọn Onkọwe Lẹhin Akoko Awọn Apọsiteli ti opin ọrundun kìn-ín-ní ati ibẹrẹ ọrundun keji C.E. Awọn ọkunrin ṣọọṣi ni opin ọrundun keji ha fi kọni bi?

LATI ìgbà tí ó sunmọ aarin ọrundun keji     ti Sanmani Tiwa titi dé opin rẹ̀, awọn     ọkunrin ṣọọṣi ti a ń pe ni Awọn Agbeja Igbagbọ lonii farahan. Wọn kọwe lati gbeja isin Kristẹni ti wọn mọ̀ lodisi awọn imọ-ọran rírorò ti ó gbodekan ninu ayé Roomu ti akoko yẹn. Iwe wọn wá gan-an ni apa ipari, ati lẹhin, iwe tí Awọn Onkọwe Lẹhin Akoko Awọn Apọsiteli kọ.

Lara Awọn Agbeja Igbagbọ ti wọn kọwe ni èdè Giriiki ni Justin Martyr, Tatian, Athenagoras, Theophilus, ati Clement ará Alexandria. Tertullian jẹ́ Agbeja Igbagbọ kan tí ó kọwe ni èdè Latin. Wọn ha kọni ni Mẹtalọkan—awọn ẹni mẹta ti wọn jẹ́ ọgba (Baba, Ọmọkunrin, ati Ẹmi Mímọ́) ninu Ọlọrun Ẹlẹ́ni-mẹta ti Kristẹndọmu ode-oni, ti ọkọọkan jẹ́ Ọlọrun otitọ, sibẹ ti kò sí Awọn Ọlọrun mẹta bikoṣe Ọlọrun kan?

“Ọmọkunrin Jẹ́ Ọmọ-Abẹ́”

Dokita H. R. Boer, ninu iwe rẹ̀ A Short History of the Early Church, sọrọ lori kókó pataki ẹ̀kọ́ Awọn Agbeja Igbagbọ pe:

“Justin [Martyr] kọni pe ṣaaju dídá ayé Ọlọrun nikan ni ó wà ati pe kò sí Ọmọkunrin kankan. . . . Nigba ti Ọlọrun fẹ́ lati dá ayé, . . . ó di baba fun alààyè ẹni bi-Ọlọrun miiran lati dá ayé fun un. Alààyè ẹni bi-Ọlọrun yii ni a pè ni . . . Ọmọkunrin nitori pe a bí i; a pè é ni Logos nitori pe a mú un lati inu Ìrònú tabi Èrò-Ọkàn Ọlọrun. . . .

“Nitori naa Justin ati Awọn Agbeja Igbagbọ miiran kọni pe Ọmọkunrin jẹ́ ẹ̀dá kan. Oun jẹ́ ẹ̀dá onipo giga kan, ẹ̀dá kan ti ó lagbara tó lati dá ayé ṣugbọn, sibẹ, ẹ̀dá kan. Ninu ẹ̀kọ́ isin ipo ibatan Ọmọkunrin si Baba yii ni a pè ni subordinationism (ẹ̀kọ́ ipò aṣiwaju ti Baba lori awọn ẹni meji tí ó kù ninu Mẹtalọkan). Ọmọkunrin jẹ́ ọmọ-abẹ́, iyẹn ni pe, ó jẹ́ onipo keji si, ó sinmi lé, Baba ni ó sì jẹ́ orisun rẹ̀. Awọn Agbeja Igbagbọ jẹ́ onigbagbọ ninu wíwà ni ipo ọmọ-abẹ́.”1

Ninu iwe The Formation of Christian Dogma, Dokita Martin Werner sọ nipa òye ijimiji julọ nipa ipo ibatan Ọmọkunrin si Ọlọrun pe:

“Ipo ibatan yẹn ni a loye lọna tí kò nitumọ meji gẹgẹ bi ọ̀kan tí ó jẹ́ ti ‘wíwà ni ipo ọmọ-abẹ́,’ iyẹn ni pe ni ero wíwà ni ipo ọmọ-abẹ́ ti Kristi si Ọlọrun. Nibikibi ti a bá ti mu ipo ibatan Jesu si Ọlọrun, Baba, wá sinu igbeyẹwo ninu Majẹmu Titun, . . . a ní i lọkan a sì ń ṣapẹẹrẹ rẹ̀ ni kedere gẹgẹ bii wíwà ni ipo ọmọ-abẹ́. Onigbagbọ pàtó julọ ninu Wíwà Ni Ipo Ọmọ-Abẹ́ ti Majẹmu Titun, ni ibamu pẹlu akọsilẹ ti Ihinrere Mẹta, ni Jesu fúnraarẹ̀ . . . Ipo akọkọ yii, gẹgẹ bi o ti duro gbọnyingbọnyin ti ó sì farahan, ni o ṣeeṣe fun lati pa araarẹ̀ mọ́ fun akoko gigun. ‘Gbogbo awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ isin giga ṣaaju akoko igbimọ ti a ṣe ni Nicaea ṣojú fun wíwà ni ipo ọmọ-abẹ́ Logos naa si Ọlọrun.’”2

Ni iṣọkan pẹlu eyi, R. P. C. Hanson, ninu iwe The Search for the Christian Doctrine of God, sọ pe:

“Kò sí ẹlẹ́kọ̀ọ́ isin ninu Ṣọọṣi Ìlà-oorùn tabi Ìwọ̀-oorùn ṣaaju ibẹsilẹ Ariyanjiyan Arian [ni ọrundun kẹrin], ti kò ka Ọmọkunrin sí ní ọ̀nà kan gẹgẹ bi ọmọ-abẹ́ si Baba.”3

Dokita Alvan Lamson, ninu iwe The Church of the First Three Centuries, fi ẹ̀rí yii nipa ẹ̀kọ́ awọn alaṣẹ ṣọọṣi ṣaaju Igbimọ ti Nicaea (325 C.E.) kún un pe:

“Rírẹlẹ̀ ní ipo ti Ọmọkunrin ni Awọn Onkọwe Ṣaaju Igbimọ Nicaea tẹnumọ ni gbogbogboo, bí kìí bá ṣe lọna ti ó baramu . . . Pe wọn wo Ọmọkunrin gẹgẹ bi ẹni ti ó yatọ gédégédé si Baba ni ó han gbangba lati inu ipo naa pe wọn tẹnumọ rírẹlẹ̀ ipo rẹ̀ gbangba-gbàǹgbà. . . . Wọn kà á si ẹni ọ̀tọ̀ gédégédé ati ọmọ-abẹ́.”4

Bakan naa, ninu iwe naa Gods and the One God, Robert M. Grant sọ ohun tí ó tẹle e yii nipa awọn Agbeja Igbagbọ:

“Itumọ Ti Isin tí awọn agbeja igbagbọ fifun ẹni ti Jesu jẹ́, iru eyi ti ó wà ninu Majẹmu Titun, ni pataki jẹ́ ti onigbagbọ ninu wíwà ni ipo ọmọ-abẹ́. Ni gbogbo ìgbà ni Ọmọkunrin maa ń jẹ́ ọmọ-abẹ́ si Baba, ẹni tí í ṣe Ọlọrun Majẹmu Laelae. . . . Ohun ti a rí ninu awọn onṣewe ijimiji wọnyi, nigba naa, ki i ṣe ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan . . . Ṣaaju Nicaea, ẹ̀kọ́ isin Kristẹni ni ó fẹrẹẹ jẹ́ ti onigbagbọ ninu wíwà ni ipo ọmọ-abẹ́ jakejado agbaye.”5

Mẹtalọkan Kristẹndọmu kọni pe Ọmọkunrin baradọgba pẹlu Ọlọrun Baba ni ayeraye, agbara, ipo, ati ọgbọn. Ṣugbọn Awọn Agbeja Igbagbọ sọ pe Ọmọkunrin kò baradọgba pẹlu Ọlọrun Baba. Wọn wo Ọmọkunrin gẹgẹ bi ọmọ-abẹ́. Iyẹn kọ́ ni ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan.

Ṣiṣagbeyọ Ẹ̀kọ́ Ọrundun Kìn-ín-ní

Awọn Agbeja Igbagbọ ati Awọn Onkọwe Ṣọọṣi ijimiji miiran ṣagbeyọ dé iwọn giga ohun ti awọn Kristẹni ọrundun kìn-ín-ní fi kọni nipa ipo ibatan Baba ati Ọmọkunrin. Ṣakiyesi bi a ṣe sọ eyi jade ninu iwe naa The Formation of Christian Dogma:

“Ni sanmani Kristẹni Ibẹrẹpẹpẹ kò si àmì iṣoro tabi ariyanjiyan iru eyikeyii nipa Mẹtalọkan, iru eyi ti ó mú awọn iforigbari mimuna jade ninu Ṣọọṣi lẹhin naa. Idi fun eyi laiṣiyemeji sinmi lé otitọ naa pe, fun isin Kristẹni Ibẹrẹpẹpẹ, Kristi jẹ́ . . . ẹ̀dá alààyè ti ayé awọn angẹli onipo giga ti ọrun, ti a dá ti a sì yàn lati ọdọ Ọlọrun fun iṣẹ mímú, . . . Ijọba Ọlọrun wọle, ni opin awọn sanmani.”6

Siwaju sii nipa ẹ̀kọ́ Awọn Onkọwe Ṣọọṣi ijimiji, The International Standard Bible Encyclopedia fohunṣọkan pe:

“Ninu ironu ijimiji julọ ti Ṣọọṣi ìtẹ̀sí ọkàn naa nigba ti a bá ń sọrọ nipa Ọlọrun Baba ni lati loye Rẹ̀ lakọọkọ pe, kì í ṣe pe ó jẹ́ Baba Jesu Kristi, ṣugbọn gẹgẹ bi orisun gbogbo ẹ̀dá alààyè. Fun idi yii Ọlọrun Baba ni, gẹgẹ bi o ti ri, Ọlọrun titayọlọla julọ. Oun ni awọn apejuwe bii alaini ibẹrẹ, alaileku, alaileyipada, atóbimáṣeéfẹnusọ, alaiṣeeri, ati ẹni ti a kò dá yẹ. Oun ni ẹni naa ti ó ti ṣe ohun gbogbo, papọ pẹlu ohun eelo iṣẹda gan-an, lati inu òfo. . . .

“Eyi lè dabi ohun ti ó damọran pe Baba nikan ni Ọlọrun lọna bibojumu at pe Ọmọkunrin ati Ẹmi wulẹ jẹ́ bẹẹ kiki lọna onipo keji. Ọpọ awọn àlàyé ọrọ ní ijimiji dàbí ẹni faramọ eyi.”7

Nigba ti iwe gbédègbẹ́yọ̀ yii ń baa lọ lati fi awọn otitọ wọnyi ṣe ọrọ ṣereṣere ati lati jẹwọ pe ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan ni a tẹwọgba ni saa akoko ijimiji yẹn, awọn otitọ mu ijẹwọ wọn lékèé. Gbé awọn ọrọ ẹlẹ́kọ̀ọ́ isin Katoliki naa John Henry Cardinal Newman olokiki yẹwo:

“Ẹ jẹ ki a gbà pe gbogbo agbo awọn ẹ̀kọ́, nipa eyi ti koko-ọrọ ti dá lé Oluwa lori, jẹ́ eyi ti awọn Ṣọọṣi Ijimiji jẹwọ lọna ṣiṣe deedee tí ó sì dọgba delẹ . . . Ṣugbọn ó daju pe ọ̀tọ̀ ni bí ọ̀ràn ṣe rí pẹlu ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan ti Katoliki. Emi kò rí ọ̀nà ti a lè gbà sọ pe ifohunṣọkan gbogbogboo ti [awọn alaṣẹ ṣọọṣi] ijimiji ṣetilẹhin fun un . . .

“Awọn Ìjẹ́wọ́ Igbagbọ kutukutu ọjọ yẹn kò mẹnukan . . . [Mẹtalọkan] rárá. Nitootọ wọn mẹnukan Mẹta kan; ṣugbọn pe ohun ijinlẹ eyikeyii wà ninu ẹ̀kọ́ naa, pe awọn Mẹta naa jẹ́ Ọ̀kan, pe Wọn baradọgba, jẹ́ ayeraye bakan naa, ti a kò dá gbogbo wọn, ti gbogbo wọn jẹ́ alagbara gbogbo, ti a kò lè loye gbogbo wọn, ni a kò sọ, bẹẹ ni a kò sì lè ri wọn fàyọ lati inu wọn.”8

Ohun Ti Justin Martyr Fi Kọni

Ọ̀kan lara Awọn Agbeja Igbagbọ ijimiji julọ ni Justin Martyr, ẹni ti ó gbé ni nǹkan bii 110 si 165 C.E. Kò si ọ̀kankan ninu iwe ti o kọ ti o sì wà titi di isinsinyi ti ó mẹnukan awọn ẹni mẹta ti wọn baradọgba ninu Ọlọrun kan.

Fun apẹẹrẹ, gẹgẹ bi Jerusalem Bible ti Katoliki ti wi, Owe 8:22-30 sọrọ nipa iwalaaye Jesu ṣaaju kí ó tó di eniyan pe: “Yahweh dá mi nigba ti ète rẹ̀ kọkọ farahan, ṣaaju eyi ti ó pẹ́ julọ ninu awọn iṣẹ rẹ̀. . . . Ibú kò sí, nigba ti a bí mi . . . Ṣaaju awọn òkè, A ti bí mi . . . Mo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ [Ọlọrun], ọ̀gá oniṣẹ ọnà.” Ni jijiroro awọn ẹsẹ wọnyi, Justin sọ ninu Dialogue With Trypho rẹ̀ pe:

“Iwe-Mimọ ti polongo pe Iru-Ọmọ yii ni a bí nipasẹ Baba ṣaaju awọn ohun gbogbo tí a dá; ati pe iyẹn ti a di baba fun yatọ gédégédé ní kíkà si iyẹn ti ó di baba funni, ni ẹnikẹni yoo gbà.”9

Niwọn bi a ti bí Ọmọkunrin lati ọdọ Ọlọrun, Justin lo ọrọ naa “Ọlọrun” niti gidi ni isopọ pẹlu Ọmọkunrin. Ó sọ ninu First Apology rẹ̀ pe: “Baba agbaye ní Ọmọkunrin kan; ẹni ti oun pẹlu, ní jíjẹ́ Ọrọ Ọlọrun bíbí-kanṣoṣo, jẹ́ Ọlọrun paapaa.”10 Bibeli tun tọka si Ọmọkunrin Ọlọrun nipa orukọ oyè naa “Ọlọrun.” Ni Aisaya 9:6 a pè é ni “Ọlọrun Alagbara.” Ṣugbọn ninu Bibeli, awọn angẹli, awọn eniyan, awọn ọlọrun èké, ati Satani ni a tun pè ni “ọlọrun.” (Awọn angẹli: Saamu 8:5; fiwe Heberu 2:6, 7. Awọn eniyan: Saamu 82:6. Awọn ọlọrun èké: Ẹkisodu 12:12; 1 Kọrinti 8:5. Satani: 2 Kọrinti 4:4.) Ninu Iwe-Mimọ lede Heberu, ọrọ naa fun “Ọlọrun,” ʼEl, wulẹ tumọ si “Ẹni Alagbara” tabi “Ẹni Alókunlágbára.” Eyi ti ó ṣe rẹ́gí pẹlu rẹ̀ ninu Iwe-Mimọ lede Giriiki ni the·osʹ.

Ju bẹẹ lọ, èdè isọrọ Heberu naa ti a lò ni Aisaya 9:6 fi iyatọ gédégédé laaarin Ọmọkunrin ati Ọlọrun hàn. Nibẹ ni a ti pe Ọmọkunrin ni “Ọlọrun Alagbara,” ʼEl Gib·bohrʹ, kì í ṣe “Ọlọrun Olodumare.” Ede isọrọ yẹn ni Heberu ni ʼEl Shad·daiʹ a sì fi silo fun Jehofa Ọlọrun ni oun nikan.

Bi o ti wu ki o ri, ṣakiyesi, pe nigba ti Justin pe Ọmọkunrin ni “Ọlọrun,” kò sọ rárá pe Ọmọkunrin jẹ́ ọ̀kan lara awọn ẹni mẹta ti wọn baradọgba, ọkọọkan awọn ẹni ti ó jẹ́ Ọlọrun ṣugbọn ti mẹtẹẹta papọ jẹ́ Ọlọrun kanṣoṣo. Dipo bẹẹ, ó sọ ninu Dialogue With Trypho rẹ̀ pe:

“Ọlọrun ati Oluwa [Jesu ṣaaju ki ó tó di eniyan] miiran . . . wà tí ó wà labẹ Olùṣẹ̀dá gbogbo nǹkan [Ọlọrun Olodumare]; ẹni [Ọmọkunrin] ti a tun ń pè ni Angẹli, nitori pe Oun [Ọmọkunrin naa] kede fun araye ohun yoowu ti Olùṣẹ̀dá gbogbo nǹkan—lori ẹni ti kò si Ọlọrun miiran—daniyan lati kede fun wọn. . . .

“[Ọmọkunrin] yatọ gédégédé si Ẹni ti ó dá ohun gbogbo,—ni kíkà, ni mo ni lọkan, kì í ṣe [yiyatọ gédégédé] ninu ifẹ-inu.”11

Ayọka fifani lọkan mọra kan wà ninu First Apology ti Justin, ori 6, nibi ti o ti gbeja ẹ̀sùn oloriṣa naa pe awọn Kristẹni jẹ́ alaigbọlọrungbọ. Ó kọwe pe:

“Ati Oun [Ọlọrun], ati Ọmọkunrin (ẹni ti ó jade lati ọdọ Rẹ̀ tí ó sì kọ́ wa ni awọn nǹkan wọnyi, ati ọpọ ẹgbẹ́ ogun awọn angẹli rere miiran tí wọn tẹle ti a sì ṣe bii Rẹ̀), ati Ẹmi alasọtẹlẹ, ni a ń jọsin ti a sì ń bọla fun.”12

Olùtúmọ̀ ayọka yii, Bernhard Lohse, ṣalaye pe: “Bi ẹni pe kò tó pe awọn angẹli ni a mẹnukan gẹgẹ bi awọn ẹ̀dá alààyè ti a bọla fun ti a sì jọsin nipasẹ awọn Kristẹni ninu kíkà yii, Justin kò lọ́tìkọ̀ lati mẹnukan awọn angẹli ṣaaju ki ó tó darukọ Ẹmi Mimọ.”13—Tun wo An Essay on the Development of Christian Doctrine.14

Nipa bayii, nigba ti ó jọ pe Justin Martyr ti yà kuro ninu ẹ̀kọ́ mimọgaara ti Bibeli ninu ọ̀ràn ẹni ti ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni ti awọn Kristẹni yoo dari ijọsin sí, oun ni kedere kò wo Ọmọkunrin gẹgẹ bi alabaadọgba pẹlu Baba, gan-an gẹgẹ bi oun kò ti ka awọn angẹli sí alabaadọgba Rẹ̀. Nipa Justin, a ṣayọlo lati inu Church of the First Three Centuries ti Lamson lẹẹkan sii:

“Justin ka Ọmọkunrin sí ọ̀tọ̀ gédégédé si Ọlọrun, ti ó sì rẹlẹ̀ sí i: yatọ gédégédé, kì í ṣe, ni èrò ode-oni, gẹgẹ bi ẹni ti ó papọ di ọ̀kan lara awọn ẹni, tabi eniyan mẹta, . . . ṣugbọn ó yatọ gédégédé ni ipilẹ ati irisi; bi ó ti ni agbara idanikan walaaye gidi, tí ó tó tẹ́rùn, yatọ si ti Ọlọrun, lati ọdọ ẹni ti ó ti gba gbogbo agbara ati awọn orukọ oyè rẹ̀; ni jíjẹ́ ẹni ti a yansipo labẹ rẹ̀, ti o sì juwọsilẹ fun ifẹ-inu rẹ̀ ninu ohun gbogbo. Baba jẹ́ onipo ajulọ; Ọmọkunrin jẹ́ ọmọ-abẹ́: Baba ni orisun agbara; Ọmọkunrin ni olùgbà: Baba pilẹṣẹ; Ọmọkunrin, gẹgẹ bi ojiṣẹ, tabi ohun eelo rẹ̀, fi sílò. Wọn jẹ́ meji ni iye, ṣugbọn wọn ṣọkan, tabi jẹ́ ọ̀kan, ninu ifẹ-inu; ifẹ-inu Baba ni ó maa ń lékè nigba gbogbo pẹlu Ọmọkunrin.”15

Ni afikun, kò sí ibi ti Justin ti sọ pe ẹmi mimọ jẹ́ ẹnikan ti ó baradọgba pẹlu Baba ati pẹlu Ọmọkunrin. Nitori naa kò sí ọ̀nà ti a lè gbà fi tootọ-inu tootọ-inu sọ ọ́ pe Justin kọni ni Mẹtalọkan ti Kristẹndọmu ode-oni.

Ohun Ti Clement Fi Kọni

Clement ará Alexandria (nǹkan bii 150 si 215 C.E.) tun pe Ọmọkunrin naa ni “Ọlọrun.” Ó tilẹ pè é ni “Ẹlẹdaa,” èdè isọrọ ti a kò lò ninu Bibeli rí ni titọka si Jesu. Ó ha ní i lọ́kàn pe Ọmọkunrin jẹ́ alabaadọgba ni gbogbo ọ̀nà pẹlu Ẹlẹdaa olodumare ni bi? Bẹẹkọ. Ó ṣe kedere pe Clement ń tọka si Johanu 1:3, nigba ti o sọ nipa Ọmọkunrin pe: “Nipasẹ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo.”16 Ọlọrun lo Ọmọkunrin rẹ̀ gẹgẹ bi aṣoju ninu awọn iṣẹ iṣẹda Rẹ̀.—Kolose 1:15-17.

Clement pe Ọlọrun Onipo-Ajulọ ni “Ọlọrun ati Baba Oluwa wa Jesu”17 ó sì sọ pe “Oluwa naa ni Ọmọkunrin Ẹlẹdaa naa.”18 Ó tun sọ pe: “Ọlọrun ohun gbogbo nikan ni ẹni rere, Ẹlẹdaa onidaajọ ododo, Ọmọkunrin sì [wà] ninu Baba.”19 Nitori naa ó kọwe pe Ọmọkunrin ní Ọlọrun kan ti ó ga jù ú lọ.

Clement sọ nipa Ọlọrun gẹgẹ bi “ẹni akọkọ ati olùfúnni ni ìyè ayeraye kanṣoṣo, eyi ti Ọmọkunrin, ẹni ti ó gbà á lọdọ Rẹ̀ [Ọlọrun], fi fun wa.”20 Olùfúnni ni ìyè ayeraye naa ni ipilẹṣẹ ni ó ṣe kedere pe ó ga nípò ju ẹni naa, gẹgẹ bi o ti ri, ti ó fi ṣọwọ si ẹlomiran. Nipa bayii, Clement sọ pe Ọlọrun “ni akọkọ, ati ẹni giga julọ.”21 Siwaju sii, ó sọ pe Ọmọkunrin “sunmọ Ẹni naa julọ ti o danikan jẹ́ Ẹni Olodumare” ati pe Ọmọkunrin “paṣẹ ohun gbogbo ni ibamu pẹlu ifẹ-inu Baba.”22 Leralera ni Clement fi ipo ajulọ Ọlọrun Olodumare lori Ọmọkunrin hàn.

Nipa Clement ará Alexandria, a kà ninu The Church of the First Three Centuries pe:

“A lè ṣayọlo ọgọọrọ awọn ayọka lati inu iwe Clement ninu eyi ti a ti tẹnumọ ipo rirẹlẹ Ọmọkunrin lọ́tọ̀ gédégédé. . . .

“Ó yà wá lẹnu pe ẹnikẹni lè ka iwe Clement pẹlu afiyesi lasan, ki o sì finuro o fun akoko kukuru kan pe ó ka Ọmọkunrin si ẹni—tí ó jọra ni kíkà—ọ̀kan—pẹlu Baba. Ẹ̀yà ẹ̀dá rẹ̀ tí ìgbáralé ati ìrẹlẹ̀lọ́lá, gẹgẹ bi o ti jọ loju wa, ni a mọ̀ nibi gbogbo. Clement gbagbọ pe Ọlọrun ati Ọmọkunrin yatọ gédégédé ni kíkà; ni èdè miiran, alààyè meji,—ọ̀kan jẹ́ onipo-ajulọ, ekeji jẹ́ ọmọ-abẹ́.”23

Siwaju sii, a lè sọ lẹẹkan sii pe: Kódà bi Clement ba jọ bi ẹni ti ó rekọja ohun ti Bibeli sọ nipa Jesu nigbamiran, kò sí ibi kankan ti ó ti sọrọ nipa Mẹtalọkan ti ó ni awọn ẹni mẹta ti wọn baradọgba ninu Ọlọrun kan. Awọn Agbeja Igbagbọ iru bii Tatian, Theophilus, ati Athenagoras, ti wọn gbé laaarin akoko Justin ati ti Clement, ní oju-iwoye kan naa. Lamson sọ pe wọn “kì í ṣe Onigbagbọ Mẹtalọkan ju Justin fúnraarẹ̀ lọ; iyẹn ni pe, wọn kò gbagbọ ninu Mẹta ti ó papọ, ti ó baradọgba, ṣugbọn wọn kọni ni ẹ̀kọ́ ti kò tanmọra patapata pẹlu igbagbọ yii.”24

Ẹ̀kọ́-Ìsìn Tertullian

Tertullian (nǹkan bii 160 si 230 C.E.) ni ẹni akọkọ lati lo ọrọ Latin naa Trinitas. Gẹgẹ bi Henry Chadwick ti ṣakiyesi, Tertullian dabaa pe Ọlọrun jẹ́ ‘ipilẹ kan ti ó papọ ni ẹni mẹta ninu.’25 Bi o ti wu ki o ri, eyi kò tumọsi, pe oun ni awọn ẹni mẹta abaradọgba ati ajumọ jẹ́ ayeraye lọkan. Bi o ti wu ki o ri, awọn èrò rẹ̀ ni awọn onkọwe lẹhin naa ti wọn ń ṣiṣẹ siha ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan fi ṣe ipilẹ.

Èrò Tertullian nipa Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mimọ yatọ gidigidi si Mẹtalọkan Kristẹndọmu, nitori pe oun jẹ́ onigbagbọ ninu wíwà ni ipo ọmọ-abẹ́. Ó wo Ọmọkunrin gẹgẹ bi ọmọ-abẹ́ si Baba. Ninu Against Hermogenes ó kọwe pe:

“A kò gbọdọ rò pe olùwà miiran eyikeyii wà ju Ọlọrun nikan lọ ẹni tí a kò bí ti a kò sì dá. . . . Bawo ni o ṣe lè jẹ́ pe ohunkohun, yatọ si Baba, gbọdọ dagba ju, ki o sì titori eyi gbayì, ju Ọmọkunrin Ọlọrun lọ, Ọrọ bíbí-kanṣoṣo ati àkọ́kọ́bí? . . . Pe [Ọlọrun] ẹni ti kò nilo Olùṣẹ̀dá lati fun un ni iwalaaye, ni a o gbéga lọpọlọpọ ni ipo ju iyẹn [Ọmọkunrin] ẹni ti ó ni olùṣe lati mú un wá sí ìyè.”26

Pẹlupẹlu, ninu Against Praxeas, ó fihan pe Ọmọkunrin yatọ sí ó sì jẹ́ ọmọ-abẹ́ si Ọlọrun Olodumare nipa sisọ pe:

“Baba ni gbogbo ipilẹ naa, ṣugbọn Ọmọkunrin jẹ́ àmújáde ati apakan odidi naa ni, gẹgẹ bi Oun Fúnraarẹ̀ ti jẹwọ pe: ‘Baba mi tobi ju mi lọ.’ . . . Nipa bayii Baba yatọ gédégédé si Ọmọkunrin, ni titobi ju Ọmọkunrin lọ, niwọn bi o ti jẹ́ pe Ẹni tí ó bí ni ti jẹ́ ọ̀kan, ati Ẹni ti a bí jẹ́ ẹlomiran; Ẹni, tí ó ránni jẹ́ ẹnikan pẹlu, ati Ẹni ti a rán jẹ́ ẹlomiran; lẹẹkan sii, Ẹni, tí ó ṣe nǹkan jẹ́ ẹnikan, Ẹni nipasẹ rẹ̀ ti a ṣe nǹkan sì jẹ́ ẹlomiran.”27

Tertullian, ninu Against Hermogenes, sọ siwaju sii pe akoko kan wà nigba ti Ọmọkunrin kò sí gẹgẹ bi ẹni gidi kan, ti o fihan pe kò ka Ọmọkunrin sí alààyè ayeraye ni èrò kan naa ti Ọlọrun gbà jẹ́.28 Cardinal Newman sọ pe: “Tertullian ni a gbọdọ kà sí elérò yíyọyẹ́ [ti ó gbagbọ ninu awọn ẹ̀kọ́ ti kò bá eyi ti a tẹwọgba mu] lori ẹ̀kọ́ ìjọjẹ́ ayeraye pẹlu Baba ti Oluwa wa.”29 Nipa Tertullian, Lamson polongo pe:

“Èrò yii, tabi Logos, gẹgẹ bi awọn Giriiki ti ń pè é, ni a yipada lẹhin naa, gẹgẹ bi Tertullian ti gbagbọ, sí Ọrọ, Ọmọkunrin, iyẹn ni, alààyè gidi kan, ti ó ti wà lati ayeraye kiki gẹgẹ bi animọ Baba. Bi o ti wu ki o ri, Tertullian ka ipo ti ó jẹ́ ti ọmọ-abẹ́ si Baba si tirẹ . . .

“Ti a bá fi alaye eyikeyii ti a rigba nipa Mẹtalọkan ni ode oni dá a, igbidanwo lati gba Tertullian là kuro lọwọ ẹ̀bi iku [gẹgẹ bi aládàámọ̀] ni kì bá tí sí ireti fun. Kò lè rí ara gba idanwo naa si fun sáà kukuru kan.”30

Kò Sí Mẹtalọkan

Bi iwọ bá nilati ka gbogbo ọrọ Awọn Agbeja Igbagbọ, iwọ yoo rí i pe bi o tilẹ jẹ pe wọn yà bàrá ni awọn ọ̀nà kan kuro ninu awọn ohun ti Bibeli fi kọni, kò sí ọ̀kankan ninu wọn ti ó kọni pe Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mimọ jẹ́ ọgbọọgba ni ayeraye, agbara, ipo, ati ọgbọn.

Eyi tun jẹ́ otitọ bakan naa nipa awọn onkọwe miiran ni ọrundun keji ati ẹkẹta, iru bii Irenaeus, Hippolytus, Origen, Cyprian, ati Novatian. Nigba ti awọn kan wá fi Baba ati Ọmọkunrin wéra ni awọn ọ̀nà kan, ni awọn ọ̀nà miiran wọn wò Ọmọkunrin gẹgẹ bi ọmọ-abẹ́ si Ọlọrun Baba. Kò sì sí ọ̀kankan ninu wọn tí ó tilẹ méfò pe ẹmi mimọ baradọgba pẹlu Baba ati Ọmọkunrin. Fun apẹẹrẹ, Origen (nǹkan bii 185 si 254 C.E.) sọ pe Ọmọkunrin Ọlọrun ni “Àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá” ati pe Iwe-Mimọ “mọ̀ ọ́n lati jẹ́ ẹni ti ó pẹ́ julọ ninu gbogbo iṣẹ iṣẹda.”31

Fifi èrò inu ṣiṣi silẹ ka iwe awọn alaṣẹ ṣọọṣi ijimiji wọnyi yoo fihan pe ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan Kristẹndọmu kò sí ni akoko wọn. Gẹgẹ bi The Church of the First Three Centuries ti sọ:

“Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan ti igbalode ti ó jẹ́ olokiki . . . kò rí itilẹhin lati inu awọn èdè isọrọ Justin: akiyesi yii ni a sì lè nasẹ rẹ̀ dé ọ̀dọ̀ gbogbo Awọn Onkọwe ṣaaju Igbimọ Nicaea; iyẹn ni pe, fun gbogbo awọn onkọwe Kristẹni fun ọrundun mẹta lẹhin ìbí Kristi. Otitọ ni pe, wọn sọrọ nipa Baba, Ọmọkunrin, ati Ẹmi alasọtẹlẹ tabi Ẹmi mimọ, ṣugbọn kì í ṣe ni ibaradọgba, kì í ṣe gẹgẹ bi ipilẹ òǹkà kan, kì í ṣe gẹgẹ bii Mẹta ninu Ọ̀kan, ni èrò eyikeyii ti awọn onigbagbọ Mẹtalọkan gbà nisinsinyi. Odikeji gan-an ni otitọ naa. Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan, gẹgẹ bi awọn Onkọwe wọnyi ti ṣalaye rẹ̀, yatọ niti gidi si ẹ̀kọ́ ode-oni. Eyi ni a sọ gẹgẹ bi otitọ ti a lè fi ẹ̀rí yẹwo gẹgẹ bi otitọ eyikeyii ninu ìtàn èrò eniyan.”32

Niti tootọ, ṣaaju Tertullian Mẹtalọkan ni a kò tilẹ mẹnukan. “Èrò yíyọyẹ́” Mẹtalọkan ti Tertullian si yatọ gidigidi si iyẹn ti a gbagbọ lonii. Bawo, nigba naa, ni ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan, gẹgẹ bi a ti loye rẹ̀ lonii, ṣe gbèrú? Ó ha jẹ́ ní Igbimọ Nicaea ni 325 C.E. bi? Awa yoo ṣayẹwo awọn ibeere wọnyi ninu Apa 4 ọ̀wọ́ yii ninu itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà ọjọ iwaju.

Awọn ìtọ́ka:

1. A Short History of the Early Church, lati ọwọ Harry R. Boer, 1976, oju-iwe 110.

2. The Formation of Christian Dogma, lati ọwọ Martin Werner, 1957, oju-iwe 125.

3. The Search for the Christian Doctrine of God, lati ọwọ R. P. C. Hanson, 1988, oju-iwe 64.

4. The Church of the First Three Centuries, lati ọwọ Alvan Lamson, 1869, oju-iwe 70 si 71.

5. Gods and the One God, lati ọwọ Robert M. Grant, 1986, oju-iwe 109, 156, 160.

6. The Formation of Christian Dogma, oju-iwe 122, 125.

7. The International Standard Bible Encyclopedia, 1982, Idipọ 2, oju-iwe 513.

8. An Essay on the Development of Christian Doctrine, lati ọwọ John Henry Cardinal Newman, Ẹ̀dà Itẹjade Kẹfa, 1989, oju-iwe 14 si 18.

9. The Ante-Nicene Fathers, ti a yẹwo ṣatunṣe lati ọwọ Alexander Roberts ati James Donaldson, Àtúntẹ̀ Ẹ̀dà Itẹjade Edinburgh ti America, 1885, Idipọ I, oju-iwe 264.

10. Ibid., oju-iwe 184.

11. The Ante-Nicene Fathers, Idipọ I, oju-iwe 223.

12. Ibid., oju-iwe 164.

13. A Short History of Christian Doctrine, lati ọwọ Bernhard Lohse, ti a tumọ lati èdè German lati ọwọ F. Ernest Stoeffler, 1963, itẹjade ẹlẹ́hìn-rírọ̀ keji, 1980, oju-iwe 43.

14. An Essay on the Development of Christian Doctrine, oju-iwe 20.

15. The Church of the First Three Centuries, oju-iwe 73 si 74, 76.

16. The Ante-Nicene Fathers, Idipọ II, oju-iwe 234.

17. Ibid., oju-iwe 227.

18. Ibid., oju-iwe 228.

19. Ibid.

20. Ibid., oju-iwe 593.

21. Ibid.

22. Ibid., oju-iwe 524.

23. The Church of the First Three Centuries, oju-iwe 124 si 125. 24. Ibid., oju-iwe 95.

25. The Early Church, lati ọwọ Henry Chadwick, itẹjade 1980, oju-iwe 89.

26. The Ante-Nicene Fathers, Idipọ III, oju-iwe 487.

27. Ibid., oju-iwe 603 si 604.

28. Ibid., oju-iwe 478.

29. An Essay on the Development of Christian Doctrine, oju-iwe 19, 20.

30. The Church of the First Three Centuries, oju-iwe 108 si 109.

31. The Ante-Nicene Fathers, Idipọ IV, oju-iwe 560.

32. The Church of the First Three Centuries, oju-iwe 75 si 76.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Clement

[Credit Line]

Historical Pictures Service

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Tertullian

[Credit Line]

Historical Pictures Service

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́