ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 4/1 ojú ìwé 20-23
  • Ọna Jehofa Ni Ọna Tí Ó Dara Julọ Lati Maa Gbé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọna Jehofa Ni Ọna Tí Ó Dara Julọ Lati Maa Gbé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ogún-Ìní Kristẹni Kan
  • Iranti Awọn Ohun Àtijọ́tijọ̀
  • Ile-Ẹkọ ati Ipinnu Pataki Kan
  • Iṣẹ Aṣaaju-Ọna ati Iṣẹ-Isin Bẹtẹli
  • Pipa Aidasitọtuntosi Mọ́
  • Oniruuru Anfaani Iṣẹ-Isin
  • Igbesi-Aye Kan Tí Ó Nitumọ, Tí Ń Tẹnilọrun   
  • A Pinnu Láti Sin Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìgbésí-Ayé Dídọ́ṣọ̀, Elérè-Ẹ̀san Nínú Iṣẹ́-Ìsìn Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Jèhófà Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Ṣàṣeyọrí, Láìka Kùdìẹ̀-Kudiẹ Mi Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Àádọ́rin Ọdún Rèé Tí Mo Ti Ń Di Ibi Gbígbárìyẹ̀ Lára Aṣọ Ẹni Tí Í Ṣe Júù Mú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 4/1 ojú ìwé 20-23

Ọna Jehofa Ni Ọna Tí Ó Dara Julọ Lati Maa Gbé

GẸGẸ BI ERKKI KANKAANPÄÄ TI SỌ Ọ́

LATI ìgbà ti mo ti jẹ́ ọmọde kan, ni gongo      mi ti jẹ́ lati ṣiṣẹsin ni ẹ̀ka Finland ti      Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tabi Bẹtẹli gẹgẹ bi a ti ń pè é. Nitori naa nigba ti alaboojuto arinrin-ajo kan beere lọwọ mi ni ìgbà ìrúwé 1941 pe, “Ìwéwèé wo ni o ní fun ọjọ-ọla?” Mo fesi pada pe: “Mo ti fẹ́ nigba gbogbo lati lọ si Bẹtẹli.”

“O jẹ́ lọ pa iru awọn àlá wọnni tì; a kì yoo ké sí ọ lae,” ni ó sọ. Lakọọkọ mo ni ìjákulẹ̀ gidigidi, ṣugbọn lẹhin naa mo pinnu lati rọra fi ọran naa lé Jehofa lọwọ. Ni iwọnba oṣu diẹ lẹhin naa, mo gba ikesini kan lati ṣiṣẹsin ni Bẹtẹli.

Mo jẹ́ ọdọmọkunrin onitiju, ẹni ọdun 17 kan nigba ti mo tẹ aago ilẹkun ni ẹ̀ka ọfiisi ni Helsinki ni ọjọ títutù nini kan ni November, ti ó mọ́ kedere ni 1941. Laipẹ ni Kaarlo Harteva, alaboojuto ẹ̀ka naa kí mi kaabọ. Ni akoko yẹn ẹ̀ka naa ní abojuto 1,135 Awọn Ẹlẹ́rìí ni Finland.

Ogún-Ìní Kristẹni Kan

Ni 1914 baba mi ti gba ẹ̀dà kan ninu itẹjade Watch Tower The Divine Plan of the Ages. Bi o ti wu ki o ri, ogun agbaye kìn-ín-ní bẹ́ silẹ laipẹ lẹhin naa, kò sì rí àyè kà á.

Ijakadi Finland fun ominira orilẹ-ede dá awọn iṣoro silẹ. Awujọ alagbara meji—Awọn Funfun ati Awọn Pupa—ni a dá silẹ. Awọn Funfun duro fun awọn oniṣowo bòḿbàtà ati awọn kò-là-kò-ṣagbe, nigba ti awọn Pupa duro fun awọn oṣiṣẹ. Baba mi gbiyanju lati wà laidasi tọtuntosi, ni títakété patapata si awujọ mejeeji. Sibẹ, awọn mejeeji kọ orukọ rẹ̀ silẹ gẹgẹ bi ẹni ti ó yẹ lati fura sí.

Gẹgẹ bi ọran ti wá rí ni ikẹhin, Baba mi ni a dẹ́bi iku fun lẹẹmeji, akọkọ lati ọwọ Awọn Funfun ati lẹhin naa lati ọwọ Awọn Pupa. Lẹ́ẹ̀kan rí nigba ti a pa ọkunrin kan ti ọwọ kò sì lè tẹ ẹni ti ó pa á, awọn ọdọmọkunrin mẹwaa, ti ó ní baba mi ninu, ni a dajọ iku fun. Ọ̀kan lara awọn olukọ baba mi, ti ó jẹ́ mẹmba ẹgbẹ́ igbimọ naa, damọran ìtúsílẹ̀ rẹ̀, wọn sì fọwọsi i. Awọn ọ̀dọ́ mẹsan-an yooku ni a fiya iku jẹ́.

Ni akoko miiran Baba ni a tún yọnda ìtúsílẹ̀ kuro ninu idajọ iku fun. Lẹhin iyẹn ó pinnu lati lọ si abẹ ilẹ, niti gidi! Oun ati arakunrin rẹ̀ ṣe ibùgbé kan ti a gbẹ́ jade lati inu ilẹ, nibi ti wọn gbé titi ti ogun naa fi pari. Lati mú ki wọn walaaye, arakunrin wọn kekere pese jijẹ ati mímu fun wọn.

Lẹhin ti ogun pari ni 1918, Baba mi gbeyawo ó sì kọ ile kan lẹbaa ibùgbé ti a gbẹ́ jade lati inu ilẹ yẹn. Mo dojulumọ rẹ̀ daradara nigba ti ó yá, niwọn bi o ti wà gẹgẹ bi ilẹ iṣere fun mi. Baba sọ fun mi pe oun ti gba ọpọlọpọ adura nigba ti oun sapamọ sibẹ labẹ ilẹ. Ó ṣeleri fun Ọlọrun pe bi oun bá jẹ́ kẹkọọ ọna lati sìn Ín, oun yoo ṣe bẹẹ.

Ni kété lẹhin ṣiṣegbeyawo, Baba pinnu lati mú ohun kan lọwọ lati kà loju ọna irin-ajo iṣẹ́-ajé. Ninu iyàrá òkè àjà, ó rí iwe The Divine Plan of the Ages ti ó ti rà ṣaaju. Ó ṣí i si akori naa “Ọjọ Jehofa” ó sì kà á. Ó ń sọ leralera fun araarẹ pe: ‘Otitọ ni eyi, otitọ ni eyi.’ Ni bíbọ́ silẹ lati inu iyàrá òkè àjà, ó sọ fun mama mi pe: “Mo ti ri isin tootọ.”

Ó fẹrẹẹ jẹ́ loju ẹsẹ ni Baba mi bẹrẹ wiwaasu fun awọn ẹlomiran nipa awọn ohun ti ó ń kẹkọọ rẹ̀, ó kọ́kọ́ bẹrẹ sii ba awọn ibatan ati aladuugbo rẹ̀ sọrọ. Lẹhin naa ó bẹrẹ sii sọ asọye itagbangba. Laipẹ awọn miiran ni adugbo naa darapọ mọ́ ọn. Lẹhin ṣiṣalabaapade Awọn Akẹkọọ Bibeli, gẹgẹ bi a ti ń pe Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nigba naa, Baba ni a bamtisi ni 1923. Nigba ti wọn bí awa ọmọ—mẹrin ni wá lẹhin-ọ-rẹhin—Baba kò ṣàìnáání kíkọ́ wa. Niti tootọ, lẹhin ti a dá ijọ kan silẹ, a paṣẹ fun wa lati lọ si gbogbo ipade.

Iranti Awọn Ohun Àtijọ́tijọ̀

Ohun àtijọ́tijọ̀ ti mo pada ranti jẹ́ nipa apejọ kan ti a ṣeto ninu ijọ ti a ń lọ ni ile ni 1929, nigba ti mo jẹ́ ọmọ ọdun marun-un. Ọpọlọpọ awọn eniyan korajọpọ lati awọn ijọ itòsí, ayanṣaṣoju kan lati ẹ̀ka ọfiisi sì wà nibẹ pẹlu. Ni awọn ọjọ wọnni ó jẹ́ àṣà, ó keretan ni Finland, lati ya awọn ọmọde si mímọ́ ni awọn apejọ. Nitori naa arakunrin naa lati Bẹtẹli ya awọn ọmọde si mímọ́, gan-an gẹgẹ bi Jesu ti ṣe nigba iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀. Emi kò tii gbàgbé iyẹn.—Maaku 10:16.

Iranti àtijọ́tijọ̀ miiran ni gbigba orukọ naa Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lò ni 1931. Baba mi, ni mímọ ijẹpataki akoko iṣẹlẹ naa, fi ironujinlẹ ka ifilọ naa nipa orukọ wa titun fun ijọ.

Lati ìgbà ti mo lè ranti mọ, emi yoo darapọ mọ́ baba mi ninu iṣẹ iwaasu. Lati bẹrẹ, emi yoo wulẹ fetisilẹ sí i, ṣugbọn asẹhinwa-asẹhinbọ mo ń ṣe iṣẹ naa funraami. Ni 1935, nigba ti alaboojuto arinrin-ajo kan bẹ̀ wá wò, mo lọ sọdọ gbogbo awọn aladuugbo wa mo sì ké sí wọn lati wá si ipade. Mo tun fi awọn iwe pẹlẹbẹ lọ̀ wọn, awọn eniyan diẹ sì gba iwọnyi.

Ile-Ẹkọ ati Ipinnu Pataki Kan

Kìkì awa mẹrẹẹrin ni a jẹ́ ọmọ fun awọn obi ti wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí ni ile-ẹkọ naa, wọn sì maa ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ niye igba nitori ṣiṣai darapọ mọ awọn ọ̀dọ́ ti ó kù ninu iwa ti kò bá ti Kristẹni mu. Bi o tilẹ jẹ pe awọn ọmọ ile-ẹkọ ẹlẹgbẹ mi gbiyanju lati tàn mi mu siga, emi kò ṣe bẹẹ lae. A tún ń fi yẹ̀yẹ́ pè wa ni ọmọlẹhin Russell (Russell ni ààrẹ akọkọ ti Watch Tower Society) tabi ọmọlẹhin Harteva (Harteva nigba naa jẹ́ alaboojuto ẹ̀ka ni Finland). Inu mi dun lati sọ pe diẹ lara awọn ọ̀dọ́ ti wọn fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ nigbakanri di Ẹlẹ́rìí lẹhin-ọ-rẹhin.

Olukọ mi fun mi niṣiiri lati tẹsiwaju ninu ìmọ̀-ẹ̀kọ́ mi, ni akoko kan mo sì ronu didi ẹnjinnia kan. Ṣugbọn nigba naa apejọpọ Ẹlẹ́rìí Jehofa kan wà ni Pori ni ìgbà iruwe 1939, eyi ti ó jasi ìkóríta iyipada kan ninu igbesi-aye mi. Emi ati arakunrin mi kekere, Tuomo, ya araawa si mímọ́ fun Jehofa a sì fami iṣapẹẹrẹ eyi han nipa bamtisimu inu omi ni apejọpọ yẹn, ni May 28, 1939. Lẹhin naa, ni ibẹrẹ September, Ogun Agbaye II bẹ́ silẹ.

Awọn ipo ni Europe yipada lọna amunijigiri. Ipo nǹkan laaarin Finland ati Soviet Union di eléwu. Baba mi tẹnumọ ọn pe Amagẹdọni tubọ ń sunmọle ó sì fun wa niṣiiri lati ṣe aṣaaju-ọna. Nitori naa ni December 1940, emi ati arakunrin mi bẹrẹ sii ṣe iṣẹ aṣaaju-ọna ni iha ariwa Finland.

Iṣẹ Aṣaaju-Ọna ati Iṣẹ-Isin Bẹtẹli

Nigba ti a ń ṣe iṣẹ aṣaaju-ọna, a gbé ni ọpọ ìgba julọ pẹlu Yrjö Kallio. Oun jẹ́ arakunrin kan ẹni ti, ni nǹkan bii 30 ọdun ṣaaju, ti di Akẹkọọ Bibeli kan ni Pennsylvania ni United States. Ara Yrjö yọ̀ mọ́ni pupọ, ó sì ṣe gbogbo ohun ti ó lè ṣe lati pese awọn ayika gbigbadun mọni fun wa. Arakunrin rẹ̀ nipa ti ara, Kyösti Kallio, sin gẹgẹ bi ààrẹ̀ Finland lati 1937 si 1940. Yrjö sọ fun wa pe oun ti jẹrii kúnnákúnná fun arakunrin oun, ni ṣiṣalaye fun un pe Ijọba Ọlọrun ni ireti kanṣoṣo fun ijọba rere ati fun alaafia wíwà pẹtiti, kari ayé.

Bi akoko ti ń kọja lọ, ifẹ mi lati di mẹmba idile Bẹtẹli dagba. Lọna ti ó ṣe wẹ́kú, laika ikilọ alaboojuto arinrin-ajo naa lodisi ṣiṣeto awọn ireti mi sí, iwe ibeere mi lati sin ní Bẹtẹli ni a gbawọle. Iṣẹ mi akọkọ nibẹ jẹ́ ti jíjẹ́ iṣẹ funni. Bi o ti wu ki o ri, laipẹ, mo ni anfaani ṣiṣiṣẹ ninu ile-iṣẹ ẹ̀rọ. Nibẹ mo ṣiṣẹ ninu ọpọlọpọ ẹ̀ka iṣẹ, ti o ní iyàrá itẹwe wa kekere ati Ẹ̀ka Iṣẹ Ikẹruranṣẹ ninu.

Pipa Aidasitọtuntosi Mọ́

Ni 1942, ni ọjọ ori 18, a pè mi fun iṣẹ-isin ologun. Niwọn bi mo ti kọ̀ lati di ẹni ti a gbà wọle, a fi mi sabẹ ifibeere wadii ọrọ alakooko gigun, ni ìgbà meji pẹlu ibọn ti a nà sí mi. Ni awọn ìgbà yooku iwa ipa gidi ni a lò. Pẹlupẹlu, laaarin akoko ifibeere wadii ọrọ naa, a fi mi sinu iyàrá ọgbà ẹwọn ti a kò mú móoru ti ó tutu rinrin.

Nikẹhin, ni January 1943, akoko tó fun emi ati Awọn Ẹlẹ́rìí miiran lati di ẹni ti a paṣẹ ijiya fun. Oloye oṣiṣẹ ologun naa ti o ti fi ibeere wadii ọrọ lẹnu wa fi dandan beere pe ki ifisẹwọn wa má dín si ọdun mẹwaa. Alufaa ẹgbẹ́ ọmọ-ogun naa ń fẹ́ idajọ ti ó tilẹ múná jù paapaa, ni fifi dandan beere ‘aṣẹ ijiya iku tabi rírán awọn ọ̀dàlẹ̀ wọnyi lọ si Russia gẹgẹ bi amí-ológun afaṣọfò [iku tí ó fẹrẹẹ daju], eyi ti yoo tọ́ sí wọn.’

Ìgbẹ́jọ́ ti kìí ṣe ojulowo ni a ṣeto. A pè mi siwaju ile-ẹjọ naa a sì paṣẹ idajọ iku fun mi. Bi o ti wu ki o ri, eyi jásí isapa miiran lati dẹrubani, niwọn bi o ti jẹ pe a tún pè mi siwaju ile-ẹjọ naa lẹ́ẹ̀kan sii bi ọjọ naa ti ń lọ ti a sì paṣẹ ijiya ọdun mẹta ati ààbọ̀ ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n amúnipàwàdà fun mi. Mo pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fun aṣẹ ijiya naa, wọn sì dín in si ọdun meji.

Ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n, ounjẹ ṣọ̀wọ́n, ìhalẹ̀mọ́ni alarankan lati ọdọ awọn ẹlẹwọn miiran sì wà. Lẹẹmeji awọn abẹ́yàkan-náà-lòpọ̀ gbéjà kò mi, ṣugbọn lọna ti ó ṣe kòńgẹ́ ire ó ṣeeṣe fun mi lati jàbọ́. Ọ̀kan lara wọn halẹ pe oun yoo pa mi bi emi kò bá ni fohunṣọkan pẹlu awọn ohun ti ó ń fẹ́. Ṣugbọn gẹgẹ bi mo ti ṣe ninu gbogbo awọn adanwo mi, mo képe Jehofa, ó sì ran mi lọwọ. Niti gasikiya, ìhàlẹ̀ ẹlẹwọn naa kì í ṣe kèrémí, nitori pe ó ti pà eniyan rí. Lẹhin ìtúsílẹ̀ rẹ̀, ọkunrin naa dá ọ̀ràn ipaniyan miiran wọn sì dá a pada sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n.

Kò sí iyemeji pe ó jẹ́ nitori pe Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a mọ fun ìṣeégbẹkẹle ni kò fi pẹ́ ti wọn fi fi mi sipo ẹlẹwọn ti a fun ni anfaani ara-ọtọ. Iṣẹ mi ni lati pín ipese ounjẹ fun awọn ẹlẹwọn miiran, a sì yọnda mi lati rin falala kaakiri ayika inu ọgbà ẹ̀wọ̀n naa. Nitori naa, kì í ṣe kiki pe mo ni ounjẹ tí ó tó funraami nikan ni ṣugbọn ó tun ṣeeṣe fun mi lati rí sí i pe awọn Kristẹni arakunrin mi ni a bojuto daradara. Arakunrin kan tilẹ sanra nigba ti ó wà ninu ẹ̀wọ̀n, ohun kan ti ó ṣọ̀wọ́n ni gbigbe ọ̀wọ́ngógó ounjẹ yẹwo!

A dá mi silẹ lominira kuro ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n ni September 1944, ni ọjọ kan naa ti a dá Arakunrin Harteva silẹ. Ìdásílẹ̀ mi tumọ si pipada sẹnu iṣẹ-isin Bẹtẹli. Mo rò ninu araami pe, ‘Ṣiṣiṣẹ kára fun wakati 16 loojọ ni Bẹtẹli ni a nilati yàn laayo lọna giga ju igbesi-aye ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n lọ.’ Emi kò tíì yẹ iṣẹ silẹ lati igba naa wá!

Oniruuru Anfaani Iṣẹ-Isin

Nigba ti o yá ni 1944, mo pade Margit, òrékelẹ́wà ọ̀dọ́ aṣaaju-ọna kan, ẹni ti ó dahun pada si ifẹ mi sí i, a sì ṣegbeyawo ni February 9, 1946. Ni ọdun wa akọkọ gẹgẹ bii tọkọtaya ti ó ti ṣegbeyawo, mo ṣiṣẹsin ni Bẹtẹli nigba ti Margit ṣiṣẹ ni Helsinki gẹgẹ bi aṣaaju-ọna kan. Lẹhin naa ni January 1947, a yàn wá sí iṣẹ ayika.

Ninu iṣẹ irinrin-ajo, a saba maa ń gbé pẹlu awọn idile a sì maa ń ṣajọpin iyàrá kan pẹlu wọn. A mọ pe wọn pese ohun tí ó dara julọ ti wọn lè pese fun wa, a kò sì ráhùn rí. Awọn ayika kere ni ọjọ wọnni, awọn ijọ kan kò sì ni Awọn Ẹlẹ́rìí tí ó tíì ṣe bamtisi rárá!

Ni 1948 a késí wa lati pada sẹnu iṣẹ-isin Bẹtẹli. Ọdun meji lẹhin naa Wallace Endres wá si Finland lati United States, a sì yàn án gẹgẹ bi alaboojuto ẹ̀ka lẹhin naa. Ó fi tọyayatọyaya fun wa niṣiiri lati maa baa lọ ni kíkọ́ ede Gẹẹsi, eyi ti a ṣe. Nipa bayii, a ké sí wa lati lọ si kilaasi 19 ti ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ti Watchtower Bible School of Gilead, eyi ti ó bẹrẹ ni South Lansing, New York, ni February 1952.

Lẹhin kikẹkọọ jade a pínṣẹ́ yàn fun wa pada si Finland. Bi o ti wu ki o ri, ṣaaju ki a tó fi United States silẹ, a fun mi ni ìdálẹ́kọọ lori ṣiṣiṣẹ pẹlu awọn ẹrọ itẹwe ni orile-iṣẹ agbaye ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Brooklyn, New York.

Ní pipada si Finland, a pín wa yàn sẹnu iṣẹ irinrin-ajo, ṣugbọn nigba ti o ṣe ni 1955 a ké sí wa pada si ẹ̀ka ti Finland. Ni ọdun yẹn mo di alaboojuto ile-iṣẹ ẹrọ, ati ni ọdun meji lẹhin naa, ni 1957, a yàn mi ni alaboojuto ẹ̀ka. Lati 1976, mo ti ṣiṣẹsin gẹgẹ bi olùṣekòkáárí Igbimọ Ẹ̀ka Finland.

Lọna ti ó múni layọ, ati baba mi ati mama mi duro bi oloootọ si Jehofa titi di igba iku wọn. Bi akoko ti ń lọ, iye ti ó ju ọgọrun-un kan lọ ninu awọn ibatan Baba mi di Ẹlẹ́rìí. Ati titi di oni yii, arakunrin ati awọn arabinrin mi ati awọn idile wọn ni gbogbo wọn ń ṣiṣẹ́sin Jehofa, ti ọ̀kan ninu awọn arabinrin mi sì jẹ́ aṣaaju-ọna.

Igbesi-Aye Kan Tí Ó Nitumọ, Tí Ń Tẹnilọrun   

Awọn ọdun naa ti papọ jẹ́ iṣẹ ati ọpọ iṣẹ sii, ṣugbọn iṣẹ naa, nitori pe ó jẹ́ iṣẹ Ọlọrun, ti jẹ eyi tí ó ó nitumọ tí ó sì ń tẹ́nilọ́rùn nitootọ. (1 Kọrinti 3:6-9) Igbesi-aye mi kò fi igba gbogbo jẹ́ eyi ti o rọrun gbẹdẹmukẹ ti ó sì gbadunmọni. Awọn iṣoro ati inira ti wà bakan naa. Ni kutukutu igbesi-aye, mo mọ̀ daju pe iwọ nilati kẹkọọ lati bá araarẹ wi. Iwọ kò lè ṣe gẹgẹ bi o ṣe fẹ nigba gbogbo. A tún oju iwoye mi ṣe niye igba, mo sì mọ ọna titọna lati maa gbé.

Fun apẹẹrẹ, awọn adanwo ati àìtó ti mo jiya wọn ni akoko ogun kọ́ mi lati gbé laisi awọn ohun faaji. Mo kẹkọọ lati mòye boya ohun kan pọndandan niti gidi tabi bẹẹkọ. Mo ṣì ni àṣà bibeere lọwọ araami boya mo nilo eyi tabi iyẹn. Ati lẹhin naa bi mo bá mọ daju pe ó ṣetan kò kúkú fi bẹẹ ṣe pataki, emi kìí rà á.

Itọsọna ti Jehofa pese nipasẹ eto-ajọ rẹ̀ ti jẹ́ eyi ti ó han gbangba. Mo ti ni ayọ rírí iye Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ó gasoke ninu awọn ọdun mi ni ẹ̀ka Finland lati 1,135 si iye ti o ju 18,000 lọ! Loootọ, mo lè rí i pe iṣẹ mi ni a ti bukun, ṣugbọn mo mọ̀ pe a ti bukun un nitori pe iṣẹ naa jẹ́ ti Jehofa kì í sìí ṣe tiwa. (1 Kọrinti 3:6, 7) Ni kutukutu igbesi-aye mi mo yan ọna Jehofa, ó sì ti jásí ọna ti o dara julọ lati maa gbé nitootọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Erkki Kankaanpää lonii, pẹlu Margit aya rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́