ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 4/1 ojú ìwé 20-24
  • Ìgbésí-Ayé Dídọ́ṣọ̀, Elérè-Ẹ̀san Nínú Iṣẹ́-Ìsìn Jehofa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbésí-Ayé Dídọ́ṣọ̀, Elérè-Ẹ̀san Nínú Iṣẹ́-Ìsìn Jehofa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àṣáálẹ́ kan tí Ó Yí Ìgbésí-Ayé Mi Padà
  • Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Wa ní Àwọn Ọdún Ìjímìjí
  • Ìyípadà kan Tí Ń Dán Ìgbàgbọ́ Wa Wò
  • Àwọn Ìmóríbọ́ Nínú Ewu
  • Ṣíṣèrànwọ́ Níbi Ìgbẹ́jọ́ Kan
  • Ogun Náà Parí​—⁠Iṣẹ́-Ìsìn Wa Ń Báa Nìṣó
  • Ọna Jehofa Ni Ọna Tí Ó Dara Julọ Lati Maa Gbé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • A Pinnu Láti Sin Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ṣíṣiṣẹ́ Sìn Lábẹ́ Ọwọ́ Ìfẹ́ Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ohun Tí Ó Lé Ní 50 Ọdún ‘Ríré Kọjá Wá’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 4/1 ojú ìwé 20-24

Ìgbésí-Ayé Dídọ́ṣọ̀, Elérè-Ẹ̀san Nínú Iṣẹ́-Ìsìn Jehofa

GẸ́GẸ́ BÍ LEO KALLIO TI SỌ Ọ́

Ọdún 1914 ni, ọjọ́ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn rírẹwà kan ń parí lọ ní àdúgbò wa ní Turku, ìlú-ńlá kan ní Finland. Lójijì, ìparọ́rọ́ náà ni ìròyìn ogun ńlá kan tí ó ti bẹ́ sílẹ̀ fọ́ yángá. Láìpẹ́ àwọn òpópónà ti kún fún àwọn tí wọn ń ronú lórí ìtúmọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ojú àwọn àgbàlagbà tí ó kọ́rẹ́lọ́wọ́ mú kí àwa ọmọdé ṣe kàyéfì nípa ohun tí yoo ṣẹlẹ̀. Ọmọ ọdún mẹ́sàn-⁠án ni mí, mo sì rántí pe eré alálàáfíà àwa ọmọdé yípadà di eré ogun.

BÍ Ó tilẹ̀ jẹ́ pé Finland kò lọ́wọ́ nínú Ogun Àgbáyé Kìn-⁠ín-ní (1914 sí 1918), ogun abẹ́lé run orílẹ̀-èdè náà ní 1918. Àwọn ìbátan àti ọ̀rẹ́ àtijọ́ dojú ohun ìjà kọ ẹnìkínní kejì nítorí ojú-ìwòye òṣèlú yíyàtọ̀síra. Ìdílé wa ẹlẹ́ni méje tọ́ ìkórìíra yìí wò. Bàbá mi, tí ó jẹ́ ẹni tí ń sọ èrò-ọ̀kan rẹ̀ jáde ní ṣàkó, ni a fi àṣẹ ọba mú tí a si sọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún méje. A dá a sílẹ̀ lẹ́yìn náà, ṣùgbọ́n nígbà náà ìlera rẹ̀ ni a ti bàjẹ́.

Ìdílé wa jìyà ebi àti àìsàn láàárín àkókò bíbanilẹ́rù yìí. Mẹ́ta nínú àwọn àbúrò mi obìnrin ṣaláìsí. Arákùnrin bàbá mi, tí ń gbé ní ìlú-ńlá Tampere, gbọ́ nípa ìdààmú wa ó sì késí bàbá àti màmá mi àti àwa ọmọ méjì tí ó ṣẹ́kù láti máa gbé pẹ̀lú òun.

Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, tí a ṣì ń gbé ni Tampere, mo pàdé ọmọbìnrin awẹ́lẹ́wà kan tí ń jẹ́ Sylvi. Òun ní ìtàn àtilẹ̀wá tí ó farajọ tèmi. Bàbá rẹ̀ ni a pa nínú ogun abẹ́lé náà, lẹ́yìn náà ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan fún ìdílé rẹ̀, Kaarlo (Kalle) Vesanto láti ìlú Pori, mú òun, arábìnrin rẹ̀, àti ìyá rẹ̀ sọ́dọ̀. O ṣètò ìṣẹ́ fún ìyá Sylvi àti fún àwọn ọmọdébìnrin náà láti lọ sí ilé-ẹ̀kọ́. Lẹ́yìn náà Sylvi ṣílọ sí Tampere láti wá iṣẹ́, níbẹ̀ ni a sì ti pàdé.

Àṣáálẹ́ kan tí Ó Yí Ìgbésí-Ayé Mi Padà

Ní 1928, Sylvi di àfẹ́sọ́nà mi, ní ọjọ́ kan a rìnrìn-àjò lọ sí Pori láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Kalle Vesanto àti ìdílé rẹ̀. Kò sí ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn tí ó tíì ní ìyọrísí bẹ́ẹ̀ lórí ìgbésí-ayé mi rí. Kalle ti fìgbà kan jẹ́ ẹlẹ́ṣin àti olùfi ẹṣin asáré kúṣẹ́kúṣẹ́ sáré ṣùgbọ́n ó ti jáwọ́ nínú òwò yẹn. Òun àti ìyàwó rẹ̀ ti di akéde onítara nípa ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun. Ìwé 1990 Yearbook of Jehovah’s Witnesses ṣàpèjúwe bí ó ṣe háyà àwọn ènìyàn láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ tí Ó Wàláàyè Nísinsìnyi Kì Yoo Kú Mọ́ Láé” sí ọwọ́ ìta ògiri ilé rẹ̀ alájà méjì. Gbólóhùn náà tóbi tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi rọrùn fún àwọn tí ó wà nínú àwọn ọkọ̀ ojú-irin tí ń yára kọjá láti kà á.

Ní alẹ́ yẹn èmi àti Kalle sọ̀rọ̀ di àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ kejì. “Èéṣe? Èéṣe? Èéṣe?” mó ń béèrè, Kalle sì ń ṣàlàyé. Níti gidi mo kọ́ ìpìlẹ̀ òtítọ́ Bibeli kí ilẹ̀ tó mọ́. Mo ṣe àkọsílẹ̀ gbogbo àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí ó ṣàlàyé onírúurú ẹ̀kọ́. Lẹ́yìn náà, nígbà tí mo padà dé ilé, mo wá ìwé àjákọ tí mò si kọ gbogbo ọ̀rọ̀ àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ náà sílẹ̀ láìṣẹ́ku ẹyọkan. Nítorí tí n kò tíì mọ Bibeli dunjú, mo lo ìwé àjákọ náà láti fi jẹ́rìí fún àwọn tí wọ́n wà ní ibi iṣẹ́ ìkọ́lé tí mo ti ń ṣiṣẹ́. Bí mo ti ń tú àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn èké fó, mo ń rí araàmi tí mò ń ṣàtúnsọ àwọn ọ̀rọ̀ Kalle: “A ti tàn yín jẹ jìnnàjìnnà, ẹ̀yin àwé yìí!”

Kalle fún mi ní àdírẹ́sì ilé kékeré kan ní Tampere níbi tí nǹkan bí 30 àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ti ń ṣe ìpàdé wọn. Ní igun kan níbẹ̀ ni mo máa ń kájọ sí ní ẹnu ilẹ̀kùn lẹ́gbẹ̀ẹ́ Arákùnrin Andersson, tí ó ni ilé kékeré náà. Wíwá sí ìpàdé mi jẹ́ ìdákúrekú, ṣùgbọ́n àdúrà ṣèrànwọ́ púpọ̀. Nígbà tí mo ń ní ìṣòro ńlá níbi iṣẹ́ nígbà kan, mo gbàdúrà pé: “Jọ̀wọ́, Ọlọrun, bí o bá lè mú mi borí àwọn ìṣòro wọ̀nyí, mo ṣèlérí láti lọ sí gbogbo ìpàdé.” Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan wulẹ̀ burú síi ni. Nígbà náà ni mo wá mọ̀ pé mò ń fún Jehofa ní ipò àfilélẹ̀, nítorí náà mo yí àdúrà mi padà sí: “Ohun yòówù kí ó ṣẹlẹ̀, mo ṣèlérí láti lọ sí gbogbo ìpàdé.” Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, àwọn ìpọ́njú mi lọ sílẹ̀, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ síí lọ sí ìpàdé déédéé.​—⁠1 Johannu 5:⁠14.

Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Wa ní Àwọn Ọdún Ìjímìjí

Ní 1929, èmi àti Sylvi ṣègbeyàwó, tí àwa méjèèjì sì fi àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ wa sí Jehofa hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi ninu omi ní 1934. Ní àwọn ọjọ́ wọnnì iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa ní nínú gbígbé ẹ̀rọ tí ń lu àwo rẹ́kọ́ọ̀dù àti rẹ́kọ́ọ̀dù dání lọ sí ilé àwọn ènìyàn tí a sì ń fi inúrere béèrè bí a bá lè sọ àsọyé Bibeli lọ́fẹ̀ẹ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ènìyàn ń gbà wá láàyè, lẹ́yìn tí wọn bá sì ti tẹ́tísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀-àsọyé tí a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ náà, wọ́n máa ń ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú wa, tí wọn sì ń gba díẹ̀ nínú àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ wa.

Pẹ̀lú ìyọ̀ọ̀da àwọn aláṣẹ, a ń gbé àwo àwọn àsọyé Bibeli kan náà wọ̀nyí sáfẹ́fẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀rọ gbohùngbohùn ní àwọn ọgbà ìtura. Ní àdúgbò a lè de àwọn gbohùngbohùn náà mọ́ òrùlé tàbí ọwọ̀n ihò èéfín. Ní àwọn ìgbà mìíràn a ń gbé àwọn àwo wọ̀nyí síi ní etí adágún níbi tí àwọn ará ìlú ti péjọ ní ogunlọ́gọ̀ wọn. A tilẹ̀ máa ń gbé ẹ̀rọ gbohùngbohùn náà sínú ọkọ̀ ojú-omi kan tí a ó sì rọra máa tukọ̀ jẹ́jẹ́ ní etídò náà. Ní àwọn ọjọ́ Sunday a óò jáde lọ fún ìwàásù ní àrọ́ko nínú bọ́ọ̀sì, ní ìgbaradì pẹ̀lú àwọn ẹ̀rọ gbohùngbohùn wa ṣíṣeyebíye àti ọ̀pọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́.

Ìyípadà kan Tí Ń Dán Ìgbàgbọ́ Wa Wò

Ní 1938, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ìsìn alákòókò-kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà, ṣùgbọ́n mo ń báa nìṣó gẹ́gẹ́ bíi bíríkìlà kan. Ní ìgbà ìrúwé tí ó tẹ̀lé e mo gba ìkésíni láti ẹ̀ka ọ́fíìsì Society láti di òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò, tí a ń pè ni alábòójútó àyíká nísinsìnyí. Ṣíṣe ìpinnu láti tẹ́wọ́gbà á kò rọrùn rárá nítorí mo gbádùn ṣíṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọ wa ní Tampere. Yàtọ̀ sí èyí, a ní ilé àdáni; a ní ọmọkùnrin ọlọ́dún mẹ́fà kan, Arto, tí kò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́; Sylvi sì ń gbádùn iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òǹtàjà ní ṣọ́ọ̀bù. Síbẹ̀, lẹ́yìn fíforíkorí, mo tẹ́wọ́gba àǹfààní àfikún iṣẹ́-ìsìn Ìjọba yìí.​—⁠Matteu 6:⁠33.

Lẹ́yìn náà ni ìṣòro mìíràn bẹ̀rẹ̀. Ogun bẹ́ sílẹ̀ ní November 30, 1939, nígbà tí àwọn ọmọ ogun Soviet yan wọ ilẹ̀ Finland. Ogun náà, tí a pè ní Ogun Ìgbà Òtútù, jà di March 1940, nígbà tí Finland gbà láti ṣe àdéhùn àlàáfíà. Ṣe ni ó dàbí ìgbà tí ìṣẹ̀dá pàápàá gbógun, nítorí ìyẹn ni ìgbà òtútù tí mo rántí pé ó mótùútù jùlọ. Mo ń lo kẹ̀kẹ́ láti lọ láti ìjọ kan sí òmíràn bí ìwọ̀n ìmótùútù ti wà ní ìwọ̀n 30 sí ìsàlẹ̀ òdo lórí òṣùwọ̀n Celsius!

Ní 1940 iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a fòfindè ní Finland. Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn náà ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ní Finland ni a sọ sẹ́wọ̀n tí a sì fagbára mú wọn láti lálàṣí níbẹ̀ nínú ipò rírorò. Ọpẹ́ ni pé, ó ṣeéṣe fún mi láti ṣiṣẹ́sin àwọn ìjọ jálẹ̀ ogun àgbáyé kejì, láti 1939 sí 1945. Èyí ń fi ọ̀pọ̀ ìgbà béèrè pé kí n fi Sylvi àti Arto sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù nígbà kọ̀ọ̀kan. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a ń fìgbà gbogbo halẹ̀ láti fi àṣẹ ọba mú mi nítorí bíbá iṣẹ́ aláìbófinmu kan nìṣó.

Mo gbọ́dọ̀ ti jẹ́ ohun àfiṣèranwò kan, ní gígun kẹ̀kẹ́ tí a di àpótí aṣọ, àpò ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́, ẹ̀rọ tí ń lu àwo rẹ́kọ́ọ̀dù àti àwọn rẹ́kọ́ọ̀dù lé. Ìdí kan tí mo fi ń gbé ẹ̀rọ rẹ́kọ́ọ̀dù náà ni láti fihàn, bí ọ̀ràn ìfàṣẹ ọba múni bá ṣẹlẹ̀, pé èmi kìí ṣe afimúfínlẹ̀ olùlo abùradà agbéniwálẹ̀ tí ń ṣamí fún ilẹ̀ Russia. Ṣe ẹ ríi, mo lè jiyàn pé bí mo bà ti jẹ́ olùlo abùradà agbéniwálẹ̀ ni, àwọn rẹ́kọ́ọ̀dù náà ìbá ti fọ́ nígbà fífò náà.

Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà kan tí mó ń ṣèbẹ̀wò sí àdúgbò kan tí a ti kìlọ̀ fún nípa amí kan, ìdílé Ẹlẹ́rìí kan ṣì mí mú fún ọ̀kan. Mo kanlẹ̀kùn ilé wọn ní ọ̀gànjọ́ òru ìgbà òtútù kan, tí ẹ̀rù sì bà wọ́n láti ṣílẹ̀kùn. Nítorí èyí mo lo òru náà nínú àká, mo farapamọ́ sínú koríko gbígbẹ láti mú kí ara mi lọ́wọ́ọ́wọ́. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì àṣìmú náà ni a yanjú, mo sì gbọ́dọ̀ sọ ọ́ pé, fún gbogbo ìyókù ìbẹ̀wò mi, àwọn mẹ́ḿbà ìdílé náà fi ọ̀làwọ́ àrà-ọ̀tọ̀ hàn sí mi!

Ní àwọn ọdún ogun náà, kìkì èmi àti Arákùnrin Johannes Koskinen nìkan ni a ṣiṣẹ́sin àwọn ìjọ tí ń bẹ ní àárín àti àríwá Finland. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ní agbègbè títóbi láti bójútó, nǹkan bí 600 kìlómítà ní gígùn. A ní ọ̀pọ̀ ìjọ láti bẹ̀wò tí o fi jẹ́ pé kìkì ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta ni a lè lò pẹ̀lú ìjọ kọ̀ọ̀kan. Ó ṣọ̀wọ́n kí ọkọ̀ ojú-irin dé sí àsìkò, àwọn bọ́ọ̀sì kò sì tó nǹkan wọ́n sì ń kún fọ́fọ́ débi pé ó ń yà wá lẹnú bí a ṣe ń dé ibi tí à ń lọ.

Àwọn Ìmóríbọ́ Nínú Ewu

Lẹ́ẹ̀kan rí, ní ìbẹ̀rẹ̀ Ogun Ìgbà Òtútù, mo lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Helsinki tí mo sì gbé páálí wíwúwo mẹ́rin ti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ti fòfindè tí n ó fi ọkọ̀ ojú-irin gbé lọ sí àwọn ìjọ. Nígbà tí mo wà ní ibùdókọ̀ ojú-irin Riihimäki, agogo ìdágìrì nípa ìgbójú sánmà kọluni bẹ̀rẹ̀ síí dún. Àwọn ṣójà inú ọkọ̀ ojú-irin náà wọ aṣọ ìgbotútù wọn, tí wọ́n sì sọ fún àwọn èrò pé kí wọ́n fi ọkọ̀ náà sílẹ̀ kíákíá kí wọ́n sì forílé pápá kan tí ó wà ní òdìkejì ibùdókọ̀ náà.

Mo sọ fún àwọn ṣójà náà láti gbé àwọn páálí mi, ní sísọ ìjẹ́pàtàkì rẹ̀ fún wọn. Mẹ́rin nínú wọn gbé páálí kọ̀ọ̀kan, tí a sì sáré kọjá orí pápá náà tí ojò-dídì ti bò ní nǹkan bí 200 mítà. A nà sílẹ̀ gbalaja, tí ẹnìkan sì jágbe mọ́ mi pé: “Éè, ọ̀gbẹ́ni, máṣe mira pẹ́kẹ́! Bí àwọn atòkèjubọ́m̀bù bá ṣàkíyèsí ìmira èyíkéyìí, wọn yóò dáná sí wa lára.” Mo tọpinpin púpọ̀ tó débi tí mo fi fi tíṣọ̀ratìṣọ́ra yí ọrùn mi láti wo ojú sánmà, níbi tí mo ti ka ọkọ̀ òfuurufú 28!

Lójijì, bọ́m̀bù tí ó búgbàù mi ilẹ̀ náà tìtì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dá ibùdókọ̀ náà sí, ọkọ̀ ojú-irin nínú èyí tí a ti ń rìnrìn-àjò náà faragbọta. Ẹ wo ìran ṣíṣàjèjì tí àfọ́kù ọkọ̀ àti ọnà ọkọ̀ ojú-irin tí ó ti lọ́pọ̀ náà jẹ́! Ní òwúrọ̀ ọjọ kejì ó ṣeéṣe fún mi láti máa bá ìrin àjò mi nìṣó pẹ̀lú àwọn páálí náà, tí àwọn ṣójà náà sí ń ba tiwọn lọ nínú ọkọ̀ ojú-irin mìíràn. Ọ̀kan nínú wọn di Ẹlẹ́rìí lẹ́yìn ogun náà, tí ó sì sọ fún mi pé àwọn ṣójà náà sọ̀rọ̀ lẹ́yìn náà nípa ọ̀gbẹ́ni ṣíṣàjèjì kan pẹ̀lú àwọn páálí rẹ̀.

Nígbà kan lẹ́yìn náà Arákùnrin Koskinen, ni a fi àṣẹ ọba mú ṣáájú kí ó tó bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-irin, níbi tí ó tí ń lọ láti bẹ ìjọ kékeré kan wò ní Rovaniemi ní àríwá Finland. A rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ti hu ìwàkíwà sí i. Nígbà tí ó tó àkókò fún mi láti bẹ ìjọ yìí kan náà wò, mo ṣètò láti sọ̀ nínú ọkọ̀ ojú-irin náà ní ibùdókọ̀ kékeré kan ní Koivu. Níbẹ̀ ni Arábìnrin Helmi Pallari ti ṣètò fún mi láti bá ìrìn-àjò yòókù nìṣó nínú ọkọ̀ akówàrà kan. Ìbẹ̀wò mi sí Ìjọ Rovaniemi yọrísírere. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí mo fi ibẹ̀ sílẹ̀ mo kó sínú ìṣòro.

Ní ojú ọ̀nà sí ibùdókọ̀ ojú-irin náà, èmi àti alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ mi ṣalábàápàdé àwọn ológun méjì kan tí wọn ń yẹ ìwé gbogbo àwọn tí ń kọjá wò. Mo sọ fún un pé, “Máṣe wo ojú wọn. Máa wo ọ̀kánkán sàn án.” A gba àárín wọn kọjá bí ẹni pé wọn kò fìgbàkan sí níbẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ síí lé wa. Lákòótán, ní ibùdókọ̀ ojú-irin náà, ó ṣeéṣe fún mi láti yẹra fún wọn láàárín èrò náà kí ń sì bẹ́ sínú ọkọ̀ ojú-irin kan tí ń lọ. Kò ṣàìsí àwọn ohun arùmọ̀lárasókè nínú iṣẹ́ ìrìn-àjò ní àwọn ọjọ́ wọnnì!

Lẹ́ẹ̀kanṣoṣo ni a fàṣẹ ọba mú mi tí a sì mú mi lọ síwájú ìgbìmọ̀ aráàlú tí ń gbanisíṣẹ́ ológun. Èrò wọn ni láti rán mi lọ sí ojú ogun. Ṣùgbọ́n tẹlifóònù dún, tí ọ̀gá ṣójà tí ó fẹ́ fi ọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò sì dáhùn. Mo gbọ́ ohùn ẹni tí ń sọ̀rọ̀ náà tí ń kígbe pé: “Kíló dé ná tí ó fi jẹ́ pé àwọn ọkùnrin olókùnrùn, aláìwúlò wọ̀nyí ni ẹ ń fi ránṣẹ́? Gbogbo ohun tí a lè ṣe ni kí a dá wọn padà. A nílò àwọn tí ara wọn dá ṣáṣá fún iṣẹ́!” Ọpẹ́ ni pé mo ní ìwé ẹ̀rí ìṣègùn pẹ̀lú mi tí ó sọ nípa ìṣòro ìlera tí mo ní. Nígbà tí mo fi èyí hàn, a yọ̀ọ̀da mi tí mo sì ń bá iṣẹ́ mi nìṣó nínú àwọn ìjọ láìsí ìdálọ́wọ́kọ́!

Ṣíṣèrànwọ́ Níbi Ìgbẹ́jọ́ Kan

Ìṣesí eléwèlè ìgbà ogun ṣì ń báa nìṣó láìdẹwọ́, a fàṣẹ ọba mú ọ̀rẹ́ mi Ahti Laeste. Ìyàwó rẹ̀ pè mí. Nígbà tí mo lọ sí ilé wọn, mo rí àkọsílẹ̀ àwọn ọlọ́pàá àdúgbò náà láàárín ìwé rẹ̀ tí ó yọ̀ọ̀da fún Ahti láti lo àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti gbàsílẹ̀ ní àwọn ọgbà ìtura gbogbogbòò ní ìlú-ńlá náà. A dé kóòtù pẹ̀lú àwọn àkọsílẹ̀ náà. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ka ẹ̀sùn náà, mo fún Arákùnrin Laeste ní àkọsílẹ̀ náà. Adájọ́ náà ní kí ṣójà kan gbé ẹ̀rọ rẹ́kọ́ọ̀dù kan àti díẹ̀ nínú ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ Bibeli tí a gbàsílẹ̀ wá kí kóòtù náà lè tẹ́tísí i. Lẹ́yìn títẹ́tísílẹ̀ sí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan, adájọ́ náà sọ pé òun kò lè rí ohunkóhun tí kò yẹ nínú ohun tí a sọ.

Lẹ́yìn náà èmi, Ahti àti aya rẹ̀, ni a sọ fún pé kí a jáde sì ọ̀dẹ̀dẹ̀ láti dúró de ìpinnu kóòtù. Ibẹ̀ ni a dúró sí ní inú-fu-àyà-fu. Níkẹyìn a gbọ́ ohùn kan tí ó sọ pé: “Olùjẹ́jọ́, jọ̀wọ́ wọlé wá.” Arákùnrin Laeste ni a dá sílẹ̀ lómìnira! Ọkàn wa kún níti tòótọ́ fún ọpẹ́ sí Jehofa bí a ṣe ń ba iṣẹ́ wa nìṣó, Arákùnrin àti Arábìnrin Laeste nínú iṣẹ́ tiwọn ní ìjọ àdúgbò, àti èmi nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ arìnrìn-àjò.

Ogun Náà Parí​—⁠Iṣẹ́-Ìsìn Wa Ń Báa Nìṣó

Ìfòfindè lórí iṣẹ́ ìwàásù wa ni a mú kúrò nígbà tí ogun parí, tí a sì tú àwọn ará sílẹ̀ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Lákòókò ọ̀pọ̀ ọdún iṣẹ́ìsìn mi, ipa tí àwọn Kristian arábìnrin sà nínú iṣẹ́ Ìjọba náà àti ní ṣíṣètìlẹ́yìn fún àwọn ọkọ wọn wú mi lórí púpọ̀púpọ̀. Ní pàtàkì ni mo kún fún ọpẹ̀ fún ìrúbọ àti ìtìlẹ́yìn Sylvi. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, mo lè ma báa lọ nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò fún ọdún 33 láìdáwọ́dúró àti lẹ́yìn náà láti ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.

Èmi àti Sylvi fún Arto níṣìírí láti bẹ̀rẹ̀ síí ṣe aṣáájú-ọ̀nà nígbà tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀, kí ó kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì, kí ó sì lọ sí Watchtower Bible School of Gilead ní United States. Ó kẹ́kọ̀ọ́yege ní Gileadi ní 1953. Lẹ́yìn náà ó fẹ́ Eeva, wọ́n sì ti jùmọ̀ nípìn-⁠ín nínú onírúurú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún, títíkan iṣẹ́ àyíká, iṣẹ́-ìsìn Beteli, àti iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ní 1988 wọ́n ṣí wá sí Tampere, ìlú-ńlá tí a ń gbé, láti tọ́jú èmi àti Sylvi nígbà tí wọ́n ń báa nìṣó gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.

Èmi àti Sylvi ti gbádùn ìgbésí-ayé dídọ́ṣọ̀ tí ó sì níbùkún pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ohun ìrántí láti fún wa níṣìírí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé okun wa ti joro púpọ̀púpọ̀. Ó jẹ́ èrè-ẹ̀san jùlọ láti ronú nípa ìdàgbàsókè tí a ti ní. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ síí ṣèbẹ̀wò sí àwọn ìjọ ní 1939, àwọn akéde Ìjọba 865 ni wọ́n wà ní Finland, ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọn ti ju 18,000 lọ!

Èmi kò mọ̀ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ìsìn alákòókò-kíkún nígbà náà lọ́hùn-⁠ún ní 1938 pé ọdún 55 lẹ́yìn náà èmi yóò ṣì máa gbádùn níní ìpín nínú rẹ̀. Láìka ti ọjọ́ ogbó sí, a ń báa lọ nínú agbára Jehofa, ní wíwo iwájú fún èrè-ẹ̀san tí a ṣèlérí fún wa. A nígbọkànlé nínú ọ̀rọ̀ onípsalmu náà pé: “Oluwa pọ̀ ní oore; àánú rẹ̀ kò nípẹ̀kun; àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìrandíran.”​—⁠Orin Dafidi 100:⁠5.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Leo àti Sylvi Kallio fi àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ wọn sí Jehofa hàn ní 1934

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Fọ́tò Leo àti Sylvi ti lọ́ọ́lọ́ọ́ bí wọ́n ti ń súnmọ́ 60 ọdún nínú iṣẹ́-ìsìn àṣekára

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́