Iwọ Ha Ranti Bi?
Iwọ ha ti ri awọn itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà ẹnu aipẹ yii pé wọn niyelori lọna gbigbeṣẹ fun ọ bi? Nigba naa, eeṣe ti o kò fi dán agbara iranti rẹ wo pẹlu awọn ohun ti o tẹle e yii:
▫ Ki ni ète pataki kan nipa awọn iwosan Jesu? Wọn ṣapejuwe kedere, fun iṣiri awọn ogunlọgọ ńlá ti awọn ẹni bi agutan lonii, pé awọn olùla Amagẹdọni já ni a o mú larada ni ọna ti ó láàlà laipẹ lẹhin Amagẹdọni. (Aisaya 33:24; 35:5, 6) —12/15, oju-iwe 12.
▫ Eeṣe ti a fi nilo irannileti lemọlemọ pe: “Ẹ ni iforiti ninu adura”? (Roomu 12:12) Awọn ikimọlẹ ati awọn ẹru-iṣẹ igbesi-aye lè rìn wá mọ́lẹ̀ tobẹẹ gẹẹ debi pe a lè gbagbe lati gbadura. Tabi awọn iṣoro lè bò wá mọ́lẹ̀ ki ó sì mú wa dawọ yíyọ̀ ninu ireti Ijọba duro, ki a sì dakẹ gbigbadura paapaa. Nipa bayii, a nilo awọn irannileti ti ń fún wa niṣiiri lati gbadura ati ni ọna yii ki a fà sunmọ Jehofa pẹkipẹki ju ti igbakigbari lọ.—12/15, oju-iwe 14.
▫ Ki ni ó fihan pe Ìkún-omi ọjọ Noa fi àmì ti kò ṣee parẹ sara iran eniyan? A ti foju diwọn rẹ̀ pe iye ti ó ju 500 awọn ìtàn-àròsọ Ìkún-omi ni iye ti o ju 250 ẹ̀yà èdè ati awọn eniyan ń sọ. Awọn ifarajọra ipilẹ diẹ ni a lè rí ninu gbogbo awọn ìtàn-àròsọ wọnyi.—1/15, oju-iwe 5.
▫ Bawo ni awọn wolii èké lonii ṣe dabi awọn wọnni ti wọn wà ni akoko Jeremaya? Awọn wolii èké lonii jẹwọ pe awọn ń ṣoju fun Ọlọrun, ṣugbọn wọn jí awọn ọrọ Ọlọrun nipa wiwaasu awọn ohun ti ó pín awọn eniyan níyà kuro ninu ohun ti Bibeli wí niti gidi. Ni pataki ni eyi jẹ́ otitọ niti ẹ̀kọ́ nipa Ijọba naa. (Jeremaya 23:30) —2/1, oju-iwe 4.
▫ Ki ni ó tumọ si nigba ti a bá bamtisi ẹnikan ni orukọ ẹmi mímọ́? Eyi tumọsi pe ẹni naa ti a ń bamtisi ti pinnu lati fọwọsowọpọ pẹlu ẹmi naa, ni ṣiṣai ṣe ohunkohun ti yoo dí iṣiṣẹ rẹ̀ lọwọ laaarin awọn eniyan Jehofa. Fun idi yii, ẹni yẹn gbọdọ fọwọsowọpọ pẹlu ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu ati pẹlu ètò alagba ninu ìjọ. (Heberu 13:7, 17; 1 Peteru 5:1-4) —2/1, oju-iwe 18.
▫ Eeṣe ti ijọsin ère fi ní ipa buburu tobẹẹ lori olujọsin? Bibeli fihan pe awọn ère jẹ́ ohun ẹlẹgbin si Jehofa Ọlọrun kò sì wúlò ninu ríran awọn olufọkansin lọwọ lati tubọ sunmọ Ọlọrun. (Deutaronomi 7:25; Saamu 115:4-8) Satani Eṣu “ti sọ ọkàn” awọn eniyan “di afọju” ki imọlẹ otitọ ma baa “mọlẹ ninu wọn.” (2 Kọrinti 4:4) Nitori naa nigba ti ó bá ń júbà ère kan, ẹnikan niti tootọ ń ṣiṣẹsin ire awọn ẹmi eṣu. (1 Kọrinti 10:19, 20)—2/15, oju-iwe 6 si 7.
▫ Eeṣe ti a fi ka awọn agutan si ohun àmúṣọrọ̀ ti o niye lori ni awọn akoko ti a kọ Bibeli?
Irun agutan jẹ́ ohun àmúṣọrọ̀ ti ń sọ araarẹ̀ dọ̀tun a sì lè lò ó lati ṣe aṣọ fun idile tabi a lè tà á. Awọn ìwo àgbò ni a lò lati kéde Jubili tabi ni a lè lò lati fọn fèrè igbe ìdágìrì tabi ìfọgbọ́ndarí ogun. Niwọn bi awọn agutan ti wà lara awọn ẹran mímọ́ ti awọn ọmọ Isirẹli lè jẹ, agbo agutan kan mú ipese ounjẹ daju, ó sì pese orisun wàrà deedee fun mímu tabi fun ṣiṣe wàràkàṣì.—3/1, oju-iwe 24 si 25.
▫ Ki ni awọn olùfẹ́ Ọlọrun ń beere fun nigba ti wọn bá gbadura fun Ijọba Ọlọrun lati dé? (Matiu 6:10) Wọn ń beere pe ki Ijọba Ọlọrun gbé igbesẹ onipinnu nipa pípa awọn eto akoso àtọwọ́dá eniyan, ti wọn ti kuna lati gbé ni ibamu pẹlu ileri wọn lati mú alaafia ati ailewu wá run. (Daniẹli 2:44)—3/15, oju-iwe 6.
▫ Awọn wo ni Awọn Agbeja Igbagbọ, wọn ha sì fi Mẹtalọkan kọni bi? Awọn Agbeja Igbagbọ ni awọn ọkunrin ṣọọṣi ti wọn gbé ni apa ti ó kẹhin ninu ọrundun keji. Wọn kọwe lati gbeja isin Kristẹni ti wọn mọ̀ ni ilodisi awọn ọgbọn imọ-ọran ti ń gbilẹ ninu ayé Roomu. Kò sí ọkankan ninu wọn ti ó fi Mẹtalọkan kọni.—4/1, oju-iwe 24 si 29.
▫ Njẹ Sekaraya, baba Johanu Arinibọmi, ni a sọ di aditi ati alailesọrọ pẹlu, bi o ti dabi ẹni pe Luuku 1:62 fihan? Geburẹli sọ pe agbara ọrọ sísọ Sekaraya ni a o nipa le lori, kì í ṣe agbara igbọran rẹ̀. (Luuku 1:18-20) Luuku 1:64 wi pe: “Ẹnu [Sekaraya] sì ṣí lọ́gán, okùn ahọn rẹ̀ sì tú, ó sì sọrọ.” Ṣakiyesi pe, a kò mẹnukan an rárá níhìn-ín pe ìgbọ́ràn rẹ̀ ni a ti nipa le lori ni ọ̀nà eyikeyii. Mimẹnukan “apẹẹrẹ” ni Luuku 1:62 lè tumọ si pe awọn ifaraṣapejuwe kan ni a ṣe lati fa ipinnu Sekaraya jade.—4/1, oju-iwe 31.