ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 4/15 ojú ìwé 31
  • Ikede

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ikede
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Itilẹhin fun Awọn Igbimọ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso
  • Bí A Ṣe Ṣètò Ìgbìmọ̀ Olùdarí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ipese Jehofa, “Awọn Ẹni Ti a Fi Funni”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ta Ló Ń Darí Àwa Èèyàn Ọlọ́run Lónìí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Ọ̀nà Wo Ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí Gbà Ń Ṣiṣẹ́ Lóde Òní?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 4/15 ojú ìwé 31

Ikede

Itilẹhin fun Awọn Igbimọ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso

Awọn mẹmba Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ti iye wọn jẹ 12 ní bayii, ń ba a lọ lati fi iṣotitọ ṣiṣẹsin ninu awọn iṣẹ ayanfunni wọn. Wọn a maa kún fun ọpẹ nigba gbogbo fun awọn mẹmba “ogunlọgọ ńlá” aduroṣinṣin ti ń pọ sii fun itilẹhin onitara wọn. (Iṣipaya 7:9, 15) Ni oju-iwoye ibisi gigadabu kari ayé, ó jọ bi ohun bibojumu ni akoko yii lati pese itilẹhin afikun diẹ fun Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Nitori naa a ti pinnu rẹ̀ lati ké si awọn oluranlọwọ melookan, ni pataki lati ara awọn ogunlọgọ ńlá, lati ṣajọpin ninu awọn ipade awọn Igbimọ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso kọọkan, iyẹn ni, Awọn Igbimọ ti ó ń rí sí ọ̀ràn Awọn Oṣiṣẹ, Iwe Títẹ̀, Iṣẹ-Isin, Ikọnilẹkọọ, ati Iwe-Kikọ. Nipa bayii, iye awọn ti ń wá si awọn ipade awọn igbimọ kọọkan wọnyi ni a o mú ga síi dori meje tabi mẹjọ. Labẹ idari awọn mẹmba igbimọ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, awọn oluranlọwọ wọnyi yoo kópa ninu awọn ijiroro wọn yoo sì ṣe oniruuru awọn iṣẹ ayanfunni ti a o fi fun wọn nipasẹ igbimọ naa. Iṣeto titun yii maa bẹrẹ iṣẹ ni May 1, 1992.

Fun ọpọlọpọ ọdun nisinsinyi, iye Awọn Ẹlẹ́rìí aṣẹku ẹni ami ororo ti ń kere sii, nigba ti iye awọn ogunlọgọ ńlá ti ń pọ sii rekọja awọn ifojusọna wa didara julọ. (Aisaya 60:22) A ti dupẹ lọwọ Jehofa tó fun imugbooro agbayanu yii! Nigba ti a fi imoore tẹwọgba orukọ titun naa, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ni 1931, gongo iye awọn akede Ijọba jẹ́ 39,372, ti ọpọ julọ ninu wọn jẹwọ jíjẹ́ arakunrin ẹni ami ororo ti Kristi. (Aisaya 43:10-12; Heberu 2:11) Ọgọta ọdun lẹhin naa, ni 1991, gongo awọn akede kari ayé jẹ́ 4,278,820, ti kìkì 8,850 ninu wọn jẹwọ jíjẹ́ aṣẹku ẹni ami ororo. Gẹgẹ bi a ti fojusọna fun un ninu imọlẹ Iwe Mimọ, “awọn ogunlọgọ ńlá” ti tayọ awọn aṣẹku ti “agbo kekere” ni iye nisinsinyi pẹlu ohun ti ó ju 480 si 1 lọ. (Luuku 12:32; Iṣipaya 7:4-9) Ni bibojuto awọn ire Ijọba ti ń gbooro sii, ó daju pe aṣẹku naa nilo wọn sì mọriri ifọwọsowọpọ ati itilẹhin ogunlọgọ ńlá.

Gẹgẹ bi a ti ṣalaye ninu itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà yii, awujọ kan wà ti ń ṣiṣẹsin pẹlu Isirẹli tẹmi lonii ti ó ṣee fiwera pẹlu awọn Netinimu ati awọn ọmọkunrin awọn iranṣẹ Solomọni ti wọn pada lati igbekun Babiloni pẹlu awọn aṣẹku Juu; awọn ti wọn kì í ṣe ọmọ Isirẹli wọnni paapaa kọja iye awọn ọmọ Lefi ti ń pada. (Ẹsira 2:40-58; 8:15-20) “Awọn ẹni ti a fi funni” lati inu awọn ogunlọgọ ńlá ti oni ni awọn Kristẹni ọkunrin ti wọn dàgbàdénú ti wọn ti ni iriri ti o pọ̀ gẹgẹ bi iyọrisi bibojuto iṣabojuto awọn ẹ̀ka, ninu iṣẹ arinrin-ajo, ati laaarin awọn ìjọ 66,000 ti a fidii wọn mulẹ nisinsinyi jakejado ilẹ̀-ayé.

Lẹnu aipẹ yii, Awọn Ile-Ẹkọ Iṣẹ-Ojiṣẹ Ijọba ni a ń ṣe kari ayé fun itọni awọn alaboojuto ati awọn iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ ti ń ṣetilẹhin fun wọn. Ni United States nikan, awọn alaboojuto 59,420 ti lọ. “Awọn àgbà ọkunrin” wọnyi ni a tipa bayii mura wọn silẹ lati mu ẹru-iṣẹ wọn ṣẹ lọna gbigbeṣẹ sii.—1 Peteru 5:1-3; fiwe Efesu 4:8, 11.

Ni orile-iṣẹ Brooklyn ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, “awọn ẹni ti a fi funni” diẹ ti ṣiṣẹsin fun ọpọ jantirẹrẹ ọdun. Iwọnyi ní awọn alaboojuto ti wọn dàgbàdénú ninu awọn ogunlọgọ ńlá ti wọn ti jèrè òye ati iriri jaburata ninu. Nipa bayii, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti yan iwọnba diẹ ninu iru awọn alaboojuto bẹẹ lati ṣetilẹhin ninu awọn ipade awọn igbimọ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Iwọnyi kò fi dandan jẹ́ awọn ọkunrin ti wọn ni akọsilẹ iṣẹ-isin gigun julọ. Kaka bẹẹ, wọn jẹ awọn ọkunrin adàgbàdénú, oniriiri pẹlu awọn itootun ti o mú wọn yẹ fun ṣiṣe itilẹhin ninu awọn pápá pataki kan. Yíyàn ti a yàn wọn lati ṣiṣẹ pẹlu igbimọ kan kò fun wọn ni ipo akanṣe kan. Gẹgẹ bi Jesu ti sọ nipa awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, “ará ni gbogbo yin.” (Matiu 23:8) Bi o ti wu ki o ri, ọpọ julọ ni a o fi si ìkáwọ́ awọn ọkunrin wọnyi, ati nitori idi eyi ‘ọpọ julọ ni a o beere lọwọ wọn.’—Luuku 12:48.

A layọ ninu itẹsiwaju eto-ajọ Jehofa lonii. Ni ohun ti ó ju ọdun mẹwaa ti ó kọja lọ, ohun ti o ti fẹrẹẹ tó ibisi ipin 100 ninu ọgọrun-un ni o ti wà ninu iye awọn wọnni ti wọn ń ṣeranṣẹ ninu pápá, ni ìlà pẹlu asọtẹlẹ nipa Dafidi Titobi ju naa, Jesu Kristi: “Ijọba yoo bí si i, alaafia kì yoo ní ipẹkun.” (Aisaya 9:7) Ni ọna kan naa ti awọn Netinimu gbà ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn alufaa ni títún awọn ogiri Jerusalẹmu ṣe, bakan naa lonii asọtẹlẹ naa nipa eto-ajọ Jehofa ni a ń mú ṣẹ: “Awọn ọmọ àlejò yoo sì mọ odi rẹ.” (Aisaya 60:10; Nehemaya 3:22, 26) Awọn Netinimu ode-oni ni a nilati yìn fun ìtara ti wọn fihan ninu gbígbé ijọsin otitọ ró, ni ṣiṣetilẹhin fun “awọn alufaa Jehofa” ninu iṣẹ eyikeyii tabi iṣẹ-isin ti a lè yàn funni ninu eto-ajọ kari ayé ti Jehofa.—Aisaya 61:5, 6, NW.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́