ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 4/15 ojú ìwé 12-17
  • Ipese Jehofa, “Awọn Ẹni Ti a Fi Funni”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ipese Jehofa, “Awọn Ẹni Ti a Fi Funni”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ọmọ Isirẹli Pada Lati Babiloni
  • Awọn Ti Kì í ṣe Ọmọ Isirẹli Pẹlu Pada
  • Alábàádọ́gba Ode-Oni Kan
  • A Fi Funni fun Iṣẹ-Isin Akanṣe
  • Yiyọnda Araawa Lonii
  • Ikede
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ẹ́sírà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • “Israeli Ọlọrun” àti “Ogunlọ́gọ̀ Ńlá”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àwọn Olùgbé Papọ̀ Ní “Ilẹ̀” Tí A Múpadàbọ̀sípò
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 4/15 ojú ìwé 12-17

Ipese Jehofa, “Awọn Ẹni Ti a Fi Funni”

“Awọn àlejò yoo sì duro, wọn ó sì bọ́ ọ̀wọ́ ẹran yin.”—AISAYA 61:5.

1. Eeṣe ti ọrọ naa “olufunni” ṣe lè pe Jehofa wá sinu ọkàn wa?

OLÙFÚNNI ọlọ́yàyà wo ni Ọlọrun jẹ́! Apọsiteli Pọọlu sọ pe: “[Jehofa] ni o fi ìyè ati eemi ati ohun gbogbo fun gbogbo eniyan.” (Iṣe 17:25) Ẹnikọọkan wa lè janfaani lati inu rironu siwa-sẹhin lori ọpọlọpọ ‘ẹbun rere ati ọrẹ pipe’ ti a rigba lati ọdọ Ọlọrun.—Jakobu 1:5, 17; Saamu 29:11; Matiu 7:7; 10:19; 13:12; 21:43.

2, 3. (a) Bawo ni a ṣe nilati dahun pada si awọn ẹbun Ọlọrun? (b) Ni ero itumọ wo ni awọn ọmọ Lefi fi jẹ́ “awọn ẹni ti a fi funni”?

2 Pẹlu idi rere onisaamu naa beere lọwọ araarẹ bi oun ṣe lè san an pada fun Jehofa. (Saamu 116:12) Ẹlẹdaa wa kò nilo ohunkohun ti awọn eniyan lè ní tabi lè fi funni niti gidi. (Saamu 50:10, 12) Bi o ti wu ki o ri, Jehofa fihan, pe ó tẹ́ oun lọrun nigba ti awọn eniyan bá fi imọriri fi araawọn fun ijọsin tootọ. (Fiwe Heberu 10:5-7.) Nipasẹ iyasimimọ, gbogbo eniyan gbọdọ yọọda araawọn fun Ẹlẹdaa wọn ẹni ti ó lè nasẹ awọn afikun anfaani de ọdọ wọn lẹhin naa, gẹgẹ bi ọ̀ràn ti ri pẹlu awọn ọmọ Lefi igbaani. Bi o tilẹ jẹ pe gbogbo awọn ọmọ Isirẹli ni a yà si mimọ fun Ọlọrun, ó yan idile Lefi ti Aaroni gẹgẹ bi alufaa lati ṣe irubọ ninu àgọ́-ìsìn ati tẹmpili. Ki ni nipa iyooku awọn ọmọ Lefi?

3 Jehofa sọ fun Mose pe: “Mú awọn ẹ̀yà Lefi wá si tosi . . . Wọn sì gbọdọ bojuto gbogbo ohun eelo àgọ́ ipade . . . Iwọ sì gbọdọ fi awọn ọmọ Lefi fun Aaroni ati awọn ọmọkunrin rẹ̀. Wọn jẹ́ awọn ẹni ti a fi funni [Heberu, nethu·nimʹ], ti a fi fun un lati inu awọn ọmọ Isirẹli.” (Numeri 3:6, 8, 9, 41, NW) Awọn ọmọ Lefi ni a “fi fun” Aaroni lati ṣe awọn iṣẹ abojuto ninu iṣẹ-isin àgọ́-ìsìn, nitori naa Ọlọrun lè wi pe: “Awọn ti a fi funni ni wọn, ti a fi fun mi lati inu awọn ọmọkunrin Isirẹli.” (Numeri 8:16, 19; 18:6, NW) Awọn ọmọ Lefi kan ṣe awọn iṣẹ rirọrun; awọn miiran rí awọn anfaani titayọ gbà, iru bii kikọni ni awọn ofin Ọlọrun. (Numeri 1:50, 51; 1 Kironika 6:48; 23:3, 4, 24-32; 2 Kironika 35:3-5) Ẹ jẹ ki a wá yí igbeyẹwo wa si awọn eniyan miiran ti a “fi funni” ati alabaadọgba ti ode-oni kan.

Awọn Ọmọ Isirẹli Pada Lati Babiloni

4, 5. (a) Awọn ọmọ Isirẹli wo ni wọn pada lati igbekun ni Babiloni? (b) Ni awọn akoko ode-oni, ki ni o baradọgba pẹlu ipada awọn ọmọ Isirẹli lati igbekun?

4 Ẹsira ati Nehemaya sọ nipa bi aṣẹku awọn ọmọ Isirẹli kan, tí Gomina Serubabeli jẹ́ aṣiwaju fun, ṣe pada lati Babiloni si ilẹ wọn, lati mu ijọsin tootọ padabọsipo. Awọn akọsilẹ mejeeji rohin pe àròpọ̀ awọn olùpadà wọnyi jẹ́ 42,360. Ẹgbẹẹgbẹrun iye yẹn jẹ́ “awọn ọkunrin eniyan Isirẹli.” Tẹle e ni akọsilẹ naa to awọn alufaa lẹsẹẹsẹ. Lẹhin naa ni ó kan nǹkan bii 350 awọn ọmọ Lefi, papọ pẹlu awọn ọmọ Lefi akọrin ati adènà. Ẹsira ati Nehemaya pẹlu kọwe nipa afikun ẹgbẹẹgbẹrun ti o han gbangba pe wọn jẹ awọn ọmọ Isirẹli, boya alufaa paapaa, ṣugbọn ti wọn kò lè fẹ̀rí akọsilẹ ìran wọn han.—Ẹsira 1:1, 2; 2:2-42, 59-64; Nehemaya 7:7-45, 61-66.

5 Aṣẹku Isirẹli yii ti a mú lọ si igbekun ti wọn sì pada lẹhin naa si Jerusalẹmu ati si Juda fi ifọkansin titayọ han fun Ọlọrun ati ojuṣe jijinlẹ fun ijọsin tootọ. Gẹgẹ bi a ti ṣakiyesi, a rí ìṣerẹ́gí tí ó bá a mu ni akoko ode-oni ninu aṣẹku Isirẹli tẹmi ti ó jade lati oko-ẹrú si Babiloni Ńlá ni 1919.

6. Bawo ni Ọlọrun ṣe lo awọn ọmọ Isirẹli tẹmi ni akoko wa?

6 Lati ìgbà itusilẹ wọn ni 1919, aṣẹku arakunrin Kristi ẹni ami ororo ti gbésẹ̀ siwaju titaratitara ninu ijọsin tootọ. Jehofa ti bukun awọn isapa wọn lati kó awọn ti ó kẹhin ninu 144,000 ti ó papọ jẹ́ “Isirẹli Ọlọrun” jọ. (Galatia 6:16; Iṣipaya 7:3, 4) Gẹgẹ bi awujọ kan, aṣẹku ẹni ami ororo parapọ jẹ́ ẹgbẹ́ “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” ti a ń lò lati pese ọpọ yanturu ounjẹ tẹmi afunni ni ìyè, eyi ti wọn ti ṣiṣẹ kára lati pín kiri yika ilẹ̀-ayé.—Matiu 24:45-47.

7. Awọn wo ni wọn ń darapọ mọ awọn ẹni ami ororo ninu ijọsin tootọ?

7 Gẹgẹ bi ọrọ-ẹkọ ti ó ṣaaju ti fihan, awọn eniyan Jehofa nisinsinyi ní araadọta-ọkẹ “awọn agutan miiran” ninu, ti wọn ní ireti ti Ọlọrun fi funni ti lila ipọnju ńlá ti ó wà niwaju gẹ́lẹ́ já. Wọn fọkan fẹ́ lati ṣiṣẹsin Jehofa titilae lori ilẹ̀-ayé, nibi ti wọn kò ti ní kébi ti wọn kò sì ni kóùngbẹ mọ́ ati nibi ti omije ibanujẹ kò ti ní ṣàn mọ́. (Johanu 10:16; Iṣipaya 7:9-17; 21:3-5) Ǹjẹ́ a rí ohunkohun ti o dọgba rẹ́gí pẹlu iru awọn ẹmi bẹẹ ninu akọsilẹ awọn olùpadàwá lati Babiloni bí? Bẹẹni!

Awọn Ti Kì í ṣe Ọmọ Isirẹli Pẹlu Pada

8. Awọn wo ni wọn tẹle awọn ọmọ Isirẹli ti wọn ń pada lati Babiloni?

8 Nigba ti ìpè naa jade fun awọn olùfẹ́ Jehofa ni Babiloni lati pada si Ilẹ Ileri, ẹgbẹẹgbẹrun awọn ti kì í ṣe ọmọ Isirẹli dahun pada. Ninu akọsilẹ ti a pese lati ọwọ Ẹsira ati Nehemaya, a kà nipa awọn “Netinimu” (ti ó tumọ si, “Awọn Ti A Fi Funni”) ati “awọn ọmọkunrin awọn iranṣẹ Solomọni,” ti apapọ iye wọn jẹ́ 392. Awọn akọsilẹ naa tun mẹnukan iye ti ó ju 7,500 awọn miiran: ‘awọn ẹrúkùnrin ati ẹrúbìnrin,’ ati bakan naa awọn “[akọrin] ọkunrin ati [akọrin] obinrin” ti wọn kì í ṣe ọmọ Lefi. (Ẹsira 2:43-58, 65, NW; Nehemaya 7:46-60, 67) Ki ni ó sún ọpọlọpọ ti wọn kì í ṣe ọmọ Isirẹli lati pada?

9. Bawo ni ẹmi Ọlọrun ṣe wémọ́ ipada lati igbekun?

9 Ẹsira 1:5 sọ nipa “gbogbo awọn ẹni ti Ọlọrun ru ẹmi wọn soke, lati goke lọ, lati kọ́ ile OLUWA [“Jehofa,” NW].” Bẹẹni, Jehofa sún gbogbo awọn wọnni ti wọn pada. Ó ru ẹmi wọn soke, iyẹn ni pe, ìtẹ̀sí ero-ori wọn ti ń sún wọn ṣiṣẹ. Ani lati inu awọn ọrun, Ọlọrun lè ṣe eyi nipa lilo ẹmi mimọ rẹ̀, ipá agbekankanṣiṣẹ rẹ̀. Nipa bayii, gbogbo awọn ti wọn dide “lati goke lọ lati kọ́ ile OLUWA [“Jehofa,” NW]” ni a ràn lọwọ “nipa ẹmi [Ọlọrun].”—Sekaraya 4:1, 6; Hagai 1:14.

Alábàádọ́gba Ode-Oni Kan

10, 11. Ibaradọgba wo ni o wà fun awọn ti kì í ṣe ọmọ Isirẹli ti wọn pada lati Babiloni?

10 Awọn wo ni iru awọn olùpadà ti wọn kì í ṣe ọmọ Isirẹli bẹẹ jẹ ojiji iṣaaju fun? Ọpọlọpọ awọn Kristẹni lè fesi pada pe: ‘Awọn Netinimu dọ́gba-rẹ́gí pẹlu “awọn agutan miiran” lonii.’ Otitọ ni, ṣugbọn ki i wulẹ ṣe awọn Netinimu lasan; nitori pe gbogbo awọn ti wọn kì í ṣe ọmọ Isirẹli ti wọn pada duro fun awọn Kristẹni lonii ti wọn kì í ṣe Isirẹli tẹmi.

11 Iwe naa You May Survive Armageddon Into God’s New Worlda sọ pe: “Kì í ṣe kiki aṣẹku tí ó jẹ́ 42,360 awọn ọmọ Isirẹli ni wọn fi Babiloni silẹ pẹlu gomina Serubabeli . . . Ẹgbẹẹgbẹrun awọn ti kì í ṣe ọmọ Isirẹli ni wọn wà . . . Yatọ si awọn Netinimu awọn miiran ti kì í ṣe ọmọ Isirẹli wà, awọn ẹrú, awọn ọ̀jáfáfá akọrin ọkunrin ati akọrin obinrin ati awọn atọmọdọmọ iranṣẹ Ọba Solomọni.” Iwe naa ṣalaye pe: “Awọn Netinimu, awọn ẹrú, akọrin ati awọn ọmọkunrin iranṣẹ Solomọni, gbogbo awọn ti kì í ṣe ọmọ Isirẹli, fi ilẹ oko-ẹrú silẹ wọn sì pada pẹlu aṣẹku ọmọ Isirẹli . . . Nitori naa o ha tọna lati ronu pe lonii awọn eniyan lati orilẹ-ede ọtọọtọ ti wọn kì í ṣe Isirẹli tẹmi yoo da araawọn pọ̀ mọ́ aṣẹku Isirẹli tẹmi ki wọn sì gbé ijọsin Jehofa Ọlọrun ga siwaju pẹlu wọn bi? Bẹẹni.” Iru awọn bẹẹ ‘ti di Netinimu, awọn akọrin, ati awọn ọmọkunrin iranṣẹ Solomọni amapẹẹrẹṣẹ ode-oni.’

12. Bawo ni Ọlọrun ṣe ń lo ẹmi rẹ̀ ni ọna akanṣe fun awọn ọmọ Isirẹli tẹmi, ṣugbọn eeṣe ti a fi lè ni idaniloju pe ó wà larọọwọto fun gbogbo awọn olujọsin rẹ̀?

12 Gẹgẹ bi o ti ri ninu apẹẹrẹ igbaani, Ọlọrun pese ẹmi rẹ̀ fun awọn wọnyi pẹlu ti wọn ń reti lati walaaye titilae lori ilẹ̀-ayé. Loootọ, a kò tun wọn bí. Ọkọọkan awọn 144,000 ni iriri jíjẹ́ ẹni ti a túnbí gẹgẹ bi ọmọkunrin tẹmi Ọlọrun lẹẹkanṣoṣo a sì fàmì ororo yàn wọn pẹlu ẹmi mimọ. (Johanu 3:3, 5; Roomu 8:16; Efesu 1:13, 14) Dajudaju, ìfàmì ororo yàn yẹn jẹ́ ifihan kanṣoṣo ti ẹmi Ọlọrun nititori agbo kekere. Ṣugbọn ẹmi Ọlorun ni a tun nilo lati ṣe ifẹ-inu rẹ̀. Fun idi yii, Jesu sọ pe: ‘Baba ni ọrun fi ẹmi mimọ rẹ̀ fun awọn wọnni ti ń beere lọwọ rẹ̀.’ (Luuku 11:13) Yala ẹni ti ń beere ni ireti ti ọrun tabi ó jẹ́ agutan miiran, ẹmi Jehofa wà larọọwọto lọpọ yanturu lati mú ète Rẹ̀ ṣẹ.

13. Bawo ni ẹmi ṣe lè ṣiṣẹ lori gbogbo awọn iranṣẹ Ọlọrun?

13 Ẹmi Ọlọrun sún ati awọn ọmọ Isirẹli ati awọn ti wọn kì í ṣe ọmọ Isirẹli lati pada si Jerusalẹmu, ó sì fun gbogbo awọn eniyan aduroṣinṣin rẹ̀ lokun ó sì ràn wọn lọwọ lonii. Yala ireti ti Ọlọrun pese fun Kristẹni kan jẹ́ ìyè ni ọrun tabi ìyè lori ilẹ̀-ayé, ó gbọdọ waasu ihinrere, ẹmi mimọ sì ń ràn án lọwọ lati jẹ oloootọ ninu iyẹn. Olukuluku wa—ohun yoowu ki o jẹ́ ireti wa—ni o yẹ ki a mú awọn eso ẹmi dagba, eyi ti gbogbo wa nilo ni ìwọ̀n kikun.—Galatia 5:22-26.

A Fi Funni fun Iṣẹ-Isin Akanṣe

14, 15. (a) Lara awọn ti kì í ṣe ọmọ Isirẹli ti wọn pada, awọn awujọ meji wo ni a ya sọtọ? (b) Awọn wo ni awọn Netinimu, ki ni wọn sì ṣe?

14 Ninu ẹgbẹẹgbẹrun awọn ti kì í ṣe Isirẹli ti ẹmi naa sún lati pada ni awọn awujọ kekere meji ti Ọrọ Ọlọrun dá fihan—awọn Netinimu ati awọn ọmọkunrin awọn iranṣẹ Solomọni. Ta ni wọn? Ki ni wọn ṣe? Ki sì ni eyi lè tumọsi lonii?

15 Awọn Netinimu jẹ́ awujọ kan ti wọn ní ipilẹṣẹ tí kì í ṣe ti ọmọ Isirẹli ti wọn sì lanfaani lati ṣe iṣẹ-ojiṣẹ pẹlu awọn ọmọ Lefi. Ranti awọn ará Kenaani lati Gibioni ti wọn di “aṣẹ́gi ati apọnmi fun ìjọ, ati fun pẹpẹ OLUWA [“Jehofa,” NW].” (Joṣua 9:27) Boya diẹ lara awọn atọmọdọmọ wọn wà lara awọn Netinimu ti wọn ń pada lati Babiloni, ati awọn miiran ti a ti fikun wọn gẹgẹ bii Netinimu bakan naa ni akoko ijọba Dafidi ati ni awọn akoko miiran. (Ẹsira 8:20) Ki ni awọn Netinimu ṣe? Awọn ọmọ Lefi ni a fi funni lati ran awọn alufaa lọwọ, ati lẹhin naa awọn Netinimu ni a fi funni lati ran awọn ọmọ Lefi lọwọ. Ani fun awọn àlejò ti a kọ nílà paapaa, eyi jẹ́ anfaani kan.

16. Bawo ni ìlà iṣẹ awọn Netinimu ṣe yipada bi akoko ti ń lọ?

16 Nigba ti awujọ naa pada lati Babiloni, ó ní awọn ọmọ Lefi diẹ ninu, ni ifiwera pẹlu awọn alufaa tabi awọn Netinimu ati “awọn ọmọkunrin awọn iranṣẹ Solomọni.” (Ẹsira 8:15-20, NW) Iwe Dictionary of the Bible, lati ọwọ Dr. James Hastings, sọ pe: “Lẹhin akoko kan a rí i pe [awọn Netinimu] ni a ti fidii wọn mulẹ patapata tobẹẹ gẹgẹ bi awujọ mimọ ti ó bá ilana mú, debi pe awọn anfaani ni a fi fun wọn.” Iwe agberohin jade ti o fi ijinlẹ ẹkọ han naa vetus testamentum ṣakiyesi pe: “Iyipada kan ṣẹlẹ. Lẹhin Ipada lati Igbekun, [awọn àlejò] wọnyi ni a kò kà sí ẹrú tẹmpili mọ́, ṣugbọn gẹgẹ bi awọn ojiṣẹ ninu rẹ̀, ni gbigbadun ipo ti o farajọra pẹlu eyi ti ó jẹ́ ti awọn ẹgbẹ awujọ miiran, ti wọn ń ṣe kòkáárí ninu Tẹmpili.”—Wo apoti naa “Ipo Kan Ti O Yipada.”

17. Eeṣe ti awọn Netinimu fi gba pupọ sii lati ṣe, ẹ̀rí ti ó bá Bibeli mu wo ni ó sì wà fun eyi?

17 Dajudaju, awọn Netinimu kò di ọgba pẹlu awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi. Awujọ ti a sọ kẹhin jẹ́ awọn ọmọ Isirẹli, ti Jehofa fúnraarẹ̀ yàn tí awọn ti kì í ṣe ọmọ Isirẹli kò sì nilati gbapò wọn. Sibẹ, awọn ìtọ́ka Bibeli ni pe loju iye awọn ọmọ Lefi ti o dínkù, awọn Netinimu ni a fun ni iṣẹ pupọ sii lati ṣe ninu iṣẹ-isin Ọlọrun. A yan àgọ́ gbígbé ti ó sunmọ tẹmpili fun wọn. Ni ọjọ Nehemaya wọn ṣiṣẹ pẹlu awọn alufaa ni títún awọn ogiri ẹ̀bá tẹmpili ṣe. (Nehemaya 3:22-26) Ọba Paṣia sì paṣẹ pe ki a dá awọn Netinimu sí kuro ninu owo-ori, gẹgẹ bi a ti dá awọn ọmọ Lefi sí nitori iṣẹ-isin tẹmpili wọn. (Ẹsira 7:24) Eyi tọka si bi “awọn ẹni ti a fi funni” wọnyi (awọn ọmọ Lefi ati awọn Netinimu) ti ní isokọra pẹkipẹki tó nigba naa ninu awọn ọ̀ràn tẹmi ati bi awọn iṣẹ-ayanfunni ti awọn Netinimu ti pọ sii ni ibamu pẹlu aini naa, bi o tilẹ jẹ́ pe a kò kà wọn sí ọmọ Lefi rí. Nigba ti Ẹsira kó awọn igbekun jọ lẹhin naa lati pada, kò sí awọn ọmọ Lefi laaarin wọn lakọọkọ. Nitori naa ó mu awọn isapa rinlẹ sii lati kó awọn diẹ jọ. Iyẹn yọrisi awọn ọmọ Lefi 38 ati 220 awọn Netinimu ti wọn ń pada lati ṣiṣẹsin gẹgẹ bi “awọn iranṣẹ . . . fun ile Ọlọrun wa.”—Ẹsira 8:15-20.

18. Awọn ọmọkunrin awọn iranṣẹ Solomọni lè ti ṣe awọn iṣẹ wo?

18 Awujọ keji tí wọn kì í ṣe awọn ọmọ Isirẹli ti a yà sọ́tọ̀ ni awọn ọmọkunrin awọn iranṣẹ Solomọni. Bibeli funni ni awọn kulẹkulẹ diẹ nipa wọn. Awọn kan jẹ́ “awọn ọmọ Sofereti.” Ẹsira fi ọrọ atọ́ka pàtó kan kun orukọ yẹn, ni sísọ ọ́ di Has·so·pheʹreth, ti ó ṣeeṣe ki o tumọ si “awọn akọwe.” (Ẹsira 2:55; Nehemaya 7:57) Wọn ti lè tipa bayii di oṣiṣẹ awọn akọwe tabi awọn aṣàdàkọ, ó ṣeeṣe ki wọn jẹ́ akọwe inu tẹmpili/ìṣàbójútó. Bi o tilẹ jẹ pe a ṣà wọn lati inu awọn àlejò, awọn ọmọkunrin awọn iranṣẹ Solomọni fẹ̀rí ifọkansin wọn si Jehofa hàn nipa fifi Babiloni silẹ ati pipada lati ṣajọpin ninu mimu ijọsin Rẹ̀ padabọsipo.

Yiyọnda Araawa Lonii

19. Ibatan wo ni ó wà laaarin awọn ẹni ami ororo lonii ati awọn agutan miiran?

19 Ni akoko wa, Ọlọrun ti lo awọn aṣẹku ẹni ami ororo gidigidi ninu mimu ipo iwaju ninu ijọsin mimọgaara ati pipolongo ihinrere. (Maaku 13:10) Awọn wọnyi ti layọ tó lati rí i ti ẹgbẹẹgbẹrun lọna mẹwaa mẹwaa, ẹgbẹẹgbẹrun lọna ọgọrọọrun, ati lẹhin naa araadọta-ọkẹ awọn agutan miiran darapọ mọ wọn ninu ijọsin! Ifọwọsowọpọ onidunnu wo ni ó sì ti wà laaarin awọn aṣẹku ati awọn agutan miiran!—Johanu 10:16.

20. Ìlóye titun wo ni ó bá ọgbọn ironu mu niti ohun ti o baradọgba pẹlu awọn Netinimu ati awọn ọmọkunrin awọn iranṣẹ Solomọni? (Owe 4:18)

20 Gbogbo awọn ti kì í ṣe ọmọ Isirẹli ti wọn pada lati igbekun ni Babiloni igbaani baradọgba pẹlu awọn agutan miiran ti wọn ń ṣiṣẹsin nisinsinyi pẹlu awọn aṣẹku ti Isirẹli tẹmi. Ki ni, bi o ti wu ki o ri, nipa otitọ naa pe Bibeli ya awọn Netinimu ati awọn ọmọkunrin iranṣẹ Solomọni sọtọ? Ninu apẹẹrẹ naa awọn Netinimu ati awọn ọmọkunrin awọn iranṣẹ Solomọni ni a fún ní awọn anfaani ti o tayọ iwọnyi ti a fifun awọn yooku tí ń pada ti wọn kì í ṣe ọmọ Isirẹli. Eyi lè jẹ́ ojiji iṣaaju daradara pe Ọlọrun lonii ti mú awọn anfaani ati afikun ẹru-iṣẹ gbooro fun awọn agutan miiran ti wọn dagbadenu ti wọn sì muratan.

21. Bawo ni awọn arakunrin kan ti wọn ní ireti ti ilẹ̀-ayé ṣe gba afikun awọn ẹru-iṣẹ ati anfaani?

21 Afikun anfaani awọn Netinimu ni a sopọ ni taarata pẹlu awọn igbokegbodo tẹmi. Awọn ọmọkunrin awọn iranṣẹ Solomọni ni ó jọ bi pe wọn gba awọn ẹru-iṣẹ ìṣàbójútó. Bakan naa lonii, Jehofa ti bukun awọn eniyan rẹ̀ pẹlu “awọn ẹbun ninu eniyan” lati bojuto awọn aini wọn. (Efesu 4:8, 11, 12, NW) Awọn ti a fikun un ninu ipese yii ni ọpọ ọgọrọọrun awọn arakunrin adàgbàdénú, oniriiri, ti wọn ń ṣajọpin ninu ‘ṣiṣoluṣọ agutan agbo,’ ti wọn ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alaboojuto ayika ati agbegbe ati ninu Awọn Igbimọ Ẹ̀ka ni 98 awọn ẹ̀ka ti Watch Tower Society. (Aisaya 61:5) Ni orile-iṣẹ agbaye ti Society, labẹ idari “ìríjú oluṣotitọ” ati Ẹgbẹ Oluṣakoso rẹ̀, awọn ọkunrin ti wọn tootun gba idalẹkọọ lati ṣeranwọ ninu ṣiṣeto awọn ipese ounjẹ tẹmi. (Luuku 12:42, NW) Awọn oluyọnda ara-ẹni olùṣèyàsímímọ́ alakooko gigun miiran ni a ti dá lẹkọọ lati mú awọn ile ati ile-iṣẹ Bẹtẹli ṣiṣẹ ati lati bojuto awọn itolẹsẹẹsẹ yika ayé ninu kikọ awọn ohun eelo ẹ̀ka titun ati awọn gbọngan fun ijọsin Kristẹni. Wọn ti tayọ ninu ṣiṣiṣẹsin gẹgẹ bi oluranlọwọ timọtimọ ti awọn aṣẹku ẹni ami ororo, ti wọn papọ jẹ́ apakan ẹgbẹ alufaa ọlọba.—Fiwe 1 Kọrinti 4:17; 14:40; 1 Peteru 2:9.

22. Eeṣe ti o fi bá a mu pe ki a fun awọn agutan miiran kan ni awọn ẹru-iṣẹ wiwuwo nisinsinyi, bawo ni ó sì ti yẹ ki a huwa pada si eyi?

22 Ni awọn akoko laelae, awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi ń ba a lọ lati ṣiṣẹsin laaarin awọn Juu. (Johanu 1:19) Bi o ti wu ki o ri, lonii, aṣẹku Isirẹli tẹmi lori ilẹ̀-ayé gbọdọ maa ba a lọ ni dídínkù. (Ṣe iyatọ ifiwera pẹlu Johanu 3:30.) Nikẹhin, lẹhin iparun raurau Babiloni Ńlá, gbogbo 144,000 ‘awọn ti a fi èdídí dí’ yoo wà ni ọ̀run fun igbeyawo Ọdọ-Agutan. (Iṣipaya 7:1-3; 19:1-8) Ṣugbọn nisinsinyi awọn agutan miiran gbọdọ maa baa lọ ni bíbísi i. Otitọ naa pe awọn kan ninu wọn, lọna ti o ṣee fiwera pẹlu awọn Netinimu ati awọn ọmọkunrin awọn iranṣẹ Solomọni, ni a ń yan awọn ẹru-iṣẹ wiwuwo fun nisinsinyi labẹ abojuto awọn aṣẹku ẹni ami ororo kò mú wọn jẹ́ akùgbùù tabi nimọlara ijọra-ẹni loju. (Roomu 12:3) Eyi fun wa ni igbọkanle pe gbàrà ti awọn eniyan Ọlọrun bá ti “jade lati inu ipọnju ńlá,” awọn ọkunrin oniriiri—“awọn ọmọ alade”—ti a ti murasilẹ lati mu ipo iwaju laaarin awọn agutan miiran yoo wà.—Iṣipaya 7:14; Aisaya 32:1, NW; fiwe Iṣe 6:2-7.

23. Eeṣe ti gbogbo wa fi nilati mu ẹmi fifunni niti iṣẹ-isin Ọlọrun dagba?

23 Gbogbo awọn ti wọn pada lati Babiloni ni wọn muratan lati ṣiṣẹ kára ki wọn sì fihan pe wọn ni ijọsin Jehofa ni òkè èrò-inú ati ọkan-aya wọn julọ. Bakan naa ni ó rí lonii. Papọ pẹlu awọn aṣẹku ẹni ami ororo, “awọn àlejò . . . duro . . . bọ́ ọ̀wọ́ ẹran.” (Aisaya 61:5) Nitori naa laika ireti ti Ọlọrun pese yoowu ti a ní sí, ati awọn anfaani yoowu ti a lè nasẹ rẹ̀ dé ọdọ awọn alagba ti a fi ẹmi yàn sipo ṣaaju idalare Jehofa ni Amagẹdọni, ẹ jẹ ki gbogbo wa mu ẹmi àìmọtara-ẹni nikan patapata, ti o péye, ti fifunni dagba. Bi o tilẹ jẹ pe a kò lè san àsanpadà fun Jehofa fun gbogbo awọn anfaani ńláǹlà rẹ̀, njẹ ki a jẹ́ aláìpínyà-ọkàn ninu ohun yoowu ti a ń ṣe ninu eto-ajọ rẹ̀. (Saamu 116:12-14; Kolose 3:23) Nipa bayii gbogbo wa lè yọnda araawa fun ijọsin tootọ, bi awọn agutan miiran ti ń ṣiṣẹsin timọtimọ pẹlu awọn aṣẹku ẹni ami ororo, ti a kádàrá lati “ṣakoso gẹgẹ bi ọba lori ilẹ̀-ayé.”—Iṣipaya 5:9, 10, NW.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Oju-iwe 142 si 148; ti a tẹjade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

Awọn Kókó Lati Ranti

◻ Ni ọna wo ni awọn ọmọ Lefi gbà jẹ “awọn ẹni ti a fi funni” ni Isirẹli igbaani?

◻ Awọn ti kì í ṣe ọmọ Isirẹli wo ni wọn pada lati igbekun, ti o jẹ́ ojiji iṣaaju fun awọn wo?

◻ Iyipada wo ni o jọ bii pé o ti ṣẹlẹ si awọn Netinimu?

◻ Nipa awọn Netinimu ati awọn ọmọkunrin awọn iranṣẹ Solomọni, ibaradọgba wo ni a mọriri nisinsinyi?

◻ Igbọkanle wo ni o ti inu ifọwọsowọpọ ti o wà laaarin awọn ẹni ami ororo ati awọn agutan miiran wá?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]

IPO KAN TI O YIPADA

Ọpọlọpọ awọn iwe atumọ-ede ati gbédègbẹ́yọ̀ Bibeli sọrọ lori awọn iyipada ti diẹ lara awọn ti kì í ṣe ọmọ Isirẹli ti wọn pada lati igbekun niriiri rẹ̀. Fun apẹẹrẹ, labẹ “Iyipada ninu ipo wọn,” Encyclopædia Biblica sọ pe: “Ipo ẹgbẹ-oun-ọgba wọn, gẹgẹ bi a ti sọ ṣaaju, ni a gbéga lọna ti o pọndandan lakooko kan naa. [Awọn Netinimu] kò farahan bii ẹrú mọ́ ni itumọ ọrọ yẹn gan-an.” (Ti a tẹ̀ lati ọwọ Cheyne ati Black, Idipọ III, oju-iwe 3399) Ninu The Cyclopædia of Biblical Literature, John Kitto kọwe pe: “A kò nilati reti rẹ̀ pe ọpọlọpọ ninu wọn [awọn Netinimu] yoo pada si ipo rirẹlẹ yii ni Palestine . . . Ifọkansin lọna ìfínnú-fíndọ̀ yọnda ara-ẹni ti awọn eniyan wọnyi tipa bayii gbé ipo awọn Netinimu ga lọna jaburata.” (Idipọ II, oju-iwe 417) The International Standard Bible Encyclopedia ṣalaye pe: “Ninu àlàyé ibatan yii ati ipilẹ wọn ni sáà akoko Solomọni, a lè rò pe awọn iranṣẹ Solomọni ní awọn ẹru-isẹ pataki ninu tẹmpili keji.”—A tẹ̀ ẹ́ lati ọwọ G. W. Bromiley, Idipọ 4, oju-iwe 570.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Nigba ti awọn ọmọ Isirẹli pada lati tún Jerusalẹmu kọ́, ẹgbẹẹgbẹrun awọn ti kì í ṣe ọmọ Isirẹli tẹle wọn

[Credit Line]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Igbimọ Ẹ̀ka ni Korea. Gẹgẹ bi awọn Netinimu igbaani ti ṣe, awọn ọkunrin ti wọn jẹ agutan miiran ní ẹru-iṣẹ wiwuwo ninu ijọsin tootọ lonii

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́