1914—Ọdun naa Ti Ó Dá Ayé Níjì
“Ogun Nla ti ọdun 1914 si 1918 dabi oju ilẹ gbigbooro kan tí ina ti jo ti o pin akoko yẹn niya si tiwa. Ni rirun ọpọlọpọ iwalaaye pupọ tobẹẹ . . . , ni pipa awọn ero-igbagbọ run, yiyi awọn èròǹgbà pada, ati fifi awọn ọgbẹ́ ìjádìí ọgbọ́n ìtànjẹ ti kò ṣe e wosan silẹ sẹhin, ó dá ọgbun ti o ṣee fojuri gidi ati ọgbun niti ero-imọlara pẹlu silẹ laaarin awọn sanmani aye meji.”—Lati inu iwe The Proud Tower—A Portrait of the World Before the War 1890-1914, lati ọwọ Barbara Tuchman.
“O ti fẹrẹẹ di apakan itan—ṣugbọn kò tíì dìí tán—nitori ọpọ ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan ti wọn wà ni ọ̀dọ́ nigba ibẹrẹ ọrundun ogun ṣiṣe pataki yii ṣì walaaye sibẹ.”—Lati inu iwe naa 1914, lati ọwọ Lyn MacDonald, ti a tẹjade ni ọdun 1987.
EEṢE ti o fi yẹ ki o ni ifẹ ọkan ninu ọdun naa 1914? ‘Ọjọ iwaju ni o kàn mi, kì í ṣe ti ìgbà ti o ti kọja,’ ni iwọ lè sọ. Pẹlu awọn iṣoro bii sisọ ayika ilẹ̀-ayé deléèérí, igbesi-aye idile ti ń wópalẹ̀, ibisi ninu iwa ọdaran, aisan ọpọlọ, airiṣẹṣe, ọjọ iwaju eniyan lè dabi eyi ti o pòkúdu. Bi o ti wu ki o ri, ọpọ awọn ti ó ti ṣayẹwo ijẹpataki ọdun 1914 ti ri idi pataki fun nini ireti ninu ọjọ-ọla kan ti o sanju.
Fun ọpọ ẹ̀wádún ni Ilé-Ìsọ́nà ti ṣalaye pe ni 1914 iran eniyan niriiri ohun ti a ń pe ni “ipilẹṣẹ ipọnju.” Ọrọ yẹn jẹ́ apakan asọtẹlẹ nla ti Jesu Kristi nipa awọn iṣẹlẹ ti yoo ṣaaju opin eto-igbekalẹ buburu ti eniyan.—Matiu 24:7, 8.
Lonii, iwọnba diẹ ninu iran eniyan ṣì lè ranti awọn iṣẹlẹ amunijigiri ti ọdun 1914. Ǹjẹ́ iran ti o ti dagba naa yoo ha kọja lọ ṣaaju ki Ọlọrun to gba ayé là kuro lọwọ iparun bi? Kì í ṣe gẹgẹ bi asọtẹlẹ Bibeli ti wi. “Nigba ti ẹyin ba ri gbogbo nǹkan wọnyi” ni Jesu wi “ki ẹ mọ pe o sunmọ etile tan lẹhin ilẹkun. Loootọ ni mo wi fun yin, iran yii ki yoo rekọja, titi gbogbo nǹkan wọnyi yoo fi ṣẹ.”—Matiu 24:33, 34.
Lati lè loye ni kikun idi ti ọdun naa 1914 fi ni iru ijẹpataki onitan bẹẹ, ṣe agbeyẹwo ipo ti ayé wà titi fi di agbedemeji ọdun 1914. Ṣaaju ìgbà naa, awọn olu-ọba nlanla iru bii Czar Nicholas ti ilẹ Russia, Kaiser Wilhelm ti ilẹ Germany, ati Olu-Ọba Franz Josef ti Austria-oun-Hungary lo agbara nla. Ọkọọkan ninu awọn ọkunrin wọnyi lè kó ohun ti o ju aadọta ọkẹ mẹrin jagunjagun jọ ki wọn si rán wọn lọ si oju ogun. Ṣugbọn awọn baba wọn ti fọwọ si iwe ohun ti a ń pe ni Ajọṣepọ Mímọ́, ni pipolongo pe Ọlọrun ti rán awọn lati ṣakoso apa ibi ọtọọtọ ninu “Ilẹ Kristẹni” nla kanṣoṣo.
Gẹgẹ bi The Encyclopædia Britannica ti wi, iwe akọsilẹ yii “ni ipa alagbara lori ọna ti a ń gbà yanju ọ̀ràn laaarin awọn orilẹ-ede ilẹ Europe ní ọrundun 19.” A lo o lati tako igbokegbodo ijọba dẹmọ ati lati ṣojurere si ohun ti a fẹnulasan pe ni ẹ̀tọ́ atọrunwa ti awọn ọba. Kaiser Wilhelm kọwe si Czar Nicholas pe: “Awa Ọba ti Kristẹni ni iṣẹ mímọ́ kanṣoṣo, ti Ọlọrun gbe kà wa lori, iyẹn ni lati gbeja ki a si di ilana eto ti [ẹtọ atọrunwa awọn ọba] mú.” Eyi ha tumọsi pe awọn ọba ilẹ Europe ni isopọ lọna kan ṣá pẹlu Ijọba Ọlọrun bi? (Fiwe 1 Kọrinti 4:8.) Ki sì ni nipa ti awọn ṣọọṣi ti wọn kín awọn ọba wọnyẹn lẹhin? Jijẹwọ ti wọn jẹwọsọ pe awọn jẹ Kristẹni ha jẹ ojulowo bi? Idahun si awọn ibeere wọnyi di eyi ti o ṣe kedere sii ni awọn ọdun ti o tẹle 1914 gẹ́lẹ́.
Lojiji, ni Oṣu August
“Ìgbà iruwe ati ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn 1914 ni ifọkanbalẹ ara-ọtọ samisi ní ilẹ Europe,” ni àgbà oṣelu ilẹ Britain naa Winston Churchill kọwe. Awọn eniyan ni gbogbogboo ní ifojusọna rere nipa ọjọ-ọla. “Aye 1914 kun fun ireti ati awọn ifojusọna rere,” ni Louis Snyder sọ ninu iwe rẹ̀ World War I.
Loootọ, fun ọpọ ọdun ni ibanidije lilekoko ti wà laaarin ilẹ Germany ati ilẹ Britain. Bi o tilẹ jẹ bẹẹ, gẹgẹ bi opitan G. P. Gooch ti ṣalaye ninu iwe rẹ̀ Under Six Reigns: “Ṣiṣeeṣe naa pe iforigbari lè má ṣẹlẹ laaarin Europe dabi eyi ti o pọ̀ ni 1914 ju 1911, 1912, tabi 1913 lọ . . . Ibaṣepọ laaarin ijọba mejeeji sàn ju bi wọn ti ṣe wà fun ọpọ ọdun lọ.” Gẹgẹ bi Winston Churchill, mẹmba igbimọ aṣofin ilẹ Britain ni ọdun 1914 ti wi: “O dabi ẹnipe ilẹ Germany wà pẹlu wa, lati wá alaafia.”
Bi o ti wu ki o ri, pẹlu iṣikapa ọmọ-aládé Ilẹ-ọba Austria-oun-Hungary ni Sarajevo ni June 28, 1914, ewu ijọngbọn ti rọ̀dẹ̀dẹ̀. Oṣu kan lẹhin naa, Olu-Ọba Franz Josef kede ibẹrẹ ogun pẹlu Serbia ti o si paṣẹ fun awọn ọmọ ogun rẹ̀ lati gbogun ti ilẹ-ọba yẹn. Ni akoko kan naa, ni alẹ́ August 3, 1914, labẹ àṣẹ Kaiser Wilhelm, agbo ọmọ ogun Germany gbogun ti ilẹ-ọba Belgium lojiji ti wọn si ń ja ija lọ siha ilẹ France. Ni ọjọ keji Britain kede ibẹrẹ ogun pẹlu Germany. Niti Czar Nicholas, oun paṣẹ kíkó agbo awọn ọmọ ogun Russia rẹpẹtẹ jọ fun ogun jíjà pẹlu Germany ati Austria-oun-Hungary. Ajọṣepọ Mímọ́ naa ti kuna lati dá awọn ọba ilẹ Europe duro ni ríri kọntinẹnti naa sinu ìpalápalù ti pipa ẹnikinni-keji lọna ipakupa kan. Ṣugbọn ìdániníjì ńláǹlà ṣì ń bọ̀ lọna.
Ṣe Ó Dopin Nigba Keresimesi?
Ibẹsilẹ ogun kò kó irẹwẹsi ba ifojusọna fun rere tí awọn eniyan ní. Ọpọ gbagbọ pe yoo mu ayé ti o sanju wa, awujọ nlanla jakejado ilẹ Europe si korajọpọ lati fi itilẹhin wọn fun un hàn. “Kò si ẹnikẹni ní 1914,” ni A. J. P. Taylor kọsilẹ ninu iwe rẹ̀ The Struggle for Mastery in Europe—1848–1918, “ti o ka awọn ewu ogun naa si ọran pataki ayafi lori ọ̀ràn ti ologun. . . . Kò si ẹni ti o reti ìjábá lọna ti ẹgbẹ́-oun-ọ̀gbà.” Kaka bẹẹ ọpọ sọ asọtẹlẹ pe yoo pari ni oṣu melookan.
Sibẹ, lọjọ gbọọrọ ṣaaju ki awọn ara Europe to bẹrẹsii ṣe ayẹyẹ Keresimesi ti ọdun wọn 1914, iforigbari ti o mu ọpọlọpọ itajẹsilẹ lọwọ ti ruyọ nibi awọn kòtò fun ààbò awọn ọmọ ogun eyi ti o fi 450 ibusọ gbooro rekọja lati Switzerland ni guusu titi de etikun ilẹ Belgium ni iha ariwa. Eyi ni wọn pe ni Oju Ija ti awọn ọmọ ogun ara Iwọ-Oorun, ti onkọwe ara Germany naa Herbert Sulzbach sì mẹnukan an ninu akọsilẹ kan ti o kọ sinu iwe akọsilẹ rẹ̀ ni ọjọ ti o kẹhin ọdun 1914. Akọsilẹ naa kà pe: “Ogun buburu yii ń baa lọ siwaju ati siwaju sii, ati nigba ti o jẹ pe o rò ní ibẹrẹ pe yoo pari ni iwọn ọ̀sẹ̀ diẹ, a kò tii róye ìgbà ti yoo pari ní bayii.” Ni akoko kan naa, ni awọn apa ibomiran ni ilẹ Europe, ija ogun ti o mu ọpọlọpọ itajẹsilẹ lọwọ ń baa lọ laaarin awọn ọmọ ogun ilẹ Russia, Germany, Austria-oun-Hungary, ati Serbia. Laipẹ iforigbari naa gbilẹ rekọja ilẹ Europe, ti a si ja ogun ni ori awọn agbami okun ati ni Africa, Aarin-Gbungbun Ila-Oorun Ayé, ati awọn erekusu okun Pacific.
Ni ọdun mẹrin lẹhin naa a ti run ilẹ Europe. Ilẹ Germany, Russia, ati Austria-oun-Hungary ni ọkọọkan wọn padanu aadọta ọkẹ kan si meji ọmọ ogun. Russia tilẹ ti padanu ijọba ọlọba rẹ̀ ninu iyipada afọtẹṣe ti Bolshevik ni ọdun 1917. Iru imunigbọnriri wo ni o jẹ fun awọn ọba ilẹ Europe ati agbo awọn alufaa ti ń ṣe alatilẹhin wọn! Awọn opitan ode-oni ṣì fi iyalẹnu wọn han sibẹ. Ninu iwe rẹ̀ Royal Sunset, Gordon Brook-Shepherd beere pe: “Bawo ni o ṣe jẹ pe awọn alakooso, tí eyi ti o pọju ninu wọn baratan nipaṣẹ àjọbí tabi igbeyawo tí gbogbo wọn si fi didaabobo ipo ọba ṣe gongo wọn, lè fayegba araawọn lati rì sinu pipa ọmọ iya ẹni nipakupa eyi ti o run pupọ ninu wọn kuro ti o si sọ awọn ti o laaja di alailagbara?”
Orilẹ-ede alailọba ti France bakan naa padanu ohun ti o ju aadọta ọkẹ awọn ọmọ ogun lọ, tí ilẹ Olu-Ọba ti Britain, ti a ti sọ iṣakoso ọlọba rẹ̀ di alailagbara ni igba pipẹ ṣaaju ogun naa, sì padanu ohun ti o ju 900,000 lọ. Ni apapọ, o ju 9 million awọn ọmọ ogun ti o ku, ti 21 million miiran si tun farapa. Niti ipadanu awọn ti kò lọ si oju ija, iwe gbedegbẹyọ naa The World Book Encyclopedia sọ pe: “Kò si ẹni ti o mọ iye awọn ara ilu ti wọn ku nitori àrùn, ijiya lọwọ ebi, ati awọn okunfa miiran ti wọn jẹ nipasẹ ogun. Awọn opitan kan gbagbọ pe bi iye awọn ọmọ ogun ti wọn ku ti tó ni iye awọn ara ilu tó pẹlu.” Arun gágá ti 1918 kórè 21,000,000 iwalaaye miiran yika ayé.
Iyipada Tegbòtigaga
Aye kò ri bakan naa mọ lẹhin Ogun Nla naa, bi a ti ṣe pe e nigba naa lọhun-un. Niwọn bi iye pupọ tobẹẹ ninu awọn ṣọọṣi Kristẹndọmu ti fi ìtara ọkàn kopa ninu rẹ̀, ọpọ awọn ti irẹwẹsi ti bá nitori riri àrísá isin ti fi isin silẹ ni fifaramọ àìgbọlọ́rungbọ́. Awọn miiran yíjú sí ilepa awọn ohun ini ti ara ati awọn adùn igbesi-aye. Gẹgẹ bi Ọjọgbọn Modris Eksteins ṣe sọ ninu iwe rẹ̀ Rites of Spring, awọn ọdun 1920 “niriiri igbe igbesi-aye fun kiki afẹ́ ati ifẹ onimọtara-ẹni nikan fun ibalopọ takọtabo ni iye ti o pọ rekọja ààlà.”
“Ogun naa,” ni Ọjọgbọn Eksteins ṣalaye, “kọlu awọn ilana iwarere.” Awọn ọkunrin ni iha mejeeji ni a ti kọ́ lati ọdọ awọn aṣaaju isin, ologun, ati ti iṣelu lati wo ipaniyan lọpọ rẹpẹtẹ bi ohun ti o bá iwarere mu. Eyi, ni Eksteins gbà pe, “ó wulẹ jẹ ikọlu buburu julọ lori ilana eto iwarere eyi ti a fẹnusọ pe ó ní ipilẹsẹ ninu ilana iwarere ti isin awọn Juu-oun-Kristẹni.” Ó fi kun un pe, “Ni Iwaju Ogun awọn ọmọ ogun ti Iwọ-Oorun ko pẹ́ ti awọn aṣẹwo fi di alabaarinpọ deedee pẹlu awọn ologun ni awọn àgọ́ wọn . . . Laaarin awọn ara ilu ti ń ṣe ilé de awọn ologun iwarere tú tòbí ati okùn ṣokoto rẹ̀ danu. Iṣẹ aṣẹwo pọ sii lọna ti o gbafiyesi.”
Nitootọ, 1914 yí ohun pupọ pada. Kò mu ayé ti o sanju wá, ogun naa kò sì wá jasi “ogun ti o fopin si gbogbo ogun,” bi ọpọ eniyan ṣe reti pe yoo jẹ. Kaka bẹẹ, gẹgẹ bi opitan naa Barbara Tuchman ti ṣakiyesi: “Awọn iwewe àfọkànyà ńláǹlà ati ìtara ọkàn ti ó ti ṣeeṣe kí ó wà titi di ọdun 1914 rọra rì diẹ-diẹ lọ si isalẹ ìjákulẹ̀ ńláǹlà.”
Bi o ti wu ki o ri, awọn kan ti wọn ṣẹlẹ́rìí jamba ọdun 1914 naa ni awọn iṣẹlẹ ọdun naa kò yàlẹ́nu. Niti tootọ, ṣaaju ki ogun naa to bẹsilẹ, wọn ti ń reti “akoko ijangbọn ti o buru jai.” Ta ni wọn? Ki sì ni wọn mọ̀ ti awọn miiran kò mọ̀?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Ifojusọna Fun Rere Ilẹ Gẹẹsi ni 1914
“Fun nǹkan bi ọrundun kan kò si ọ̀tá kankan ti o ti i farahan ni awọn òkun ti o yí erekuṣu wa ká. . . . Ó nira paapaa lati finuwoye ṣiṣeeṣe ti hihalẹmọ alaafia awọn etikun alalaafia wọnyi. . . . Ilu London kò tii figbakan layọ ati aasiki to bayii rí. Kò tii sí ìgbà kan rí ti pupọ lati ṣe, ati lati rí, ati lati gbọ́ tii pọ̀ tó bayii rí. Kò si ẹni ti o fura ìbáà ṣe agba tabi ọmọde pe ohun ti awọn ń niriiri rẹ̀, ni akoko alailafiwe naa ni 1914, niti gidi, jẹ́, opin sanmani kan.”—Iwe naa Before the Lamps Went Out, lati ọwọ Geoffrey Marcus.