Awọn Irisi-Iran Lati Ilẹ Ileri
Ó Pese fun Isirẹli ni Sinai
FOJU inu wo araadọta-ọkẹ—awọn ọkunrin, obinrin, ati ọmọde—ti wọn forile inu “aginju ńlá ti o sì ní ẹ̀rù, nibi ti ejo amúbíiná wà, ati akeekee, ati ọ̀dá, nibi ti omi kò si”!
Awọn ọrọ Ọlọrun wọnni ti a rí ni Deutaronomi 8:15 mu ohun ti ó ti lè dabii irin-ajo ẹlẹ́rù kan ni iwaju awọn ọmọ Isirẹli bi wọn ti jade kuro ni Ijibiti ti wọn sì rìn wọnu aginju Sinai ṣe kedere sini lọkan. Iṣoro lilekoko kan: Ta ni yoo pese ounjẹ ati omi pípọ̀tó?
Awọn ọmọ Isirẹli ti wà ninu ìsìn-ẹrú pada sẹhin lọhun-un ni ibi ti omi Naili ti pinya wọnu òkun, ṣugbọn wọn kò ṣalaini. Awọn aworan ara ogiri ni ara awọn iboji igbaani fi akojọpọ oniruuru èso àjàrà, ẹ̀gúsí, ati awọn irugbin miiran hàn, ati bakan naa ẹja ati awọn adiẹ ti a ń sìn ti yoo jẹ ki oniruuru ounjẹ wà. Nigba naa, ẹ wo bi ìráhùn ìyánhànhàn ninu aginju ti péye tó: “Ta ni yoo fun wa ni ẹran jẹ? Awa ranti ẹja, ti awa ti ń jẹ ni Ijibiti ni ọ̀fẹ́; ati apálá, ati bàrà, ati ewebẹ, ati alubọsa, ati eweko.”—Numeri 11:4, 5; 20:5.
Laipẹ lẹhin ti awọn ọmọ Isirẹli kọja Okun Pupa, wọn loye bi Sinai ti ri niti gidi. Wọn kò gba ọ̀nà ti awọn oniṣowo maa ń gba daadaa ti ó wà ni ariwa ṣugbọn wọn yiju siha ṣonṣo ilẹ onigun mẹta ti omi yika. Nigba ti wọn fi maa rin tó nǹkan bii 50 ibusọ ninu aginju naa, aini wọn fun omi jọ bi pe ó lekoko. Wọn kò lè mu ohun ti wọn rí, nitori pe ó koro ó sì ṣeeṣe ki ó ni awọn àrùn. “Ki ni awa yoo mu?” ni wọn pariwo. Ọlọrun dá sí i, ni sisọ omi naa di didun.—Ẹkisodu 15:22-25.
Ṣakiyesi irisi itolọwọọwọ awọn ràkúnmí ti o wà loke yii. Iwọ lè mọriri ọ̀ràn bi yoo ti lè ṣeeṣe fun Isirẹli lati maa baa lọ la aginju naa já siha Oke Sinai. Bawo ni wọn yoo ṣe maa baa lọ lati ri omi ti ó pọ̀ tó—ati ounjẹ—fun araawọn ati bakan naa fun awọn agbo ati agutan wọn ti wọn nilati pa mọ́ laaye?—Ẹkisodu 12:38.
Wọn rin jinna lọ si ìhà guusu kò sì pẹ ti wọn ri omi atunilara ati ounjẹ ni Elimu. (Ẹkisodu 15:27) Bi o ti wu ki o ri, iyẹn kì í ṣe ibi ti wọn ń lọ. Wọn forile “oke Ọlọrun,” Oke Sinai. (Ẹkisodu 3:1; 18:5; 19:2; 24:12-18) Iyẹn jẹ́ ibusọ 75 jinna réré—ọpọ ibusọ ilẹ olókè pagunpagun, ti kò lómi.
Bi awujọ titobi ńlá naa ti tẹsiwaju siha Oke Sinai, wọn sunmọ tosi—o sì ṣeeṣe ki wọn duro ni—ibi omi titobi ju ninu aginju naa ti a mọ̀ si Feiran. Apa kekere ninu rẹ̀ hàn kedere ninu aworan loju-ewe ẹ̀gbẹ́.a Ó lọ rekọja ọ̀nà ti ó wà laaarin òkè meji ninu aginju naa, siha Okun Pupa (Gulf of Suez). Ẹ wo itura ti o ṣeeṣe fun wọn lati rí nibẹ!
Nigba ti apejuwe ‘aginju ńlá kan ti ń muni kun fun ẹ̀rù’ lè yẹ aginju Sinai lapapọ, awọn ọmọ Isirẹli lè gbadun òjìji awọn ọ̀pẹ rẹ̀gẹ̀jì rẹ̀gẹ̀jì ati awọn igi miiran ni ibi omi inu aginju ti Feiran. Wọn yoo rí awọn eso date pípọ̀tó, ti ń pese ounjẹ oju ẹsẹ ati ipese ti wọn lè kó dani pẹlu wọn.
Gbogbo eyi ni o ṣeeṣe nitori pe omi abẹ́lẹ̀ a maa rú sita ni Feiran. Foju inu woye bí imọlara rẹ yoo ṣe rí bi iwọ bá wà ninu aginju aṣálẹ̀ ti o sì ṣadeedee ri omi tutu lati mu! Eyi ṣapejuwe pe ni Sinai paapaa awọn ibi ti a ti lè ri omi wà. Nigba miiran kànga ni a gbọdọ gbẹ́ dé ìwọ̀n kan. Yoo wá gba iṣẹ lati fa awọn korobá tabi ìṣà-omi ti ó kun fun omi ṣiṣekoko naa, paapaa bi a bá nilati fun awọn agbo ati awọn ọ̀wọ́ ẹran ni omi. Titi di oni olonii Bedouin [awọn darandaran ara Arab] ni awọn kànga nibi ti wọn ti lè fa omi fun araawọn ati fun awọn rakunmi wọn maa ń famọra.—Fiwe Jẹnẹsisi 24:11-20; 26:18-22.
Bẹẹni, laika awọn akoko nigba ti wọn kùn lori ohun ti ó dabii aini ti kò ṣee bori sí, awọn ọmọ Isirẹli ni omi ati ounjẹ. Nigbamiran Ọlọrun pese iru bẹẹ lọna iyanu. (Ẹkisodu 16:11-18, 31; 17:2-6) Ni awọn akoko miiran a maa farahan bi ẹni pe ó dari wọn si “ibi isinmi” nibi ti a ti lè tẹ́ awọn aini wọn gidi lọ́rùn nipasẹ awọn ipese adanida. (Numeri 10:33-36) Ni gbogbo akoko yii ná, ó nawọ́ ọpọ yanturu ti ń duro de awọn oluṣotitọ ni Ilẹ Ileri jade siwaju wọn.—Deutaronomi 11:10-15.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Aworan naa wà larọọwọto ni ìwọ̀n ti o tubọ tobi ninu 1992 Calendar of Jehovah’s Witnesses.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.