Irisi-iran Lati Ilẹ Ileri
Beerṣeba Ibi ti Kànga ti Tumọsi Ìyè
“LATI Dani titi dé Beerṣeba.” Awọn olùka Bibeli mọ apola ọ̀rọ̀ yẹn bi ẹni mọ owó. O ṣapejuwe gbogbo Israeli, lati Dani, nitosi ààlà iha ariwa, si Beerṣeba, ni guusu. Alaafia iṣakoso Solomoni ni a ṣapejuwe rẹ̀ bayii: “Juda ati Israeli ń gbé ni alaafia, olukuluku labẹ àjàrà rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ rẹ̀, lati Dani titi dé Beerṣeba, ni gbogbo ọjọ Solomoni.”—1 Ọba 4:25; Awọn Onidajọ 20:1.
Bi o ti wu ki o ri, awọn iyatọ ti o wà laaarin Dani ati Beerṣeba ni ninu ju bi wọn ti jinna si araawọn tó lọ. Fun apẹẹrẹ, Dani gbadun òjò pupọ; omi ń ṣàn lati inu ilẹ lati di ọ̀kan ninu awọn orisun Odo Jordani, bi a ti ri i ninu fọto ti o wà lápá ọ̀tún. Ẹ wo bi Beerṣeba ṣe yatọ tó, nitori ti o wà ni agbegbe ilẹ gbigbẹ, laaarin agbegbe òkun ati opin iha guusu Òkun Òkú.
Ni agbegbe Beerṣeba, ojo ọdọọdun jẹ́ kiki lati ori ìwọ̀n inṣi mẹfa si mẹjọ. Ní mímọ iyẹn, ṣakiyesi fọto oke kekere, tabi òkìtì Beerṣeba ti o wà loke yii.a Àwọ̀ ewé ti o rí fihàn pe a ya fọto naa lẹhin òjò akoko iruwe ti kò pọ̀, nigba ti awọn papa ti ó wà layiika Beerṣeba tutù yọ̀yọ̀ fun akoko kukuru. Awọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti ń bẹ nitosi rẹ̀ dara—wọn sì dara sibẹ—fun ọ̀gbìn ọkà.
Nitori pe agbegbe naa gbẹ, awọn akọsilẹ Bibeli nipa Beerṣeba tẹnumọ ẹ̀tọ́ kànga ati omi. Ilu-nla naa wà nitosi awọn ọ̀nà tabi awọn oju ọ̀nà èrò ti o la aginju aṣalẹ naa kọja lọ jìnnà siha guusu. Bi o ti lè finú wò ó, awọn arinrin-ajo ti wọn ń kọja tabi ti wọn ń duro níhìn-ín yoo nilo omi fun araawọn ati fun awọn ẹran wọn. Iru omi bẹẹ kò rú jade lati inu ilẹ, gẹgẹ bi o ti ri ni Dani, ṣugbọn a lè rí i lati inu awọn kànga. Niti tootọ, ọ̀rọ̀ Heberu naa beʼerʹ tọka si kòtò tabi ihò kan ti a gbẹ́ lati fa ipese omi nisalẹ ilẹ. Beerṣeba tumọsi “Kanga Ibura” tabi, “Kànga Meje.”
Abrahamu ati idile rẹ̀ gbé ní Beerṣeba ati tòsí rẹ̀ fun ìgbà pipẹ, wọn sì mọ ijẹpataki awọn kànga. Nigba ti Hagari iranṣẹbinrin Sara sá lọ si aginju, o ti lè ṣeto lati rí omi lati inu awọn kànga tabi lati ọwọ́ awọn ara Bedouin ti wọn ń lò wọn—iru bi awọn obinrin Bedouin ni oju-iwe ti o tẹlee yii ti ń fa omi lati inu kànga kan ni Ilẹ Sinai ti omi fẹrẹẹ yika. Nigba ti Abrahamu nilati lé Hagari jade pẹlu ọmọkunrin rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ èébú, ó fi pẹlu inurere pese omi fun mimu. Ki ni ṣẹlẹ nigba ti iyẹn tán? “Ọlọrun sì ṣí i ni oju, o sì rí kànga omi kan; o lọ, o sì pọnmi kún ìgò naa, o sì fi fun ọmọdekunrin naa mu.”—Genesisi 21:19.
Lati ibo ni Abrahamu ti rí omi ti o pọn kún ìgò omi Hagari? Boya nibi kànga ti ó ti gbẹ́ ni, nitosi eyi ti o gbin igi tamariski si. (Genesisi 21:25-33) A lè sọ pe awọn onimọ ijinlẹ ri idi yíyàn ti Abrahamu yan igi tamariski fi baamu nisinsinyi, nitori pe igi yii ní awọn ewé tẹ́ẹ́rẹ́ tẹ́ẹ́rẹ́ ti kìí padanu ọ̀rinrin pupọ, ki o baa lè jẹ́ pe yoo lè gbèrú laika ọ̀gbẹlẹ̀ agbegbe yii si.—Wo aworan ti o wà nisalẹ yii.
Ilẹ ti Abrahamu gbẹ́ ni a mẹnukan ni isopọ pẹlu aáwọ̀ kan laaarin oun ati ọba Filistini kan. Kànga jẹ́ ohun-ìní ṣiṣeyebiye nitori ọ̀wọ́ngógó omi lapapọ ati làálàá ti o gbà lati gbẹ́ kànga jijin kan. Niti gidi, nigba naa lọhun-un, ó jẹ́ mímú awọn ẹ̀tọ́ ohun-ìní ẹni ẹlẹ́ni mọ́ tẹni lati lo kànga kan laigba àṣẹ.—Fiwe Numeri 20:17, 19.
Bi iwọ bá ṣebẹwo si Oke Kekere Beerṣeba, iwọ le yọju wo kànga jijin kan ni gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ apa iha guusu ila-oorun. Kò si ẹnikẹni ti o mọ ìgbà ti a kọ́kọ́ gbẹ́ ẹ la inu apata lile kọja ti a sì wá fi okuta mọ odi yí apa oke rẹ̀ (eyi ti a rí nisalẹ yii) ká lẹhin naa. Awọn awalẹpitan ode-oni kó pantiri kuro lori rẹ̀ ni ọgọrun-un ẹsẹ bata sisalẹ láìdé isalẹ rẹ̀. Ọ̀kan ninu wọn sọ pe: “Ohun ti ń dánniwò ni lati pari ero pe kànga yii ni . . . ‘Kànga Ìbúra’ nibi ti Abrahamu ati Abimeleki ti dá majẹmu wọn.”—Biblical Archaeology Review.
Dajudaju, Beerṣeba wá gbèrú ni títóbi ni akoko Bibeli, ni didi ilu-nla olódi kan pẹlu ẹnu-ibode nla kan. Ṣugbọn kọkọrọ kan si wíwà ati aṣeyọrisirere rẹ̀ ni omi pataki naa lati inu kànga rẹ̀ jijin.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun aworan Oke Kekere Beerṣeba ti o tubọ tobi, wo 1993 Calendar of Jehovah’s Witnesses.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.