ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KÍRÓNÍKÀ 29-32
Ìjọsìn Tòótọ́ Gba Ìsapá
Bíi Ti Orí Ìwé
Hesekáyà fẹ́ kí àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ṣe ìjọsìn tòótọ́, ó sì ṣàṣeyọrí
746 sí 716 Ṣ.S.K.
Ìṣàkóso Hesekáyà
NÍSÀN 746 Ṣ.S.K.
Ọjọ́ 1 sí 8: Ó sọ àgbàlá inú lọ́hùn-ún di mímọ́
Ọjọ́ 9 sí 16: Ó fọ ilé Jèhófà mọ́
Ètùtù fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti ìmúbọ̀sípò ìjọsìn tòótọ́ bẹ̀rẹ̀
740 Ṣ.S.K.
Samáríà pa run
Hesekáyà ní kí gbogbo àwọn tó lọ́kàn rere pé jọ láti jọ́sìn Ọlọ́run
Ó ní kí àwọn sárésáré pín lẹ́tà tó fi ṣèfilọ̀ Ìrékọjá jákèjádò ilẹ̀ náà, láti Bíá-ṣébà dé Dánì
Àwọn kan fi wọ́n ṣẹ̀sín, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló wá síbi Ìrékọjá náà