Idi Ti Bibeli Fi Jẹ Ẹbun Onímìísí Ti Ọlọrun
BIBELI sọ pe: “Ọlọrun jẹ́ ifẹ” o si sọ pe tirẹ̀ ni ọgbọn ati agbara. (1 Johanu 4:8, New World Translation [Gẹẹsi]; Joobu 12:13; Aisaya 40:26) Ó sọ fun wa pe “idajọ ni gbogbo ọna rẹ̀.” (Deutaronomi 32:4) Gẹgẹ bi Bibeli ti wi, Ọlọrun ń fi awọn animọ bii aanu ati ìyọ́nú han pẹlu.—Ẹkisodu 34:6; Roomu 9:15.
Nitori pe Bibeli ka iru awọn animọ bẹẹ si ti Jehofa Ọlọrun, o fa awọn eniyan oluwakiri sunmọ ọn. Iwe yii sọrọ nipa iṣẹda, orisun ẹ̀ṣẹ̀ ati iku, ati ọna lati gbà làjà pẹlu Ọlọrun. Ó nawọ ireti amunilọkanyọ ti Paradise ti a mu padabọsipo sori ilẹ̀-ayé jade. Ṣugbọn gbogbo eyi wulo kiki bi a ba lè fidi rẹ̀ mulẹ pe Bibeli jẹ ẹbun onímìísí lati ọdọ Ọlọrun.
Bibeli ati Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀
Bibeli ti fi ìgbà gbogbo bori ọrọ lámèyítọ́. Fun apẹẹrẹ, nigba ti a bá ka a pẹlu ọkan-aya ti kò ni ẹ̀tanú, a rí i pe o bá ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tootọ mu. Niti tootọ, a pese Bibeli gẹgẹ bi atọnisọna nipa tẹmi, kì í ṣe bi iwe idanilẹkọọ imọ ijinlẹ. Ṣugbọn jẹ ki a wò ó boya Bibeli gbà pẹlu awọn otitọ ti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀.
Igbekalẹ Ara Ẹda Alaaye: Bibeli sọ lọna pipeye pe ‘gbogbo apá’ ọlẹ̀ eniyan kan ni a ‘kọ silẹ.’ (Saamu 139:13-16) Ọpọlọ, ọkan-aya, ẹ̀dọ̀fóró, oju—iwọnyi ati gbogbo apa miiran ninu ara ni a ‘kọ silẹ’ sinu akojọ ofin apilẹ̀-àbùdá ẹyin ti a ti sọ dọmọ ninu ile ọlẹ̀ iya naa. Ohun ti akojọ ofin yii ní ninu ni awọn akọsilẹ akoko inu lọhun-un fun ifarahan ọkọọkan awọn apa wọnyi ni ọ̀nà ti o yẹ ki wọn gbà tẹlera. Sì rò ó wò ná! Otitọ yii nipa idagbasoke ara eniyan ni a ṣakọsilẹ rẹ̀ ninu Bibeli ni ohun ti o fẹrẹẹ tó 3,000 ọdun ṣaaju ki awọn onimọ ijinlẹ tó ṣàwárí akojọ ofin apilẹ̀-àbùdá.
Igbesi Aye Ẹranko: Gẹgẹ bi Bibeli ti wi, “ehoro . . . ń jẹ àpọ̀jẹ.” (Lefitiku 11:6) François Bourlière (The Natural History of Mammals, 1964 oju-iwe 41) sọ pe: “Aṣa ‘pípọ̀,’ tabi jíjẹ́ ki ounjẹ kọja lẹẹmeji ninu ìfun dipo ẹ̀ẹ̀kanṣoṣo pere, dabi ẹni pe ó jẹ́ iru ihuwasi wiwọpọ kan laaarin awọn ehoro onirun ati ehoro. Awọn ehoro ile onírun lára sábà maa ń jẹun ti wọn sì ń gbé ounjẹ mì laijẹ pe wọn jẹ ìgbẹ́ wọn òru, eyi ti o maa ń parapọ jẹ́ ohun ti o pọ tó ilaji apapọ ohun ti ó wà ninu ikùn wọn ni owurọ. Laaarin awọn ehoro onírun lára pípọ̀ ń wáyé lẹẹmeji loojọ, aṣa kan naa ni a sì rohin nipa ehoro Oyinbo.” Ni ọ̀nà yii, iwe naa Mammals of the World (lati ọwọ E. P. Walker, 1964, Idipọ II, oju-iwe 647) sọ pe: “Eyi lè ri bakan naa pẹlu ‘jíjẹ àpọ̀jẹ’ laaarin awọn ẹranko afọ́mọlọ́mú ti ń pọ ounjẹ pada sẹnu jẹ.”
Iwalẹpitan: Awọn ọba, ilu-nla, ati orilẹ-ede inu Bibeli ni a ti mu wá si ojutaye pẹlu awari awọn wàláà alámọ̀, ohun eelo amọ̀, awọn ikọwe, ati awọn nǹkan bẹẹ bẹẹ miiran. Fun apẹẹrẹ, iru awọn eniyan bii awọn ara Hiti ti a mẹnukan ninu Iwe Mimọ wà rí niti tootọ. (Ẹkisodu 3:8) Ninu iwe rẹ̀ The Bible Comes Alive, Sir Charles Marston sọ pe: “Awọn wọnni ti wọn ti mi igbagbọ tí awọn eniyan ni gbogbogboo ní ninu Bibeli, ti wọn sì jin ọla-aṣẹ rẹ̀ lẹsẹ, ni idakeji awọn ni a ń jinlẹsẹ nipasẹ ẹri ti a ti mú wá sojutaye, a si ti pa ọla-aṣẹ wọn run. Ohun ti awọn awalẹpitan ti hú jade nilẹ ń lé lámèyítọ́ aṣebajẹ kuro lori pápá otitọ tí ó runiloju sinu eyi ti a mọ̀ si ìtàn àlọ́.”
Iwalẹpitan ti ti Bibeli lẹhin ni ọpọlọpọ ọna. Fun apẹẹrẹ, awọn awari ti jẹrii si otitọ awọn ibi ati orukọ ti a ri ninu Jẹnẹsisi ori 10. Awọn awalẹ̀ ti walẹ kuro loju ilu-nla Uri ti Kaldea, aarin gbungbun igbokegbodo iṣowo ati isin nibi ti a ti bí Aburahamu. (Jẹnẹsisi 11:27-31) Loke ojúsun Gihoni ni guusu ìhà ila-oorun Jerusalẹmu, awọn awalẹpitan ṣawari ilu-nla ti awọn ara Jebusi ti Ọba Dafidi gbà. (2 Samuẹli 5:4-10) Ikọwe Siloamu ti a gbẹ́ si ara igun kan lara oju iho omi, tabi oju iṣan-omi ti Ọba Hesekaya, ni a ṣawari rẹ̀ ni ọdun 1880. (2 Ọba 20:20) Iṣubu Babiloni sọwọ Kirusi Nla naa ni ọdun 539 B.C.E. ni a sọ itan rẹ̀ ninu Iwe Itan Nabonidus Chronicle, ti a hú jade ninu ilẹ ni ọrundun 19 C.E. Kulẹkulẹ inu iwe Ẹsiteri ni a jẹrii tilẹhin pẹlu awọn ikọwe lati ilu Persepolis ati awọn ohun ti a ṣawari ni aafin Ọba Xerxes (Ahasuerusi) ni ilu Ṣuṣani, tabi Susa, laaarin ọdun 1880 ati 1890 C.E. Ikọwe kan ti a rí ninu ahoro yàrá iṣere Roomu kan ni Kesaria ni 1961 fẹ̀rí wíwà gomina Roomu Pontu Pilatu han, ẹni ti o fa Jesu kalẹ fun kikan mọgi.—Matiu 27:11-26.
Imọ Ẹkọ Nipa Sánmọ̀: Ni nǹkan bii 2,700 ọdun sẹhin—ọdun gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ṣaaju ki awọn eniyan lapapọ to mọ̀ pe ayé ri roboto—wolii Aisaya kọwe pe: ‘Ẹnikan wà ti o jokoo lori òbìrí ayé.’ (Aisaya 40:22) Ọrọ ede Heberu naa chugh ti a tumọ nihin-in si “òbìrí,” ni a lè tumọ si “róbótó” pẹlu. (A Concordance of the Hebrew and Chaldee Scriptures, lati ọwọ B. Davidson) Bakan naa, pẹlu, “òbìrí” ti ofuurufu aye ni a lè ri kedere lati gbangba ojude ofuurufu ati nigba miiran bi a bá ń rìnrìn àjò ninu ọkọ ofuurufu ti o bá fò ga roke lálá. Lọna ti o ṣe kòńgẹ́, Joobu 26:7 sọ pe Ọlọrun “fi aye rọ̀ ni oju òfo.” Otitọ ni eyi, nitori awọn onimọ ẹkọ nipa sanmọ mọ̀ pe ayé kò ni ohun ti a lè fojuri kan ti o gbé e duro.
Imọ Ẹkọ Nipa Eweko: Awọn kan fi iṣina dori opin ero naa pe Bibeli láṣìṣe nitori pe Jesu Kristi sọ nipa “wóro irugbin mustadi” gẹgẹ bii eyi ti o “kere ju gbogbo irugbin ti o wà ni ilẹ lọ.” (Maaku 4:30-32) O ṣeeṣe ki Jesu ti ni irugbin igi mustadi dudu (Brassica nigra tabi Sinapis nigra) lọkan, eyi ti o jẹ nǹkan bii 0.039 si 0.063 íǹṣì ní ìbú. Bi o tilẹ jẹ pe awọn irugbin miiran wa ti wọn kere ju bẹẹ lọ, iru bii awọn irugbin igi orchid ti o kéré-bí-ìyẹ̀fun, kii ṣe awọn eniyan ti ń gbin orchid ni Jesu ń bá sọrọ. Awọn Juu ara Galili wọnni mọ pe lara awọn oriṣiriṣi irugbin ti awọn àgbẹ̀ adugbo ń gbin, irugbin mustadi ni o kere julọ. Jesu ń sọrọ nipa Ijọba naa, kii ṣe pe o ń kọnilẹkọọ nipa awọn eweko.
Imọ Ẹkọ Nipa Itan Ipele Ilẹ̀, Okuta ati Ẹda Inu Ilẹ̀-Ayé: Niti irohin iṣẹlẹ Bibeli nipa iṣẹda, onimọ ẹkọ nipa itan ipele ilẹ, okuta ati ẹda inu ilẹ̀-ayé ti a mọ bi ẹni mọ owó naa Wallace Pratt sọ pe: “Bi a bá kesi mi gẹgẹ bi onimọ ẹkọ nipa itan ipele ilẹ, okuta ati ẹda inu ilẹ̀-ayé lati ṣalaye kukuru nipa oye wa ti ode-oni nipa ibẹrẹ ilẹ̀-ayé ati idagbasoke iwalaaye ori rẹ̀ fun awọn eniyan ti kò fi bẹẹ lajú, ti wọn jẹ́ darandaran, bi iru awọn ẹya ti a kọ Iwe Jẹnẹsisi sí, yoo nira fun mi lati ṣe daradara ju pe ki ń wulẹ tẹle eyi ti o pọju ninu ede inu ori akọkọ ti Jẹnẹsisi timọtimọ.” Pratt ṣakiyesi pe itolẹsẹẹsẹ awọn iṣẹlẹ inu Jẹnẹsisi—ipilẹṣẹ awọn agbami okun, iyọrijade ilẹ̀, ati lẹhin naa ifarahan iwalaaye ẹda inu okun, awọn ẹyẹ, ati awọn ẹda afọ́mọlọ́mú—jẹ niti gidi eyi ti o ba itotẹlera iṣẹlẹ awọn ẹka pataki pataki ti akoko inu itan ipele ilẹ̀, okuta ati ẹda inu ilẹ̀-ayé ṣe deedee.
Imọ Ẹkọ Iṣegun: Ninu iwe rẹ̀ The Physician Examines the Bible, C. Raimer Smith kọwe pe: “O jẹ iyalẹnu gidigidi fun mi pe Bibeli ṣe wẹku to bẹẹ lati inu oju-iwoye ti iṣegun. . . . Nibi ti a bá ti mẹnukan ìṣètọ́jú, bii fun oówo, ọgbẹ́, ati bẹẹ bẹẹ lọ, o ṣe wẹku ani loju idiwọn ti ode-oni paapaa. . . . Iye awọn eniyan ti o pọ̀ gan an ṣì nigbagbọ ninu ọpọ ohun asan iru bii, pe eso igi buckeye kan ti o wà ninu àpò yoo ṣedilọwọ fun nini àrùn àwọ́ká; pe mimu ọ̀pọ̀lọ́ dani yoo ṣokunfa ara yíyi; pe bi a bá we asọ pupa mọ ọrùn yoo ṣewosan fun ọgbẹ ọna ọfun; pe gbígbé àpò tí eweko asafetida wà ninu rẹ̀ kọ́rùn yoo ṣediwọ fun awọn àrùn; pe gbogbo ìgbà ti ọmọde kekere kan ba ń ṣaisan a jẹ pe o ni aràn; ati bẹẹ bẹẹ lọ, ṣugbọn kò si iru awọn ọrọ bẹẹ ninu Bibeli. Eyii ninu araarẹ̀ gbafiyesi ati fun mi o jẹ ẹri miiran pe o ni ipilẹṣẹ atọrunwa.”
O Ṣe e Gbarale Niti Kulẹkulẹ Itan
Ninu iwe rẹ̀ A Lawyer Examines the Bible, agbẹjọro Irwin H. Linton ṣakiyesi pe: “Nigba ti awọn iṣẹ iwe kikọ, itan arosọ ati ijẹwọ eke a maa ṣọra lati fi awọn iṣẹlẹ ti a rohin si ibikan ti o jinna ati akoko kan ti kò ṣe gúnmọ́, ti wọn sì ń tipa bẹẹ rú awọn ofin akọkọ ti awa agbẹjọro kọ́ nipa igbẹjọ ofin ile-ẹjọ daradara kan, pe ‘ipolongo gbọdọ funni ní akoko ati ibi iṣẹlẹ,’ irohin Bibeli fun wa ni akoko ati ibi ti awọn nǹkan ti a rohin ti ṣẹlẹ pẹlu iṣepato ti ó pọ̀ julọ.”
Lati fidi koko yii mulẹ, Linton tọkasi Luuku 3:1, 2. Nibẹ onkọwe Ihinrere naa mẹnukan awọn ijoye oṣiṣẹ meje ki a baa lè fidi akoko naa mulẹ nigba ti Jesu Kristi bẹrẹ iṣẹ ojiṣẹ Rẹ̀. Ṣakiyesi awọn kulẹkulẹ ti Luuku pese ninu awọn ọrọ wọnyi: “Ni ọdun kẹẹdogun ijọba Tiberiu Kesari, nigba ti Pontiu Pilatu jẹ́ Baalẹ, Judia, ti Herodu si jẹ́ tetrarki Galili, Filipi arakunrin rẹ̀ si jẹ́ tetrarki Iturea ati ti Trakoniti, Lisania si jẹ́ tetrarki Abilene. Ti Anna oun Kayafa ń ṣe olori awọn alufaa, nigba naa ni ọrọ Ọlọrun tọ Johanu ọmọ Sakaraya wá ní ijù.”
Bibeli kun fun awọn kulẹkulẹ ti o jọra. Siwaju sii, awọn apakan ninu rẹ̀ bii ti awọn Ihinrere ni a kọ silẹ ni sáà ti aṣa iṣẹdalẹ awọn Juu, Giriiki, ati awọn ara Roomu ti dagbasoke gidigidi. Ó jẹ akoko awọn agbẹjọro, onkọwe, alakooso, ati iru awọn eniyan miiran bẹẹ. Dajudaju, nigba naa, bi awọn kulẹkulẹ ti a ri ninu awọn Ihinrere ati ni awọn apa miiran ninu Bibeli kò ba ti jẹ́ otitọ gidi, awọn ni a kì ba ti túfó gẹgẹ bi eyi ti o kun fun jìbìtì. Ṣugbọn awọn opitan aye alaijẹ ti isin fidi iru awọn kókó bii wíwà Jesu mulẹ. Fun apẹẹrẹ, nipa ti Jesu ati awọn ọmọlẹhin rẹ̀ opitan ara Roomu naa Tacitus kọwe pe: “Christus, lati inu ẹni ti orukọ naa [Kristẹni] ti ní ipilẹṣẹ rẹ̀, fojúwiná ijiya lílégbákan nigba ijọba Tiberius ni ọwọ́ ọkan lara awọn aṣoju ọba wa Pontius Pilatus.” (Annals, Book XV, 44) Ipe perepere Bibeli niti ọrọ ìtàn ṣeranwọ lati fẹ̀rí han pe o jẹ ẹbun Ọlọrun fun araye.
Ẹ̀rí Titobi Julọ
Bi o tilẹ jẹ pe imọ ẹkọ nipa iwalẹpitan, sánmọ̀, itan, ati awọn papa imọ miiran ti Bibeli lẹhin, igbagbọ ninu rẹ̀ ko sinmi lé iru awọn ijẹwọ bẹẹ. Lara ọpọ ẹ̀rí ti ó wà pe Bibeli jẹ ẹbun onímìísí ti Ọlọrun fun wa, ko si ẹri titobi ju ti a le gbekalẹ ju imuṣẹ awọn asọtẹlẹ rẹ̀ lọ.
Jehofa Ọlọrun ni Orisun asọtẹlẹ tootọ. Nipasẹ wolii rẹ̀ Aisaya, oun wi pe: “Kiyesi i, nǹkan iṣaaju ṣẹ, nǹkan titun ni emi si n sọ: ki wọn tó hù, mo mu yin gbọ́ wọn.” (Aisaya 42:9) Ju bẹẹ lọ, Bibeli sọ pe awọn onkọwe rẹ̀ ni Ọlọrun misi nipasẹ ẹmi mimọ rẹ̀, tabi ipá agbekankan ṣiṣẹ. Fun apẹẹrẹ, Kristẹni apọsiteli Pọọlu kọwe pe: “Gbogbo iwe mimọ, [ni] o ni imisi Ọlọrun.” (2 Timoti 3:16) Apọsiteli Peteru kọwe pe: “Ko si ọkan ninu asọtẹlẹ inu iwe mimọ ti o ní itumọ ikọkọ. Nitori asọtẹlẹ kan kò ti ipa ifẹ eniyan wá rí; ṣugbọn awọn eniyan ń sọrọ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun bí a ti ń dari wọn lati ọwọ́ ẹmi mimọ wá.” (2 Peteru 1:20, 21) Nitori naa ẹ jẹ ki a wo asọtẹlẹ Bibeli.
Lara awọn ọgọrọọrun asọtẹlẹ ti o wà ninu Bibeli ni awọn wọnni ti o nii ṣe pẹlu olu-ilu Asiria, Ninefe, “ìlú ẹ̀jẹ̀” ti o gbin ibẹru sinu awọn orilẹ-ede jakejado Aaringbungbun Ila-oorun igbaani fun eyi ti o ju ọrundun 15 lọ. (Nahumu 3:1) Sibẹ, ní otente agbara Ninefe, Bibeli sọtẹlẹ pe: “[Ọlọrun] yoo si sọ Ninefe di ahoro, ati di gbigbẹ bi aginju. Agbo-ẹran yoo si dubulẹ ni aarin rẹ̀, gbogbo ẹranko awọn orilẹ-ede: ati ẹyẹ òfu ati òòrẹ̀ yoo ma gbe atẹrigba rẹ̀, ohun wọn yoo kọrin ni oju ferese; idahoro yoo wà ninu iloro: nitori ti oun yoo ṣi iṣẹ kedari silẹ.” (Sefanaya 2:13, 14) Lonii, awọn oluṣebẹwo rii pe kiki okiti alapa kan ni o sami si ibi ilẹ isọdahoro Ninefe igbaani. Siwaju sii, awọn agbo agutan ń jẹ papa nibẹ, gẹgẹ bi a ti sọtẹlẹ.
Ninu iran, wolii Daniẹli ri àgbò oniwo meji kan ati akọ ewurẹ pẹlu iwo alagbara kan laaarin awọn oju rẹ̀. Ewurẹ naa kan agbo naa mọlẹ, ni ṣíṣẹ́ awọn iwo rẹ̀ mejeeji. Lẹhin naa, iwo ewurẹ naa ti o lagbara ni a ṣẹ́, ti awọn iwo mẹrin si yọ jade ní ipo rẹ̀. (Daniẹli 8:1-8) Angẹli Geburẹli naa ṣalaye pe: “Àgbò naa ti iwọ rí ti o ni iwo meji nì, awọn ọba Media ati Persia ni wọn. Òbúkọ onirun nì ni ọba Giriiki: iwo nla ti o wà laaarin oju rẹ̀ mejeeji ni ọba ekinni. Njẹ bi eyiini si ti ṣẹ́, ti iwo mẹrin miiran si dide duro nipo rẹ̀, ijọba mẹrin ni yoo dide ninu orilẹ-ede naa, ṣugbọn ki yoo ṣe ninu agbara rẹ̀.” (Daniẹli 8:20-22) Gẹgẹ bi ọrọ itan ti fihan, àgbò oníwo meji naa—Ilẹ-Ọba Media-ati-Persia—ni a doju ijọba rẹ̀ bolẹ nipasẹ “ọba Giriiki.” Akọ-ewurẹ iṣapẹẹrẹ yẹn ní “iwo nla” ti o jẹ́ Alẹkisanda Nla funraarẹ. Lẹhin iku rẹ̀, awọn ọgagun rẹ̀ mẹrin dipo “iwo nla” yẹn nipa gbigbe araawọn kalẹ ninu agbara “ijọba mẹrin.”
Ọpọ tabua awọn asọtẹlẹ ninu Iwe Mimọ lede Heberu (“Majẹmu Laelae”) ni a ti muṣẹ ni isopọ pẹlu Jesu Kristi. Diẹ ninu iwọnyi ni awọn onkọwe Iwe Mimọ Kristẹni lede Giriki (“Majẹmu Titun”) ti a misi latọrunwa lo lati darí ọrọ si i. Fun apẹẹrẹ, onkọwe Ihinrere naa Matiu ṣalaya imuṣẹ tí awọn asọtẹlẹ Iwe Mimọ ní ninu ibi Jesu nipasẹ wundia kan, ninu nini aṣaaju Rẹ̀ kan, ati iwọle Rẹ si Jerusalẹmu lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan. (Fi Matiu 1:18-23; 3:1-3; 21:1-9 wera pẹlu Aisaya 7:14; 40:3; Sekaraya 9:9.) Iru awọn asọtẹlẹ ti a muṣẹ bẹẹ ṣeranwọ lati fi ẹ̀rí han pe Bibeli niti tootọ jẹ ẹbun ti Ọlọrun misi.
Imuṣẹ asọtẹlẹ Bibeli ni lọwọlọwọ yii fẹri han pe awa ń gbé ninu “ikẹhin ọjọ.” (2 Timoti 3:1-5) Awọn ogun, aito ounjẹ, ajakalẹ àrùn, ati awọn isẹlẹ ti ko ni alabaadọgba ní iwọn jẹ apakan “ami wíwànihin-in” Jesu ninu agbara Ijọba. Ami yẹn pẹlu tun wémọ́ igbokegbodo yika ayé ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti iye wọn lé ni million mẹrin, ti wọn ń waasu ihinrere Ijọba naa ti a ti fidi rẹ̀ múlẹ̀. (Matiu 24:3-14, NW; Luuku 21:10, 11) Asọtẹlẹ Bibeli ti ń ni imuṣẹ nisinsinyi pẹlu tun mú un dá wa loju pe ijọba oke ọrun ti Ọlọrun labẹ Jesu Kristi laipẹ yoo mu aye titun ti ayọ ayeraye wá fun araye onigbọran.—2 Peteru 3:13; Iṣipaya 21:1-5.
Apoti isọfunni ti o bá a rìn yii ti a fun lakori naa “Awọn Asọtẹlẹ Bibeli ti ó ní Imuṣẹ” gbe kiki diẹ kalẹ ninu awọn ọgọrọọrun asọtẹlẹ Bibeli ti a le tò lẹsẹẹsẹ. Imuṣẹ diẹ ninu awọn wọnyi ni a tọkasi ninu Iwe Mimọ naa funraawọn, ṣugbọn eyi ti o yẹ fun afiyesi ni pataki ni awọn asọtẹlẹ ti a ń muṣẹ lonii.
Boya, iwọ le ri awọn idagbasoke kan pato yika aye ti a sọtẹlẹ ninu Bibeli. Ṣugbọn eeṣe ti o ko fi wadii siwaju sii? Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yoo fi tayọtaya pese awọn afikun kulẹkulẹ bi iwọ ba beere fun un. Ǹjẹ́ ki iwakiri olotiitọ ọkàn rẹ fun imọ nipa Ẹni Giga Julọ ati awọn ète rẹ̀ yi ọ lọkan pada lati gbagbọ pe Bibeli niti tootọ jẹ ẹbun ti onímìísí Ọlọrun.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 7]
AWỌN ASỌTẸLẸ BIBELI TI O NÍ IMUṢẸ
ASỌTELẸ IMUṢẸ
Jẹnẹsisi 49:10 A fi Juda ṣe ẹya-iran ọlọba ti Isirẹli
Sefanaya 2:13, 14 A sọ Ninefe dahoro ni nǹkan bii
632 B.C.E.
Jeremaya 25:1-11; Iṣẹgun Jerusalẹmu bẹrẹ isọdahoro
Aisaya 39:6 70 ọdun (2 Kironika 36:17-21;
Aisaya 13:1, 17-22; Kirusi ṣẹgun Babiloni; Awọn Juu pada
44:24-28; 45:1, 2 si ilẹ ibilẹ wọn (2 Kironika
36:20-23; Ẹsira 2:1-6)
Daniẹli 8:3-8, 20-22 Media-ati-Persia ni a doju ijọba wọn
dé nipasẹ Alẹkisanda Nla ti a sì pín
Ilẹ-oba Giriiki si meji
Aisaya 7:14; Mika 5:2 Jesu ni wundia kan bi ní Bẹtilẹhẹmu
Daniẹli 9:24-26 Fifi ororo yan Jesu gẹgẹ bi Mesaya
(29 C.E.) (Luuku 3:1-3, 21-23)
Aisaya 9:1, 2 Iṣẹ ojiṣẹ ìlanilọ́yẹ̀ Jesu bẹrẹ ni
Galili (Matiu 4:12-23)
Aisaya 53:4, 5, 12 Iku Kristi gẹgẹ bi ẹbọ irapada (Matiu
20:28; 27:50)
Saamu 22:18 Ṣíṣẹ́ gègé lé aṣọ awọleke Jesu (Johanu
19:23, 24)
Saamu 16:10; Ajinde Jesu ni ọjọ kẹta (Maaku 16:
1-6; Matiu 12:40 1 Kọrinti 15:3-8)
Luuku 19:41-44; 21:20-24 Iparun Jerusalẹmu lati ọwọ awọn ara
Roomu (70 C.E.)
Luuku 21:10, 11; Ija ogun ti kò ní alabaadọgba, iyan,
Matiu 24:3-13; isẹlẹ, ajakalẹ arun, iwa ailofin, ati bẹẹ
2 Timoti 3:1-5 bẹẹ lọ, ti ń fi “awọn ọjọ ikẹhin” hàn
Matiu 24:14; Ipolongo yika aye nipasẹ Awọn Ẹlẹ́rìí
Aisaya 43:10;Saamu 2:1-9 Jehofa pe Ijọba Ọlọrun ni a ti fidi rẹ̀
múlẹ̀ ti yoo si ṣẹgun gbogbo awọn
alatako laipẹ
Matiu 24:21-34; Idile agbaye ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti
Iṣipaya 7:9-17 wọn ń jọsin Ọlọrun ti wọn si ń murasilẹ
fun lila “ipọnju nla naa” já
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ogun, iyan, ajakalẹ arun, ati awọn isẹlẹ ti ṣokunfa ipalara pupọ lonii, ṣugbọn aye titun ti alaafia ati ayọ ku si dẹdẹ