ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 7/1 ojú ìwé 4-7
  • Ireti Ṣẹgun Ainireti!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ireti Ṣẹgun Ainireti!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipilẹ naa Fun Ireti
  • Ireti—“Ti O Daju Ti O sì Duroṣinṣin”
  • Ireti—“Ìdákọ̀ró fun Ọkàn”
  • ‘Dì í Mú Ṣinṣin’!
  • Jẹ́ Kí Ìrètí Tó O Ní Dá Ẹ Lójú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Ìrètí Tó O Ní Ò Ní Já Ẹ Kulẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ibo Lo Ti Lè Rí Ìrètí Tòótọ́?
    Jí!—2004
  • Ní Ìrètí Nínú Jèhófà Kó o Sì Jẹ́ Onígboyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 7/1 ojú ìwé 4-7

Ireti Ṣẹgun Ainireti!

NINU iwe atumọ ọrọ naa Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary, ainireti ni a tumọ si “ipadanu ireti patapata.” Ni kedere, nigba naa, lati ṣẹgun ainireti, a nilo ireti!

Aláìríbátiṣé kan ti ó di dandan fun lati maa gbé ní ẹ̀gbẹ́ oju-ọna kì yoo di alainireti patapata bi ó bá ni ireti. Ireti tilẹ lè fun awọn ti ayẹwo fihan pe wọn ń jiya lọwọ isorikọ ni igboya ati okun lati lè farada a. Ṣugbọn ireti naa gbọdọ jẹ eyi ti o ṣee fọkantẹ! Ki ni eyi tumọsi?

Ipilẹ naa Fun Ireti

Gbé ohun ti o ṣẹlẹ si Sara, iyawo babanla naa Abrahamu yẹwo. Ni sisunmọ ẹni 90 ọdun, oun jẹ́ àgàn sibẹ ti o sì ti di alainireti nipa mimu ọmọ jade fun ìgbà pipẹ. Sibẹ, nigba ti ọkọ rẹ̀ jẹ́ ẹni 99 ọdun, Jehofa ṣatunsọ ileri ti o ti ṣe ni ọpọ ọdun ṣaaju—Abrahamu niti tootọ yoo ni “iru-ọmọ,” tabi ajogún. Abrahamu mọ pe eyi jẹ ileri kan ti o ṣee fọkantẹ. Finuro bi ayọ Sara ti nilati pọ tó nigba ti, lọna iṣẹ iyanu, iṣẹlẹ amọkanyọ naa waye, ti o sì bi Isaaki! (Genesisi 12:2, 3; 17:1-4, 19; 21:2) Igbẹkẹle Abrahamu ninu Ọlọrun ni a kò ṣì lọna, ani gẹgẹ bi aposteli Paulu ti ṣalaye: “[Abrahamu] kò fi aigbagbọ ṣiyemeji ileri Ọlọrun; ṣugbọn ó le ni igbagbọ, ó ń fi ogo fun Ọlọrun.”—Romu 4:20.

Ni kikọwe si awọn Ju ti wọn ti di Kristian ni ọjọ rẹ̀, Paulu ronu pe wọn lè gbọkanle ileri Ọlọrun fun igbala nipasẹ Jesu fun awọn idi yiyekooro meji. Ni fifa ileri Ọlọrun fun Abrahamu yọ ati ibura atọrunwa Rẹ̀ ti o bá a rìn, aposteli naa jiroro pe: “Eniyan a maa fi ẹni ti o pọju wọn bura: ibura naa a sì fi opin si gbogbo ijiyan wọn fun ifẹsẹmulẹ ọ̀rọ̀. Ninu eyi ti bí Ọlọrun ti . . . ń fẹ gidigidi lati fi aileyipada ìmọ̀ rẹ̀ hàn fun awọn ajogún ileri, o fi ibura saaarin wọn. Pe, nipa ohun aileyipada meji, ninu eyi ti kò lè ṣeeṣe fun Ọlọrun lati ṣèké, ki awa ti o ti sá sabẹ aabo lè ni ìṣírí ti o daju lati di ireti ti a gbekalẹ niwaju wa mu.” (Heberu 6:16-18) Bẹẹni, awọn ileri Ọlọrun jẹ otitọ ti wọn sì ṣee fọkantẹ. Jehofa ni olodumare ati ẹni ti o lè mú imuṣẹ ọrọ tirẹ̀ alára daniloju lọna ti kò lẹgbẹ.

Ireti—“Ti O Daju Ti O sì Duroṣinṣin”

Paulu kọwe pe ireti awọn Kristian jẹ́ eyi “ti o daju ti o sì duroṣinṣin.” (Heberu 6:19) Paulu mọ ibi ti ireti rẹ̀ ta gbongbo si. Oun ṣalaye pe: “Ó [ireti naa] sì wọ inu ile lọ lẹhin aṣọ ìkélé.” Ki ni eyi tumọ si? O ṣe kedere pe Paulu ń tọka si tempili igbaani ni Jerusalemu. Ninu eyi ni iyàrá ìkélé Ibi Mimọ Julọ wà, ti a yasọtọ lara iyooku ile naa nipasẹ aṣọ ìkélé kan. (Eksodu 26:31, 33; Matteu 27:51) Nitootọ, tempili gidi ti o wà ni Jerusalemu ni a ti parun fun ìgbà pípẹ́. Nitori naa, lonii, ki ni Ibi Mimọ Julọ yii bá dọgba?

Ọ̀run fúnraarẹ̀ ni, nibi ti Ọlọrun fúnraarẹ̀ wà lori ìtẹ́! Paulu ṣalaye eyi nigba ti o sọ pe Jesu lẹhin igoke re ọ̀run rẹ̀ “kò wọ ibi mimọ ti a fi ọwọ́ ṣe lọ [ninu tempili ni Jerusalemu], tíí ṣe apẹẹrẹ ti otitọ; ṣugbọn o lọ si ọ̀run paapaa, nisinsinyi lati farahan ni iwaju Ọlọrun fun wa.” (Heberu 9:24) Nitori naa ireti Kristian, ti ń ràn wá lọwọ lati jà lodisi ainireti, kò sinmile awọn eniyan oṣelu ṣugbọn lori eto atọrunwa. Ó sinmile Ẹnikanṣoṣo naa ti Ọlọrun ti yàn, Jesu Kristi, ẹni ti o fi iwalaaye rẹ̀ ṣe irapada ẹṣẹ wa ti o sì farahan nisinsinyi niwaju Ọlọrun nitori tiwa. (1 Johannu 2:1, 2) Siwaju sii, gẹgẹ bi a ti ń fihan ni gbogbo ìgbà ninu oju-iwe irohin yii, Jesu kan-naa yii ni ẹni kanṣoṣo ti a yàn latọrunwa lati ṣakoso gẹgẹ bi Ọba Ijọba ọ̀run ti Ọlọrun ti o sì ti ń ṣe bẹẹ lati 1914. Ijọba ọ̀run yii laipẹ yoo mu gbogbo ohun tí ń fa ainireti bá ọpọlọpọ kuro.

Ireti—“Ìdákọ̀ró fun Ọkàn”

Lati mú un dá awọn onkawe rẹ̀ loju pe ireti wọn fun igbala nipasẹ Jesu ni a gbekari otitọ, Paulu lo ohun ti o jọra lati ṣe ifiwera. “Eyi [ireti],” ni ó ṣalaye, “tí awa ní bi ìdákọ̀ró ọkàn.”—Heberu 6:19.

Ìdákọ̀ró jẹ́ ohun ti awọn arinrin-ajo bii Paulu mọ daradara. Ìdákọ̀ró ìgbà atijọ jọra gan-an pẹlu awọn ti ode-oni, eyi ti a sábà maa ń fi irin oníga meji ti o tẹ̀ wá soke ṣe lati di isalẹ òkun mú. Ni oju ọ̀nà irin-ajo si Romu ni nǹkan bii 58 C.E., ọkọ̀ òkun Paulu wà ninu ewu rírì sisalẹ omi. Ṣugbọn bi ọkọ̀ oju-omi naa ti ń wọnu omi ti kò ṣe bẹẹ jìn, awọn awakọ̀ “sọ ìdákọ̀ró mẹrin silẹ ni idikọ̀.” Ọpẹlọpẹ awọn ìdákọ̀ró wọnyẹn, ọkọ̀ naa la ìjì naa kọja laisewu.—Iṣe 27:29, 39, 40, 44.

Nigba naa, ki ni, iwọ gbọdọ ṣe lati mu ki ireti rẹ daju gẹgẹ bi ìdákọ̀ró ki iwọ baa lè la eto ọrọ ajé lilekoko, ailera nipa ti ara tabi ero imọlara, tabi iru “ìjì” eyikeyii miiran ti o lè wá si ipa-ọna rẹ já? Lakọọkọ, mú un dá araarẹ loju pe awọn ileri Bibeli jẹ́ eyi ti o ṣee gbẹkẹle. “Wadii ohun gbogbo daju.” (1 Tessalonika 5:21) Fun apẹẹrẹ, nigba ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bá tun bá ọ sọrọ, fetisilẹ si ohun ti wọn bá sọ. Bi wọn ki i bá fi bẹẹ ṣebẹwo si ibi ti o ń gbé, wá wọn rí ni Gbọngan Ijọba ti o sunmọ ọ julọ. A kì yoo fi ipá mú ọ lati darapọ mọ wọn, ṣugbọn wọn yoo késí ọ lati tẹwọgba ẹkọ Bibeli lọfẹẹ, eyi ti a ṣeto rẹ̀ fun didari nibikibi ati nigbakugba ti o bá rọrun fun ọ.

Iru ikẹkọọ bẹẹ yoo mú un dá ọ loju pe Ọlọrun “ni olusẹsan fun awọn ti o fi ara balẹ wá a.” (Heberu 11:6) Iwọ yoo kẹkọọ pe laipẹ Ijọba Ọlọrun labẹ Ọba naa, Kristi Jesu, yoo mu ìwà ibajẹ ati aiṣedaajọ ododo ti ó ń fa ainireti fun ọpọlọpọ lonii kuro. Labẹ Ijọba yẹn, ilẹ̀-ayé yii ni a o dápadà si Paradise, Ọlọrun yoo sì fi ìyè ayeraye fun awọn wọnni ti o fẹran rẹ̀. (Orin Dafidi 37:29; Ìfihàn 21:4) Iru ireti ologo wo ni eyi jẹ́!

Farabalẹ ka Bibeli lati rí i pe ireti yii jẹ́ otitọ. Nigba naa ṣiṣẹ lati mu ipo ibatan ara-ẹni timọtimọ dagba pẹlu Ọlọrun, ni didi ọ̀rẹ́ rẹ̀ gẹgẹ bi Abrahamu ti jẹ́. (Jakọbu 2:23) Niwọn bi Jehofa ti jẹ “Olugbọ adura,” sọ awọn aniyan rẹ fun un. Nigba ti wíwá rẹ si ọ̀dọ̀ rẹ̀ bá jẹ́ ti olotiitọ inú, adura rẹ yoo ṣeranwọ fun ọ ni mímú ẹrù-ìnira rẹ fúyẹ́ ki o sì ṣẹgun ainireti rẹ. Ẹmi Ọlọrun tilẹ lè ṣí ọ̀nà silẹ lati yi ipo ti ń mú ọ sorikọ pada.—Orin Dafidi 55:22; 65:2; 1 Johannu 5:14, 15.

‘Dì í Mú Ṣinṣin’!

Lẹhin didamọran pe ki awọn ọmọ-ẹhin ẹlẹgbẹ rẹ̀ “maa wadii ohun gbogbo daju,” Paulu fikun un pe: “Ẹ di eyi ti o dara mú ṣinṣin.” (1 Tessalonika 5:21) Ọ̀nà kan lati gba ṣe eyi ni lati kẹgbẹpọ pẹlu awọn eniyan ti wọn di ireti Kristian mú ṣinṣin pẹlu. Ọlọgbọn ọba Solomoni kilọ pe: “Ẹni ti ó ń bá ọlọgbọn rìn yoo gbọ́n; ṣugbọn ẹgbẹ́ awọn aṣiwere ni yoo ṣegbe.” (Owe 13:20) Maṣe jẹ ki ẹtanu tabi imọlara airọgbọ dí ọ lọwọ lati wá ibakẹgbẹpọ rere. Fun apẹẹrẹ, laaarin Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni awọn eniyan ti wọn jẹ́ alainireti nigba kan rí wà. Ṣugbọn ikẹkọọ Bibeli wọn, ni isopọ pẹlu ibakẹgbẹpọ alayọ ti awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn, fokun fun ipo ibatan wọn pẹlu Jehofa ti o sì pese ireti ti o dabii ìdákọ̀ró, ti o ṣee fọkantẹ fun wọn. Eyi ha ṣẹgun ainireti niti gidi bi? Dajudaju o ṣe bẹẹ.

Gbé ọ̀ràn ti Annmarie yẹwo, ẹni ti a tì lọ sinu ainireti nitori jijiya ibanilo buburu jai lati ọwọ ọkọ rẹ̀. “Mo pinnu lati fopin si iwalaaye mi,” ni ó ṣalaye, “ṣugbọn fun awọn idi kan mo pinnu lati gbadura si Ọlọrun lakọọkọ ná. Mo ranti sisọ pe, ‘Eeṣe ti o kò fi lè ràn mi lọwọ? Fun akoko pipẹ ni mo ti ni ireti ninu rẹ, ṣugbọn òtúbáńtẹ́ ni o jásí.’ Mo pari adura mi ni rironu pe igbesi-aye kò ni ète ninu, nipa bẹẹ emi pẹlu yoo kú. Ni iṣẹju yẹn mo gbọ́ ọwọ́ kíkàn lara ilẹkun. Mo pinnu lati ṣaláìkàásí, ni rireti pe ẹni yoowu ti ìbáà wà nibẹ yoo bá tirẹ lọ bópẹ́ bóyá.

“Kíkànkùn naa ń baa lọ laidawọduro, mo sì kún fun idaamu. Mo nu omije oju mi nù kuro mo sì lọ lati ri ẹni ti o wà lẹnu ilẹkun, ni rireti pe emi yoo tete dá araami silẹ ni kiakia ki n lè ṣe ohun ti mo petepero lati ṣe. Ṣugbọn,” ni Annmarie sọ, “ọpẹ ni fun Jehofa, kò ṣẹlẹ ni ọ̀nà yẹn, nitori nigba ti mo ṣí ilẹkun, mo ri awọn obinrin meji ti wọn duro sibẹ. Nitootọ, n kò mọ ohun ti mo lè ṣe mọ́, emi kò sì loye ohun ti wọn ń sọ niti gidi. Ṣugbọn wọn fun mi ni iwe kan ti yoo ṣalaye pe igbesi-aye ní ète ninu. Iyẹn gan-an ni mo nilo lati tun tannáran ifẹ-ọkan mi ninu igbesi-aye lẹẹkan sii.” Awọn olubẹwo rẹ̀ ṣeto fun ikẹkọọ Bibeli deedee pẹlu rẹ̀. Annmarie kẹkọọ lati di ọ̀rẹ́ Ọlọrun. Eyi, ní ọwọ keji ẹ̀wẹ̀, fun un ni ète ninu igbesi-aye. Nisinsinyi oun ń ṣeranwọ fun awọn ẹlomiran lati nigbẹkẹle ninu Ọlọrun.

Boya iwọ ti nireti fun mimu opin deba ainireti laimọ gbogbo ohun ti ó ni ninu. Ṣugbọn bi iwọ bá ti gbadura rí pe: “Ki ijọba rẹ dé; ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bii ti ọ̀run, bẹẹ ni ni ayé,” nigba naa iwọ ti gbadura fun dídé Ijọba Ọlọrun labẹ Jesu Kristi, ti yoo fopin si gbogbo awọn nǹkan wọnni ti ń fa awọn eniyan ọlọkan-aya titọ lọ sinu ainireti. (Matteu 6:10) Idakẹkọọ Bibeli rẹ ati ibakẹgbẹpọ deedee pẹlu awọn ẹlomiran ti wọn ni iru igbẹkẹle kan naa yẹn yoo fi okun fun didi ireti rẹ mú fun Ijọba Jehofa lati de ki o sì mú Paradise wá si ilẹ̀-ayé wa. (1 Timoteu 6:12, 19) Eyi ni ireti ologo ti iwe irohin yii ń kede rẹ̀ ninu gbogbo itẹjade kọọkan. Gbá ireti naa mú tọkantọkan lati jà lodisi ainireti. Nitootọ, ireti “kìí sìí dojutini.”—Romu 5:5.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Kikẹkọọ Bibeli fun wa ni ireti ti ń ṣiṣẹ gẹgẹ “bi ìdákọ̀ró ọkàn”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́