ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 8/1 ojú ìwé 4-7
  • Mimọriri Ẹbun Ṣiṣeyebiye Ti Iwalaaye

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mimọriri Ẹbun Ṣiṣeyebiye Ti Iwalaaye
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iyipada Ṣeeṣe!
  • Ifilọni Ìyè Ayeraye ti Ọlọrun
  • Kí Nìdí Tí Ẹ̀bùn Yìí Fi Ṣe Iyebíye Gan-an?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Fi Hàn Pé O Mọyì Ẹ̀mí
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Bó O Ṣe Lè Mọyì Ìwàláàyè Tí Ọlọ́run Fún Ẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ǹjẹ́ Ó Wù Ọ́ Láti Wà Láàyè Títí Láé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 8/1 ojú ìwé 4-7

Mimọriri Ẹbun Ṣiṣeyebiye Ti Iwalaaye

IWALAAYE—ohun ìní ṣiṣeyebiye wo ni o jẹ́! Laisi i a kò lè ṣe ohunkohun. Gbàrà ti a bá ti padanu rẹ̀, a kò lè mu un padabọsipo nipasẹ ọ̀nà eniyan eyikeyii. Bi iwalaaye wa bá wà ninu ewu, a ń ṣe gbogbo ohun ti o bá ṣeeṣe lọna ti o ba ọgbọn mu lati tọju rẹ̀. Họwu, awọn kan yoo tilẹ wá aranṣe ti o ju ti ẹ̀dá lọ nigba ti wọn bá wà ninu idaamu!

A rán wa leti akọsilẹ Bibeli nipa ọkọ̀ oju-omi kan ti ìjì okun lilagbara gbámú. Nigba ti ó kù diẹ ki ó rì, “awọn atukọ bẹru, olukuluku sì kigbe si ọlọrun rẹ̀.” Nigba ti o yá, gbogbo wọn lapapọ kigbe jade si Ọlọrun tootọ naa pe: “Awa bẹ̀ ọ́, Oluwa [“Jehofa,” NW] awa bẹ̀ ọ́, maṣe jẹ ki awa sègbé.” Akọsilẹ Bibeli naa tun sọ pe: “Wọn kó ẹrù ti ó wà ninu ọkọ̀ dà sinu okun, lati mú un fẹ́rẹ̀.”—Jona 1:4-6, 14; fiwe Iṣe 27:18, 19.

Awọn atukọ wọnni tilẹ ṣetan lati fi awọn ohun ìní ti ara ti wọn ṣìkẹ́ rubọ ninu isapa lati pa iwalaaye wọn mọ́. A lè fi ohun miiran dípò ohun ìní ti ara—ṣugbọn kì í ṣe iwalaaye. Ati nitori pe a ṣìkẹ́ iwalaaye lọna adanida, a ń sá sẹhin kuro ninu ewu. A ń founjẹ bọ́, fi aṣọ bò, a sì ń ṣikẹ ara wa. A ń wá itọju iṣegun nigba ti a bá ń ṣaisan.

Bi o tilẹ ri bẹẹ, Olufunni ni ìyè beere fun ohun pupọ sii ni ọwọ́ wa ju wiwulẹ tẹle idaabobo ara-ẹni ti a dá mọ́ wa lọ. Ó ṣetan, iwalaaye jẹ́ ẹbun ti kò ṣee diyele, ó sì wá lati ọdọ Ẹni pataki julọ ni gbogbo agbaye. Lati inu imọriri atọkanwa fun ẹbun naa ati Ẹni ti ó fi í funni, kò ha yẹ ki a ṣìkẹ́ iwalaaye bi? Iyẹn kò ha sì ní wémọ́ níní ọ̀wọ̀ fun iwalaaye awọn ẹlomiran bi?

Kò gbọdọ yà wá lẹnu, nigba naa, pe Ofin ti Jehofa Ọlọrun fun orilẹ-ede Israeli ní awọn aṣẹ ti a ṣeto lati daabobo iwalaaye ati ilera awọn ẹlomiran ninu. (Eksodu 21:29; Deuteronomi 22:8) Awọn Kristian lonii gbọdọ daniyan nipa aabo ti ara bakan naa. Fun apẹẹrẹ, bi iwọ bá ní awọn ọmọde ninu ile rẹ, iwọ ha fi awọn nǹkan bii ìlẹ̀kẹ̀, pín-ìn-nì, tabi awọn ohun mímú ṣóńṣó ti o lè ṣokunfa ipalara mimuna fun ọmọ kan ti ń fi wọn ṣere tabi tí ń fi wọn sẹnu laimọwọmẹsẹ silẹ nibi ti ọwọ́ wọn ti lè tó o bi? Awọn kẹmika ati oogun eléwu ni a ha pamọ kuro nibi ti ọwọ awọn ọmọde ti lè tó o bi? Bi omi bá dà silẹ, iwọ ha ń tètè nù ún kuro lati ṣediwọ fun ijamba bi? Iwọ ha tètè ń bojuto atunṣe awọn ohun eelo oníná manamana ti ó ti bajẹ bi? Ọkọ̀ irinna rẹ̀ ha ń gba atunṣe deedee bi? Iwọ ha jẹ́ awakọ ti kì í ṣe elewu bi? Bi iwọ bá mọriri iṣeyebiye iwalaaye niti gidi, iwọ ni a o sún lati lo iṣọra ti o bá ọgbọ́n mu ni awọn agbegbe ti o farajọra wọnyi.

Ó banininujẹ lati sọ, bi o ti wu ki o ri, pe awọn kan kò tilẹ mọriri iniyelori iwalaaye wọn. Fun apẹẹrẹ, ta ni kò mọ lonii pe siga mimu kò bá ilera mu? Sibẹ, araadọta-ọkẹ ni aṣa yii mú lẹ́rú, nigba ti ilera wọn ń jò rẹhin ni gbogbo ìgbà ti wọn bá ti fa èéfín majele naa simu. Awọn miiran ń lo oogun nilokulo, ati awọn miiran sibẹ ọtí lile, gbogbo rẹ̀ sí ìwuléwu wọn. AIDS jẹ́ àrùn apani eyi ti kò ni iwosan ti a mọ. Ṣugbọn ọpọlọpọ ìbá ti yẹra fun kíkó àrùn yii bi wọn bá ti ṣá iwapalapala takọtabo, iru ilokulo oogun kan bayii, ati ìfàjẹ̀sínilára tì. Iru aini imọriri ọlọ́ràn ibanujẹ wo ni eyi jẹ́ fun iwalaaye!—Romu 1:26, 27; 2 Korinti 7:1.

Iyipada Ṣeeṣe!

Awọn wọnni ti wọn mọriri Jehofa, Atobilọla Ẹlẹdaa wọn, ní idi lilagbara lati wo iwalaaye gẹgẹ bi eyi ti o ṣeyebiye. Iwalaaye jẹ́ ẹbun mímọ́ ọlọ́wọ̀ rẹ̀. Nitori naa wọn wà ní imuratan lati ṣe awọn iyipada yoowu ti o bá pọndandan lati lò ó gẹgẹ bi ẹbun atọrunwa. Gbé iriri Kwaku, olukọ kan ni Ghana yẹwo. Ọ̀mùtí paraku ni, ó ń fi igbesi-aye rẹ̀ ṣòfò.

Kwaku níran pe: “Mo gbiyanju lati fipa mú aya mi lati bọwọ fun mi, eyi ti o sábà maa ń jalẹ si ariyanjiyan gbigbona ati ìjà, ni pataki nigba ti mo bá ti mọtiyo. Nitori fifi imukumu kẹ́ araami bajẹ, emi kìí sábà ni owo lọwọ, mo sì maa ń ṣalaibojuto ojuṣe mi ni pipese owo fun itilẹhin idile mi leralera. Lọna ti o yeni, eyi bí aya mi nínú gidigidi. Nigbakigba ti owó bá tán ni ọwọ mi (eyi sì ń ṣẹlẹ lemọlemọ), mo ń ṣe ohunkohun ti mo lè ṣe lati ṣetilẹhin fun àṣà mi. Nigbakanri mo lọ jinna debi lilo owo ti mo ti gbà lọwọ awọn ọmọ ile-ẹkọ mi fun ète fifi orukọ wọn silẹ fun idanwo gbogbogboo. Mo dágbálé imukumu ọtí mo sì tun ra ọtí fun awọn ọ̀mu ẹlẹgbẹ mi. Ko pẹ ti ọjọ ìjíhìn lé mi bá. Bí kìí bá ṣe pe ọ̀gá ile-ẹ̀kọ́ mi tete dá sí i lakooko ni, emi ìbá ti padanu iṣẹ mi.

“Igbesi-aye mi rí rádaràda. Itiju bá mi, ṣugbọn mo bori rẹ̀ laipẹ. Nigba ti o yá mo bẹrẹ sii mu awọn ironu ifọwọ ara-ẹni pa ara-ẹni dagba nitori pe mo nimọlara pe mo jẹ́ aláṣetì ninu igbesi-aye. Sibẹ, emi kò lè ja àjàbọ́ kuro lọwọ ìfìmukúmu ọtí kẹ́ ara-ẹni bajẹ. Ṣugbọn ni ọjọ kan ninu ile ọtì mo kówọnú ìjà alariwo ọmutipara wọn sì gún mi lọ́bẹ, mo wá mọ̀ lọna bibanininujẹ pe ìfẹ́ mi fun ọtí líle yoo ná mi ni iwalaaye mi ni ọjọ kan.

“Ni gbogbo ìgbà yii, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń ṣebẹwo si ile wa loorekoore, ni gbigbiyanju lati mú wa lọ́kàn-ìfẹ́ ninu Bibeli. Emi ati aya mi ti maa ń sá fun wọn nigba gbogbo nitori pe a ronu pe wọn jẹ́ ayọnilẹnu. Bi o ti wu ki o ri, ni akoko kan, mo pinnu lati fi ibanikẹdun fetisilẹ si wọn. Ko pẹ ti ikẹkọọ Bibeli la oju mi si ifojusọna agbayanu ti wiwalaaye titilae ninu eto igbekalẹ titun ti Ọlọrun. Bi mo ti tubọ ń kẹkọọ Bibeli pẹlu iranlọwọ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sii tó, bẹẹ ni imọriri mi fun Jehofa gẹgẹ bi Olùfúnni-ní-Ìyè wa ati fun ẹbun iwalaaye rẹ̀ ṣe ń ga sii tó, bẹẹ sì ni ìṣeéfisílò imọran Bibeli ti ń wú mi lori tó. Eyi fun mi niṣiiri siwaju sii lati fọ igbesi-aye mi mọ́ tonitoni. Eyi kò rọrun, bi mo ti nilati maa baa niṣo ni didena ọtí ati awọn alabaakẹgbẹ mi atijọ. Jehofa, Olugbọ adura, rí ipinnu ọkan-aya mi ó sì gbọ́ mi.a

“Bi o tilẹ jẹ pe aya mi kì í ṣe ọ̀kan lara Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ó bu ọ̀wọ̀ ti ó ga fun emi ati isin mi nisinsinyi nitori iyipada giga ti o ṣakiyesi ninu igbesi-aye mi ati ninu ọ̀ràn ipo ibatan lọ́kọláya wa. Awọn aladuugbo wa kò nilati làjà laaarin emi ati aya mi mọ́. Mo ṣikẹ alaafia ero-inu ti mo ń gbadun nisinsinyi. Dajudaju, mimọriri Jehofa Ọlọrun gẹgẹ bi Olùfúnni-ni-Ìyè wa, titẹwọgba oju-iwoye rẹ̀ lori iṣeyebiye iwalaaye, ati ṣiṣegbọran si awọn itọni rẹ̀ lori bi a ṣe nilati gbé ni kìkì ọ̀nà igbesi-aye ti o níláárí.”

Ifilọni Ìyè Ayeraye ti Ọlọrun

Ẹgbẹẹgbẹrun, bii Kwaku, ni Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ràn lọwọ lati “gbé ọkunrin titun nì wọ̀, eyi ti a dá nipa ti Ọlọrun ni ododo ati ni ìwà mímọ́ otitọ.” (Efesu 4:24) Wọn ti wá mọriri kì í ṣe kìkì igbesi-aye wọn isinsinyi nikan ni ṣugbọn ireti ìyè ayeraye ninu paradise ilẹ̀-ayé pẹlu. Bibeli ṣeleri pe ninu Paradise ti a ti ọwọ́ Ọlọrun dá yẹn, kò ni sí olùgbé ilẹ̀-ayé ti yoo tun niriiri irora ebi ajáni-nínújẹ mọ́, nitori pe “Oluwa awọn ọmọ-ogun yoo se àsè ohun abọpa fun gbogbo orilẹ-ede.”—Isaiah 25:6.

Ni lọwọlọwọ, bi igbesi-aye tilẹ jẹ ẹbun agbayanu kan, ó wulẹ wà fun ìgbà diẹ ni. Gbogbo eniyan ni o dojukọ ikú, ikọlu adániníjì wo sì ni ikú jẹ́! Àsọdùn kọ́, lati kiyesi ẹnikan ti o nifẹẹ sí ki o pòórá laaarin awọn alaaye lọ sinu ìdákẹ́rọ́rọ́ sàárè ń danilaamu gbáà. Ṣugbọn labẹ Ijọba Ọlọrun, ti Kristi yoo ṣakoso, ileri Jehofa yoo ní imuṣẹ pe: “Ki yoo sì sí ikú mọ, tabi ọ̀fọ̀, tabi ẹkún, bẹẹ ni ki yoo sí irora mọ́: nitori pe ohun atijọ ti kọja lọ.”—Ìfihàn 21:4.

Ni ìgbà yẹn ẹbun iwalaaye ni a o mú gbooro ni iru ọ̀nà agbayanu kan. Awọn olùla ipọnju ikẹhin ja lori ilẹ̀-ayé yii yoo ni anfaani lati wọnu ẹkunrẹrẹ iwalaaye. Ati nigba naa, nipasẹ ajinde, imupada wá si ìyè, Jehofa Ọlọrun yoo mu ẹbun ti kò ṣee diyele rẹ̀ padabọsipo fun awọn wọnni ti wọn sùn ninu ikú. (Johannu 5:24, 28, 29) Eyi yoo tumọsi ipadabọ awọn ololufẹ ti wọn ti kú ati awọn ọkunrin igbaani ti wọn bẹru Ọlọrun!

Gbogbo eyi ha ti dara ju lati jẹ́ otitọ bi? Bẹẹkọ, nitori pe “kò sí ohun ti Ọlọrun kò le ṣe.”—Luku 1:37; fiwe Jobu 42:2.

Siwaju sii, Jehofa Ọlọrun fúnraarẹ̀ ti pese ẹ̀rí fun araye pe gbogbo eyi ni yoo ṣẹlẹ. Bawo? Nipa fifi ẹnikan ti ó ṣọ̀wọ́n fun ọkan-aya rẹ̀ rubọ, Ọmọkunrin rẹ̀ ọ̀wọ́n, Jesu Kristi, lati rà wá pada kuro ninu ẹṣẹ ati ikú. Romu 8:32 mú un dá wa loju pe: “Ẹni [Jehofa Ọlọrun] ti kò dá Ọmọ oun tikaraarẹ sí, ṣugbọn ti o jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ fun gbogbo wa, yoo ha ti ṣe ti ki yoo fun wa ni ohun gbogbo pẹlu rẹ̀ lọfẹẹ?” Bibeli sọ fun wa pe eyi yoo ní ninu fífọ araye mọ́ tonitoni kuro ninu ijẹrabajẹ ti iwarere ati mímu gbogbo iru aiṣedajọ ododo, iwa-ọdaran, ati iwa-ipa kuro. (Isaiah 11:9) Iwalaaye ni a ki yoo foju pọ́ọ́kú wò mọ́ lae.

Àní nisinsinyi paapaa, labẹ awọn ipo aipe, iwalaaye lè gbadunmọni lọpọlọpọ. Ta ni kò ni inudidun sí òórùn itasansan ounjẹ gbigbadunmọni, imọlara afẹ́fẹ́ lẹ́lẹ́ ni ọjọ olóoru kan, ìran òkè titobi ńlá kan, wíwọ̀ oòrùn pípọ́n dẹ̀dẹ̀ kan, odò títòrò minimini ti ó rọra ń ṣàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, awọn òdòdó lílẹ́wà meremere ti o gbani lafiyesi, ìró ohùn orin ti o ládùn, tabi orin awọn ẹyẹ? Duro fun ìgbà diẹ ná. Ronu, ki ni yoo jọ lati gbadun iru awọn nǹkan bẹẹ titi ayeraye?

Ó ha bá ọgbọ́n mu rara, nigba naa, lati gbé anfaani ṣiṣeyebiye ti wiwalaaye titilae sọnu nitori fàájì onigba diẹ eyikeyii tí ipa-ọna igbesi-aye alainironu, onígbọ̀jẹ̀gẹ́, lè fi funni? (Fiwe Heberu 11:25.) Pẹlu ọgbọ́n, Bibeli gbà wá niyanju ‘lati gbé igbesi-aye wa ti o ṣẹku, kì í ṣe fun ìfẹ́-ọkàn awọn eniyan mọ́, bikoṣe fun ìfẹ́-inú Ọlọrun.’ (1 Peteru 4:2) A fi tọkantọkan fun ọ niṣiiri, bẹẹni, rọ̀ ọ́, lati ṣe bẹẹ nipa kikẹkọọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli, ati fifi awọn nǹkan ti o kọ́ silo. (Johannu 13:17) Iwọ yoo tipa bayii wá sinu ipo ibatan rere pẹlu Jehofa, Ọlọrun ti o kun fun akunwọsilẹ iwarere-iṣeun ati aanu, ẹni ti o lè san èrè fun ọ pẹlu ìyè ayeraye!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bíbọ́ lọwọ ìwà imukumu ọtí jẹ́ iṣẹ́-òpò kan ti o ṣòroó bori, ti o ń bere fun iranlọwọ olóye iṣẹ niye ìgbà. Wo iwe irohin alabaakẹgbẹ wa, Ji! ti May 22, 1992 (Gẹẹsi), fun isọfunni ti ó lè ṣeranlọwọ lori kókó ẹ̀kọ́ yii.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ọ̀nà ti o gbà ń gbe igbesi-aye rẹ̀ ha fi imọriri hàn fun iwalaaye bi?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ayé titun ti Ọlọrun yoo yọnda fun wa lati gbadun awọn fàájì iwalaaye titi ayeraye!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́