ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 8/1 ojú ìwé 13-18
  • Bawo ni Iwọ Ṣe Ń Sáré Ninu Eré-ìje Fun Ìyè?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bawo ni Iwọ Ṣe Ń Sáré Ninu Eré-ìje Fun Ìyè?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Eré-ìje fun Ìyè
  • Lo Ikora-Ẹni-Nijaanu Ninu Ohun Gbogbo
  • Sáré “Kì í ṣe bi Ẹni ti Kò Daloju”
  • O Lè Fara Dà á Dé Òpin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • “Ẹ Sáré ní Irúfẹ́ Ọ̀nà Bẹ́ẹ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • “Sá Eré Ìje Náà Dé Ìparí”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Sisa Eré-Ìje Naa Pẹlu Ifarada
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 8/1 ojú ìwé 13-18

Bawo ni Iwọ Ṣe Ń Sáré Ninu Eré-ìje Fun Ìyè?

“Ẹyin kò mọ̀ pe awọn ti ń sare ìje, gbogbo wọn ni ń sare nitootọ, ṣugbọn ẹnikan ni ń gba èrè naa? Ẹ sare bẹẹ, ki ẹyin ki o lè ri gba.”—1 KORINTI 9:24.

1. Ki ni Bibeli fi ipa-ọna Kristian wa wé?

BIBELI fi iwakiri wa fun ìyè ainipẹkun wé eré-ìje kan. Ni opin igbesi-aye rẹ̀, aposteli Paulu sọ nipa araarẹ̀ pe: “Emi ti ja ìjà rere, emi ti pari eré-ìje mi, emi ti pa igbagbọ mọ́.” Ó rọ awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ lati ṣe ohun kan-naa nigba ti o wi pe: “Ẹ jẹ ki a pa ohun idiwọ gbogbo tì si apakan, ati ẹṣẹ ti o rọrun lati di mọ wa, ki a sì maa fi suuru sure ìje ti a gbé ka iwaju wa.”—2 Timoteu 4:7; Heberu 12:1.

2. Ibẹrẹ afunni niṣiiri wo ni a rí ninu eré-ìje fun ìyè?

2 Ifiwera naa jẹ́ ọ̀kan ti o tọ́ nitori pe eré-ìje kan ní ibẹrẹ, ipa-ọna ti a gbekalẹ, ati ìlà ipari, tabi gongo kan ninu. Bẹẹ ni ó rí pẹlu igbesẹ itẹsiwaju tẹmi wa siha ìyè. Gẹgẹ bi a ti rí i, lọdọọdun ẹgbẹẹgbẹrun lọna ọgọrọọrun awọn eniyan ń ní ibẹrẹ rere ninu eré-ìje fun ìyè. Ni ọdun marun-un ti o kẹhin, fun apẹẹrẹ, 1,336,429 awọn eniyan ti bẹrẹ eré-ìje naa gẹgẹ bi a ti maa ń ṣe e nipa iyasimimọ ati iribọmi inu omi. Iru ibẹrẹ alagbara bẹẹ jẹ́ eyi ti ń funni niṣiiri julọ. Bi o ti wu ki o ri, ohun ti ó ṣe pataki, ni lati maa baa lọ ninu eré-ìje naa titi di ìgbà ti a ba dé ìlà ipari. Iwọ ha ń ṣe eyi bi?

Eré-ìje fun Ìyè

3, 4. (a) Bawo ni Paulu ṣe ṣalaye ijẹpataki biba a lọ ninu iṣisẹrin ni ìyára kan-naa ninu eré-ìje? (b) Bawo ni awọn kan ṣe kùnà lati kọbiara si amọran Paulu?

3 Lati tẹnumọ ijẹpataki bibaa lọ ninu eré-ìje naa, Paulu rọni pe: “Ẹyin kò mọ̀ pe awọn ti ń sare ìje, gbogbo wọn ni ń sare nitootọ, ṣugbọn ẹnikan ni ń gba èrè naa? Ẹ sare bẹẹ, ki ẹyin ki o lè ri gbà.”—1 Korinti 9:24.

4 Loootọ, ninu awọn eré igbaani, kìkì ẹnikan ni ó lè gba ẹbun eré kan. Bi o ti wu ki o ri, ninu eré-ìje fun ìyè, olukuluku ni o lẹtọọ si ẹbun eré naa. Kìkì pe ó pọndandan lati wà ni ipa-ọna naa titi dé ipari! Lọna ti o munilayọ, ọpọlọpọ ti fi iṣotitọ sá eré-ìje naa titi dé opin igbesi-aye wọn, gẹgẹ bi aposteli Paulu ti ṣe. Araadọta-ọkẹ ṣì ń ba eré sísá naa lọ. Bi o ti wu ki o ri, awọn kan ti kuna lati lakaka siwaju tabi ní ilọsiwaju siha ìlà ipari. Kaka bẹẹ, wọn fààyè gba awọn nǹkan miiran lati dí wọn lọwọ debi pe yala wọn kuro lori ìlà eré-ìje naa tabi di ẹni ti kò tootun mọ́ ni awọn ọ̀nà kan. (Galatia 5:7) Eyi gbọdọ fun gbogbo wa ni idi lati ṣayẹwo ọ̀nà ti a gbà ń sare ninu eré-ìje fun ìyè.

5. Paulu ha ń fi eré-ìje fun ìyè wé eré ìbáradíje bi? Ṣalaye.

5 A lè beere ibeere naa pe: Ki ni Paulu ni lọkan nigba ti o sọ pe “ẹnikan ni ń gba èrè naa”? Gẹgẹ bi a ti kiyesi i ni iṣaaju, oun kò ní i lọ́kàn pe laaarin gbogbo awọn wọnni ti wọn bẹrẹ ninu eré-ìje fun ìyè, kìkì ẹnikanṣoṣo ni yoo gba èrè ìyè ainipẹkun. Lọna ti o hàn gbangba iyẹn kò lè rí bẹẹ, nitori leralera, ni ó mú un ṣe kedere pe ifẹ-inu Ọlọrun ni pe ki awọn eniyan oniruuru gbogbo di ẹni ti a gbala. (Romu 5:18; 1 Timoteu 2:3, 4; 4:10; Titu 2:11) Bẹẹkọ, kì í ṣe pe ó ń sọ pe eré-ìje fun ìyè jẹ́ ìfagagbága ninu eyi ti olukopa kọọkan ń gbiyanju lati bori gbogbo awọn ti o kù. Awọn ará Korinti mọ̀ daradara pe iru ẹmi ìfagagbága bẹẹ wà laaarin kìkì awọn abáradíje ninu Eré Isthmian, eyi ti a sọ pe o tilẹ gbayì ni akoko yẹn ju Eré Olympic lọ. Nigba naa, ki ni Paulu ní lọ́kàn?

6. Ki ni ayika ọ̀rọ̀ fihàn nipa ijiroro Paulu nipa sárésáré ati eré-ìje?

6 Ni titọka si àkàwé saresare, Paulu ni ipo akọkọ ń jiroro awọn ifojusọna tirẹ fun igbala. Ninu awọn ẹsẹ ti o ṣaaju, ó ṣapejuwe bi o ti ṣiṣẹ kára ti ó sì lo araarẹ̀ tokuntokun ni ọpọlọpọ ọ̀nà. (1 Korinti 9:19-22) Lẹhin naa, ni ẹsẹ 23, ó sọ pe: “Emi sì ń ṣe ohun gbogbo nitori ti ihinrere, ki emi ki o lè jẹ́ alabaapin ninu rẹ̀ pẹlu yin.” Ó mọ̀ daju pe igbala oun ni a kò mu daju kìkì nitori pe a yan oun lati jẹ́ aposteli tabi nitori pe ó ti lo ọpọlọpọ ọdun ninu wiwaasu fun awọn ẹlomiran. Ki o baa lè ṣajọpin ninu awọn ibukun ihinrere, oun gbọdọ maa baa lọ lati ṣe ohun gbogbo ti ó wà nikaawọ rẹ̀ nititori ihinrere. Oun gbọdọ sáré pẹlu èrò kikun ti bibori, ni lilo araarẹ̀ tokuntokun gan-an gẹgẹ bi ẹni pe ó ń sáré ninu eré-ìje ẹlẹ́sẹ̀ ninu Eré Isthmian, nibi ti ‘ẹnikan ti ń gba èrè naa.’—1 Korinti 9:24a.

7. Ki ni a nilo lati “sáré bẹẹ, ki ẹyin ki o lè ri gba”?

7 Pupọ wà ti a lè kẹkọọ lati inu eyi. Bi o tilẹ jẹ pe olukuluku ẹni ti ń darapọ ninu eré-ìje naa ń fẹ́ lati bori, kìkì awọn wọnni ti wọn pinnu patapata lati bori ni wọn ni ifojusọna eyikeyii ti ṣiṣe bẹẹ. Fun idi yii, a kò gbọdọ nimọlara itẹra-ẹni lọrun kìkì nitori pe a ti darapọ mọ eré-ìje naa. A kò gbọdọ nimọlara pe gbogbo nǹkan yoo dara nitori pe a wà ‘ninu otitọ.’ A lè jẹ́ orukọ naa Kristian, ṣugbọn ǹjẹ́ a ní animọ àfidánimọ̀ ti a lè fi fẹ̀rí hàn pe a jẹ́ Kristian bi? Fun apẹẹrẹ, ǹjẹ́ a ń ṣe ohun ti a mọ̀ pe Kristian kan gbọdọ ṣe bi—ki a wá sí awọn ipade Kristian, ki a nipin-in ninu iṣẹ-ojiṣẹ pápá, ati bẹẹ bẹẹ lọ? Bi o bá ri bẹẹ, iyẹn yẹ ni igboriyin fun, a sì gbọdọ saakun lati foriti i ninu iru awọn àṣà titayọ bẹẹ. Bi o ti wu ki o ri, ó ha ṣeeṣe, pe a lè janfaani sii ninu ohun ti a ń ṣe bi? Fun apẹẹrẹ, awa ha ń murasilẹ nigba gbogbo lati fi oun kan ṣetilẹhin fun awọn ipade naa bi? Awa ha ń saakun lati fi ohun ti a kọ́ silo ninu igbesi-aye wa bi? Awa ha ń fun mimu ijafafa wa sunwọn sii ni afiyesi ki a lè funni ni ijẹrii kúnnákúnná laika awọn idena ti a ń bá pade ninu pápá sí bi? Awa ha ń muratan lati tẹwọgba ipenija ti pipada lọ sọdọ awọn olùfìfẹ́hàn ki a sì dari ikẹkọọ Bibeli pẹlu wọn bi? “Ẹ sáré bẹẹ, ki ẹyin ki o lè ri gba,” ni Paulu rọni.—1 Korinti 9:24b.

Lo Ikora-Ẹni-Nijaanu Ninu Ohun Gbogbo

8. Ki ni ó ti lè sún Paulu lati rọ awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ lati ‘lo ikora-ẹni-nijaanu ninu ohun gbogbo’?

8 Ni akoko igbesi-aye rẹ̀, Paulu ti rí ọpọlọpọ ti wọn ti dẹ̀rìn, súlọ, tabi dawọ duro ninu eré-ìje fun ìyè. (1 Timoteu 1:19, 20; Heberu 2:1) Idi niyẹn ti o fi rán awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ létí leralera pe wọn wà ninu ìjìjàdù afitokuntokun ṣe ti ń baa lọ. (Efesu 6:12; 1 Timoteu 6:12) Ó bá àkàwé nipa sárésáré lọ siwaju diẹ sii ó sì sọ pe: “Ati olukuluku ẹni ti ń jijadu ati bori a maa ni iwọntunwọnsi [“ikora-ẹni-nijaanu,” NW] ninu ohun gbogbo.” (1 Korinti 9:25a) Ni sisọ eyi, Paulu ń sọrọ bá ohun kan ti awọn Kristian ará Korinti mọ dunju daradara, iyẹn ni, idalẹkọọ mimuna tí awọn olùbáradíje ninu Eré Isthmian ń tẹle.

9, 10. (a) Bawo ni orisun kan ṣe ṣapejuwe awọn olùkópa ninu idije ninu Eré Isthmian? (b) Ni pataki ki ni o yẹ fun akiyesi nipa apejuwe naa?

9 Apejuwe kínníkínní nipa olùdíje kan lẹnu idalẹkọọ niyii:

“Pẹlu itẹlọrun ati laisi ikunsinu o fi araarẹ sabẹ awọn ofin ati ikalọwọko ti idalẹkọọ oloṣu mẹwaa rẹ̀, eyi ti bi kò bá sí oun lè ṣàídíje. . . . Ó ń yangàn nipa inira, àárẹ̀, ati ìsẹ́ra-ẹni rẹ̀, ó sì kà á sí ohun ìmúyangàn kan lati takete patapata si ohunkohun ti o lè fi iwọn kín-ín-kínní dìn ṣiṣeeṣe rẹ̀ lati ṣaṣeyọri kù. Ó ń rí awọn ọkunrin miiran ti wọn ń jẹun falala, ti wọn ń sinmi nigba ti o ń mí hẹlẹ fun fifi ara ṣe wahala, ti wọn ń ṣe yọ̀tọ̀mì ninu agbada omi ìwẹ̀, ti wọn ń gbadun igbesi-aye nidii faaji; ṣugbọn ó ṣọ̀wọ́n kí oun tó ní èrò ìlara, nitori pe o fi tọkantọkan fẹ́ ẹbun naa, idalẹkọọ mimuna sì jẹ́ kò-ṣeé-má-ṣe. Ó mọ̀ pe awọn ṣiṣeeṣe ti oun ní yoo pòórá bi ó bá dẹra fun ìlekoko idalẹkọọ naa ni akoko eyikeyii.”—The Expositor’s Bible, Idipọ V, oju-ewe 674.

10 Ohun ti o fa ọkàn-ìfẹ́ pataki mọra ni akiyesi tiṣọratiṣọra naa pe ẹni naa ti ń gba idanilẹkọọ “kà á sí ohun imuyangan kan” lati tẹle iru ọ̀nà igbaṣe deedee lilekoko ti ìsẹ́ra-ẹni bẹẹ. Niti tootọ, ‘ó ṣọ̀wọ́n kí ó tó ní èrò ilara’ si ìdẹ̀ra ati idẹrun ti o rí ti awọn miiran ń gbadun. Awa ha lè kọ́ ohun kan lati inu eyi bi? Bẹẹni, nitootọ.

11. Oju-iwoye ti kò bojumu wo ni a gbọdọ ṣọra lodisi nigba ti a bá ń lọwọ ninu eré-ìje fun ìyè?

11 Pada ranti awọn ọ̀rọ̀ Jesu pe “gbooro ni ẹnu-ọna naa, ati oníbùú ni oju-ọna naa ti o lọ si ibi iparun; ọpọlọpọ ni awọn ẹni ti ń bá ibẹ wọle. Nitori bi híhá ti ni ẹnu-ọna naa, ati tooro ni oju-ọna naa, ti o lọ si ibi ìyè, diẹ ni awọn ẹni ti o ń rìn ín.” (Matteu 7:13, 14) Bi o ti ń saakun lati rìn ni ‘oju-ọna híhá gádígádí,’ iwọ ha ṣe ilara ominira ati ìrọ̀rùn ti o jọbi pe awọn wọnni ti wọn wà ní ọ̀nà keji ń gbadun bi? Iwọ ha nimọlara pe iwọ ń padanu diẹ lara awọn nǹkan ti awọn miiran ń ṣe, eyi ti o lè jọbi eyi ti kò buru ninu araawọn bi? Ó rọrun fun wa lati nimọlara ni ọ̀nà yii bi a bá kùnà lati fi idi ti a fi dẹ́sẹ̀ lé ipa-ọna yii sọkan. “Ǹjẹ́ wọn ń ṣe é lati gba adé idibajẹ; ṣugbọn awa eyi ti kì í dibajẹ,” ni Paulu sọ.—1 Korinti 9:25b.

12. Eeṣe ti a fi lè sọ pe ogo ati òkìkí ti awọn eniyan ti wá kiri dabi ade ti ń dibajẹ ti a fifunni nibi Eré Isthmian?

12 Olùborí ni ibi Eré Isthmian ń gba ẹ̀gbà ọ̀ṣọ́ ti a fi igi ẹ̀gún Isthmus tabi iru awọn igi miiran bẹẹ ṣe, eyi ti ó ṣeeṣe ki ó rọ ni iwọnba ọjọ tabi ọ̀sẹ̀ diẹ. Dajudaju, kì í ṣe fun ẹ̀gbà ọ̀ṣọ́ ti o lè parun ni awọn sárésáré ń jàdù fun ṣugbọn fun ogo, ọla, ati òkìkí ti ń ba a rìn. Orisun kan rohin pe nigba ti aṣẹ́gun naa bá pada délé, oun ni a o kí kaabọ gẹgẹ bi ajagunṣẹgun akọni. Niye ìgbà ogiri ilu ni a ń wó palẹ ki awọn èrò ti wọn tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́rìn tẹle e baa lè kọja, ọwọ̀n ni a sì ń gbéró lati bọla fun un. Laika gbogbo eyi sí, bi o ti wu ki o ri, ogo rẹ̀ ṣì jẹ́ eyi ti o lè dibajẹ. Lonii, awọn eniyan ti wọn mọ awọn ti awọn akọni ti ń ṣẹgun wọnni jẹ́ kò tó nǹkan, ọpọ julọ ni kò sì bikita. Awọn wọnni ti wọn fi akoko, okun, ilera, ati ayọ idile wọn paapaa rubọ lati jere agbara, òkìkí, ati ọrọ̀ ninu ayé, ṣugbọn ti wọn kò lọ́rọ̀ siha Ọlọrun, yoo rí pe “ade” ọrọ̀ alumọni wọn bi igbesi-aye wọn, wulẹ ń kọja lọ ni.—Matteu 6:19, 20; Luku 12:16-21.

13. Bawo ni ipa-ọna igbesi-aye ẹnikan ti o wà ninu eré-ìje fun ìyè ṣe yatọ si ti sárésáré kan?

13 Olùdíje ninu eré idije kan lè muratan lati tẹwọgba awọn ohun abeere fun lilekoko ti idalẹkọọ, iru awọn wọnni ti a ṣapejuwe loke yii, ṣugbọn kìkì fun ìgbà kukuru ni. Gbàrà ti eré naa bá ti pari, wọn a pada si ọ̀nà igbesi-aye wọn deedee. Wọn ṣì lè maa ṣe idalẹkọọ lati ìgbà dé ìgbà lati pa ijafafa wọn mọ, ṣugbọn wọn ki i tẹle ipa-ọna kan-naa ti ìsẹ́ra-ẹni mimuna, ó kere tan titi di ìgbà ti idije ti o tẹle bá fi tó. Kì í ṣe bẹẹ pẹlu awọn wọnni ti wọn wà ninu eré-ìje ìyè. Fun wọn idalẹkọọ ati ìsẹ́ra-ẹni gbọdọ jẹ́ ọ̀nà igbesi-aye.—1 Timoteu 6:6-8.

14, 15. Eeṣe ti olukopa ninu eré-ìje fun ìyè fi gbọdọ lo ikora-ẹni-nijaanu nigba gbogbo?

14 “Bi ẹnikẹni ba fẹ́ tẹle mi,” ni Jesu Kristi sọ fun awọn ọmọ-ẹhin ati awọn miiran ti wọn korajọ, “jẹ ki o kọ araarẹ delẹ (tabi, “ó gbọdọ sọ pe, ‘Bẹẹkọ’ fun araarẹ,” itumọ Charles B. Williams) ki ó sì gbé òpó igi ìdálóró rẹ̀ ki o sì maa tọ̀ mi lẹhin nigba gbogbo.” (Marku 8:34, NW) Nigba ti a ba tẹwọgba ikesini yii, a gbọdọ muratan lati ṣe bẹẹ “nigba gbogbo,” kì í ṣe nitori pe akanṣe animọ ti o yẹ fun ìyìn wà ninu ìsẹ́ra-ẹni, ṣugbọn nitori pe akoko kukuru ti ailọgbọn-ninu ẹnikan, ifasẹhin kan ninu iṣediyele rere, lè pa gbogbo ohun ti a ti gbéró run, ani ki o tilẹ fi ire alaafia ayeraye wa paapaa sinu ewu. Itẹsiwaju tẹmi ni a sábà maa ń ní ni ìwọ̀n ìṣísẹ̀ ti kò yára, ṣugbọn ẹ wo bi a ti lè sọ ọ di asán ni kiakia tó bi a ko bá wà lojufo nigba gbogbo!

15 Siwaju sii pẹlu, Paulu rọ̀ wá pe a gbọdọ lo ikora-ẹni-nijaanu “ninu ohun gbogbo,” iyẹn ni pe, a gbọdọ ṣe bẹẹ délẹ̀ ninu gbogbo ìhà igbesi-aye. Eyi bá ọgbọn rere mu nitori pe bi ẹnikan ti a ń dálẹ́kọ̀ọ́ bá fi ara jìn tabi gbé igbesi-aye ibalopọ takọtabo ti a kò ṣakoso, ki ni yoo jẹ́ rere gbogbo irora ati àárẹ̀ ti o ń farada? Bakan-naa ninu eré-ìje wa fun ìyè, a gbọdọ lo ikora-ẹni-nijaanu ninu ohun gbogbo. Ẹnikan le ṣakoso araarẹ̀ ninu iru awọn nǹkan bii imutipara ati agbere, ṣugbọn iniyelori eyi dínkù bi ó bá jẹ́ onínúfùfù ati oníjà. Tabi ki ni bi o ba jẹ́ onipamọra ati oninuure si awọn ẹlomiran, ṣugbọn ti ó pa ẹṣẹ ikọkọ kan mọ sọkan ninu igbesi-aye araarẹ? Fun ikora-ẹni-nijaanu lati ṣanfaani ni kikun, a gbọdọ lò ó “ninu ohun gbogbo.”—Fiwe Jakọbu 2:10, 11.

Sáré “Kì í ṣe bi Ẹni ti Kò Daloju”

16. Ki ni o tumọsi lati sáré “kì í ṣe bi ẹni ti kò daloju”?

16 Ní riri awọn isapa amunilomi ti a nilo lati ṣaṣeyọri ninu eré-ìje fun ìyè, Paulu ń baa lọ lati sọ pe: “Nitori naa bẹẹ ni emi ń sáré, kì í ṣe bi ẹni ti kò daloju; bẹẹ ni emi ń jà, kì í ṣe bi ẹnikan ti ń lu afẹfẹ.” (1 Korinti 9:26) Ọ̀rọ̀ naa “kò daloju” ní olowuuru tumọsi “kò hàn gbangba” (Kingdom Interlinear), “ti a kò rí, ti kò lámì” (Lange’s Commentary). Fun idi yii, lati sáré “kì í ṣe bi ẹni ti kò daloju” tumọsi pe fun gbogbo oluṣakiyesi ó gbọdọ hàn gbangba gan-an ibi ti sárésáré naa forile. The Anchor Bible tumọ rẹ̀ si “kì í ṣe ni ipa-ọna lọ́kọlọ̀kọ.” Bi iwọ bá ri itotẹlera awọn àmì àtẹ́lẹsẹ̀ ti o ṣe wọ́gọwọ̀gọ lọ soke sodo etikun, ti o yipo lọ siwa-sẹhin, ti o tilẹ lọ́rí pada nigba miiran, yoo ṣoro fun ọ lati ronu pe ẹni naa ń sáré rárá, ki a má tii sọ pe ó ni èrò kankan nipa ibi ti o forile. Ṣugbọn bi iwọ bá ri itotẹlera awọn àmì àtẹ́lẹsẹ̀ ti o di ìlà títọ́, gigun kan, ti àmì àtẹ́lẹsẹ̀ kọọkan wà niwaju ti iṣaaju ti gbogbo rẹ̀ sì ni alafo ti o baradọgba, iwọ yoo pari èrò pe awọn àmì àtẹ́lẹsẹ̀ naa jẹ́ ti ẹnikan ti o mọ ibi ti o ń lọ niti gidi.

17. (a) Bawo ni Paulu ṣe fihàn pe oun ń sare “kì í ṣe bi ẹni ti kò daloju”? (b) Bawo ni a ṣe lè ṣafarawe Paulu ni ọ̀nà yii?

17 Igbesi-aye Paulu fihàn kedere pe oun ń sáré “kì í ṣe bi ẹni ti kò daloju.” Ó ni ẹ̀rí ti ó pọ̀ tó lati fihàn pe oun jẹ Kristian ojiṣẹ ati aposteli kan. Ó ni kìkì gongo ilepa kan, ó sì ń lo araarẹ̀ tokuntokun ni gbogbo ọjọ ayé rẹ̀ lati jere rẹ̀. Ète rẹ̀ ni a kò yipada nipasẹ òkìkí, agbara, ọrọ̀, tabi idẹra, ani bi o tilẹ jẹ́ pe ó ṣeeṣe ki oun ti ri eyikeyii ninu iwọnyi gbà. (Iṣe 20:24; 1 Korinti 9:2; 2 Korinti 3:2, 3; Filippi 3:8, 13, 14) Bi o ti ń wẹhin pada wo ipa-ọna igbesi-aye rẹ, iru ipa-ọna wo ni iwọ rí? Ìlà tí ó tọ́ pẹlu ibi idarisi ti o ṣe kedere tabi ọ̀kan ti o jẹ ti onírìn régberègbe laini ète? Ẹ̀rí ha wà pe iwọ ń jìjàdù ninu eré-ìje fun ìyè bi? Ranti, a wà ninu eré-ìje yii, ki i wulẹ ṣe lati gbiyanju lati ṣe ohun kan ṣugbọn laisi ìtara, gẹgẹ bi a ti lè sọ pe ó jẹ́, ṣugbọn lati dé ìlà ipari.

18. (a) Ki ni a lè fiwera pẹlu ‘lilu afẹfẹ’ ni ìhà tiwa? (b) Eeṣe ti iyẹn fi jẹ́ ipa-ọna ti o lewu lati tẹle?

18 Ni ṣiṣe ifiwera pẹlu eré idaraya, Paulu sọ siwaju sii pe: “Emi ń jà, kì í ṣe bi ẹnikan ti ń lu afẹfẹ.” (1 Korinti 9:26b) Ninu ìjìjàdù wa fun ìyè, a ní ọpọlọpọ ọ̀tá, ti o ni Satani, ayé, ati aipe ara tiwa funraawa ninu. Bii akànṣẹ́ igbaani, a gbọdọ lè lù wọn bolẹ̀ nipa awọn ìkọlù ẹ̀ṣẹ́ ti a dari daradara. Lọna ti o muni layọ, Jehofa Ọlọrun ń dá wa lẹkọọ ó sì ń ràn wá lọwọ ninu ìjà naa. Ó pese awọn itọni ninu Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ninu awọn itẹjade ti a gbekari Bibeli, ati ni awọn ipade Kristian. Bi o ti wu ki o ri, bi a bá ń ka Bibeli ati awọn itẹjade ti a sì ń lọ sí awọn ipade ṣugbọn ti a kò fi awọn ohun ti a ń kọ́ silo, awa kò ha ń fi awọn isapa wa ṣòfò, ni ‘lilu afẹfẹ’ bi? Ṣiṣe bẹẹ fi wá si ipo elewu gan-an. A ń rò pe a ń wọ̀jà ki a sì tipa bayii ní èrò aabo èké, ṣugbọn ti awa kò ṣẹgun awọn ọ̀tá wa. Idi niyẹn ti ọmọ-ẹhin naa Jakọbu fi gbani niyanju pe: “Ki ẹ jẹ́ oluṣe ọ̀rọ̀ naa, ki ó má sì ṣe olùgbọ́ nikan, ki ẹ ma tan araayin jẹ.” Gan-an gẹgẹ bi ‘lilu afẹfẹ’ kò ṣe ni sọ awọn ọ̀tá wa di alailera, bẹẹ ni jíjẹ́ “olugbọ nikan” kò ṣe ni mú ki o daju pe a ń ṣe ifẹ-inu Ọlọrun.—Jakọbu 1:22; 1 Samueli 15:22; Matteu 7:24, 25.

19. Bawo ni a ṣe lè ri i daju pe a kò di ẹni itanu lọna kan ṣáá?

19 Nikẹhin, Paulu sọ aṣiiri aṣeyọri rẹ̀ fun wa pe: “Emi ń pọ́n araami loju, mo sì ń mu un wá sabẹ itẹriba: pe lẹhin ti mo ti waasu fun awọn ẹlomiran, nitori ohunkohun, ki emi tikaraami maṣe di ẹni itanu.” (1 Korinti 9:27) Bii Paulu, awa pẹlu gbọdọ jẹ ọ̀gá lori ẹran-ara aipe wa dipo yiyọnda rẹ̀ lati jẹ́ ọ̀gá wa. A nilati wa gbòǹgbò awọn ìtẹ̀sí, ìyánhànhàn, ati ìfẹ́-ọkàn ti ẹran-ara jade. (Romu 8:5-8; Jakọbu 1:14, 15) Ṣiṣe bẹẹ lè ronilara, niwọn bi ọ̀rọ̀ ti a tumọsi ‘pọ́n loju’ ti tumọ ni olowuuru si ‘lù lábẹ́ oju’ (Kingdom Interlinear). Bi o ti wu ki o ri, kò ha sàn lati jiya ojú dúdú, gẹgẹ bi a ti lè sọ pe o jẹ́, ki a sì yè ju lati juwọsilẹ fun awọn ìfẹ́-ọkàn ti ẹran-ara abẹ̀ṣẹ̀ ki a sì kú?—Fiwe Matteu 5:28, 29; 18:9; 1 Johannu 2:15-17.

20. Eeṣe ti o fi jẹ́ kanjukanju ni pataki nisinsinyi lati ṣayẹwo bi a ṣe ń sáré ninu eré-ìje fun ìyè?

20 Lonii, a ń sunmọ ìlà ipari eré-ìje naa. Akoko fun fifunni ni awọn ẹbun ti kù si dẹ̀dẹ̀. Fun awọn Kristian ẹni-ami-ororo, ó jẹ́ “èrè ipe giga Ọlọrun ninu Kristi Jesu.” (Filippi 3:14) Fun awọn wọnni ti ogunlọgọ ńlá, ó jẹ́ ìyè ainipẹkun lori paradise ilẹ̀-ayé. Pẹlu ohun ti o pọ to eyi lati jere tabi lati padanu, ẹ jẹ ki a pinnu, gẹgẹ Paulu ti ṣe, pe a kò “di ẹni itanu.” Ǹjẹ́ ki olukuluku wa fi aṣẹ naa sọkan pe: “Ẹ sáré bẹẹ, ki ẹyin ki o lè ri gba.”—1 Korinti 9:24, 27.

Iwọ Ha Sọyeranti Bi?

◻ Eeṣe ti o fi tọ́ lati fi igbesi-aye awọn Kristian wé eré-ìje kan?

◻ Bawo ni eré-ìje fun ìyè ṣe yatọ sí eré-ìje àfẹsẹ̀sá?

◻ Eeṣe ti a fi gbọdọ lo ikora-ẹni-nijaanu nigba gbogbo ati “ninu ohun gbogbo”?

◻ Bawo ni ẹnikan ṣe ń sare “kì í ṣe bi ẹni ti kò daloju”?

◻ Eeṣe ti o fi lewu lati wulẹ maa “lu afẹfẹ”?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ẹ̀gbà ọ̀sọ́ agbégbá-orókè, ati ogo ati ọla bakan-naa, jẹ́ eyi ti ń ṣá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́