Fífèdèfọ̀—Ohun Agbayanu Kan Tí Ń Pọ̀ Sii
“AGBARA kan ti gorí ahọ́n mi awọn ọ̀rọ̀ naa sì wulẹ ń tú jade yàà bi omi ni. Iru ayọ wo ni ó jẹ́! Mo ni imọlara imọtonitoni ara-ọtọ. Emi kò tún tii rí bakan-naa mọ lati ìgbà naa wá,” ni ẹnikan ti ó ní iriri ara-ọtọ ti fifi “èdè ajeji” kan fọ̀ fiyalẹnu sọ ketekete.
Apejuwe ẹnikan nipa iriri rẹ̀ akọkọ niti fifi “èdè ajeji” kan fọ̀ ni eyi jẹ́. ‘Ṣugbọn ki ni iyẹn?’ ni awọn kan lè fi ẹ̀tọ́ beere. Ó ń tọkasi àṣà tabi igbagbọ awọn ṣọọṣi kan nibi ti awọn ọkunrin ati obinrin ti fidaniloju sọ pe ẹmi Ọlọrun ni ó sún awọn lati fi èdè ilẹ miiran tabi èdè ajèjì ti wọn kò mọ̀ sọrọ.
Ohun agbayanu ti isin tí ń pọ sii ni ó jẹ́. Nigba kan rí a wò ó gẹgẹ bi iṣẹlẹ kan ti o jẹ́ ti awọn onigbagbọ Pentecostal nikanṣoṣo péré, fífèdèfọ̀ nisinsinyi ti tayọ rekọja awọn ààlà ìpín ti oriṣiriṣi isin lati ni awọn isin Baptist, Episcopal, Lutheran, Methodist, Presbyterian, ati Roman Katoliki ninu. Ipo ẹnikan nigba ti o bá wà ninu ipo yii ni a ti ṣapejuwe gẹgẹ bii ayọ agbayanu, imọlara ẹhanna, ìraníyè, ati ìmúníyè. Awọn kan tilẹ pè é ni iriri onigboonara. Awo ati agbara mẹ́mìímẹ́mìí wà ti ó tan mọ́ fífèdèfọ̀.
Ki ni Ó Fa Ifẹ-Ọkan fun Ẹbun Ahọ́n Lonii?
Ninu iwe rẹ̀ Tongues of the Spirit, Cyril G. Williams damọran pe “ìtanmọ́ra laaarin èrò imọlara ikuna, ati ìfẹ́-ọkàn fun ‘awọn èdè’” lè wà. Ó ṣapejuwe rẹ̀ gẹgẹ bii ọ̀nà-ìgbàṣe ìmaratuni ti o ní “ijẹpatakì ìwonisàn gẹgẹ bi eyi ti ń mú pákáǹleke dinku” ati “eyi ti ń pari iforigbari inu-lọhun-un” kan. Ijakulẹ ninu iṣẹ ṣọọsi, másùnmáwo ti ero imọlara, ikuna ninu iṣẹ igbesi-aye, ọ̀fọ̀, awọn pákáǹleke iṣẹ inu ile, tabi amodi ninu idile ni a tọka si gẹgẹ bii awọn kókó abajọ ti o dákún iru ọ̀rọ̀ sisọ aláyọ̀ agbayanu bẹẹ.
Bakan-naa, ninu The Psychology of Speaking in Tongues, John P. Kildahl sọ pe “aniyan jẹ́ ohun akọkọ-beere fun mímú agbara lati fèdèfọ̀ dagba.” Nipasẹ iwakiri àdáṣe ati ifọrọwanilẹnuwo ti a fiṣọra ṣe, a rí i pe “iye ti o ju ipin 85 ninu ọgọrun-un ninu awọn afèdèfọ̀ ti niriiri yánpọnyánrin aniyan ti ó hàn gbangba kedere ṣaaju ìfèdèfọ̀ wọn.” Fun apẹẹrẹ, ìyá kan fẹ́ lati fèdèfọ̀ ki o báa lè gbadura fun ọmọkunrin rẹ̀ ti kansa mú. Ọkunrin kan bẹrẹ sii fèdèfọ̀ laaarin sáá akoko aileṣepinnu rẹ̀ lori igbega lẹnu iṣẹ ti a fi lọ̀ ọ́. Obinrin kan bẹrẹ sii fèdèfọ̀ laaarin ọsẹ kan lẹhin ti ọkọ rẹ̀ ti darapọ mọ Alcoholic Anonymous [Ajọ kan ti ń ran awọn ọ̀mùtí lọwọ lati ṣẹpa ìwà bárakú wọn].
Ki ni Ẹnikan Ń Niriiri Rẹ̀?
Ẹlomiran ti o ti fèdèfọ̀ fun ìgbà akọkọ rohin pe: “Mo nimọlara igbonara latokedelẹ, ati otutu-ringindin ati ìléròrò òógùn, gbígbọ̀n ati iru àárẹ̀ kan ni awọn apá ati ẹsẹ mi.” Ni isopọ pẹlu iriri ìfèdèfọ̀, iṣarasihuwa ajeji ti awọn kan rí i pe ó ń dani laamu sábà maa ń wà. Fun apẹẹrẹ, “ọdọmọbinrin kan fẹrẹẹ fi itọ́ sé araarẹ̀ léèémí bi o ti nà gbalaja sori àga kan, ti o sì ju ìpàkọ́ nù sẹhin, awọn ìgìgìísẹ̀ rẹ̀ wà lori ilẹ, ti awọn ẹsẹ̀ rẹ̀ sì le pọnpọn.” Nigba ipade ijọ kan “ọkunrin kan gbókìtì lati ipẹkun kan si ikeji ninu ṣọọṣi.”
“Fun awọn eniyan kan,” ni Ọjọgbọn William J. Samarin kọwe, “fífèdèfọ̀ jẹ́ ipo jíjẹ́ ẹni ti a fi Ẹmi Mimọ baptisi.” Laisi i, awọn ni a “mú nimọlara gẹgẹ bi ẹni ti kò pé tán.” A tun wò ó “gẹgẹ bi idahun kan si adura, idaniloju ìfẹ́ ati itẹwọgba Ọlọrun.” Awọn miiran ti sọ pe ó fi wọn silẹ pẹlu imọlara ti iṣọkan, ayọ, ati alaafia inu-lọhun-un, ati pẹlu “imọlara agbara ti ó tubọ ga ju” ati “imọlara ìdámọ̀ ti o tubọ lagbara sii.”
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ alayọ agbayanu ha jẹ́ ẹ̀rí nipa iṣiṣẹ ẹmi mimọ niti tootọ bi? Ǹjẹ́ iriri naa dá ẹnikan fihàn gédégbé gẹgẹ bi Kristian tootọ kan bi? Fífèdèfọ̀ ha jẹ́ apakan ijọsin ti o ṣetẹwọgba lonii bi? Awọn ibeere wọnyi lẹtọọ si ohun ti ó ju idahun oréfèé kan lọ. Eeṣe? Nitori pe a fẹ́ ki ijọsin wa ní itẹwọgba ati ibukun Ọlọrun.