Ẹbun Ahọ́n Ha Jẹ́ Apakan Isin Kristian Tootọ Bi?
“MO NIMỌLARA, bi mo ti fetisilẹ sí i ti ó ń fi ìfèdèfọ̀ gbadura, bi ẹni pe agbara ti ń runisoke kan wà ninu afẹfẹ,” ni Bill sọ lẹhin ti oun ati awọn mẹfa miiran ti pejọ niwaju oniwaasu naa lẹbaa pẹpẹ ṣọọṣi. Iru awọn iriri bẹẹ ha tún ìṣiṣẹ́ ẹmi mimọ ni ọrundun kìn-ín-ní ṣe bi? Wọn ha fi isin ti Bibeli hàn bi? A lè rí awọn idahun ti ń tẹnilọrun nipa ṣiṣayẹwo Iwe Mimọ tiṣọratiṣọra.
Akọsilẹ Bibeli fihàn pe nigba ti a bá ta eyikeyii ninu ẹbun agbayanu ti ẹmi látaré, ó keretan ọ̀kan ninu awọn aposteli 12 tabi aposteli Paulu wà nibẹ. Akọkọ ninu awọn akọsilẹ iṣẹlẹ pàtó mẹta nipa fífèdèfọ̀ ni o wáyé laaarin 120 awọn ọmọ-ẹhin Jesu ti wọn korajọ ni Jerusalemu ni Pentekosti 33 C.E. (Iṣe 2:1-4) Ọdun mẹta ati ààbọ̀ lẹhin naa, nigba ti awujọ awọn ará Itali aláìkọlà kan ń fetisilẹ si Peteru bi o ti ń waasu, wọn gba ẹmi wọn sì bẹrẹ sii “fọ oniruuru èdè, wọn sì ń yin Ọlọrun logo.” (Iṣe 10:44-48) Ati ni ọdun 19 lẹhin Pentekosti, ní nǹkan bii 52 C.E., Paulu bá awujọ kan ni Efesu sọrọ ó sì gbé ọwọ rẹ̀ lé awọn ọmọ-ẹhin 12. Awọn pẹlu “ń fọ èdè miiran, wọn sì ń sọ asọtẹlẹ.”—Iṣe 19:6.
Ki ni Idi fun Ẹbun Ahọ́n?
Gan-an ṣaaju ki o tó goke re ọrun, Jesu sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ pe: “Ẹyin óò gba agbara, nigba ti ẹmi mimọ bá bà lée yin: ẹ o sì maa ṣe ẹlẹ́rìí mi ni Jerusalemu, ati . . . titi dé opin ilẹ̀-ayé.” (Iṣe 1:8) Ṣakiyesi pe oun tipa bayii funni ni àmì naa gan-an nipa bi a ó ti ṣaṣepari iṣẹ ijẹrii ńláǹlà yii—pẹlu itilẹhin ẹmi mimọ.
Ìmọ̀-ẹ̀rọ ijumọsọrọpọ ìgbàlódé ti ó mú ki o ṣeeṣe fun wa lati fi awọn ihin-iṣẹ ranṣẹ yika ayé ní ọpọlọpọ èdè kò sí nigba naa lọhun-un. Ihinrere ni wọn nilati tankalẹ ni pataki pẹlu ọ̀rọ̀ ẹnu, ati ninu eyi ẹbun agbayanu ti fífèdèfọ̀ yoo jẹ́ eyi ti o ṣeranwọ gan-an. Bẹẹ ni ọ̀ràn rí bi awọn Kristian ọrundun kìn-ín-ní ti waasu fun awọn Ju ati aláwọ̀ṣe ni Jerusalemu ni Pentekosti 33 C.E. Awọn ará Partia, Media, Elamu, Krete, Arabia, awọn olùgbé Mesopotamia, Judea, Kappadokia, Pontu, ati agbegbe Asia, ati awọn àtìpó lati Romu, gbọ́ “iṣẹ iyanu ńlá Ọlọrun” ni èdè wọn wọn sì loye ohun ti wọn sọ. Ẹgbẹẹdogun yára di onigbagbọ.—Iṣe 2:5-11, 41.
Otitọ ti a sábà maa ń gbójú fòdá ni pe fífèdèfọ̀ wulẹ jẹ́ ọ̀kan lara awọn ọ̀nà ìṣiṣẹ́ mẹsan-an ti ẹmi mimọ tí aposteli Paulu mẹnukan ninu lẹta rẹ̀ si awọn Kristian ni Korinti. Bi o tilẹ jẹ pe Paulu wo fífèdèfọ̀ gẹgẹ bii ẹbun kikere ju kan, ó ṣeyebiye fun ijọ ijimiji naa ninu titan ihinrere nipa Ijọba Ọlọrun ti ọrun kalẹ. Ó jẹ́ ọ̀kan lara “awọn ẹbun” ti ó dákún idagba ni iye ati ìgbéró ijọ Kristian aṣẹṣẹ dasilẹ naa.—1 Korinti 12:7-11; 14:24-26.
Oniruuru ọ̀na ìṣiṣẹ́ ẹmi mimọ ni ọrundun kìn-ín-ní, papọ pẹlu fífèdèfọ̀, tun jẹ́ ẹ̀rí ti o ṣeefojuri pe Ọlọrun kò lo ijọ Israeli ogbologbo ọlọdun 1,500 mọ́ gẹgẹ bi awọn eniyan akanṣe. Laiṣiyemeji, ifọwọsi rẹ̀ nisinsinyi wà pẹlu ijọ Kristian titun naa, tí Ọmọkunrin bíbí-kanṣoṣo rẹ̀ dasilẹ.—Fiwe Heberu 2:2-4.
Awọn ìfihànsóde ẹmi wọnyi jẹ́ abala ilé pataki ninu fifidii ijọ Kristian ti kò tíì dagba mulẹ ati ríràn án lọwọ lati dagba di gende. Paulu ṣalaye pe lẹhin ti wọn bá ti ṣiṣẹ fun ète wọn tan, awọn ẹbun agbayanu wọnyi yoo dawọ duro: “Bi o bá ṣe pe isọtẹlẹ ni, wọn óò dopin; bi o bá ṣe pe ẹbun ahọ́n ni, wọn óò dakẹ.”—1 Korinti 13:8.
Bẹẹni, Bibeli ṣe kedere pe ẹbun ahọ́n yoo dakẹ́. Ṣugbọn nigba wo? Iṣe 8:18 fihàn pe awọn ẹbun ẹmi ni a gbà “nipa gbigbe ọwọ́ léni . . . awọn aposteli.” Lọna ti o hàn gbangba, nigba naa, pẹlu ikú aposteli ti o gbẹhin, ìtalátagbà awọn ẹbun ẹmi yoo dakẹ—papọ pẹlu fífèdèfọ̀. Fun idi yii, nigba ti awọn wọnni ti wọn ti gba ẹbun wọnyi lati ọwọ́ awọn aposteli bá tun ti kọja lọ kuro loju ìran ayé, ẹbun agbayanu naa yoo dawọduro. Nigba ti ó bá fi maa di ìgbà naa ijọ Kristian yoo ti ni akoko lati di eyi ti a fidiii rẹ̀ mulẹ yoo sì ti tankalẹ dé ọpọlọpọ ilẹ.
“Awọn Èdè Ajeji” ati Iṣetumọ Wọn
Gbígbérí lẹẹkansii ti ode-oni nipa ìfèdèfọ̀ ni “awọn kan ti kà sí ti awọn eniyan alaidurosojukan ti wọn ń hùwà ki wọn baa lè pe afiyesi si araawọn, nigba ti awọn miiran kà á sí eyi ti ó farajọ ohun agbayanu ti sisọrọ ní èdè akoko awọn Aposteli.” Ninu awọn akojọpọ ṣọọṣi ti ode-oni nibi ti sisọrọ ni “awọn èdè ajeji” ti ń ṣẹlẹ, ó sábà maa ń wémọ́ ìbújáde imọlara ayọ agbayanu ti awọn ìró-ohùn tí kò yéni. Lọna ti ó bá eyi mu, ẹnikan jẹwọ pe: “Mo lo ẹbun ahọ́n mi julọ ní ikọkọ fun ironujinlẹ temi funraami. . . . Oju máa ń tìmí diẹ niwaju awọn eniyan miiran.” Ẹlomiran rohin pe: “Mo gbọ́ awọn ọ̀rọ̀ temi funraami, emi kò loye wọn, ṣugbọn mo ń baa lọ lati nimọlara pe a ń ti ahọ́n mi lati sọrọ.”
Isọfunni ti o ṣeyebiye gidi wo ni iru awọn èdè ajeji bẹẹ ń mu jade, kí sì ni nipa itumọ kan? Awọn wọnni ti wọn jẹwọ iṣetumọ ọrọ sísọ yii ti funni ni awọn alaye ti o yatọ nipa awọn ọrọ isọjade kan-naa ti kò yéni. Eeṣe ti ó fi yatọ? Wọn dín iniyelori ijẹpataki iyatọ gédégédé naa kù nipa sisọ pe “Ọlọrun fun ẹnikan ni iṣetumọ ọrọ sísọ kan ati fun ẹlomiran iṣetumọ miiran.” Ẹnikan gbà pe: “Mo ti ṣakiyesi awọn akoko iṣẹlẹ nibi ti iṣetumọ naa kì í tií ṣe iru eyi ti o péye.” D. A. Hayes, ninu iwe rẹ̀ The Gift of Tongues, tọka si apẹẹrẹ kan nibi ti ọkunrin kan ti kọ̀ lati ṣetumọ ọrọ sísọ obinrin kan ti ó fi ahọ́n ajeji kan sọrọ nitori pe “èdè naa jẹ́ aláìmọ́ julọ ninu àìmọ́.” Iyatọ ifiwera wo ni iyẹn jẹ́ si fífèdèfọ̀ ti o wáyé ni ọrundun kìn-ín-ní ti ó sì jẹ́ fun gbígbé ijọ ró niti gidi!—1 Korinti 14:4-6, 12, 18.
Awọn kan lonii fidaniloju sọ pe awọn gbọ́ iṣetumọ agbayanu, wọn sì lè fi otitọ-inu gbagbọ pe Ọlọrun ń lo ẹbun yii nigba ti ó bá “fẹ́ lati fun awọn eniyan ni ihin-iṣẹ taarata.” Ṣugbọn ihin-iṣẹ wo lati ọdọ Ọlọrun ni a nilo lonii ti Jesu Kristi ati awọn aposteli kò pese fun wa? Paulu, ti oun fúnraarẹ̀ ni ẹbun ẹmi mimọ, sọ pe: “Gbogbo iwe mimọ ti o ni imisi Ọlọrun ni o sì ni èrè fun ẹkọ, fun ibaniwi, fun itọni, fun ikọni ti o wà ninu ododo: Ki eniyan Ọlọrun ki ó lè pé, ti a ti mura silẹ patapata fun iṣẹ rere gbogbo.”—2 Timoteu 3:16, 17.
Otitọ naa ni pe, ijọ Kristian kì í ṣe ọmọ-ọwọ́ mọ́, ati nipa bayii awọn ìfihàn atọrunwa tabi awọn ẹbun oníṣẹ́ẹ̀yanu ti ẹmi ni a kò nilo mọ́ lati jẹ́rìí si ìlà iṣẹ rẹ̀. Bibeli kilọ pe: “Ṣugbọn bi o ṣe awa ni, tabi angẹli kan lati ọ̀run wá, ni ó bá waasu ihinrere miiran fun yin ju [“ti o yatọ sí,” The New English Bible] eyi ti a ti waasu fun yin lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu.”—Galatia 1:8.
Ìfèdèfọ̀ oniṣẹ-iyanu ni kò pọndandan mọ́, kò sì sí ipilẹ ti o bá Bibeli mu fun gbigbagbọ pe ó jẹ́ apakan isin Kristian tootọ lonii. Nisinsinyi ti Bibeli ti pé perepere ti ó sì wà larọọwọto lọna gbigbooro, a ni ohun ti a nilo ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ó jẹ ki a jèrè ìmọ̀ pipeye kan nipa Jehofa ati Ọmọkunrin rẹ̀ tí ń sinni lọ si ìyè ainipẹkun.—Johannu 17:3; Ìfihàn 22:18, 19.
Àní ni ọrundun kìn-ín-ní paapaa, aposteli Paulu ni a fi àpàpàǹdodo mú lati kọwe si ijọ ni Korinti lati tún oju-iwoye wọn ṣe nipa idi ti a fi fun awọn Kristian ijimiji ni ẹbun ahọ́n. Ó jọ bii pe, awọn kan ni ẹbun ahọ́n ti famọra, wọn sì ń huwa bii ọmọ kekere, alaidagba nipa tẹmi. Ijẹpataki ti o pọ̀ jù ni a so mọ́ “ahọ́n.” (1 Korinti 14:1-39) Paulu tẹnumọ ọn pe kì í ṣe gbogbo awọn Kristian ní ọrundun kìn-ín-ní ni wọn fi ahọ́n oniṣẹẹyanu sọrọ. Kò pọndandan fun igbala wọn. Àní nigba naa lọhun-un nigba ti ó wà, ẹbun ahọ́n wà ni ipo keji si isọtẹlẹ oniṣẹẹyanu. Fífèdèfọ̀ nigba naa kì í ṣe, kì í sìí ṣe, ohun abeere-fun kan fun awọn Kristian lati jere ìyè ainipẹkun.—1 Korinti 12:29, 30; 14:4, 5.
Agbara Ti Ó Wà Lẹhin Ahọ́n Ajeji Lonii
Awọn kan gbagbọ pe agbara idari ti o wà lẹhin awọn afèdèfọ̀ lonii ni awọn aṣaaju ṣọọṣi onigbagbọ mẹ́mìímẹ́mìí ti wọn ń sún awọn mẹmba agbo wọn lati gba agbara-iṣe yii. Ninu awọn ọ̀ràn kan a ń mú un wá nipasẹ animọ ero-imọlara ati àìwà-déédéé. Cyril G. Williams, ninu iwe Tongues of the Spirit, sọ pe ó ti di “àmì igbagbọ ninu eto ọ̀tọ̀kùlú-ọlọ́lá laaarin awujọ naa ninu ọpọlọpọ apẹẹrẹ” ó sì fun ẹnikan ni “iyì ijẹpataki ati ọla-aṣẹ ni oju awujọ naa ati ni oju araawọn pẹlu.” Isunniṣe naa, nitori naa, lè jẹ́ ìfẹ́-ọkàn lati wà lara awujọ èdè-àjèjì gigaju naa.
Ààrẹ Loyola University ìgbà naa Donald P. Merrifield ṣakiyesi pe “ahọ́n lè jẹ́ iriri onigboonara, tabi, gẹgẹ bi awọn kan ti wí, ọ̀kan ti o burúbèṣù.” Alufaa-ṣọọṣi Todd H. Fast sọ pe: “Ahọ́n jẹ́ alárìíyànjiyàn. Eṣu ní ọpọlọpọ ọ̀nà ti ó gbà ń nípa lori wa.” Bibeli fúnraarẹ̀ kilọ pe Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ lè lo agbara idari lori awọn eniyan ki o sì dari ọrọ sísọ wọn. (Iṣe 16:17, 18) Jesu huwa lodisi ẹmi eṣu kan ti ó sún ọkunrin kan lati kigbe ki o sì ṣubú lulẹ. (Luku 4:33-35) Paulu kilọ pe ‘Satani yoo yí araarẹ̀ pada si angẹli imọlẹ.’ (2 Korinti 11:14) Awọn wọnni ti wọn ń wá ẹbun ahọ́n ti Ọlọrun kò fi sori awọn eniyan rẹ̀ mọ́ lonii ń ṣí araawọn silẹ fun itanjẹ Satani niti gidi, ẹni ti, a kilọ fun wa nipa rẹ̀ pe, yoo lo “agbara gbogbo, ati àmì ati iṣẹ iyanu èké.”—2 Tessalonika 2:9, 10.
Ahọ́n—Ati Isin Kristian Tootọ
Awọn Kristian ọrundun-kìn-ín-ní ti wọn gba ẹbun fífèdèfọ̀ lò ó lati ṣalaye awọn ohun ńlá Ọlọrun. Itẹnumọ ni a gbekari aini naa lati ṣetumọ ihin-iṣẹ ti a fi ahọ́n sọ ni kedere ki gbogbo eniyan baa lè loye rẹ̀ ki o sì yọrisi ìgbéró ọpọlọpọ. (1 Korinti 14:26-33) Paulu ṣíni létí pe: “Bi kò ṣe pe ẹyin bá ń fi ahọ́n yin sọrọ ti o yéni, a o ti ṣe mọ ohun ti a ń wí? nitori pe ẹyin ó sọrọ si ofurufu.”—1 Korinti 14:9.
Nigba ti ẹmi Ọlọrun fun awọn Kristian ijimiji ni ẹbun ahọ́n, kò mú ki wọn sọ ọ̀rọ̀ gbuuru onisọkusọ ti kò lọgbọn-ninu tabi ti kò ṣee tumọ. Ni ibamu pẹlu imọran Paulu, ẹmi mimọ pese ọrọ sísọ ti o yọrisi jijẹ ki ihinrere di eyi ti a tubọ “waasu rẹ̀ ninu gbogbo ẹ̀dá ti ń bẹ labẹ ọ̀run.”—Kolosse 1:23.
Nipa awọn ọjọ ikẹhin eto igbekalẹ isinsinyi, Jesu Kristi paṣẹ pe: “A kò lè ṣaima kọ́ waasu ihinrere [nipa Ijọba ti a ti fidii rẹ̀ mulẹ] ni gbogbo orilẹ-ede.” (Marku 13:10) Gẹgẹ bi o ti rí ni ọrundun kìn-ín-ní, gbogbo ẹ̀dá gbọdọ gbọ́ ihin-iṣẹ Ijọba naa. Eyi ṣeeṣe nitori pe Bibeli ni a ti tumọ nisinsinyi, ni odidi tabi ni apakan, si eyi ti o fẹrẹẹ tó 2,000 èdè. Ẹmi kan-naa ti ó fi kún inú awọn Kristian ijimiji lati fi aiṣojo ati igboya sọrọ ni ó ń ti iṣẹ iwaasu ńláǹlà ati alágbàyanu ti ijọ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ode-oni lẹhin. Nipa ọ̀rọ̀ ẹnu ati nipa lilo ọgbọ́n ijinlẹ iwe títẹ̀ lati mú ki otitọ ti o bá Iwe Mimọ mu wà larọọwọto nipasẹ oju-iwe ti a tẹ̀, wọn ń sọ “èdè mimọ gaara” naa. Ihin-iṣẹ yii ni ó ń kọja lọ si awọn orilẹ-ede ati erekuṣu okun ti o ju 200 lọ. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa danikan duro gẹgẹ bi awọn eniyan tí ẹmi Ọlọrun ń sún lati sọ awọn ohun ńlá Ọlọrun di mímọ̀.—Sefaniah 3:9, NW; 2 Timoteu 1:13.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ijẹrii lati ẹnu-ọna dé ẹnu-ọna ni Japan
Ijẹrii lati inu ọkọ̀ oju-omi de inu ọkọ̀ oju-omi ni Colombia
Nisalẹ: Ikẹkọọ Bibeli ni Guatemala
Lábẹ́: Ijẹrii igberiko ni Netherlands