Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ gbólóhùn-ọ̀rọ̀ náà “ní ẹ̀mí,” tí a rí ní 1 Korinti 14:37, túmọ̀sí pé ẹnìkan ti gba ẹ̀mí mímọ́ ní èrò ìtumọ̀ jíjẹ́ ẹni-àmì-òróró, tàbí ó ha túmọ̀sí pé òun ní ẹ̀bùn oníṣẹ́-ìyanu láti ọwọ́ ẹ̀mí?
Nínú New World Translation of the Holy Scriptures, ẹsẹ yìí kà pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun jẹ́ wòlíì tàbí òun ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, kí ó jẹ́wọ́ àwọn ohun tí mo ń kọ sí yín, nítorí òfin-àṣẹ Oluwa ni wọ́n.”—1 Korinti 14:37.
Òǹkàwé kan lè gba àpólà-ọ̀rọ̀ náà “ní ẹ̀bùn ẹ̀mí” gẹ́gẹ́ bí ìtọ́ka sí òtítọ́ náà pé àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-ín-ní ni a fẹ̀mí bí tí wọ́n sì di àwọn ọmọkùnrin tẹmi Ọlọrun. Tàbí àpólà-ọ̀rọ̀ náà ni a lè lóye láti kan ẹni tí ó ti rí ẹ̀bùn àkànṣe ti ẹ̀mí mímọ́ gbà. Ìtumọ̀ tí ó kẹ́yìn yìí ní ó jẹ́ ọ̀kan tí ó ṣeéṣe, gẹ́gẹ́ bí ipò àtilẹ̀wá ti fihàn.
Aposteli Paulu níhìn-ín lo ọ̀rọ̀ Griki náà pneu·ma·ti·kosʹ, èyí tí ó ní èrò ìtumọ̀ ìpìlẹ̀ “tí ó jẹmọ́ ẹ̀mí, tẹ̀mí.” Àwọn irú rẹ̀ ni a lò nínú àpèjúwe náà “ara ẹ̀mí,” “ìbùkún ẹ̀mí,” “ìmòye . . . tíí ṣe ti ẹ̀mí,” àti ilé ẹ̀mí.”—1 Korinti 15:44; Efesu 1:3; Kolosse 1:9; 1 Peteru 2:5.
Nínú àwọn ọ̀ràn wọnyẹn, Bibeli dárúkọ kókó-ọ̀rọ̀ náà (ara, ìbùkún, ìmòye, ilé) tí “ẹ̀mí” ṣàpèjúwe. Ṣùgbọ́n nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn, èrò ìtumọ̀ àti ìṣètumọ̀ tí ó yẹ nípa “ẹ̀mí” ni a gbọ́dọ̀ pinnu láti inú ọ̀rọ̀ àyíká. Fún àpẹẹrẹ, 1 Korinti 2:14, 15 ṣe ìyàtọ̀ ìfiwéra ìṣarasíhùwà ọkùnrin ti ara kan pẹ̀lú ti pneu·ma·ti·kosʹ, èyí tí ó túmọ̀ lọ́nà tí ó bọ́gbọ́nmu sí “ọkùnrin ẹ̀mí.”
Korinti Kìn-ín-ní orí 12 sí 14 kó àfiyèsí jọ sórí àwọn ẹ̀bùn oníṣẹ́-ìyanu ti ẹ̀mí mímọ́. Ọlọrun fún àwọn Kristian ìjímìjí ní ìwọ̀nyí láti ṣàṣefihàn pé òun kò lo Israeli àbínibí mọ́ ṣùgbọ́n òun ń bùkún Kristian “Israeli Ọlọrun” nísinsìnyí. (Galatia 6:16) Nípa àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí, Paulu kọ̀wé pé: “Ǹjẹ́ onírúurú ẹ̀bùn ni ó wà, ṣùgbọ́n ẹ̀mí kan-náà ni.” (1 Korinti 12:4) Àkànṣe ọgbọ́n, ìmọ̀, àti ìgbàgbọ́ wà lára àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí náà, gẹ́gẹ́ bí sísọtẹ́lẹ̀, fífèdèfọ̀, àti títúmọ̀ èdè ti ṣe wà.—1 Korinti 12:8-11.
Àwọn Kristian ní Korinti tí Paulu kọ̀wé sí ni a fẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun yàn. Paulu sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn nínú yín sì ti jẹ́ rí: ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín nù, ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti dá yín láre ní orúkọ Jesu Kristi Oluwa, àti nípa ẹ̀mí Ọlọrun wa.” (1 Korinti 6:11; 12:13) Bẹ́ẹ̀ni, gbogbo wọn ti gba “àmì-ìdánilójú ohun tí ń bọ̀, èyíinì ni, ẹ̀mí náà.” (2 Korinti 5:5, NW) Bí ó ti wù kí ó rí, kìí ṣe gbogbo wọn ni ó gba ẹ̀bùn àkànṣe kan nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. Ó sì dàbí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni fífèdèfọ̀ fà lọ́kàn mọ́ra, ní síso ìjẹ́pàtàkì tí kò yẹ mọ́ ẹ̀bùn yìí. Paulu kọ̀wé láti tún ìrònú wọn ṣe ó sì ṣàlàyé pé àwọn ahọ́n kò ní ṣàǹfààní fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn bí ẹ̀bùn sísọtẹ́lẹ̀ yóò ti ṣe. Ní òpin orí 12, Paulu gba àwọn ará Korinti nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa fi ìtara ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn tí ó tóbi jù.”—1 Korinti 12:28-31.
Lẹ́yìn náà, ní ìbẹ̀rẹ̀ orí 14, ó rọni pé: “Ẹ máa lépa ìfẹ́, kí ẹ sì máa fi ìtara ṣàfẹ́rí [ta pneu·ma·ti·kaʹ], ṣùgbọ́n kí ẹ kúkú lè máa sọtẹ́lẹ̀.” Ṣàfẹ́rí kí ni? Àwọn Kristian wọnnì kò níláti ṣàfẹ́rí ẹ̀mí ìfòróró yanni kan, nítorí pé wọ́n ní irú ìyẹn ná. Lọ́nà tí ó bọ́gbọ́nmu Paulu ní “àwọn ẹ̀bùn” ẹ̀mí lọ́kàn, èyí tí ó rọ̀ wọ́n, ní òpin orí 12, láti ṣàfẹ́rí. Fún ìdí yìí, New World Translation of the Holy Scriptures ṣètumọ̀ 1 Korinti 14:1 pé: “Ẹ máa lépa ìfẹ́, síbẹ̀ ẹ máa fi ìtara wá àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí kiri.” Àwọn ìtumọ̀ Bibeli mìírán níhìn-ín ṣètumọ̀ ta pneu·ma·ti·kaʹ sí “àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí” tàbí “àwọn ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí.”
Pẹ̀lú ipò àtilẹ̀wá yẹn, a ṣàkíyèsí pé nítòsí ìparí orí 14, Paulu so sísọtẹ́lẹ̀ àti pneu·ma·ti·kosʹ mọ́ra. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ẹsẹ 1, àyíká-ọ̀rọ̀ náà dámọ̀ràn pé òun ní jíjẹ́ ẹni tí a fún ní ẹ̀bùn ẹ̀mí lọ́kàn. The New Testament in Modern Speech, láti ọwọ́ R. F. Weymouth, ṣàmúlò ìṣètumọ̀ náà: “Bí ẹnikẹ́ni bá ka araarẹ̀ sí wòlíì tàbí ọkùnrin kan tí ó ní àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí, jẹ́ kí ó mọ̀ ohun tí mo ń kọ̀wé rẹ̀ nísinsìnyí dájú gẹ́gẹ́ bí Oluwa ti pàṣẹ.”
Bẹ́ẹ̀ni, gbogbo àwọn Kristian, yálà wọ́n ní ẹ̀bùn sísọtẹ́lẹ̀ tàbí ẹ̀bùn ti ẹ̀mí èyíkéyìí mìíràn, níláti gba ìmọ̀ràn tí Paulu kọ̀wé rẹ̀ nípa bí àwọn nǹkan ṣe níláti wáyé nínú ìjọ kí wọ́n sì tẹ̀lé e.