Iwọ Ha Ti Ṣiro Iye Ti Yoo Ná Ọ Bi?
“KÍNLA! Ṣe pe o ń kọ ifilọni agbayanu bi eyi?” Agbara káká ni olùbójútó naa fi lè gbagbọ ninu ohun ti o ṣẹṣẹ gbọ́ tán. Ọmọ-abẹ́ rẹ̀, obinrin kan ti a bọ̀wọ̀ fun nitori òye-iṣẹ́ ati iwarere rẹ ṣẹṣẹ kọ ifilọni kan lati lọ kẹkọọ loke òkun fun ọdun meji ni níná owo ile-iṣẹ naa ni. Eeṣe ti oun fi ṣe bẹẹ?
Lati tẹwọgba ifilọni naa, obinrin naa ṣalaye pe, yoo tumọsi didi ẹni ti a pínníyà kuro lọdọ ọkọ ati awọn ọmọ rẹ̀ fun ọdun meji. Oun yoo ṣàárò wọn gidigidi. Eyi ti o tun ṣe pataki ju ni pe oun yoo pa iṣẹ ti Ọlọrun fifun un gẹgẹ bi iyawo ati ìyá tì. Ohun ti yoo ná an niti ero-imọlara ati tẹmi yoo ti jẹ iye owo giga ju kan lati san. Nipa bẹẹ, lẹhin ṣiṣiro ohun ti yoo ná an, oun pinnu lati kọ ifilọni naa.
Ki ni iwọ ìbá ti ṣe ki a sọ pe iwọ ni o wà ni ipo rẹ̀? Lọna ti o ṣe kedere, kì í ṣe gbogbo eniyan ni yoo gbà pẹlu ipinnu tí obinrin Kristian yii ṣe. Awọn kan, bii awọn oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ̀ lè nimọlara pe oun ti padanu anfaani ọlọla fun mímú iṣẹ igbesi-aye rẹ̀ gbooro sii. Awọn miiran tilẹ lè fẹ̀sùn kàn án pe kò ronu nipa ọjọ-ọla idile rẹ̀, ó ṣetan ọdun meji yoo yára kọja lọ. Sibẹ ipinnu rẹ̀ kì í ṣe ti oníwàǹwára tabi ti ero-imọlara alainironu. Ó jẹ́ eyi ti a gbé ka ori ironu ti ó jinlẹ ati awọn ilana aríranjìnnà. Ki ni awọn wọnyi?
Ó Ju Ọgbọ́n-orí Lasan Lọ
Ọkunrin ọlọgbọn julọ ti ó tíì rìn lori ilẹ̀-ayé rí, Jesu Kristi, pese ilana atọnisọna ninu ọ̀kan lara awọn òwe-àkàwé rẹ̀. “Nitori ta ni ninu yin ti ń pète ati kọ́ ile-iṣọ, ti kì yoo kọ́ jokoo ki o ṣiro iye owó rẹ̀, bi oun ni tó ti yoo fi pari rẹ̀?” ni Jesu beere. “Ki ó má baà jẹ́ pe nigba ti ó bá fi ipilẹ ile sọlẹ tán, ti kò lè pari rẹ̀ mọ, gbogbo awọn ti ó rí i a bẹrẹ sii fi i ṣe ẹlẹ́yà, wi pe, Ọkunrin yii bẹrẹ sii ile í kọ́, kò sì lè pari rẹ̀.”—Luku 14:28-30.
Olukuluku eniyan yoo gbà pe ó lọgbọn ninu lati ṣiro iye ti yoo náni ṣaaju pipinnu lati ṣe ohun pataki eyikeyii. Fun apẹẹrẹ, bi ẹnikan bá fẹ lati ra ile kan, oun yoo ha kùgìrì ni fifọwọsi gbigbe iṣẹ fun agbaṣẹṣe láìtilẹ̀ ṣiro iye ti yoo ná an ki o sì rí i daju pe oun ni agbara inawo lati lè pari eto inawo naa bi? Omugọ ni a o pè é bi ó bá ṣe iru nǹkan bẹẹ. Bẹẹni, ọgbọ́n-orí ni lati kọkọ ṣiro iye ti yoo náni ṣaaju ki ẹnikan tó bẹrẹ idawọle kan.
Kókó wo ni Jesu ń mú ṣe kedere ninu òwe-àkàwé yẹn niti gidi? Ṣaaju ninasẹ òwe-àkàwé naa, ó sọ pe: “Ẹni yoowu ti kò bá gbé òpó igi idaloro rẹ̀ ki o sì maa tọ̀ mi lẹhin kò lè jẹ́ ọmọ-ẹhin mi.” (Luku 14:27, NW) Nipa bayii, kókó ọ̀rọ̀ naa kò fihàn pe Jesu kàn wulẹ ń funni ni imọran onilaakaye fun awọn idawọle wa ojoojumọ. Kàkà bẹẹ, oun ń sọrọ nipa ṣiṣiro ohun ti ó ń náni ni isopọ pẹlu didi ọmọ-ẹhin rẹ̀.
Nipasẹ òwe-àkàwé rẹ̀, Jesu ṣalaye pe lati di ọmọ-ẹhin rẹ̀ ń beere fun iyipada ati awọn irubọ. Eeṣe? Nitori pe eto igbekalẹ awọn nǹkan isinsinyi jẹ́ olufẹ ọrọ̀ alumọni ti a sì ń sún un nipasẹ ifẹ ara-ẹni. Ohun ti o kan eyi ti o pọ julọ ninu awọn eniyan ni títẹ́ ifẹ ẹran-ara wọn lọrun, ti wọn pe afiyesi ti o kere tabi ki ó má tilẹ si rárá si aini wọn nipa tẹmi tabi ibatan wọn pẹlu Ọlọrun. (2 Timoteu 3:1-4) Iṣarasihuwa tabi ẹmi yii, bi o ti wu ki o ri, jẹ́ eyi ti o lodi ni taarata si eyi ti Jesu Kristi fihàn. “Ọmọ eniyan wá” ni oun sọ “kì í ṣe ki a maa ṣe iranṣẹ fun un bikoṣe lati ṣe iranṣẹ ati lati fi ọkàn rẹ̀ funni ni irapada ni paṣipaarọ fun ọpọlọpọ.” Oun gbé iniyelori giga julọ lori ohun tẹmi dipo awọn ohun ti ara nigba ti o wi pe: “Ẹmi ni í sọni di aaye; ara kò ní èrè kan.”—Matteu 20:28, NW; Johannu 6:63.
Nitori naa, nigba ti Jesu gba awọn ẹni ti ó fẹ́ di ọmọ-ẹhin rẹ̀ nimọran lati ṣiro ohun ti ń náni, oun ń sọrọ ni pataki, kì í ṣe nipa iniyelori nǹkan ti ara, bikoṣe awọn ohun tẹmi. Ki ni ohun ti o ṣe pataki ju fun wọn, èrè ohun ti ara tí ayé nawọ rẹ̀ síni tabi anfaani tí jíjẹ́ ọmọ-ẹhin ń nawọ rẹ̀ sini? Idi niyii ti o fi jẹ pe lẹhin ti o ti funni ni òwe-àkàwé naa ati ọ̀kan ti o fara pẹ́ ẹ, oun pari ọ̀rọ̀ pe: “Gẹgẹ bẹẹ ni, ẹnikẹni ti ó wù ki o ṣe ninu yin, ti kò bá kọ ohun gbogbo ti ó ní silẹ, kò lè ṣe ọmọ-ẹhin mi.” (Luku 14:33) Ṣe ẹni ti ń bọ̀ wá di ọmọ-ẹhin naa ti muratan ti o sì ti gbaradi lati ṣe iru irubọ yẹn tabi ó ha jẹ́ iye owó giga kan lati san bi?
Oju-iwoye Kan Ti Ó Wà Deedee
Àní bi o tilẹ jẹ pe awọn ohun ti ara lè mu awọn anfaani ṣiṣe kedere ti o sì tètè ṣee ṣakiyesi ni kiakia wá, awọn anfaani lati inu awọn ilepa tẹmi ni o ń wà pẹtiti julọ ti ó sì ń tẹnilọrun. Jesu ronu ni ọ̀nà yii: “Ẹ maṣe to iṣura jọ fun araayin ni ayé, nibi ti kokoro ati ìpáàrà íbà á jẹ́, ati nibi ti awọn ole írunlẹ̀ ti wọn sìí jale. Ṣugbọn ẹ to iṣura jọ fun araayin ni ọ̀run nibi ti kokoro ati ìpáàrà kò lè baajẹ, ati nibi ti awọn ole kò lè runlẹ ki wọn sì jale.” (Matteu 6:19, 20) Ni ọjọ wa ifosoke owó-ọjà, ilọsilẹ ninu eto káràkátà, ìforíṣánpọ́n ile ifowopamọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti mu iparun bá ọpọlọpọ ti wọn fi igbẹkẹle wọn sinu kìkì awọn ọrọ̀ ohun ti ara. Sibẹ aposteli Paulu gbaninimọran lati “tẹ oju wa mọ́, kì í ṣe awọn ohun ti a ń rí, bikoṣe awọn ohun airi. Nitori awọn ohun ti a ń rí jẹ fun ìgbà diẹ, ṣugbọn awọn ohun airi jẹ́ ainipẹkun.” (2 Korinti 4:18) Bi o tilẹ rí bẹẹ, bawo ni awa ṣe lè mu iru oju-iwoye yẹn dagba?
Awa lè ṣe bẹẹ nipa ṣiṣafarawe Awokọṣe ati Awofiṣapẹẹrẹ wa, Jesu Kristi. Nigba ti o wà lori ilẹ̀-ayé, oun kì í ṣe aṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ niti gbigbadun awọn ohun yiyẹ, gẹgẹ bi ẹ̀rí ti fihàn nipasẹ otitọ naa pe oun nigba kan nipin-in ninu apejẹ igbeyawo ati àsè ounjẹ. Bi o ti wu ki o ri, oun ni kedere fi awọn ohun tẹmi si ipo akọkọ. Lati baa lè ṣe ifẹ-inu Baba rẹ̀ ni aṣepe, oun muratan lati kọ awọn ohun ti a kà sí kòṣeémánìí silẹ. Nigba kan oun kede pe: “Awọn kọlọkọlọ ni [ihò], awọn ẹyẹ oju ọ̀run sì ni ìtẹ́; ṣugbọn ọmọ eniyan kò ni ibi ti yoo fi ori rẹ lé.” (Luku 9:58) Oun ka ṣiṣe ifẹ-inu Baba rẹ̀ si oun ti o ṣe kókó ti o sì gbadunmọni tí oun fi fi otitọ ọkàn sọ pe: “Ounjẹ mi ni lati ṣe ifẹ ẹni ti o rán mi, ati lati pari iṣẹ rẹ̀.”—Johannu 4:34.
Jesu fi òye rẹ̀ lati ṣediyele ohun ti ó dara hàn nipasẹ ọ̀nà ti oun gbà kọ awọn idanwo Satani. Eṣu gbiyanju lati jẹ ki Jesu lo agbara ti Ọlọrun fifun un lati mú anfaani wá fun Araarẹ̀, lati tẹ́ awọn aini ohun ti ara Rẹ̀ lọrun, ati lati jere òkìkí ayé ati ìgbajúgbajà. Jesu mọ daradara pe iru awọn anfaani ti a lè gbé ibeere dide si bẹẹ ni ọwọ lè tẹ̀ kìkì ni iye owó giga kan—ipadanu itẹwọgba Ọlọrun—iye owó kan ti o ga ju ohun ti o ní imuratan lati san, nitori ti oun ṣikẹ ipo ibatan rẹ̀ pẹlu Baba rẹ̀ ju ohunkohun miiran lọ. Idi niyẹn ti oun fi kọ awọn ifilọni Satani laiṣe tabi-ṣugbọn, laisi ìlọ́tìkọ̀.—Matteu 4:1-10.
Gẹgẹ bi ọmọlẹhin Kristi, dajudaju awa fẹ lati ni òye kan-naa lati ṣediyele ohun ti o dara gẹgẹ bi Ọ̀gá wa. Ninu eto awọn nǹkan isinsinyi labẹ iṣakoso Satani, ọpọlọpọ awọn nǹkan ti o dabi ẹni pe wọn nawọ awọn anfaani didara sini ni o wà ṣugbọn ti wọn lè ba ipo ibatan wa pẹlu Ọlọrun jẹ niti gidi. Iru awọn nǹkan bẹẹ bii bibaa lọ ni wíwá ipo giga ninu ayé, lilepa ìmọ̀-ẹ̀kọ́ iwe giga lati mu ipo ẹni ga sii, fífẹ́ alaigbagbọ sọna, tabi lilọwọ ninu eto iṣowo ti a lè gbé ibeere dide si lè fi irọrun ṣamọna si ipadanu igbagbọ ati lẹhin-ọ-rẹhin ṣiṣubu kuro ninu ojurere Jehofa. A gbọdọ fi tiṣọratiṣọra ṣiro iye ti o ń náni nigba ti a bá kò wá loju pẹlu iru awọn idanwo bẹẹ.
Ọgbọ́n Tootọ Aabo Kan
Ni awọn ọdun diẹ sẹhin, ọ̀dọ́ ọkunrin Kristian kan ni ilu titobi kan ni Far East ní anfaani lati lọ si òkè-òkun lati mú ìmọ̀-ẹ̀kọ́ rẹ̀ tẹsiwaju. Bi o tilẹ jẹ pe oun ti ni ìmọ̀-ẹ̀kọ́ ayé didara kan ati iṣẹ ti ń mówó wálé daradara kan tẹlẹ, oun nimọlara pe eyi kò tó; ó fẹ́ lati mú ipo rẹ̀ sunwọn sii ninu igbesi aye. Awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ gbiyanju lati ronu papọ pẹlu rẹ̀ ni ibamu pẹlu awọn kókó Iwe Mimọ ti a ṣẹṣẹ gbeyẹwo, ṣugbọn ó ṣorikunkun ó sì lọ pẹlu ipetepero naa. Bi o tilẹ jẹ pe oun gbiyanju lati di igbagbọ rẹ̀ mú lakọọkọ, ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó padanu imọriri rẹ̀ fun otitọ Bibeli, iyemeji sì bẹrẹ sii dide. Ni nǹkan bii ọdun kan ṣáá, ó padanu igbagbọ rẹ̀ patapata ó sì jẹwọ jíjẹ́ onigbagbọ-Ọlọrun-ko-ṣee-mọ. A gba pe, jijere ipo giga nipasẹ ìmọ̀-ẹ̀kọ́ ayé ti a mú gbooro sii mú ìwọ̀n itẹlọrun wá fun un. Ṣugbọn fun ogo ìgbà diẹ ni, iye owó giga wo ni oun ti nilati san—rírì ọkọ̀ igbagbọ rẹ̀ ati ewu pipadanu ìyè ayeraye!—1 Timoteu 1:19.
Ni ọwọ keji ẹ̀wẹ̀, awọn ti wọn kọ̀ lati jẹ́ ki ohunkohun wu ipo ibatan wọn pẹlu Ọlọrun lewu ti karugbin ọpọ ibukun lati ọdọ Jehofa.
Apẹẹrẹ kan ni ti ọdọkunrin kan ti o ni òkòwò iṣẹ-ọna ile ni ilu-nla kan-naa ti a tọka si loke yii. Ni kìkì iwọnba oṣu diẹ lẹhin ti o ti bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, a kò ó loju pẹlu ifilọni adanniwo kan—lati ṣe iṣẹ atunṣe oni $30,000 kan. Bi o ti wu ki o ri, yoo ni ninu rírú awọn akojọ ofin ilé-kíkọ́ kan ati awọn ilana ilu lati lè kọ́ awọn ile kan ti kò bofinmu. Niwọn bi o sì ti kẹkọọ pe awọn Kristian gbọdọ jẹ oluṣegbọran si ofin, o mọ pe lati gba iṣẹ naa lè tumọsi pipadanu ojurere Ọlọrun. (Romu 13:1, 2) Lẹhin wíwọn ọ̀ràn naa wò tiṣọratiṣọra, o kọ iṣẹ naa silẹ. Ki ni abajade rẹ̀? Ihuwa nipa igbagbọ yii jẹ kókó manigbagbe kan ninu itẹsiwaju rẹ̀ nipa tẹmi. Laaarin ọdun yẹn, ó tẹsiwaju de ipo iyasimimọ ati iribọmi. Ó ta òkòwò rẹ̀ ti o sì nawọ gán iṣẹ kan ti o fun un laaye pupọ pupọ sii fun ilepa awọn ohun tẹmi. Oun nisinsinyi ń fi ayọ ati itara ṣiṣẹsin Jehofa.
Awọn ọdọkunrin mejeeji yii ṣiro iye ti yoo ná wọn. Ki ni o mu iyatọ wa ninu yíyàn wọn? Ọgbọ́n oniwa-bi-Ọlọrun ni! Bawo ni o ṣe jẹ́ bẹẹ? Ọgbọ́n jẹ́ agbara-iṣe naa lati lo ìmọ̀ lọna ti o sábà maa ń mu awọn anfaani pipẹtiti wá, ti ọgbọ́n oniwa-bi-Ọlọrun sì tumọsi lilo ìmọ̀ ni ila pẹlu ète Ọlọrun fun wa. Nigba ti awọn ọdọkunrin mejeeji ní ìmọ̀ Bibeli diẹ, ifisilo rẹ̀ lẹnikọọkan wọn ṣamọna si abajade ọtọọtọ. Iwe Owe sọ pe: “Nigba ti ọgbọ́n bá wọ inu rẹ lọ, tí ìmọ̀ sì dùn mọ́ ọkàn rẹ; imoye yoo pa ọ́ mọ́, oye yoo si maa ṣọ́ ọ: Lati gbà ọ́ ni ọwọ́ ẹni ibi.”—Owe 2:10-12.
Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli, ni orisun awọn ọgbọ́n tootọ eyi ti iwọ lè maa yiju si nigba gbogbo fun itọsọna nigba ti iwọ bá nilati ṣe awọn ipinnu pataki. Dipo didi ọlọgbọn ni oju araàrẹ, ṣe igbọran si imọran naa: “Fi gbogbo àyà rẹ gbẹkẹle Oluwa; má sì ṣe tẹ̀ sí ìmọ̀ araàrẹ. Mọ̀ ọ́n ni gbogbo ọ̀nà rẹ: oun ó sì maa tọ́ ipa-ọna rẹ.” (Owe 3:5, 6) A gbọdọ jẹ́ onirẹlẹ ki a sì muratan lati gba ẹ̀kọ́, ni yiyẹra fun ifẹ-inu ara-ẹni ati ẹmi idadurolominira ayé ti o gbilẹ kaakiri lonii.
Bẹẹni, a kò lè yẹra fun kíká ohun ti a bá gbìn, ó sì bá ẹ̀tọ́ ati idajọ ododo mu pe ki a rẹrù abajade awọn ipinnu ati yíyàn ti a bá ṣe. (Galatia 6:7, 8) Nitori naa ṣiro iye ti yoo ná ọ ṣaaju idawọle kọọkan. Maṣe faaye gba ohun ti o jọ bi anfaani lati jà ọ́ lólè nipa tẹmi tabi ipo ibatan rẹ pẹlu Jehofa Ọlọrun. Gbadura fun ọgbọ́n ati idajọ rere lati lè ṣe awọn ipinnu ti o tọ́, nitori ipinnu ti iwọ bá ṣe nisinsinyi lè tumọsi iyatọ laaarin ìyè ainipẹkun ati ikú ainipẹkun!—Fiwe Deuteronomi 30:19, 20.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Oun yoo ha fi igbokegbodo tẹmi tabi iṣẹ-igbesi-aye ti ayé sí ipo kìn-ín-ní ninu igbesi-aye bi?