Gbogbo Awọn Kristian Tootọ Gbọdọ Jẹ́ Ajihinrere
“Ṣe iṣẹ ajihinrere [tabi, ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji].”—2 TIMOTEU 4:5, NW. akiyesi ẹsẹ-iwe.
1. Ki ni ihinrere ti awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ni ọrundun kìn-ín-ní waasu rẹ̀?
KI NI ó tumọsi lonii lati jẹ́ ajihinrere? Iwọ ha jẹ́ ọ̀kan bi? Ọ̀rọ̀ naa “ajihinrere” wá lati inu ọ̀rọ̀ Griki naa eu.agge.li.stes<u27>, eyi ti o tumọsi “oniwaasu ihinrere.” Lati ìgbà idasilẹ ijọ Kristian ni 33 C.E., ihinrere Kristian tànmọ́lẹ̀ sori ohun eelo Ọlọrun fun igbala ó sì polongo pe Jesu Kristi yoo pada wá nigba ti ó bá yá lati bẹrẹ iṣakoso Ijọba rẹ̀ lori araye.—Matteu 25:31, 32; 2 Timoteu 4:1; Heberu 10:12, 13.
2. (a) Bawo ni ohun ti ihinrere naa ní ninu ṣe di eyi ti a sọ di kikun sii ni ọjọ wa? (b) Iṣẹ aigbọdọmaṣe wo ni ó já lé gbogbo awọn Kristian tootọ lejika lonii?
2 Lati 1914 lọ, ẹ̀rí bẹrẹ sii ga sii pe àmì ti Jesu ti fifunni nipa ipadabọ ati wíwàníhìn-ín alaiṣeefojuri rẹ̀ ni ó ń ní imuṣẹ. (Matteu 24:3-13, 33) Lẹẹkan sii, ihinrere lè ní ọ̀rọ̀ naa “ijọba Ọlọrun kù sí dẹ̀dẹ̀” ninu. (Luku 21:7, 31; Marku 1:14,15) Nitootọ, akoko ti tó fun asọtẹlẹ Jesu ti a ṣakọsilẹ rẹ̀ ni Matteu 24:14 lati niriiri imuṣẹ ńláǹlà: “A ó sì waasu ihinrere ijọba yii ni gbogbo ayè lati ṣe ẹ̀rí fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo sì dé.” Nitori naa, jijihinrere nisinsinyi ní ninu fífi tìtaratìtara kede Ijọba Ọlọrun ti a ti fidii rẹ̀ mulẹ ati awọn ibukun ti yoo mú wa fun araye onigbọran laipẹ. Gbogbo awọn Kristian wà labẹ aṣẹ lati ṣe iṣẹ yii ati lati “sọni di ọmọ-ẹhin.”—Matteu 28: 19, 20, NW; Ìfihàn 22:17.
3. (a) Itumọ siwaju sii wo ni ọ̀rọ̀ naa “ajihinrere” ní? (Wo Insight on the Scriptures, Idipọ 1, oju-iwe 770, ìlà 2, ipinrọ 2.) (b) Awọn ibeere wo ni eyi gbé dide?
3 Ni afikun si wiwaasu ihinrere naa ni gbogbogboo, Bibeli lo èdè-ìsọ̀rọ̀ naa “ajihinrere” ni ero-itumọ akanṣe kan nipa awọn wọnni ti wọn fi ipinlẹ ilẹ wọn silẹ lati waasu ihinrere ni awọn ẹkùn ti a kò tíì waasu nibẹ rí. Ni ọrundun kìn-ín-ní, ọpọlọpọ ajihinrere ti wọn jẹ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ni wọn wà, iru bii Filippi, Paulu, Barnaba, Sila, ati Timoteu. (Iṣe 21:8; Efesu 4:11) Ṣugbọn ki ni nipa akoko akanṣe tiwa lati 1914? Ǹjẹ́ awọn eniyan Jehofa lonii ti mú araawọn wà larọọwọto bii ajihinrere ni adugbo ati bakan-naa bii ajihinrere ti o jẹ́ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji?
Itẹsiwaju Lati 1919
4, 5. Ki ni a fojusọna fun ninu iṣẹ ajihinrere ní kete lẹhin 1914?
4 Nigba ti Ogun Agbaye I sunmọ ipari ni 1918, awọn iranṣẹ Ọlọrun niriiri atako tí ń pọ sii lati ọdọ awọn apẹhinda papọ pẹlu awujọ alufaa Kristẹndọm ati awọn oṣelu alajọṣepọ wọn. Nitootọ, jijihinrere ti awọn ojulowo Kristian fẹrẹẹ dawọduro ni June 1918 nigba ti a fi awọn aṣaaju oṣiṣẹ Watch Tower Society ni United States sẹ́wọ̀n 20 ọdun labẹ awọn ẹ̀sùn èké. Awọn ọ̀tá Ọlọrun ha ti ṣaṣeyọri ninu mímú opin débá wiwaasu ihinrere bi?
5 Láìròtẹ́lẹ̀, ni March 1919 awọn oṣiṣẹ Society ni a tú silẹ ti a sì dáláre kuro ninu awọn ẹ̀sùn èké ti ó gbé wọn dé ẹ̀wọ̀n. Pẹlu ominira ti wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà, awọn Kristian ẹni-ami-ororo wọnyi mọ pe iṣẹ pupọ rẹpẹtẹ ṣì wà lati ṣe ṣaaju ki wọn tó lè di ẹni ti a kojọpọ si èrè wọn ti ọ̀run gẹgẹ bi ajumọgogun ninu Ijọba Ọlọrun.—Romu 8:17; 2 Timoteu 2:12; 4:18.
6. Bawo ni iṣẹ ajihinrere ṣe tẹsiwaju laaarin 1919 ati 1939?
6 Lẹhin lọhun-un ni 1919 iye ti o kere ju 4,000 ni wọn wà ti wọn rohin ṣiṣajọpin ninu títan ihinrere naa kálẹ̀. Ni ẹwadun meji ti ó tẹle e, awọn eniyan melookan yọnda araawọn gẹgẹ bi ajihinrere ti o jẹ́ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji, awọn diẹ ni a sì rán lọ si awọn orilẹ-ede Africa, Asia, ati Europe. Nigba ti o fi maa di 1939, lẹhin iwaasu Ijọba fun 20 ọdun, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti pọ̀ tó iye ti o ju 73,000 lọ. Ibisi titayọ yii, ti a ṣaṣepari laika ọpọlọpọ inunibini sí, ni ó jọra pẹlu ohun ti ó wáyé ni awọn ọdun ibẹrẹ ti ijọ Kristian.—Iṣe 6:7; 8:4, 14-17; 11:19-21.
7. Ni ọdun 47 C.E. ati 1939, ipo ti o farajọra wo ni ó wà nipa iṣẹ Kristian ajihinrere?
7 Sibẹ, ọpọ julọ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni akoko yẹn ni wọn pọ̀ lápọ̀jù ni awọn orilẹ-ede Protẹstant ti ń sọ èdè Gẹẹsi. Nitootọ, iye ti ó ju ipin 75 ninu ọgọrun-un ninu 73,000 awọn akede Ijọba wá lati Australia, Britain, Canada, New Zealand, ati United States. Gẹgẹ bi ọ̀ràn ti rí ni nǹkan bii 47 C.E., ohun kan ni a nilo lati fun awọn ajihinrere niṣiiri lati tubọ fi afiyesi si awọn orilẹ-ede ilẹ̀-ayé ti a kò fi bẹẹ ṣiṣẹ nibẹ.
8. Nigba ti o fi maa di 1992, ki ni Ilé-Ẹkọ Gilead ti ṣaṣepari rẹ̀?
8 Ìkálọ́wọ́kò akoko-ogun ati inunibibini kò lè dáwọ́ ẹmi mimọ alagbara ti Jehofa duro kuro ninu sísún awọn iranṣẹ rẹ̀ lati murasilẹ fun imugbooro titobi sii. Ni 1943, nigba ti Ogun Agbaye II wà ni ògógóró rẹ̀, eto-ajọ Ọlọrun dá Watchtower Bible School of Gilead silẹ pẹlu èrò títan ihinrere kálẹ̀ lọna gbigbooro sii. Nigba ti o fi maa di March 1992, ilé-ẹ̀kọ́ yii ti rán 6,517 awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji jade lọ si 171 awọn orilẹ-ede ọtọọtọ. Ni afikun, awọn ọkunrin ni a dalẹkọọ lati bojuto awọn ẹ̀ka Watch Tower Society ni awọn ilẹ okeere. Bẹrẹ lati 1992, ninu 97 awọn olùṣekòkáárí Igbimọ Ẹ̀ka, 75 ni a dalẹkọọ ni Gilead.
9. Awọn itolẹsẹẹsẹ idanilẹkọọ wo ni ó ti kó ipa kan ninu itẹsiwaju iṣẹ jijihinrere ati sisọni di ọmọ-ẹhin?
9 Yatọ si Ilé-Ẹ̀kọ́ Gilead, awọn itolẹsẹẹsẹ idanilẹkọọ miiran ti mura awọn eniyan Jehofa silẹ lati mú iṣẹ ajihinrere wọn gbooro ki wọn sì mú un sunwọn sii. Fun apẹẹrẹ, Ilé-ẹ̀kọ́ Iṣẹ-ojiṣẹ Iṣakoso Ọlọrun ń gbéṣẹ́ṣe ninu ijọ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jakejado ayé. Iṣeto yii, papọ pẹlu Ipade Iṣẹ-isin ọsọọsẹ, ti dá araadọta-ọkẹ awọn akede Ijọba lẹkọọ lati jẹ́ ẹni ti o jafafa ninu iṣẹ-ojiṣẹ itagbangba. Ilé-ẹ̀kọ Iṣẹ-ojiṣẹ Ijọba tún wà, eyi ti ń pese idanilẹkọọ ti ó ṣeyebiye fun awọn alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ ki awọn wọnyi baa lè bojuto awọn ijọ tí ń dagba sii lọna didara ju. Ilé-ẹ̀kọ́ Iṣẹ-isin Aṣaaju-ọna ti seranwọ fun ọpọlọpọ awọn ajihinrere alakooko-kikun lati tubọ di ọjafafa ninu igbokegbodo iwaasu wọn. Ni lọ́ọ́lọ́ọ́ yii, Ilé-ẹ̀kọ́ Idanilẹkọọ Iṣẹ-ojiṣẹ ti gbéṣẹ́ṣe ni oniruuru orilẹ-ede lati ran awọn alagba ati awọn iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ ti wọn kò tíì gbeyawo lọwọ lati di Timoteu ode-oni.
10. Ki ni ó ti jẹ́ iyọrisi gbogbo idanilẹkọọ titayọlọla ti a ń pese nipasẹ eto-ajọ Ọlọrun? (Fi isọfunni ti ó wà ninu apoti kun un.)
10 Ki ni ó ti jẹ́ iyọrisi gbogbo idanilẹkọọ yii? Ni 1991, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti dé gongo awọn akede Ijọba ti o ti ju million mẹrin lọ daradara ti wọn ń gbéṣẹṣe ni awọn orilẹ-ede 212. Bi o ti wu ki o ri, laidabii ipo ti ó wà ni 1939, iye ti ó ju ipin 70 ninu ọgọrun-un awọn wọnyi wá lati awọn ilẹ Katoliki, Orthodox, awọn ti kì í ṣe ti Kristian, ati awọn ilẹ miiran, nibi ti èdè Gẹẹsi kì í tií ṣe èdè ti ó gbilẹ julọ.—Wo apoti “Imugbooro Lati 1939.”
Eeṣe Ti Wọn Fi Ṣaṣeyọri
11. Ta ni aposteli Paulu fi ìyìn aṣeyọri rẹ̀ gẹgẹ bi ojiṣẹ kan fun?
11 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò yin araawọn fun imugbooro yii. Dipo bẹẹ, wọn wo iṣẹ wọn ni ọ̀nà ti aposteli Paulu gbà wò ó, gẹgẹ bi oun ti ṣalaye ninu lẹta rẹ̀ si awọn ará Korinti. “Ki ni Apollo ha jẹ́? ki ni Paulu sì jẹ́? bikoṣe awọn iranṣẹ nipasẹ ẹni ti ẹyin ti gbagbọ, ati olukuluku gẹgẹ bi Oluwa ti fun. Emi gbìn Apollo bomirin; ṣugbọn Ọlọrun ni ń mú ibisi wá. Ǹjẹ́ kì í ṣe ẹni ti o ń gbìn nǹkankan, bẹẹ ni kì í ṣe ẹni ti ń bomirin; bikoṣe Ọlọrun ti o ń mú ibisi wá. Nitori alabaaṣiṣẹpọ pẹlu Ọlọrun ni awa: ọ̀gbá Ọlọrun ni yin, ile Ọlọrun ni yin.”—1 Korinti 3:5-7, 9.
12. (a) Ipa wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kó ninu aṣeyọrisirere ijihinrere Kristian? (b) Ta ni a ti yàn sípò gẹgẹ bi Ori ijọ Kristian, kí sì ni ọ̀nà pataki kan lati ṣàṣefihàn itẹriba wa fun ipo ori rẹ̀?
12 Kò si iyemeji pe idagbasoke àrà-ọ̀tọ̀ ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa niriiri rẹ̀ jẹ́ nitori ibukun Ọlọrun. Iṣẹ Ọlọrun ni. Ni mímọ otitọ yii dájú, wọn ń baa lọ lati fi araawọn fun kikẹkọọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun deedee. Wọn gbé gbogbo ohun ti wọn ń fi kọ́ni ninu iṣẹ ajihinrere wọn kari Bibeli. (1 Korinti 4:6; 2 Timoteu 3:16) Kọkọrọ miiran si aṣeyọri jijihinrere wọn miiran ni mímọ̀ Ẹni naa ti Ọlọrun yàn sipo gẹgẹ bi Ori ijọ daju, Oluwa Jesu Kristi. (Efesu 5:23) Awọn Kristian ọrundun kìn-ín-ní fi eyi hàn nipa fifọwọsowọpọ pẹlu awọn ti Jesu yàn sipo gẹgẹ bi aposteli. Awọn ọkunrin wọnyi, papọ pẹlu awọn alagba ijọ Jerusalem miiran, parapọ di ẹgbẹ oluṣakoso Kristian ọrundun kìn-ín-ní. Lati ọ̀run wá Oluwa Jesu Kristi lo awujọ awọn Kristian ogboṣaṣa yii lati yanju awọn ariyanjiyan ki wọn sì funni ni itọsọna fun iṣẹ jijihinrere. Ifọwọsowọpọ onitara Paulu pẹlu iṣeto atọrunwa yii yọrisi ibisi ninu awọn ijọ ti ó bẹwo. (Iṣe 16:4, 5; Galatia 2:9) Bakan-naa lonii, nipa titoro pinpin mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati fifi titaratitara fọwọsowọpọ pẹlu itọsọna tí ń wá lati ọdọ Ẹgbẹ́ Oluṣakoso, awọn Kristian ajihinrere ni a fi aṣeyọri ninu iṣẹ-ojiṣẹ wọn daloju.—Titu 1:9; Heberu 13:17.
Kika Awọn Ẹlomiran Si Ẹni Ti Ó Lọ́lá Jù
13, 14. (a) Imọran wo ni aposteli Paulu fifunni gẹgẹ bi a ti ṣakọsilẹ rẹ̀ ni Filippi 2:1-4? (b) Eeṣe ti ó fi ṣe pataki lati ranti imọran yii nigba ti a bá ń ṣajọpin ninu iṣẹ ajihinrere?
13 Aposteli Paulu fi ojulowo ifẹ hàn fun awọn olùwá-òtítọ́ kò sì fi ẹmi ironu ìlọ́lájù tabi ẹmi ẹ̀yà-tèmi-lọ̀gá hàn. Nipa bayii, oun lè gba awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ nimọran lati ‘ka awọn ẹlomiran sí ẹni ti o lọ́lá jù.’—Filippi 2:1-4.
14 Lọ́nà kan-naa, awọn Kristian ajihinrere lonii kò ní ẹmi ironu ìlọ́lájù nigba ti wọn bá ń bá awọn eniyan oniruuru ẹ̀yà ati ipilẹ igbesi-aye lò. Ọ̀kan lara Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lati United States, ti a yàn lati ṣiṣẹ́ gẹgẹ bi ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ni Africa, sọ pe: “Mo kàn ṣá mọ̀ pe a kò lọ́lá jù. Ó lè jẹ́ pe a ní owó pupọ si ati ohun ti a ń pè ní ìmọ̀-ẹ̀kọ́ ṣiṣekoko, ṣugbọn wọ́n [awọn eniyan ibilẹ naa] ní awọn animọ ti ó tayọ tiwa.”
15. Bawo ni awọn wọnni ti a pínṣẹ́ yàn fun ni ilẹ okeere ṣe lè fi ojulowo ọ̀wọ̀ hàn fun awọn ọmọ-ẹhin lọ́la?
15 Dajudaju, nipa fifi ojulowo ọ̀wọ̀ hàn fun awọn wọnni ti a ń ṣajọpin ihinrere pẹlu, awa yoo tubọ mú un rọrun fun wọn lati tẹwọgba ihin-iṣẹ Bibeli. Ó tún maa ń ṣeranwọ nigba ti ajihinrere ti o jẹ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji kan bá fihàn pe oun layọ lati gbé laaarin awọn eniyan ti a yan oun sí lati ràn lọwọ. Ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji alaṣeyọrisirere kan ti ó ti lo ọdun 38 sẹhin ni Africa ṣalaye pe: “Mo nimọlara jijinlẹ ninu mi lọhun pe ile mi niyi, ati awọn wọnyi ninu ijọ nibi ti a yàn mi sí sì ni arakunrin ati arabinrin mi. Nigba ti mo ti pada si Canada fun isinmi, emi kò nimọlara wíwànílé niti gidi. Ni ọsẹ ti o kẹhin tabi nǹkan ni Canada, mo wulẹ ń daniyan ṣáá lati pada ni. Mo maa ń nimọlara ni ọ̀nà yẹn nigba gbogbo. Mo sọ fun awọn akẹkọọ Bibeli ati awọn arakunrin ati awọn arabinrin mi bi mo ti layọ tó lati pada lẹẹkansii, wọn sì mọriri rẹ̀ pe mo fẹ́ lati wà pẹlu wọn.”—1 Tessalonika 2:8.
16, 17. (a) Ipenija wo ni ọpọ awọn ajihinrere ti wọn jẹ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ati ni adugbo ti tẹwọgba ki wọn baa lè tubọ gbéṣẹ́ ninu iṣẹ-ojiṣẹ? (b) Iriri wo ni ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji kan ní nitori sisọrọ ni èdè adugbo?
16 Nigba ti wọn rí agbo ńlá kan ti awọn elédè-àjèjì laaarin ipinlẹ adugbo wọn, awọn kan ti ṣe isapa lati kọ́ èdè naa, ni fífihàn lọna yii pe wọn ka awọn miiran si ẹni ti ó lọ́lá jù. “Ni ìhà guusu Africa,” ni ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji kan ṣakiyesi, “imọlara àìfọkàntánni maa ń wà nigba miiran laaarin awọn eniyan ti wọn ni ipilẹ igbesi-aye ti Africa ati awọn eniyan ti wọn ni ipilẹ igbesi-aye ti Europe. Ṣugbon sisọrọ ti a ń sọrọ ni èdè adugbo maa ń tètè lé imọlara yii lọ.” Sisọ èdè awọn wọnni ti a ń bá ṣajọpin ihinrere jẹ́ aranṣe ńláǹlà ninu dídé inu ọkan-aya wọn. Ó beere fun iṣẹ aṣekara ati itẹpẹlẹmọ ti a fi irẹlẹ ṣe. Ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ni orilẹ-ede Asia kan ti ṣalaye pe: “Lati maa ṣe aṣiṣe leralera ti a sì ń fi ọ́ rẹ́rìn-ín nigba gbogbo fun awọn aṣiṣe rẹ lè jẹ́ idanwo kan. Ó lè jọbi pe ó rọrun lati juwọsilẹ.” Bi o ti wu ki o ri, ifẹ fun Ọlọrun ati aladuugbo ran ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji yii lọwọ lati foriti i.—Marku 12:30, 31.
17 Bi a ṣe le reti, awọn eniyan ni a ń wúlórí nigba ti àjèjì kan bá saakun lati bá wọn ṣajọpin ihinrere ni èdè tiwọn. Nigba miiran ó ń yọrisi awọn ibukun airotẹlẹ. Ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji kan ni orilẹ-ede Lesotho ti Africa ń fi èdè Sesotho ba obinrin miiran sọrọ, ẹni ti ó ń ṣiṣẹ ní ibi ijokoo ti a ti ń hun aṣọ. Ojiṣẹ ijọba kan lati orilẹ-ede Africa miiran ń rin irin-ajo ibẹwo ni ayika naa ó sì gbọ́ ijumọsọrọpọ naa. Ọkunrin naa wá ó sì fi tọyayatọyaya gboriyin fun un, bẹẹ pẹlu ni oun bẹrẹ sii bá ojiṣẹ ijọba naa sọrọ ni èdè tirẹ funraarẹ. “Eeṣe ti o kò fi wá si [orilẹ-ede mi] ki o sì ṣiṣẹ laaarin awọn eniyan wa, niwọn bi o tún ti gbọ́ èdè Swahili?” ni ó beere. Pẹlu ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa fesi pada pe: “Iyẹn yoo dara. Ṣugbọn emi jẹ́ ọkan ninu Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ati ni lọwọlọwọ yii iṣẹ wa ni a fofinde ni orilẹ-ede rẹ.” “Jọwọ,” ni ó fesi pada, “maṣe nimọlara pe gbogbo wa ni ó lodi si iṣẹ yin. Ọpọlọpọ ninu wa faramọ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Boya ni ọjọ kan ṣá iwọ yoo lè kọni lẹkọọ falala laaarin awọn eniyan wa.” Ni ìgbà diẹ lẹhin naa, ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa ni ó layọ lati gbọ́ pe Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a ti yọnda ominira fun lati jọsin ni orilẹ-ede yẹn kannaa.
Mimuratan Lati Yááfì Awọn Ẹ̀tọ́
18, 19. (a) Ni ọ̀nà pataki wo ni Paulu gbà saakun lati ṣafarawe Ọ̀gá rẹ̀, Jesu Kristi? (b) Sọ iriri kan (eyi ti ó wà ninu ipinrọ tabi tirẹ funraarẹ) lati fi ijẹpataki yiyẹra fun okunfa idigbolu eyikeyii fun awọn wọnni ti a ń bá ṣajọpin ihinrere.
18 Nigba ti aposteli Paulu kọwe pe: “Ẹ maa ṣe afarawe mi, àní gẹgẹ bi emi ti ń ṣe afarawe Kristi,” oun ṣẹṣẹ ń jiroro aini naa lati yẹra fun mímú awọn ẹlomiran kọsẹ ni, ní sisọ pe: “Bi ẹyin bá ń jẹ, tabi bi ẹyin bá ń mu, tabi ohunkohun ti ẹyin bá ń ṣe, ẹ maa ṣe gbogbo wọn fun ogo Ọlọrun. Ẹ maṣe jẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀, ìbá ṣe fun awọn Ju, tabi fun awọn Hellene, tabi fun ijọ Ọlọrun: Àní bi emi ti ń wu gbogbo eniyan ni ohun gbogbo, láìwá èrè ti ara mi, bikoṣe ti ọpọlọpọ, ki a lè gbà wọn là.”—1 Korinti 10:31-33; 11:1.
19 Awọn ajihinrere bii Paulu, ti wọn muratan lati ṣe awọn irubọ fun anfaani awọn wọnni ti wọn ń waasu fun, ń karugbin ọpọ ibukun. Fun apẹẹrẹ, ni orilẹ-ede Africa kan, tọkọtaya ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji kan lọ si hotẹẹli adugbo fun ounjẹ lati ṣayẹyẹ àyájọ́ igbeyawo wọn. Lakọọkọ wọn ní i lọ́kàn lati beere fun ọtí papọ pẹlu ounjẹ naa, niwọn bi a kò ti dẹ́bi fun ìlò awọn ohun mímu ọlọ́tí líle niwọntunwọnsi ninu Bibeli. (Orin Dafidi 104:15) Ṣugbọn lẹhin naa tọkọtaya yii pinnu lati maṣe ṣe bẹẹ aìbáàmọ̀ ó lè bi awọn eniyan adugbo naa ninu. “Ni akoko diẹ lẹhin naa,” ni ọkọ naa sọyeranti, “a pade ọkunrin kan ti ó jẹ́ olori alásè ni hotẹẹli yen, a sì bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli pẹlu rẹ̀. Ni ìgbà pipẹ lẹhin naa ó sọ fun wa pe: ‘Ẹyin ha ranti ìgbà ti ẹ wá si hotẹẹli fun ounjẹ bi? Gbogbo wa wà lẹhin ilẹkun ilé ìdáná ti a ń wò yin. Ṣe ẹ rí i, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti ṣọọṣi sọ fun wa pe ó lodi lati mu ọtí. Sibẹ, nigba ti wọn bá wá si hotẹẹli, wọn ń beere fun ọtí ní falala. Nitori naa a pinnu pe bi ẹ bá beere fun ohun mímu ọlọ́tí kan, awa kì yoo fetisilẹ si yin nigba ti ẹ bá wá waasu fun wa.’” Lonii, olori alásè yẹn ati awọn miiran ti wọn ṣiṣẹ ni hotẹẹli naa jẹ́ Ẹlẹ́rìí ti a ti baptisi.
Ọpọ Lati ṣe Sibẹ
20. Eeṣe ti ó fi ṣe pataki pe ki a farada a gẹgẹ bi ajihinrere onitara, anfaani alayọ wo ni ọpọlọpọ sì ń gbámú?
20 Bi opin eto igbekalẹ buburu yii ti ń yára sunmọtosi, ọpọlọpọ sì ń yánhànhàn lati gbọ́ ihinrere naa, ó sì tubọ jẹ́ kanjukanju sii ju ti ìgbakigba ri lọ fun gbogbo Kristian lati farada a gẹgẹ bi ajihinrere oluṣotitọ. (Matteu 24:13) Iwọ ha lè mú ipin rẹ ninu iṣẹ yii gbooro sii nipa didi ajihinrere ni èrò itumọ akanṣe kan bii ti Filippi, Paulu, Barnaba, Sila, ati Timoteu bi? Ọpọ ń ṣe ohun kan ti o farajọra nipa didarapọ mọ òtú awọn aṣaaju-ọna ti wọn sì ń mú araawọn wà larọọwọto lati ṣiṣẹsin ni awọn ibi ti aini ti tubọ pọ sii wà.
21. Ni ọ̀nà wo ni “ilẹkun ńlá àbáwọlé sinu igbokegbodo” ti di eyi ti a ṣí silẹ fun awọn eniyan Jehofa?
21 Lẹnu aipẹ yii, pápá salalu fun jijihinrere ti ṣí silẹ ni awọn orilẹ-ede Africa, Asia, ati ìhà Ila-oorun Europe, nibi ti a ti ká iṣẹ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lọ́wọ́kò nigbakanri. Gẹgẹ bi ọ̀ràn ti rí pẹlu aposteli Paulu, “ilẹkun ńlá àbáwọlé sinu igbokegbodo ni a ti ṣí silẹ” fun awọn eniyan Jehofa. (1 Korinti 16:9, NW) Fun apẹẹrẹ, awọn ajihinrere ti wọn jẹ́ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti wọn dé si orilẹ-ede Mozambique ti Africa lẹnu aipẹ yii ni wọn kò kápá iye awọn eniyan ti wọn fẹ́ ikẹkọọ Bibeli ṣe ikẹkọọ. Ẹ wo bi a ti lè layọ tó pe iṣẹ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a ti dámọ̀ lọna ofin ni ilẹ yẹn bẹrẹ lati February 11, 1991!
22. Yala ipinlẹ adugbo wa ni a ti ṣe daradara tabi bẹẹkọ, ki ni gbogbo wa gbọdọ pinnu lati ṣe?
22 Ni awọn ilẹ nibi ti a ti maa ń figba gbogbo ní ominira ijọsin, awọn arakunrin wa pẹlu ń gbadun ibisi ti ń baa lọ. Bẹẹni, nibi yoowu ti a ń gbé, ‘pupọ rẹpẹtẹ ṣì wà lati ṣe ninu iṣẹ Oluwa.’ (1 Korinti 15:58) Bi iyẹn ti jẹ bẹẹ, ẹ jẹ ki a maa baa lọ lati lo akoko ti ó ṣẹku lọna ọlọgbọ́n gẹgẹ bi ẹnikọọkan wa ti ‘ń ṣe iṣẹ ajihinrere, ni ṣiṣe iṣẹ-ojiṣẹ wa láṣepé.’—2 Timoteu 4:5; Efesu 5:15, 16.
Iwọ Ha Lè Ṣalaye Bi?
◻ Ki ni ajihinrere kan?
◻ Bawo ni a ṣe sọ ohun ti ihinrere ní ninu di kíkún sii lẹhin 1914?
◻ Bawo ni iṣẹ ijihinrere ṣe tẹsiwaju lati 1919?
◻ Awọn kókó abajọ pataki wo ni wọn ti dakun aṣeyọrisirere iṣẹ ajihinrere naa?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
Imugbooro Lati 1939
Gbé awọn apẹẹre lati awọn àgbáálá ilẹ mẹta nibi ti a rán awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti a dalẹkọọ ni Gilead lọ yẹwo. Lẹhin lọhun-un ni 1939 kìkì 636 awọn akede Ijọba ni wọn rohin lati Iwọ-oorun Africa. Nigba ti ó fi maa di 1991, iye yii ti pọ sii dé eyi ti ó ju 200,000 ni awpn orilẹ-ede 12 ti Iwọ-oorun Africa lọ. Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji tún ti dakun ibisi siṣàrà-ọ̀tọ̀ ni awọn orilẹ-ede Guusu America. Ọ̀kan ni Brazil, eyi ti o ga sii lati 114 awọn olupokiki Ijọba ni 1939 dé gongo 335,039 ni April 1992. Idagbasoke ti o jọra tẹle díde awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ni awọn orilẹ-ede Asia. Nigba Ogun Agbaye II, iye kekere ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Japan ni a ṣe inunibini si lọna mimuna, ti iṣẹ wọn sì durogbagidi sojukan. Lẹhin nna, ni 1949, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji 13 dé lati ṣe iranwọ lati tun iṣẹ naa ṣetojọ. Ni ọdun iṣẹ-isin yẹn, iye ti o kere si mẹwaa awọn akede ibilẹ rohin iṣẹ-isin pápá ni odindi Japan, nigba ti ó jẹ́ pe ni April 1992 apapọ aropọ awọn akede dé 167,370.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]
Kristẹndọm Ati lṣoro Èdè
Diẹ ninu awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti Kristẹndọm ṣe isapa afitọkantọkan ṣe lati kọ́ èdè àjèjì, ṣugbon ọpọlọpọ reti pe ki awọn eniyan adugbo sọ èdè Oyinbo wọn. Gẹgẹ bi Geoffrey Moorhouse ti ṣalaye ninu iwe rẹ̀ The Missionaries:
“Iṣoro naa ni pe gbígbọ́ èdè ibilẹ ni a rí leralera pupọ ju gẹgẹ bi ohun ti kò ju ọ̀nà titumọ Iwe Mimọ lọ. Isapa ti kò tó nǹkan ni a ṣe ni ifiwera, yala lati ọdọ ẹnikọọkan tabi lati ọdọ awọn awujọ ti ó ń lò wọn, ni rírí i daju pe ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji kan lè sọrọ si ọmọ ibilẹ kan ni èdè tirẹ̀ pẹlu ìyọ̀mọ́nilẹ́nu ti ó lè danikan mu ìlóye jijinlẹ wà laaarin awọn eniyan meji. Olukuluku ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji yoo kọ́ àkójọ-ọ̀rọ̀ adugbo táátààtá . . . Rekọja iyẹn, ijumọsọrọpọ ni a ń ṣe ni gbogbogboo ni ìrò-ohùn buruku ati afinipe dindinrin ti a ń fẹnu lasan pe ni pidgin-English [àmúlùmálà-èdè Gẹẹsi] pẹlu ìgbàṣebi patapata rẹ̀ pe ó pọndandan fun ọmọ ibilẹ Africa lati mú araarẹ̀ bá èdè Gẹẹsi ti olùbẹ̀wò rẹ̀ mu. Dé àyè ti o buru tó, sibẹ eyi tun jẹ́ ìfihàn ìlọ́lájù ẹ̀yà ìran.”
Ni 1922 lle-Ẹkọ Ikẹkọọ Awọn ará Gabasi ati Africa ni London tẹ irohin kan jade lori ọ̀ràn iṣoro èdè. “Èrò wa ni,” ni irohin naa sọ, “pe ìwọ̀n ipindọgba ìjáfáfá ti awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji tí dé ninu èdè abinibi . . . kere gan-an lọna ti ó burujai ati tí ó tilẹ̀ léwu paapaa.”
Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti Watch Tower Society ti sábà maa ń ka kíkọ́ èdè adugbo si ọ̀ranyàn, eyi ti o ṣeranwọ lati ṣalaye aṣeyọrisirere wọn ninu pápá ijihin-iṣẹ-Ọlọrun.