Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ajíhìnrere Tòótọ́
1 Jésù Kristi gbé ẹrù iṣẹ́ jíjíhìnrere karí gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ní pàtó, ó pàṣẹ fún wọn láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà. (Mát. 24:14; Ìṣe 10:42) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ìjímìjí fi àpẹẹrẹ èyí lélẹ̀ bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba náà láìdábọ̀—kì í ṣe ní àwọn ibi ìjọsìn nìkan ṣùgbọ́n níbikíbi tí wọ́n bá ti bá àwọn ènìyàn pàdé ní gbangba, àti bí wọ́n ti ń lọ láti ilé dé ilé. (Ìṣe 5:42; 20:20) Gẹ́gẹ́ bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí, a ti fi ara wa hàn pé a jẹ́ Kristẹni ajíhìnrere tòótọ́, tí ń wàásù ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà ní 232 ilẹ̀ tí a sì batisí àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun tí ó lé ní mílíọ̀nù kan ní ọdún mẹ́ta péré tí ó kọjá! Èé ṣe tí iṣẹ́ ìjíhìnrere wa fi ṣàṣeyọrí tó bẹ́ẹ̀?
2 Ìhìn Rere Ń Ru Wá Sókè: Àwọn ajíhìnrere jẹ́ oníwàásù, tàbí ońṣẹ́ ìhìn rere. Nítorí náà, a ní àǹfààní amọ́kànyọ̀ ti kíkéde Ìjọba Jèhófà—ojúlówó ìhìn rere kan ṣoṣo tí a lè sọ fún ìran ènìyàn tí ìdààmú ti bá. A kún fún ìtara ọkàn nípa ìmọ̀ tí a ti jèrè ṣáájú nípa àwọn ọ̀run tuntun tí yóò fi òdodo ṣàkóso ilẹ̀ ayé tuntun tí ó jẹ́ aráyé olódodo nínú Párádísè tí ń bọ̀. (2 Pét. 3:13, 17) Àwa nìkan ni ó fayọ̀ tẹ́wọ́ gba ìrètí yìí, a sì ń háragàgà láti ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.
3 Ìfẹ́ Tòótọ́ Ń Sún Wa Ṣiṣẹ́: Ìjíhìnrere jẹ́ iṣẹ́ tí ń gba ẹ̀mí là. (Róòmù 1:16) Ìdí nìyẹn tí a fi ń ní ìdùnnú kíkọyọyọ nínú títan ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kálẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere tòótọ́, a nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn, ìyẹn sì ń sún wa láti ṣàjọpín ìhìn rere náà pẹ̀lú wọn—àwọn ìdílé wa, aládùúgbò, ojúlùmọ̀, àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Ṣíṣe iṣẹ́ yìí tọkàntọkàn jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà tí ó dára jù lọ tí a lè gbà fi ìfẹ́ wa tòótọ́ hàn fún àwọn ẹlòmíràn.—1 Tẹs. 2:8.
4 Ẹ̀mí Ọlọ́run Ń Tì Wá Lẹ́yìn: Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kí ó dá wa lójú pé nígbà tí a bá ṣe iṣẹ́ tiwa ti gbígbin irúgbìn Ìjọba àti bíbu omi rin ín, Jèhófà ni ó “ń mú kí ó máa dàgbà.” Ìyẹn gan-an ni ohun tí a rí tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ètò àjọ wa lónìí. (1 Kọ́r. 3:5-7) Ẹ̀mí Ọlọ́run ni ó ń tì wá lẹ́yìn nínú ìgbòkègbodò ìjíhìnrere wa tí ó sì ń fún wa ní àṣeyọrí ńláǹlà.—Jóẹ́lì 2:28, 29.
5 Nítorí ìṣírí tí ó wà nínú 2 Tímótì 4:5 láti “ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere” àti nítorí ìfẹ́ wa fún gbogbo ènìyàn, ǹjẹ́ kí a sún wa láti ṣàjọpín ìhìn rere Ìjọba amọ́kànyọ̀ náà ní gbogbo àǹfààní tí ó bá ṣí sílẹ̀ fún wa, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé pé Jèhófà yóò máa bá a lọ láti bù kún iṣẹ́ wa.