ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jóẹ́lì 2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jóẹ́lì

      • Ọjọ́ Jèhófà àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ (1-11)

      • Ìkésíni láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà (12-17)

        • “Ọkàn yín ni kí ẹ fà ya” (13)

      • Ohun tí Jèhófà sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ (18-32)

        • “Èmi yóò tú ẹ̀mí mi” (28)

        • Àwọn ohun ìyanu lójú ọ̀run àti ní ayé (30)

        • Àwọn tó ń ké pe orúkọ Jèhófà yóò rí ìgbàlà (32)

Jóẹ́lì 2:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ayé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 33:2, 3; Emọ 3:6
  • +Sef 1:14, 16; Mal 4:1

Jóẹ́lì 2:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọsánmà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Emọ 5:18, 20
  • +Sef 1:15
  • +Joẹ 1:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2007, ojú ìwé 13

    5/1/1992, ojú ìwé 12

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 142-143

Jóẹ́lì 2:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joẹ 1:19
  • +Jẹ 2:8

Jóẹ́lì 2:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ifi 9:7

Jóẹ́lì 2:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ifi 9:9
  • +Owe 30:27

Jóẹ́lì 2:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 11

Jóẹ́lì 2:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2020, ojú ìwé 2-3

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2009, ojú ìwé 18-19

    5/1/1998, ojú ìwé 11

    5/1/1992, ojú ìwé 12-13

    Ọjọ́ Jèhófà, ojú ìwé 172-173

Jóẹ́lì 2:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ohun ọṣẹ́.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2020, ojú ìwé 2-3, 5

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2009, ojú ìwé 18-19

    5/1/1998, ojú ìwé 11

    5/1/1992, ojú ìwé 12-13

    Ọjọ́ Jèhófà, ojú ìwé 172-173

Jóẹ́lì 2:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wíńdò.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2020, ojú ìwé 2-3, 5

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 11-12

    5/1/1992, ojú ìwé 12-13

Jóẹ́lì 2:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joẹ 2:31; Mt 24:29; Lk 21:25; Ifi 9:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 12

Jóẹ́lì 2:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joẹ 2:25
  • +Joẹ 2:2
  • +Jer 30:7; Emọ 5:18; Sef 1:15
  • +Ifi 6:16, 17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 9, 12

    12/15/1997, ojú ìwé 11

Jóẹ́lì 2:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 4:1; Ho 12:6; 14:1, 2
  • +1Sa 7:6; 2Kr 20:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 15-16

Jóẹ́lì 2:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ó jẹ́ olóore ọ̀fẹ́.”

  • *

    Tàbí “yí ìpinnu pa dà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 22:18, 19; Sm 51:17; Ais 57:15
  • +2Sa 1:11, 12
  • +Ais 48:9
  • +Ẹk 34:6; Nọ 14:18; Ne 9:17; Sm 106:44, 45; Mik 7:18, 19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 15-16

Jóẹ́lì 2:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “yí ìpinnu pa dà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 30:8, 9; Jer 18:7, 8; Sef 2:2, 3

Jóẹ́lì 2:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ẹ sọ ààwẹ̀ di mímọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joẹ 1:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ọjọ́ Jèhófà, ojú ìwé 137

Jóẹ́lì 2:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àgbààgbà.”

  • *

    Ní Héb., “yàrá ìgbéyàwó.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:10
  • +Di 31:12; 2Kr 20:3, 13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ọjọ́ Jèhófà, ojú ìwé 137

Jóẹ́lì 2:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gọ̀bì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 8:12
  • +Di 32:26, 27; Sm 79:9, 10; Mik 7:10

Jóẹ́lì 2:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:36; Ais 60:10; Ida 3:22; Ho 11:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 17-18

Jóẹ́lì 2:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 62:8, 9; Emọ 9:13; Mal 3:10
  • +Isk 34:29; 36:15

Jóẹ́lì 2:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “yóò kọjú sí ọ̀nà òkun.”

  • *

    Ìyẹn, Òkun Òkú.

  • *

    Ìyẹn, Òkun Mẹditaréníà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 34:2, 3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2020, ojú ìwé 3, 5

Jóẹ́lì 2:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 17-18

Jóẹ́lì 2:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 30:23; 51:3
  • +Isk 34:27
  • +Emọ 9:14; Sek 8:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 17-18

Jóẹ́lì 2:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 12:6; Sek 10:7
  • +Le 26:4; Di 11:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 17-18

Jóẹ́lì 2:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:10; Emọ 9:13; Mal 3:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 17-18

Jóẹ́lì 2:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joẹ 1:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2020, ojú ìwé 3

Jóẹ́lì 2:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:5
  • +Di 26:10, 11
  • +Sef 3:11

Jóẹ́lì 2:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 46:5
  • +Le 26:11, 12; Isk 37:26, 27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    5/1/1992, ojú ìwé 13

Jóẹ́lì 2:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 32:15; 44:3; Isk 39:29
  • +Iṣe 2:16-18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2020, ojú ìwé 3, 6-7

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    10/2017, ojú ìwé 8

    Ọjọ́ Jèhófà, ojú ìwé 166-167

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2002, ojú ìwé 15

    5/1/1998, ojú ìwé 13-15

    5/15/1995, ojú ìwé 11

    2/15/1994, ojú ìwé 18

    5/1/1992, ojú ìwé 13

Jóẹ́lì 2:29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2020, ojú ìwé 3, 6-7

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2002, ojú ìwé 15

    5/1/1998, ojú ìwé 13-15

    5/15/1995, ojú ìwé 11

Jóẹ́lì 2:30

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àmì.”

  • *

    Tàbí “èéfín tó rí bí òpó.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 2:19, 20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 13-14, 18-19

    12/15/1997, ojú ìwé 16-17

    2/15/1994, ojú ìwé 18-19

Jóẹ́lì 2:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 24:29; Mk 13:24, 25; Lk 21:25; Ifi 6:12
  • +Sef 1:14, 15; Mal 4:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 13-14, 18-19

    12/15/1997, ojú ìwé 16-17

    3/1/1997, ojú ìwé 14-15

    2/15/1995, ojú ìwé 20-21

    2/15/1994, ojú ìwé 18-19

    5/1/1992, ojú ìwé 13

Jóẹ́lì 2:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 2:21; Ro 10:13
  • +Ọbd 17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    10/2017, ojú ìwé 8

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2007, ojú ìwé 13

    5/1/1998, ojú ìwé 13-19

    12/15/1997, ojú ìwé 16-17, 19-20

    5/1/1992, ojú ìwé 13, 15

    Ọjọ́ Jèhófà, ojú ìwé 187-190

Àwọn míì

Jóẹ́lì 2:1Isk 33:2, 3; Emọ 3:6
Jóẹ́lì 2:1Sef 1:14, 16; Mal 4:1
Jóẹ́lì 2:2Emọ 5:18, 20
Jóẹ́lì 2:2Sef 1:15
Jóẹ́lì 2:2Joẹ 1:6
Jóẹ́lì 2:3Joẹ 1:19
Jóẹ́lì 2:3Jẹ 2:8
Jóẹ́lì 2:4Ifi 9:7
Jóẹ́lì 2:5Ifi 9:9
Jóẹ́lì 2:5Owe 30:27
Jóẹ́lì 2:10Joẹ 2:31; Mt 24:29; Lk 21:25; Ifi 9:2
Jóẹ́lì 2:11Joẹ 2:25
Jóẹ́lì 2:11Joẹ 2:2
Jóẹ́lì 2:11Jer 30:7; Emọ 5:18; Sef 1:15
Jóẹ́lì 2:11Ifi 6:16, 17
Jóẹ́lì 2:12Jer 4:1; Ho 12:6; 14:1, 2
Jóẹ́lì 2:121Sa 7:6; 2Kr 20:3
Jóẹ́lì 2:132Ọb 22:18, 19; Sm 51:17; Ais 57:15
Jóẹ́lì 2:132Sa 1:11, 12
Jóẹ́lì 2:13Ais 48:9
Jóẹ́lì 2:13Ẹk 34:6; Nọ 14:18; Ne 9:17; Sm 106:44, 45; Mik 7:18, 19
Jóẹ́lì 2:142Kr 30:8, 9; Jer 18:7, 8; Sef 2:2, 3
Jóẹ́lì 2:15Joẹ 1:14
Jóẹ́lì 2:16Ẹk 19:10
Jóẹ́lì 2:16Di 31:12; 2Kr 20:3, 13
Jóẹ́lì 2:172Kr 8:12
Jóẹ́lì 2:17Di 32:26, 27; Sm 79:9, 10; Mik 7:10
Jóẹ́lì 2:18Di 32:36; Ais 60:10; Ida 3:22; Ho 11:8
Jóẹ́lì 2:19Ais 62:8, 9; Emọ 9:13; Mal 3:10
Jóẹ́lì 2:19Isk 34:29; 36:15
Jóẹ́lì 2:20Ais 34:2, 3
Jóẹ́lì 2:22Ais 30:23; 51:3
Jóẹ́lì 2:22Isk 34:27
Jóẹ́lì 2:22Emọ 9:14; Sek 8:12
Jóẹ́lì 2:23Ais 12:6; Sek 10:7
Jóẹ́lì 2:23Le 26:4; Di 11:14
Jóẹ́lì 2:24Le 26:10; Emọ 9:13; Mal 3:10
Jóẹ́lì 2:25Joẹ 1:4
Jóẹ́lì 2:26Le 26:5
Jóẹ́lì 2:26Di 26:10, 11
Jóẹ́lì 2:26Sef 3:11
Jóẹ́lì 2:27Sm 46:5
Jóẹ́lì 2:27Le 26:11, 12; Isk 37:26, 27
Jóẹ́lì 2:28Ais 32:15; 44:3; Isk 39:29
Jóẹ́lì 2:28Iṣe 2:16-18
Jóẹ́lì 2:30Iṣe 2:19, 20
Jóẹ́lì 2:31Mt 24:29; Mk 13:24, 25; Lk 21:25; Ifi 6:12
Jóẹ́lì 2:31Sef 1:14, 15; Mal 4:5
Jóẹ́lì 2:32Iṣe 2:21; Ro 10:13
Jóẹ́lì 2:32Ọbd 17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jóẹ́lì 2:1-32

Jóẹ́lì

2 “Ẹ fun ìwo ní Síónì!+

Ẹ kéde ogun ní òkè mímọ́ mi.

Kí jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà,*

Torí ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀!+ Ó sún mọ́lé!

 2 Ó jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù,+

Ọjọ́ ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà,+

Bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀ lórí àwọn òkè.

Àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n pọ̀, tí wọ́n sì lágbára;+

Kò tíì sí irú wọn rí,

Irú wọn kò sì ní sí mọ́ láé,

Jálẹ̀ àwọn ọdún láti ìran dé ìran.

 3 Iná ń jẹ àwọn ohun tó wà níwájú wọn,

Ọwọ́ iná sì ń run àwọn ohun tó wà lẹ́yìn wọn.+

Ilẹ̀ iwájú wọn dà bí ọgbà Édẹ́nì,+

Àmọ́ aginjù tó ti di ahoro ló wà lẹ́yìn wọn,

Kò sì sí ohun tó lè yè bọ́.

 4 Wọ́n rí bí ẹṣin,

Wọ́n sì ń sáré bí ẹṣin ogun.+

 5 Ìró wọn dà bíi ti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin tó ń bẹ́ gìjà lórí àwọn òkè,+

Bí ìró iná ajófòfò tó ń jó àgékù pòròpórò.

Wọ́n dà bí àwọn alágbára, tí wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti jagun.+

 6 Ìdààmú máa bá àwọn èèyàn náà nítorí wọn,

Ìbẹ̀rù yóò sì hàn lójú gbogbo èèyàn.

 7 Wọ́n ń rọ́ gììrì bí àwọn jagunjagun,

Wọ́n gun ògiri bí àwọn ọmọ ogun,

Wọ́n tò tẹ̀ léra,

Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò sì kúrò lójú ọ̀nà rẹ̀.

 8 Wọn kì í ti ara wọn;

Kálukú wọn ń tọ ọ̀nà tirẹ̀.

Bí ohun ìjà* bá gbé àwọn kan ṣubú lára wọn,

Àwọn tó ṣẹ́ kù kì í tú ká.

 9 Wọ́n rọ́ wọnú ìlú, wọ́n sáré lórí ògiri.

Wọ́n gun orí àwọn ilé, wọ́n sì gba àwọn ojú fèrèsé* wọlé bí olè.

10 Ilẹ̀ mì tìtì níwájú wọn, ọ̀run sì mì jìgìjìgì.

Oòrùn àti òṣùpá ti ṣókùnkùn,+

Àwọn ìràwọ̀ kò sì mọ́lẹ̀ mọ́.

11 Jèhófà yóò gbé ohùn sókè níwájú àwọn ọmọ ogun rẹ̀,+ torí wọ́n pọ̀ gan-an nínú ibùdó rẹ̀.+

Alágbára ni ẹni tó ń mú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣẹ;

Torí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jèhófà, ó sì ń bani lẹ́rù.+

Ta ló lè fara dà á?”+

12 “Síbẹ̀, ẹ fi gbogbo ọkàn yín pa dà sọ́dọ̀ mi báyìí,” ni Jèhófà wí,+

“Kí ẹ gbààwẹ̀,+ kí ẹ sunkún, kí ẹ sì pohùn réré ẹkún.

13 Ọkàn yín ni kí ẹ fà ya,+ kì í ṣe ẹ̀wù yín,+

Kí ẹ sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run yín,

Torí ó ń gba tẹni rò,* ó jẹ́ aláàánú, kì í tètè bínú,+ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ gidigidi,+

Òun yóò sì pèrò dà* nípa àjálù náà.

14 Ta ló mọ̀ bóyá ó máa tún ìpinnu ṣe, kó sì pèrò dà,*+

Kó sì mú kí ìbùkún ṣẹ́ kù fún yín,

Kí ẹ lè fi ọrẹ ọkà àti ọrẹ ohun mímu fún Jèhófà Ọlọ́run yín?

15 Ẹ fun ìwo ní Síónì!

Ẹ kéde ààwẹ̀;* ẹ pe àpéjọ ọlọ́wọ̀.+

16 Ẹ kó àwọn èèyàn náà jọ; ẹ sọ ìjọ di mímọ́.+

Ẹ kó àwọn àgbà ọkùnrin* jọ, kí ẹ sì kó àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ ọwọ́ jọ.+

Kí ọkọ ìyàwó jáde kúrò nínú yàrá rẹ̀ tó wà ní inú, kí ìyàwó pẹ̀lú kúrò nínú yàrá* rẹ̀.

17 Kí àwọn àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà sunkún

Láàárín ibi àbáwọlé* àti pẹpẹ,+ kí wọ́n sì sọ pé:

‘Jèhófà, jọ̀ọ́ ṣàánú àwọn èèyàn rẹ;

Má ṣe jẹ́ kí àwọn èèyàn fi ogún rẹ ṣẹlẹ́yà,

Kó wá di pé àwọn orílẹ̀-èdè á máa jọba lórí wọn,

Tí àwọn èèyàn á fi máa sọ pé, “Ibo ni Ọlọ́run wọn wà?”’+

18 Jèhófà yóò ní ìtara nítorí ilẹ̀ rẹ̀,

Yóò sì ṣàánú àwọn èèyàn rẹ̀.+

19 Jèhófà yóò dá àwọn èèyàn rẹ̀ lóhùn pé:

‘Màá fi ọkà àti wáìnì tuntun àti òróró ránṣẹ́ sí yín,

Yóò sì tẹ́ yín lọ́rùn;+

Mi ò ní jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè fi yín ṣẹlẹ́yà mọ́.+

20 Màá lé àwọn ará àríwá jìnnà sí yín;

Màá fọ́n wọn ká sí ilẹ̀ tí kò lómi tó sì ti di ahoro,

Àwọn tó wà níwájú yóò forí lé ọ̀nà òkun* ìlà oòrùn*

Àwọn tó wà lẹ́yìn yóò sì forí lé ọ̀nà òkun ìwọ̀ oòrùn.*

Òórùn wọn yóò gbalẹ̀ kan,

Wọn yóò sì máa rùn ṣáá;+

Torí pé Òun yóò ṣe àwọn ohun ńlá.’

21 Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀.

Máa yọ̀, kí inú rẹ sì dùn, torí pé Jèhófà máa ṣe àwọn ohun ńlá.

22 Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ẹran inú igbó,

Torí àwọn ibi ìjẹko inú aginjù yóò hu ewéko tútù,+

Àwọn igi yóò sì mú èso jáde;+

Igi ọ̀pọ̀tọ́ àti igi àjàrà yóò so wọ̀ǹtìwọnti.+

23 Ẹ̀yin ọmọ Síónì, ẹ máa yọ̀, kí Jèhófà Ọlọ́run yín sì mú inú yín dùn;+

Torí ó máa rọ òjò fún yín ní ìwọ̀n tó yẹ nígbà ìwọ́wé,

Yóò sì rọ òjò lé yín lórí,

Nígbà ìwọ́wé àti nígbà ìrúwé, bíi ti tẹ́lẹ̀.+

24 Ọkà tó mọ́ máa kún àwọn ibi ìpakà,

Wáìnì tuntun àti òróró á sì kún àwọn ibi ìfúntí yín ní àkúnwọ́sílẹ̀.+

25 Màá sì san àwọn ohun tí ẹ ti pàdánù láwọn ọdún yẹn fún yín

Àwọn ọdún tí ọ̀wọ́ eéṣú, eéṣú tí kò níyẹ̀ẹ́, ọ̀yánnú eéṣú àti eéṣú tó ń jẹ nǹkan run fi jẹ irè oko yín,

Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọ ogun mi tí mo rán sáàárín yín.+

26 Ó dájú pé ẹ ó jẹ àjẹyó,+

Ẹ ó sì yin orúkọ Jèhófà Ọlọ́run yín,+

Ẹni tó ti ṣe ohun ìyanu fún yín;

Wọn ò ní dójú ti àwọn èèyàn mi mọ́ láé.+

27 Ẹ ó sì mọ̀ pé mo wà láàárín Ísírẹ́lì+

Àti pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kò sí ẹlòmíì!

Wọn ò ní dójú ti àwọn èèyàn mi mọ́ láé.

28 Lẹ́yìn ìyẹn, èmi yóò tú ẹ̀mí mi + sára onírúurú èèyàn,

Àwọn ọmọ yín lọ́kùnrin àti lóbìnrin yóò sì máa sọ tẹ́lẹ̀,

Àwọn àgbà ọkùnrin yín yóò máa lá àlá.

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín yóò sì máa rí ìran.+

29 Kódà, ní àwọn ọjọ́ náà,

Èmi yóò tú ẹ̀mí mi sára àwọn ẹrúkùnrin mi àti sára àwọn ẹrúbìnrin mi.

30 Èmi yóò fi àwọn ohun ìyanu* hàn lójú ọ̀run àti ní ayé,

Ẹ̀jẹ̀ àti iná pẹ̀lú ọwọ̀n èéfín.*+

31 Oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá yóò sì di ẹ̀jẹ̀+

Kí ọjọ́ ńlá Jèhófà tó ń bani lẹ́rù tó dé.+

32 Gbogbo ẹni tó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà yóò sì rí ìgbàlà;+

Torí àwọn tó sá àsálà yóò wà ní Òkè Síónì àti ní Jerúsálẹ́mù+ bí Jèhófà ṣe sọ,

Àwọn tó là á já tí Jèhófà pè.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́