Bí Ó Bá Ń Yọrí sí Rere, Máa Lò Ó!
1 Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ń bá a lọ láti máa pèsè onírúurú àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a dábàá fún lílò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún wa. Èyí ń fún wa ní èrò tuntun nípa bí a ṣe lè ru ọkàn-ìfẹ́ sókè nínú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. Ó lè jẹ́ pé oṣooṣù ni o máa ń sapá láti kọ́ ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, àwọn akéde kan lè rí i pé nígbà tí wọn óò fi lo ọ̀kan nínú wọn fún ìgbà díẹ̀, ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa mìíràn yóò pèsè àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tuntun. Ó hàn gbangba pé mímọ ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tuntun kan dunjú lè ṣàìrọrùn fún ẹni gbogbo, bí wọ́n ti ń kọ́ láti mọ èyí tí a fún wọn ṣáájú ní àmọ̀dunjú lọ́wọ́.
2 Dájúdájú, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn aṣáájú ọ̀nà àti àwọn akéde mìíràn ni ó wà tí wọ́n ń lo àkókò púpọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Síwájú sí i, àwọn ìjọ púpọ̀ ni wọ́n máa ń kárí gbogbo ìpínlẹ̀ wọn láàárín àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀. Nínú àwọn àyíká ipò yìí, àwọn akéde máa ń fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba àwọn ọ̀nà ìyọsíni àti èrò tuntun láti fi gbé ìhìn iṣẹ́ náà kalẹ̀. Èyí ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú òye iṣẹ́ wọn pọ̀ sí i. Ó tún ń mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn jẹ́ èyí tí ó túbọ̀ dùn mọ́ wọn tí ó sì ń méso jáde, ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìpèníjà tí wọ́n bá bá pàdé.
3 Ohun yòówù kí ọ̀ràn náà jẹ́, bí o bá ti múra ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ kan sílẹ̀ tí ó ń kẹ́sẹ járí dáadáa ní mímú ọkàn-ìfẹ́ dàgbà, rí i dájú pé o ń bá a lọ láti lò ó! Kò pọndandan láti jáwọ́ nínú lílo ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ gbígbéṣẹ́ kan tí ó ń yọrí sí rere. Wulẹ̀ mú un bá ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni fún oṣù lọ́ọ́lọ́ọ́ mu. Bí o ti ń ṣàyẹ̀wò àwọn àbá tí a fi fúnni nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, wá àwọn kókó tí ó fà ọ́ lọ́kàn mọ́ra tí ìwọ yóò fẹ́ láti mú wọnú ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ.
4 Nítorí náà, nígbà tí o bá gba ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tuntun, rántí pé àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú rẹ̀ wulẹ̀ jẹ́ àbá. Bí o bá lè lò wọ́n, ìyẹn dára. Ṣùgbọ́n, bí o bá ti rí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tí ó ń yọrí sí rere ní ìpínlẹ̀ rẹ, máa lò ó! Ohun tí ó ṣe pàtàkì ni pé kí o “ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún” lọ́nà rere, ní wíwá àwọn tí ó yẹ rí, kí o sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn.—2 Tím. 4:5.