Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún February
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní February 2
Orin 166
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run.
15 min: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ajíhìnrere Tòótọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàtúnyẹ̀wò àpótí tí ó wà ní ojú ìwé 19 nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti September 1, 1992.
20 min: “Ran Àwọn Aládùúgbò Rẹ Lọ́wọ́ Láti Ṣàwárí Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.” Ṣàyẹ̀wò àpilẹ̀kọ, kí o tọ́ka sí bí a ṣe pète àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a dábàá láti ru àwọn tí ó bá fetí sílẹ̀ sókè kí ó sì sún wọn ṣiṣẹ́. Jẹ́ kí àgbàlagbà kan ṣàṣefihàn ìpínrọ̀ 3 àti 4, kí èwe kan sì ṣàṣefihàn ìpínrọ̀ 5 àti 6.
Orin 208 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní February 9
Orin 96
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
15 min: “Lo Ìwé Ìléwọ́ Lọ́nà Rere.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Fi ìrírí tí ó wà nínú Ilé Ìṣọ́ ti December 1, 1996, ojú ìwé 13, ìpínrọ̀ 15 kún un.
20 min: “Jíjẹ́rìí fún Àwọn Ènìyàn Láti Inú Gbogbo Èdè àti Ẹ̀sìn.” (Ìpínrọ̀ 1 sí 9) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Mẹ́nu kan àwọn èdè tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ń sọ ní ìpínlẹ̀ rẹ, kí o sì fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọ ní lọ́wọ́ fún àwọn èdè náà hàn. Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé rẹ̀ ní ìpínrọ̀ 9, jẹ́ kí ẹnì kan ṣàṣefihàn bí a ṣe lè lo ìwé kékeré Good News for All Nations.
Orin 220 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní February 16
Orin 75
15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó. Ṣàyẹ̀wò “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Ọjọ́ Àpéjọ Àkànṣe.”
10 min: Ìdí Tí Ó Fi Yẹ Kí O Lọ sí Àwọn Ìpàdé Kristẹni. Alàgbà jíròrò àwọn kókó pàtàkì nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti August 15, 1993, ojú ìwé 8 sí 11, kí ó tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì lílọ sí gbogbo ìpàdé déédéé.
20 min: “Jíjẹ́rìí fún Àwọn Ènìyàn Láti Inú Gbogbo Èdè àti Ẹ̀sìn.” (Ìpínrọ̀ 10 sí 27) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Mẹ́nu kan àwọn ẹ̀sìn tí kì í ṣe Kristẹni tí ó wà ní ìpínlẹ̀ rẹ. Jẹ́ kí akéde onírìírí kan ṣàṣefihàn bí a ṣe lè kọ́kọ́ jẹ́rìí fún ẹnì kan tí ó jẹ́ ẹlẹ́sìn Búdà, Híńdù, Júù, tàbí Mùsùlùmí—èyíkéyìí tí ó bá wọ́pọ̀ jù lọ ní àdúgbò.
Orin 15 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní February 23
Orin 4
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní March. Mẹ́nu kan àbá kan tàbí méjì lórí bí a ṣe lè fi ìwé Ìmọ̀ lọni, kí o lo àwọn kókó láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1996, ojú ìwé 8. Tẹnu mọ́ góńgó bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.
15 min: “Bí Ó Bá Ń Yọrí sí Rere, Máa Lò Ó!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Jẹ́ kí akéde onírìírí kan tàbí méjì láti inú àwùjọ ṣàlàyé ní ṣókí nípa àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò nígbà gbogbo nítorí rírọrùn tí àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ náà rọrùn àti àwọn àṣeyọrí tí ó ti mú wá. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kí àwọn kan sọ àwọn ọ̀nà ìyọsíni tí a dábàá láìpẹ́ yìí tí ó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tí ó sì ti gbéṣẹ́.
20 min: Fi Àwọn Ìgbékalẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ Dánra Wò. Ọ̀rọ̀ àsọyé ṣókí tí a gbé karí Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ojú ìwé 98, ìpínrọ̀ 8 àti 9. Tẹnu mọ́ bí ó ṣe yẹ kí a ṣàyẹ̀wò àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wa kí a sì ronú nípa àwọn ọ̀nà tí a fi lè túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i. Jẹ́ kí àwọn arábìnrin méjì ṣàṣefihàn bí wọ́n ṣe ṣàyẹ̀wò bí wọ́n ti ṣe sí ní ẹnú ọ̀nà, kí wọ́n sì jíròrò bí wọ́n ṣe lè sunwọ̀n sí i. Wọ́n tún ṣe ìfidánrawò ráńpẹ́ láti gbìyànjú ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n wéwèé láti lò lọ́jọ́ iwájú, wọ́n sì fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì ní àwọn àbá tí ó wúlò. Alága parí ọ̀rọ̀ nípa fífún gbogbo ará níṣìírí láti ṣàyẹ̀wò àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn kí wọ́n sì fi wọ́n dánra wò.
Orin 103 àti àdúrà ìparí.