Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Jẹ́ Kí Àwọn Ọmọ Yín Jẹ́ Ìdùnnú Fún Yín
“Bàbá rẹ àti ìyá rẹ yóò yọ̀.”—ÒWE 23:25.
1. Kí ni yóò mú kí àwọn òbí rí orísun ìdùnnú nínú àwọn ọmọ wọn?
ẸWO bí ó ti dára tó láti rí igi kékeré kan tí ó ń dàgbà, tí ó sì di igi ràbàtà, tí ó ń pèsè ẹwà àti ibòji—ní pàtàkì tí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni ó gbìn ín, tí ó sì tọ́jú rẹ̀! Bákan náà, àwọn òbí tí wọ́n tọ́jú àwọn ọmọ, tí wọ́n dàgbà di adàgbàdénú ìránṣẹ́ Ọlọ́run, máa ń rí ìdùnnú ńlá nínú wọn, gẹ́gẹ́ bí òwe Bíbélì ṣe sọ pé: “Bàbá olódodo ni yóò yọ̀ gidigidi: ẹni tí ó sì bí ọmọ ọlọgbọ́n, yóò ní ayọ̀ nínú rẹ̀. Bàbá rẹ àti ìyá rẹ yóò yọ̀, inú ẹni tí ó bí ọ yóò dùn.”—Òwe 23:24, 25.
2, 3. (a) Báwo ni àwọn òbí ṣe lè yẹra fún ìbìnújẹ́ àti ìkorò ọkàn? (b) Kí ni àwọn igi kékeré àti àwọn ọmọ́ nílò kí wọ́n baà lè di orísun ìdùnnú?
2 Síbẹ̀, ọmọ kan kì í ṣàdédé di “olódodo,” kì í sì í ṣàdédé di “ọlọgbọ́n.” A nílò ìsapá gidigidi láti mú kí àwọn ọmọ́ má ṣe jẹ́ orísun “ìbìnújẹ́” àti “ìkorò ọkàn,” àní bí mímú igi kékeré kan dàgbà di igi ràbàtà ti ní iṣẹ́ nínú. (Òwe 17:21, 25) Fún àpẹẹrẹ, èdó lè ran igi kékeré kan lọ́wọ́ láti mú kí ó dàgbà di igi títọ́ sangbọndan, kí ó sì lágbára. Ìpèsè omi déédéé ṣe pàtàkì, ó sì lè béèrè pé kí a dáàbò bo igi kékeré kan kúrò lọ́wọ́ kòkòrò. Ní paríparí rẹ̀, rírẹ́wọ́ rẹ̀ yóò ṣèrànwọ́ láti mú igi kan tí ó lẹ́wà jáde.
3 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé àwọn ọmọ́ nílò irú àwọn nǹkan bí ìdálẹ́kọ̀ọ́ oníwà-bí-Ọlọ́run, fífi omi òtítọ́ Bíbélì tẹ́ wọn lọ́rùn, dídáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ ìwà ìbàjẹ́, àti ìbáwí onífẹ̀ẹ́ láti gé àwọn ànímọ́ tí a kò fẹ́ dànù. Láti pèsè àwọn ohun kò-ṣeé-má-nìí wọ̀nyí, a rọ àwọn bàbá ní pàtàkì láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Kí ni èyí ní nínú?
Gbé Ìtẹnumọ́ Karí Ọ̀rọ̀ Jèhófà
4. Ẹrù iṣẹ́ wo ni àwọn òbí ní sí àwọn ọmọ wọn, kí sì ni a ń béèrè kí wọ́n tó lè kúnjú rẹ̀?
4 “Ìlànà èrò orí Jèhófà” túmọ̀ sí ṣíṣàkóso ìrònú wa láti bá ìfẹ́ inú Jèhófà mu. Nígbà náà, àwọn òbí gbọ́dọ̀ gbin ìrònú Jèhófà nípa àwọn ọ̀ràn sínú èrò inú àwọn ògo wẹẹrẹ wọn. Wọ́n tún gbọ́dọ̀ ṣàfarawé àpẹẹrẹ Ọlọ́run ti pípèsè ìbáwí oníyọ̀ọ́nú, tàbí ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ń tọ́ni sọ́nà. (Orin Dáfídì 103:10, 11; Òwe 3:11, 12) Ṣùgbọ́n kí àwọn òbí tó lè ṣe èyí, àwọn fúnra wọ́n gbọ́dọ̀ gba ọ̀rọ̀ Jèhófà sínú, gẹ́gẹ́ bí Mósè, wòlíì Ọlọ́run, ṣe ṣí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì létí pé: “Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí [láti ọ̀dọ̀ Jèhófà], tí mo pa láṣẹ fún ọ ní òní, kí ó máa wà ní àyà rẹ.”—Diutarónómì 6:6, ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.
5. Ìgbà wo àti ọ̀nà wo ni àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì ní láti gbà fún àwọn ọmọ wọn nítọ̀ọ́ni, kí sì ni ó túmọ̀ sí láti “gbìn”?
5 Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, ṣíṣàṣàrò, àti àdúrà ń mú àwọn òbí gbára dì láti ṣe ohun tí Mósè pa láṣẹ tẹ̀ lé e pé: “Ìwọ́ gbọ́dọ̀ gbin [ọ̀rọ̀ Jèhófà] sínú ọmọkùnrin rẹ, ìwọ sì gbọ́dọ̀ sọ nípa wọn nígbà tí ìwọ́ bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí ìwọ́ bá ń rìn ní ọ̀nà àti nígbà tí ìwọ́ bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí ìwọ́ bá dìde.” (NW) Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tí a túmọ̀ sí “gbìn,” túmọ̀ sí “láti tún sọ,” “láti sọ léraléra,” “láti tẹ̀ mọ́ni lọ́kàn ní kedere.” Kíyè sí bí Mósè ṣe túbọ̀ tẹnu mọ́ àìní náà láti mú kí ọ̀rọ̀ Jèhófà máa wà ní ipò kíní ní sísọ pé: “Kí ìwọ kí ó . . . so wọ́n mọ́ ọwọ́ rẹ fún àmì, kí wọn kí ó sì máa ṣe ọ̀já ìgbàjú níwájú rẹ. Kí ìwọ kí ó sì kọ wọ́n sára òpó ilé rẹ, àti sára ilẹ̀kùn ọ̀nà òde rẹ.” Ní kedere, Jèhófà béèrè pé kí àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn ní àfiyèsí onífẹ̀ẹ́, tí ó ṣe déédéé!—Diutarónómì 6:7-9.
6. Kí ni àwọn òbí ní láti gbìn sínú àwọn ọmọ wọn, kí sì ni àǹfààní rẹ̀?
6 Kí ni “ọ̀rọ̀ wọ̀nyí” tí í ṣe ti Jèhófà tí àwọn òbí ní láti gbìn sínú àwọn ọmọ wọn? Mósè ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàtúnsọ ohun tí a sábà ń pè ní Òfin Mẹ́wàá tán ni, títí kan àṣẹ láti má ṣe ṣìkà pànìyàn, láti má ṣe ṣàgbèrè, láti má ṣe jalè, láti má ṣe jẹ́rìí èké, àti láti má ṣe ṣojú kòkòrò. Irú àwọn ohun àbéèrèfún ní ti ìwà híhù bẹ́ẹ̀, títí kan àṣẹ náà láti “fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ OLÚWA Ọlọ́run rẹ,” ní pàtàkì, jẹ́ ohun tí àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì ní láti gbìn sínú àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ wọn. (Diutarónómì 5:6-21; 6:1-5) Ìwọ kì yóò ha fohùn ṣọ̀kan pé irú ẹ̀kọ́ tí àwọn ọmọ nílò lónìí nìyí?
7. (a) Kí ni a fi àwọn ọmọ wé nínú Bíbélì? (b) Kí ni a óò gbé yẹ̀ wò nísinsìnyí?
7 A sọ fún bàbá tí ó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Obìnrin rẹ yóò dà bí àjàrà rere eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ: àwọn ọmọ rẹ yóò dà bí igi ólífì yí tábìlì rẹ ká.” (Orin Dáfídì 128:3) Síbẹ̀, kí àwọn òbí tó lè rí ìdùnnú nínú “igi kékeré” wọn, dípò nínírìírí ìbànújẹ́, wọ́n gbọ́dọ̀ ní ọkàn-ìfẹ́ ara ẹni, tí a ń fi hàn lójoojúmọ́, nínú àwọn ọmọ wọn. (Òwe 10:1; 13:24; 29:15, 17) Ẹ jẹ́ kí á ṣàyẹ̀wò bí àwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n bomi rin wọ́n nípa tẹ̀mí, kí wọ́n dáàbò bò wọ́n, kí wọ́n sì fi tìfẹ́tìfẹ́ bá wọn wí lọ́nà tí wọn óò fi rí ojúlówó orísun ìdùnnú nínú wọn.
Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
8. (a) Ta ni ó dúró bí èdó ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún Tímótì? (b) Nígbà wo ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà bẹ̀rẹ̀, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
8 Ronú ná nípa Tímótì, kí á sọ ọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ẹni tí ó rí ìrànlọ́wọ́ gbà, láti ọ̀dọ̀ èdó méjì tí ó fìdí múlẹ̀—ìyá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ àgbà. Níwọ̀n bí bàbá Tímótì ti jẹ́ Gíríìkì, tí ó sì hàn gbangba pé ó jẹ́ aláìgbàgbọ́, ìyá rẹ̀ tí ó jẹ́ Júù, Yùníìsì, àti ìyá-ìyá rẹ̀, Lọ́ìsì, ni ó kọ́ ọmọdékùnrin náà ‘láti ìgbà ọmọdé jòjòló nínú ìwé mímọ́.’ (Tímótì Kejì 1:5; 3:15; Ìṣe 16:1) A san èrè jìngbìnnì fún jíjẹ́ aláápọn tí wọ́n jẹ́ aláápọn nínú kíkọ́ Tímótì lẹ́kọ̀ọ́—àní nígbà tí ó wà ní ìkókó—nípa “iṣẹ́ ìyanu tí [Jèhófà] ti ṣe.” (Orin Dáfídì 78:1, 3, 4) Tímótì di míṣọ́nnárì ní ilẹ̀ òkèèrè, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ nígbà tí ó ṣì wà ní ọ̀dọ́langba, ó sì kó ipa pàtàkì nínú fífún àwọn ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ lókun.—Ìṣe 16:2-5; Kọ́ríńtì Kìíní 4:17; Fílípì 2:19-23.
9. Báwo ni àwọn èwe ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ láti yẹra fún ìdẹkùn ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì?
9 Ẹ̀yin òbí, irú èdó ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo ni ẹ jẹ́? Fún àpẹẹrẹ, ẹ ha ń fẹ́ kí àwọn ọmọ yín mú ojú ìwòye tí ó wà déédéé dàgbà nípa àwọn nǹkan ti ara bí? Nígbà náà, ẹ gbọ́dọ̀ fi àpẹẹrẹ tí ó tọ́ lélẹ̀ nípa ṣíṣàìlépa àwọn ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, tàbí àwọn ohun mìíràn tí ẹ kò nílò ní ti gidi. Bí ẹ bá yàn láti lépa àwọn àǹfààní ti ara, kí ó má ṣe yà yín lẹ́nu nígbà tí àwọn ọmọ yín bá fara wé e yín. (Mátíù 6:24; Tímótì Kìíní 6:9, 10) Ní tòótọ́, bí èdó ìdálẹ́kọ̀ọ́ kò bá tọ́ sangbọndan, báwo ni igi kékeré ṣe lè dàgbà lọ́nà tí ó tọ́ sangbọndan?
10. Ìdarísọ́nà ta ni ó yẹ kí àwọn òbí máa wá nígbà gbogbo, ìṣarasíhùwà wo ni ó sì yẹ kí wọ́n ní?
10 Àwọn òbí tí ń rí ìdùnnú nínú àwọn ọmọ wọn yóò máa wá ìrànwọ́ Ọlọ́run déédéé láti kọ́ wọn, ní fífi ìgbà gbogbo gbé ohun tí ó jẹ́ ire dídára jù lọ nípa tẹ̀mí fún àwọn ọmọ wọn yẹ̀ wò. Ìyá ọlọ́mọ mẹ́rin kan ròyìn pé: “Àní kí á tó bí àwọn ọmọ wa, a máa ń gbàdúrà déédéé sí Jèhófà láti ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ òbí rere, láti jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà, kí a sì fi í sílò nínú ìgbésí ayé wa.” Ó fi kún un pé: “‘Jèhófà ní àkọ́kọ́’ kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe gbólóhùn ṣákálá, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé wa.”—Àwọn Onídàájọ́ 13:8.
Pípèsè “Omi” Déédéé
11. Kí ni igi kékeré àti àwọn ọmọdé nílò fún ìdàgbàsókè?
11 Ní pàtàkì, àwọn igi kékeré nílò ìpèsè omi tí ó ṣe déédéé, bí àwọn igi tí ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ lẹ́bàá odò ti fi hàn. (Fi wé Ìṣípayá 22:1, 2.) Àwọn ìkókó pẹ̀lú yóò yára dàgbà nípa tẹ̀mí bí a bá pèsè omi òtítọ́ Bíbélì fún wọn déédéé. Ṣùgbọ́n, àwọn òbí ní láti ronú nípa bí àkókò tí ọmọ wọ́n fi lè pọkàn pọ̀ ṣe gùn tó. Bóyá àkókò tí a ké kúrú, tí a fi ń fúnni ní ìtọ́ni lóòrèkóòrè yóò túbọ̀ gbéṣẹ́ ju àkókò gígùn bíi mélòó kan. Má ṣe fojú tín-ín-rín ìníyelórí irú àkókò kúkúrú bẹ́ẹ̀. Lílo àkókò pa pọ̀ ṣe pàtàkì láti mú kí ipò ìbátan pẹ́kípẹ́kí wà láàárín òbí àti ọmọ, ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí tí Ìwé Mímọ́ fún níṣìírí léraléra.—Diutarónómì 6:6-9; 11:18-21; Òwe 22:6.
12. Kí ni ìníyelórí gbígbàdúrà pẹ̀lú àwọn ògo wẹẹrẹ?
12 Ọ̀kan nínú àkókò tí a lè lò pẹ̀lú àwọn ògo wẹẹrẹ lè jẹ́ ní àṣálẹ́. Èwe kan rántí pé: “Àwọn òbí mi máa ń jókòó sí etí ibùsùn wa lálaalẹ́, wọn a sì tẹ́tí sí wa bí a ṣe ń gbàdúrà tiwa.” Òmíràn sọ nípa ọ̀kan nínú ìjẹ́pàtàkì ṣíṣe èyí pé: “Ìyẹ́n sọ ọ́ di àṣà fún mi láti máa gbàdúrà sí Jèhófà lálaalẹ́ kí n tó lọ sùn.” Nígbà tí àwọn ọmọ bá ń gbọ́ lójoojúmọ́ tí àwọn òbí wọn ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, tí wọ́n sì ń gbàdúrà sí i, òun yóò di ẹni gidi sí wọn. Ọ̀dọ́kùnrin kan sọ pé: “Mo lè di ojú mi nínú àdúrà sí Jèhófà, kí n sì rí ẹnì kan tí ó jẹ́ bàbá àgbà ní ti gidi. Àwọn òbí mi ràn mí lọ́wọ́ láti lóye pé Jèhófà ń kó ipa kan nínú gbogbo ohun tí a bá ṣe, tí a bá sì sọ.”
13. Kí ni sáà ìtọ́ni ṣíṣe déédéé lè ní nínú?
13 Láti ran àwọn ògo wẹẹrẹ lọ́wọ́ láti fa omi òtítọ́ Bíbélì mu, àwọn òbí lè fi ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tí ó gbéṣẹ́ kún àwọn sáà ìtọ́ni tí a ń ṣe déédéé. Òbí àwọn ọmọ méjì tí wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ọ̀dọ́langba wí pé: “Àwọn ọmọ méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti nǹkan bíi ọ̀sẹ̀ mélòó kan àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn, láti máa jókòó jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba.” Bàbá kan ṣàkàwé ohun tí ìdílé rẹ̀ ṣe pé: “A kọ orúkọ gbogbo ìwé Bíbélì lẹ́sẹẹsẹ sórí àwọn káàdì atọ́ka, a sì gbìdánwò láti tò wọ́n bí wọ́n ṣe tẹ̀ léra, gbogbo wá ń ṣe é lọ́kọ̀ọ̀kan. Ìgbà gbogbo ni àwọn ọmọ́ máa ń fojú sọ́nà fún èyí.” Ọ̀pọ̀ ìdílé máa ń fi sáà ìtọ́ni ṣókí kún un ṣáájú oúnjẹ tàbí lẹ́yìn oúnjẹ. Bàbá kan sọ pé: “Àkókò oúnjẹ alẹ́ ti jẹ́ àkókò dáradára fún wa láti jíròrò ẹsẹ Bíbélì ojoojúmọ́.”
14. (a) Àwọn ìgbòkègbodò tí ń mérè wá nípa tẹ̀mí wo ni a lè bá àwọn ògo wẹẹrẹ ṣàjọpín? (b) Agbára wo ni àwọn ọmọdé ní láti kẹ́kọ̀ọ́?
14 Àwọn ògo wẹẹrẹ tún máa ń gbádùn títẹ́tí sí àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì ṣíṣe kedere nínú Iwe Itan Bibeli Mi.a Tọkọtaya kan sọ pé: “Nígbà tí àwọn ọmọ wà ní kékeré, a máa ń kárí ẹ̀kọ́ kan nínú Iwe Itan Bibeli, lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ yóò múra bí àwọn ẹni ìgbàanì, wọn yóò sì fi ìtàn náà ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́ kúkúrú. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ èyí, wọ́n sì sábà máa ń rin kinkin mọ́ ọn pé kí àwọn ṣe ju ìtàn kan lọ ní àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ kan.” Má ṣe fojú kéré agbára tí ọmọ rẹ ní láti kẹ́kọ̀ọ́! Àwọn ọmọ ọdún mẹ́rin wà tí wọ́n ti kọ́ gbogbo àkòrí Iwe Itan Bibeli sórí, tí wọ́n sì ti kọ́ bí a ti í ka Bíbélì pàápàá! Èwe kan rántí pé nígbà tí òún jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ta ààbọ̀, òún máa ń ṣi “ìpinnu ìdájọ́” pè léraléra, ṣùgbọ́n bàbá rẹ̀ fún un níṣìírí láti túbọ̀ máa fi dánrawò.
15. Àwọn ọ̀ràn wo ni a lè bá àwọn ọmọ jíròrò, ẹ̀rí wo ni ó sì wà pé irú àwọn ìjíròrò bẹ́ẹ̀ níye lórí?
15 Ẹ tún lè lo àkókò tí ẹ bá lò pẹ̀lú àwọn ògo wẹẹrẹ yín láti mú wọn gbára dì láti ṣàjọpín omi òtítọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, irú bíi dídáhùn ní ìpàdé. (Hébérù 10:24, 25) Èwe kan rántí pé: “Ní àkókò tí a bá ń ṣe ìfidánrawò, mo máa ń dáhùn ní ọ̀rọ̀ ara mi. A kò fún mi láyè láti wulẹ̀ kà á láìlóye rẹ̀.” Ní àfikún sí i, a lè kọ́ àwọn ọmọ láti nípìn-ín lọ́nà tí ó ṣe gúnmọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Obìnrin kan tí àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run tọ́ dàgbà ṣàlàyé pé: “A kì í ṣe òṣiṣẹ́fapájánú tí ó wulẹ̀ máa ń tẹ̀ lé àwọn òbí wa lọ sẹ́nu iṣẹ́ wọn. A mọ̀ pé a ní ìpín kan, àní bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ kìkì títẹ aago ẹnu ọ̀nà, kí a sì fi ìwé ìléwọ́ lọni. Nípa fífara balẹ̀ múra sílẹ̀ ṣáájú ìgbòkègbodò òpin ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, a mọ ohun tí a óò sọ. A kì í jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ Saturday, kí á sì máa béèrè bóyá a óò lọ sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. A mọ̀ pé a óò lọ.”
16. Èé ṣe tí ṣíṣe déédéé nínú ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé pẹ̀lú àwọn ọmọ́ fi ṣe pàtàkì?
16 A kò lè tẹnu mọ́ àìní náà láti máa pèsè omi òtítọ́ Bíbélì déédéé fún àwọn ògo wẹẹrẹ jù, èyí tí ó túmọ̀ sí pé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ṣe pàtàkì. Bàbá ọlọ́mọ méjì kan ṣàlàyé pé “kókó abájọ pàtàkì tí ó máa ń bí àwọn ọmọ nínú ni àìṣe-nǹkan-déédéé.” (Éfésù 6:4) Ó wí pé: “Èmi àti ìyàwó mi yan ọjọ́ kan àti àkókò kan, a sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ní ìbámu pẹ̀lú ìtòlẹ́sẹẹsẹ yẹn láìyingin. Kò pẹ́ tí àwọn ọmọ fi máa ń fojú sọ́nà fún un ní àkókò yẹn.” Gbogbo irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ láti ìgbà ọmọdé jòjòló ṣe pàtàkì, ní ìbámu pẹ̀lú òkodoro òtítọ́ náà pé, ‘Ibi tí a bá tẹ ọ̀mùnú sí, ni igi yóò dàgbà sí.’
17. Kí ni ó ṣe pàtàkì bíi pípèsè òtítọ́ Bíbélì fún àwọn ògo wẹẹrẹ?
17 Pípèsè òtítọ́ Bíbélì fún àwọn ògo wẹẹrẹ ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n àpẹẹrẹ òbí ṣe pàtàkì lọ́nà kan náà pẹ̀lú. Àwọn ọmọ rẹ ha rí ọ pé o ń kẹ́kọ̀ọ́, pé o ń lọ sí ìpàdé déédéé, pé o ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, àní, pé o ń rí orísun ìdùnnú nínú ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà? (Orin Dáfídì 40:8) Ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́nà tí ó gba àfiyèsí, ọmọbìnrin kan sọ nípa ìyá rẹ̀, ẹni tí ó ti fara da àtakò ọkọ rẹ̀, tí ó sì ti tọ́ àwọn ọmọ mẹ́fà dàgbà láti di àwọn Ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ pé: “Ohun tí ó wú wa lórí jù lọ ni àpẹẹrẹ Màmá fúnra rẹ̀—ó gbéṣẹ́ ju ọ̀rọ̀ ẹnu lọ.”
Pípèsè Ààbò fún Àwọn Ògo Wẹẹrẹ
18. (a) Báwo ni àwọn òbí ṣe lè pèsè ààbò tí àwọn ọmọ nílò fún wọn? (b) Irú ìtọ́ni wo ni àwọn ògo wẹẹrẹ ní Ísírẹ́lì rí gbà nípa àwọn ẹ̀yà ara ìbímọ?
18 Bí igi kékeré ti sábà máa ń nílò ààbò kúrò lọ́wọ́ àwọn kòkòrò eléwu, àwọn ògo wẹẹrẹ nílò ààbò kúrò lọ́wọ́ “àwọn ènìyàn burúkú” nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú yìí. (Tímótì Kejì 3:1-5, 13) Báwo ni àwọn òbí ṣe lè pèsè ààbò yìí? Ó jẹ́ nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti jèrè ọgbọ́n àtọ̀runwá! (Oníwàásù 7:12) Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì—títí kan “àwọn ògo wẹẹrẹ” wọn—láti tẹ́tí sí kíka Òfin rẹ̀, tí ó kan mímọ ìyàtọ̀ láàárín ìbálòpọ̀ tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. (Diutarónómì 31:12, NW; Léfítíkù 18:6-24) A mẹ́nu kan àwọn ẹ̀yà ara ìbímọ léraléra, títí kan “kórópọ̀n” àti “ẹ̀yà ìbálòpọ̀.” (Léfítíkù 15:1-3, 16; 21:20; 22:24, NW; Númérì 25:8; Diutarónómì 23:10) Nítorí bí ìwà ìbàjẹ́ ayé òde òní ti légbá kan tó, àwọn ògo wẹẹrẹ ní láti mọ ọ̀nà tí ó tọ́ àti ọ̀nà tí kò tọ́ láti lo irú àwọn ẹ̀yà ara wọn tí ó wà lára ìṣẹ̀dá tí Ọlọ́run sọ pé “dáradára ni.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:31; Kọ́ríńtì Kìíní 12:21-24.
19. Kí ni ìtọ́ni bíbá a mu wẹ́kú láti pèsè fún àwọn ògo wẹẹrẹ nípa àwọn ẹ̀yà ara ìkọ̀kọ̀ wọn?
19 Fún àbájáde dídára jù lọ, kí àwọn òbí méjèèjì lápapọ̀, tàbí alágbàtọ́ kọ̀ọ̀kan, fi àwọn ẹ̀yà ara ìkọ̀kọ̀ ọmọ kan hàn án. Lẹ́yìn náà, kí wọ́n ṣàlàyé pé a kò gbọ́dọ̀ gba ẹlòmíràn láyè láti fọwọ́ kan àwọn ẹ̀yà ara wọ̀nyí. Níwọ̀n bí àwọn abọ́mọdéṣèṣekúṣe ti sábà máa ń dán bí àwọn ògo wẹẹrẹ ṣe ń hùwà padà sí ìfìbálòpọ̀-lọni lọ́nà àyíínìke wò, kí a kọ́ ọmọ kan láti má ṣe gba gbẹ̀rẹ́ rárá, kí ó sì sọ pé: “Màá fi ẹjọ́ rẹ sùn!” Kọ́ àwọn ògo wẹẹrẹ rẹ láti máa fi ẹjọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìyànjú láti fọwọ́ kàn wọ́n lọ́nà kan tí ó ni wọ́n lára sùn nígbà gbogbo, láìka ẹ̀rù tí ẹni yẹn lè dá bà wọ́n sí.
Pípèsè Ìbáwí Onífẹ̀ẹ́
20. (a) Báwo ni ìbáwí ṣe dà bíi rírẹ́wọ́ igi? (b) Kí ni agbára ìdarí tí ìbáwí máa ń ní lákọ̀ọ́kọ́, ṣùgbọ́n kí ni yóò jẹ́ àbájáde rẹ̀?
20 Àwọn ògo wẹẹrẹ máa ń jàǹfààní láti inú ìbáwí onífẹ̀ẹ́, bí igi ṣe máa ń jàǹfààní nígbà tí a bá rẹ́wọ́ rẹ̀. (Òwe 1:8, 9; 4:13; 13:1) Nígbà tí a bá gé àwọn ẹ̀ka tí a kò fẹ́, àwọn yòó kù máa ń ráyè dàgbà dáradára. Nítorí náà, bí àwọn ọmọ rẹ bá ń darí àfiyèsí pàtàkì sí àwọn nǹkan ìní ti ara tàbí tí wọ́n bá ń tẹ̀ sí kíkẹ́gbẹ́ búburú tàbí lílọ́wọ́ nínú eré ìnàjú tí kò gbámúṣé, àwọn ìtẹ̀sí wọ̀nyí dà bí àwọn ẹ̀ka tí a ní láti gé dànù. Bí a bá mú wọn kúrò, a óò ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti dàgbà lọ́nà ti ẹ̀mí. Irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ lè má dùn mọ́ni ní ìbẹ̀rẹ̀, gan-an bí rírẹ́wọ́ igi kan ṣe lè fa ìdíwọ́ díẹ̀ fún un. Ṣùgbọ́n, ìdàgbàsókè àkọ̀tun lọ́nà tí o ń fẹ́ kí ọmọ rẹ̀ gbà dàgbà ni àbájáde rere tí ìbáwí máa ń ní.—Hébérù 12:5-11.
21, 22. (a) Kí ni ó fi hàn pé ìbáwí kì í dùn mọ́ni láti fúnni, bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í dùn mọ́ni láti gbà? (b) Èé ṣe tí kò fi yẹ kí àwọn òbí fà sẹ́yìn nínú fífúnni ní ìbáwí?
21 A gbà láìjanpata pé, ìbáwí kì í dùn mọ́ni, ì báà jẹ́ láti fúnni tàbí láti gbà á. Bàbá kan sọ pé: “Ọmọkùnrin mi ń lo àkókò púpọ̀ pẹ̀lú èwe kan tí àwọn alàgbà ti kìlọ̀ fún mi pé kò dára láti bá kẹ́gbẹ́. Ó yẹ kí n ti tètè gbégbèésẹ̀ ju bí mo ti ṣe. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọkùnrin mi kò lọ́wọ́ nínú ìwà àìtọ́ kan gúnmọ́, ó gba àkókò díẹ̀ láti ṣàtúnṣe ìrònú rẹ̀.” Ọmọkùnrin náà sọ pé: “Nígbà tí a já mi gbà lọ́wọ́ ọ̀rẹ́minú mi, ìbànújẹ́ dorí mi kodò.” Ṣùgbọ́n ó fi kún un pé: “Ìpinnu tí ó dára ni èyí, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni a yọ ọ́ lẹ́gbẹ́.”
22 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ìbáwí ẹ̀kọ́ ni ọ̀nà ìyè.” Nítorí náà, láìka bí ìbáwí ṣe lè ṣòro tó láti fi fúnni, má ṣe fawọ́ rẹ̀ sẹ́yìn fún àwọn ọmọ rẹ. (Òwe 6:23; 23:13; 29:17) Bí àkókò ti ń lọ, wọn yóò kún fún ìmoore pé o tọ́ wọn sọ́nà. Èwe kan wí pé: “Mo rántí bí inú ṣe máa ń bí mi gidigidi sí àwọn òbí mi nígbà tí wọ́n bá bá mi wí. Nísinsìnyí, inú yóò túbọ̀ bí mi jù bẹ́ẹ̀ lọ ká ní àwọn òbí mi ti fawọ́ ìbáwí yẹn sẹ́yìn fún mi ni.”
Èrè Náà Yẹ Ìsapá Tí A Ṣe
23. Èé ṣe tí gbogbo àfiyèsí onífẹ̀ẹ́ tí a bá fún àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ fi yẹ fún ìsapá náà?
23 Kò lè sí iyè méjì nípa rẹ̀, àwọn ọmọ tí àwọn òbí, títí kan àwọn ẹlòmíràn, bá ń rí orísun ìdùnnú nínú wọ́n jẹ́ àbájáde ọ̀pọ̀ àfiyèsí onífẹ̀ẹ́, lójoojúmọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, gbogbo ìsapá tí a ṣe lórí wọn—yálà wọ́n jẹ́ ọmọ nípa ti ara tàbí nípa tẹ̀mí—tò bẹ́ẹ̀ fún èrè tí a lè rí gbádùn. Àpọ́sítélì Jòhánù arúgbó fi èyí hàn nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Èmi kò ní èrèdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ìṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.”—Jòhánù Kẹta 4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Kí ni igi kékeré àti àwọn ọmọ nílò kí wọ́n baà lè yẹ fún oríyìn?
◻ Báwo, lọ́nà kan náà, ni àwọn òbí ṣe lè jẹ́ èdó ìdálẹ́kọ̀ọ́ gbígbéṣẹ́?
◻ Kí ni àkókò ìtọ́ni fún àwọn ògo wẹẹrẹ lè ní nínú, kí ni a sì ní láti kọ́ wọn láti dènà?
◻ Báwo ni ìbáwí ṣe ń ṣàǹfààní fún ọmọ kan, bí rírẹ́wọ́ igi ṣe ń ṣàǹfààní fún igi?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da onínúure Green Chimney’s Farm