Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run
Liberia: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Monrovia ni a padà ṣí ní September 1, lẹ́yìn tí a ti tì í pa fún oṣù 15 nítorí ogun abẹ́lé. Wọ́n ròyìn góńgó tuntun ju ti ìgbàkígbà rí lọ ti 1,977 akéde ní September.
Mòsáńbíìkì: Góńgó tuntun 28,005 akéde ni a dé ní September. Góńgó ti tẹ́lẹ̀ jẹ́ 25,790 ní May 1975, nítorí náà èyí jẹ́ ọ̀gangan pàtàkì nínú ọ̀rọ̀-ìtàn ìṣàkóso Ọlọ́run ní Mòsáńbíìkì.
Nepal: Góńgó tuntun 306 akéde ni a dé ní September. Èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 500 ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni a ń darí nísinsìnyí.
St. Helena: Agboolé kọ̀ọ̀kan tí ó wà ní erékùṣù yìí ni a fún ní ẹ̀dà Ìròyìn Ìjọba No. 35.
Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè bẹ̀rẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn pẹ̀lú góńgó tuntun àwọn akéde tí ó fi ìpín 5 nínú ọgọ́rùn-ún ju ti ìpíndọ́gba ọdún tí ó kọjá: Hong Kong, 4,230; Madagascar, 8,749 (tí ó ní góńgó tuntun 912 aṣáájú ọ̀nà déédéé nínú); Taiwan, 3,497.