-
Ìmọ̀ Ọlọrun Tòótọ́ Ń Sinni Lọ sí ÌyèIṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—1996 | March
-
-
Ìmọ̀ Ọlọrun Tòótọ́ Ń Sinni Lọ sí Ìyè
1 Jesu sọ nínú àdúrà sí Bàbá rẹ̀ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ iwọ, Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo naa sínú.” (Joh. 17:3) Ẹ wo irú èrè ńlá tí ìyẹ́n jẹ́! Nípa lílo ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, a lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí wọ́n ní láti ṣe láti wà láàyè títí láé. Kí ni a lè sọ láti ru ọkàn-ìfẹ́ wọn sókè, kí ó sì sún wọn láti fẹ́ láti ka ìwé Ìmọ̀?
2 O lè lo ìgbékalẹ̀ tí ó gbé Bibeli jáde gẹ́gẹ́ bí orísun ìtọ́sọ́nà ṣíṣeé mú lò, nípa sísọ pé:
◼ “A ń jíròrò pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wa nípa ibi tí a ti lè rí orísun ìtọ́sọ́nà ṣíṣeé mú lò láti kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé. Nígbà kan, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn kọ́kọ́ máa ń yẹ Bibeli wò. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ìṣarasíhùwà àwọn ènìyàn ti yí padà; ọ̀pọ̀ ń ṣiyè méjì nípa Bibeli, ní wíwulẹ̀ kà á sí ìwé kan tí àwọn ènìyàn kọ. Kí ní èrò rẹ? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìdí dáradára kan wà tí a fi lè sọ pé Bibeli gbéṣẹ́ ní ọjọ́ wa. [Ka 2 Timoteu 3:16, 17.] Àwọn ìlànà Bibeli ṣeé fi sílò nísinsìnyí gan-an gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣeé fi sílò nígbà tí Ọlọrun mí sí kíkọ Bibeli.” Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí ojú ìwé 16, kí o sì ṣàlàyé ṣókí lórí ìtọ́sọ́nà gbígbéṣẹ́ tí a rí nínú Ìwàásù Jesu Lórí Òkè. Ka àyọkà tí ó wà ní ìpínrọ̀ 11 tàbí èyí tí ó wà ní ìpínrọ̀ 13. Fi ìwé náà lọ̀ ọ́, kí o sì ṣètò láti padà wá láti dáhùn ìbéèrè náà, Báwo ni àwa fúnra wa ṣe lè jàǹfààní láti inú ìmọ̀ tí ó wà nínú Bibeli?
3 Níwọ̀n bí àdúrà tí jẹ́ àkòrí ọ̀rọ̀ kan tí ọ̀pọ̀ ènìyàn nífẹ̀ẹ́ sí, o lè fẹ́ láti jíròrò rẹ̀ nípa bíbéèrè pé:
◼ “Pẹ̀lú gbogbo ìṣòro líle koko tí a gbọ́dọ̀ dojú kọ nínú ìgbésí ayé òde òní, ìwọ́ ha rò pé àdúrà lè jẹ́ ìrànwọ́ gidi fún wa? [Dánu dúró fún èsì.] Ọ̀pọ̀ ronú pé àwọ́n ti sún mọ́ Ọlọrun nípa gbígbàdúrà sí i àti pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ti fún wọn ní okun inú, ohun tí Bibeli sì ṣèlérí gan-an nìyẹn. [Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí ojú ìwé 156, kí o sì ka Filippi 4:6, 7.] Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹnì kan lè ronú pé a kì í dáhùn àdúrà òun nígbà míràn. Àkòrí yìí jíròrò ‘Bí O Ṣe Lè Súnmọ́ Ọlọrun.’ [Fi ìwé náà lọ̀ ọ́ ní iye owó tí a ń fi síta.] Orí yìí tún ṣàlàyé bí a ṣe lè fetí sí Ọlọrun, níwọ̀n bí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ kì í ti í ṣe alápá kan. A lè jíròrò èyí nígbà míràn tí mo bá padà wa.”
4 Ìwọ yóò ha fẹ́ láti gbìyànjú ìyọsíni tààràtà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ kan bí? Ọ̀kan nìyí tí ó lè yọrí sí rere fún ọ:
◼ “A ń fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ lọni. Ìwọ́ ha ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rí bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Jẹ́ kí ń fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ń lò hàn ọ́.” Fi ìwé Ìmọ̀ hàn án, ṣí i sí ojú ìwé 3 kí onílé lè rí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé náà, kí o sì béèrè pé, “O ha ti ṣe kàyéfì rí nípa ohun tí Bibeli ní í sọ lórí àwọn kókó wọ̀nyí bí?” Ṣí i sí orí tí onílé fi ọkàn-ìfẹ́ hàn sí jù lọ, kí o sì ka àwọn ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀. Ṣàlàyé pé ìwọ yóò fẹ́ láti fi bí a ṣe ń kárí àwọn ìsọfúnni yìí nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wa hàn ní ṣókí. Yálà o bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, fí ìwé náà lọ̀ ọ́ ní iye owó tí a ń fi síta.
5 Lónìí, ọ̀pọ̀ jaburata ènìyàn ń dáhùn padà sí ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọrun tòótọ́ náà. (Isa. 2:2-4) Ó jẹ́ àǹfààní wa láti ran iye ẹni tí ó bá ṣeé ṣe lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jehofa, kí ó sì sìn wọ́n lọ sí ìyè.—1 Tim. 2:4.
-
-
Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Jèrè Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí ÌyèIṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—1996 | March
-
-
Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Jèrè Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè
1 Aposteli Paulu ṣàlàyé pé ó jẹ́ ‘ìfẹ́-inú Ọlọrun pé kí gbogbo onírúurú ènìyàn wá sí ìmọ̀ pípéye nipa òtítọ́.’ (1 Tim. 2:4) Báwo ní a ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti gba ìmọ̀ yẹn sínú? Ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ẹni tí ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun ti ru ọkàn-ìfẹ́ wọn sókè jẹ́ ọ̀nà kan. Ìtẹ̀jáde yìí gbé òtítọ́ Bibeli kalẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe kedere, tí ó rọrùn, tí a sì ṣà yàn dáradára. Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, a lè sin onírúurú ènìyàn lọ sí ìyè. Kí ni a lè sọ láti fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pẹ̀lú wa?
2 Fún àwọn tí ó fi ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú Bibeli gẹ́gẹ́ bí ìtọ́sọ́nà gbígbéṣẹ́, o lè padà lọ láti fí ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ wọ́n, bóyá ní sísọ pé:
◼ “Nígbà tí mo kọ́kọ́ wá síbí, a jíròrò ìdí tí a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé Bibeli gẹ́gẹ́ bí orísun ìtọ́sọ́nà gbígbéṣẹ́. Nítorí pé Ọlọrun ni ó mí sí i, Bibeli tún jẹ́ orísun dídájú fún ìtùnú àti ìrètí, àní gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn aposteli Kristi ti sọ. [Ka Romu 15:4.] Ní òpin ìjíròrò wa àkọ́kọ́, mo béèrè ìbéèrè náà pé, Báwo ni àwa fúnra wa ṣe lè jàǹfààní láti inú ìmọ̀ tí ó wà nínú Bibeli?” Ka ìpínrọ̀ 18, ní ojú ìwé 11, nínú ìwé Ìmọ̀. Ṣàlàyé pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ó tó mílíọ̀nù márùn-ún kárí ayé, ní ríran àwọn ènìyàn níbi gbogbo lọ́wọ́ láti gba ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun sínú. Ṣe àṣefihàn kúkúrú lórí bí a ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́, ní lílo ìpínrọ̀ márùn-ún àkọ́kọ́ ní orí 1.
3 Bí ó bá jẹ́ pé àdúrà ni àkòrí ọ̀rọ̀ tí o bá ẹnì kan jíròrò lákọ̀ọ́kọ́, o lè gbìyànjú ìyọsíni yìí nínú ìsapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́:
◼ “Mo lérò pé o gbádùn ìsọfúnni nípa àdúrà tí a jíròrò láti inú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Mo ṣèlérí láti padà wá láti bá ọ jíròrò, bí àwọn tí ń gbàdúrà sí Ọlọrun ṣe lè fetí sílẹ̀ sí i pẹ̀lú. Kíyè sí ohun tí a sọ ní ojú ìwé 158. [Ka ìpínrọ̀ 18.] Nípa báyìí, nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli fúnra ẹni, a ń fetí sí ohun tí Ọlọrun ní í sọ fún wa. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń fà wá sún mọ́ ọn, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti dojú kọ àwọn ìṣòro ojoojúmọ́ tí a tìtorí rẹ̀ gbàdúrà. Inú mi yóò dùn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú rẹ.” Bí ẹni náà bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, bẹ̀rẹ̀ orí kìíní ìwé Ìmọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
4 Bí o bá lo ìyọsíni tààràtà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ẹni tí ó gba ìwé, o lè sọ èyí láti máa bá ìjíròrò àkọ́kọ́ nìṣó:
◼ “Mo ṣe àkànṣe ìsapá láti tún bẹ̀ ọ́ wò, nítorí pé mo fẹ́ sọ fún ọ sí i nípa ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ọ̀fẹ́ tí a ń ṣe. Mo fi ẹ̀dá kan ìwé yìí, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí a ń lò láti fi bá àwọn ènìyàn kẹ́kọ̀ọ́, sílẹ̀ fún ọ. Kíyè sí bí ó ti fún wa níṣìírí láti gbé Ọ̀rọ̀ Ọlọrun yẹ̀ wò. [Ka ìpínrọ̀ 23 ní ojú ìwé 22.] Bí ìwọ yóò bá jọ̀wọ́ mú ẹ̀dà ìwé tìrẹ, bóyá yóò ṣeé ṣe fún wa láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ wa nìṣó níbi tí a dúró sí ní ìjọ́sí.” Bí ẹ kò bá bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nígbà ìkésíni àkọ́kọ́, o lè sọ pé: “Bóyá èyí yóò jẹ́ àkókò dáradára kan fún mi láti fi bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli hàn.” Lẹ́yìn tí o bá ti gbé ìpínrọ̀ díẹ̀ yẹ̀ wò, ṣètò àkókò pàtó kan láti padà wá fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tí yóò tẹ̀ lé e.
5 Lílo ìwé Ìmọ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́ yóò mú kí a lè tan ìmọ̀ pípéye kálẹ̀ fún ìbùkún àwọn ẹlòmíràn. (Owe 15:7) Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ yóò mú ìdùnnú wa fún àwọn tí ó ní ọkàn títọ́, yóò sí jẹ́ ìsúnniṣe alágbára fún wọn láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú òdodo Jehofa, tí yóò sìn wọ́n lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀.
-