Ran Àwọn Aládùúgbò Rẹ Lọ́wọ́ Láti Ṣàwárí Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
1 Ènìyàn ti ṣe ọ̀pọ̀ àṣeyọrí nínú ìgbòkègbodò sáyẹ́ǹsì ní ọ̀rúndún ogún yìí. Èyí ti pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé tí ọwọ́ kò tí ì tẹ̀ rí fún àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn láti onírúurú ipò láwùjọ ti kùnà lọ́nà tí ó bani nínú jẹ́ nínú apá kan nínú ìgbésí ayé ènìyàn—ìdílé. Ìkùnà wọn jẹ́ nítorí tí wọ́n gbójú fo àwọn ìlànà Jèhófà Ọlọ́run, ọ̀dọ̀ Ẹni “tí olúkúlùkù ìdílé ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé ti gba orúkọ rẹ̀.”—Éfé. 3:15.
2 Àìmọye àwọn ìdílé ni ó ní Bíbélì, ṣùgbọ́n eruku ti bò ó lórí pẹpẹ ìkówèésí dípò kí wọ́n lò ó láti yanjú àwọn ìṣòro ìdílé. Kí a tó lè rí ayọ̀ ìdílé, a gbọ́dọ̀ fi àwọn ìtọ́sọ́nà àti ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò. Ní February, a óò ṣe ìsapá aláápọn láti ṣàjọpín ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Àwọn àbá mélòó kan lórí bí a ṣe lè fi ìwé náà lọni nìyí:
3 Bí o bá bá òbí kan pàdé nínú iṣẹ́ ilé dé ilé, o lè ru ọkàn-ìfẹ́ sókè nípa sísọ pé:
◼ “Pẹ̀lú gbogbo másùnmáwo àti hílàhílo tí a ń dojú kọ lójoojúmọ́, o ha rò pé ó ṣeé ṣe láti gbádùn ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀ ní ti gidi bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Àṣírí ayọ̀ ìdílé tòótọ́ ni a lè rí nínú fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Ìdílé tí ó bá fi wọ́n sílò yóò gbádùn àlàáfíà Ọlọ́run. [Ka Aísáyà 32:17, 18.] Ìwé yìí, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, fi àwọn ìlànà tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbé agboolé wa ró hàn.” Ṣí ojú ìwé 11, kí o sì ka ìpínrọ̀ 20. Fi ìwé náà lọ̀ ọ́ fún ọrẹ ₦55.
4 Nígbà tí o bá padà ṣe ìbẹ̀wò o lè máa bá ìjíròrò náà nìṣó lọ́nà yìí:
◼ “Nígbà tí a kọ́kọ́ pàdé, mo rí i pé o bìkítà nípa ìdílé rẹ ní tòótọ́. Èmi yóò fẹ́ láti tọ́ka sí ohun kan nínú ìwé tí o gbà tí mo rò pé ìwọ yóò mọrírì. Àkòrí tí ó kẹ́yìn ṣàlàyé àṣírí gidi fún ayọ̀ ìdílé. [Ka ìpínrọ̀ 2 ní ojú ìwé 183.] Kíyè sí i pé ṣíṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni kọ́kọ́rọ́ náà. A dámọ̀ràn pé kí àwọn ìdílé jùmọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti mọ ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ àti bí wọ́n ṣe lè fi í sílò nínú agboolé. A ń fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ń gbà kìkì oṣù díẹ̀ láti parí lọni lọ́fẹ̀ẹ́. Bí o bá fẹ́ kí n ṣe bẹ́ẹ̀, èmi yóò fi bí a ṣe ń darí rẹ̀ hàn ọ́.” Padà lọ pẹ̀lú ìwé Ìmọ̀ fún ìjíròrò síwájú sí i.
5 Nígbà tí o bá ń bá èwe kan sọ̀rọ̀ ní ìpínlẹ̀ rẹ, o lè lo ọ̀nà ìyọsíni yìí:
◼ “Ọ̀pọ̀ èwe lónìí máa ń ráhùn pé àwọn òbí wọn kì í gbọ́ wọn yé. Kí ni o rò pé ó ń fa èyí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìwé yìí tí a ṣe lọ́nà tí ó dára gan-an láti yanjú àwọn ìṣòro ìdílé ṣe àwọn àlàyé tí ó dùn mọ́ni yìí lórí kókó ẹ̀kọ́ náà, ‘Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ Olótìítọ́ Inú àti Aláìlábòsí.’ [Ka ìpínrọ̀ 4 lójú ewé 65 nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.] Àwọn ìpínrọ̀ tí ó tẹ̀ lé e pèsè ìmọ̀ràn tí ó yè kooro lórí bí a ṣe lè mú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ nínú ìdílé sunwọ̀n sí i. Àkọlé ìwé yìí ni Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Ẹ̀dà yìí lè jẹ́ tìrẹ fún ọrẹ ₦55.” Ṣètò fún ìpadàbẹ̀wò.
6 O lè máa bá ìjíròrò rẹ àkọ́kọ́ nìṣó pẹ̀lú èwe kan nípa ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ láàárín òbí àti ọmọ nípa sísọ pé:
◼ “Ìfẹ́-ọkàn rẹ láti gbádùn ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tí ó gbámúṣé nínú ìdílé rẹ wú mi lórí. Gẹ́gẹ́ bí èwe, kí ni o lè ṣe láti mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí rẹ sunwọ̀n sí i? [Jẹ́ kí ó fèsì. Ṣí ìwé Ayọ̀ Ìdílé sí ojú ewé 65, kí o sì ka ìpínrọ̀ 5.] Ìrírí ti fi hàn pé àṣeyọrí tí ó dára jù lọ ni a lè rí nípa títẹ̀lé ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ tí a rí nínú Bíbélì.” Fi ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? lọ̀ ọ́. Ṣàlàyé pé àwọn ẹ̀kọ́ 16 inú rẹ̀ pèsè ìtòlẹ́sẹẹsẹ nípa ìhìn iṣẹ́ tí ó wà nínú Bíbélì. Ka ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà ní ojú ìwé 2, lẹ́yìn náà, kí ẹ sì jọ jíròrò ẹ̀kọ́ kìíní pa pọ̀.
7 Má ṣe dáwọ́ dúró ní fífún irúgbìn Ìjọba nítorí pé Jèhófà yóò bù kún àwọn ìsapá rẹ ní ríran àwọn aládùúgbò rẹ lọ́wọ́ láti ṣàwárí àṣírí ayọ̀ ìdílé.—Máàkù 12:31.