ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/98 ojú ìwé 1
  • “Ẹ Máa Ṣe Èyí ní Ìrántí Mi”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Máa Ṣe Èyí ní Ìrántí Mi”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tá A Fi Ń Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • “Ẹ Máa Ṣe Èyí”—April 5 La Máa Ṣe Ìrántí Ikú Kristi
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • “Ẹ Máa Ṣe Èyí Ní Ìrántí Mi”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Ìdí Tí A Fi Ń Lọ Síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 3/98 ojú ìwé 1

“Ẹ Máa Ṣe Èyí ní Ìrántí Mi”

1 Ẹ̀dá ènìyàn ní ìtẹ̀sí láti jẹ́ kí ìjẹ́pàtàkì àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì pa rẹ́ bí àkókò ti ń lọ. Ìdí kan nìyí tí Jésù fi pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tí ó ń dá “oúnjẹ alẹ́ Olúwa” sílẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Láti ìgbà náà wá, ní àyájọ́ ikú Jésù, àwọn Kristẹni ti ń fi ìgbọràn bá a nìṣó láti máa “pòkìkí ikú Olúwa, títí yóò fi dé.”—1 Kọ́r. 11:20, 23-26.

2 Wàyí o, láìpẹ́, Jésù yóò gba àwọn tí ó kẹ́yìn nínú “agbo kékeré” tí ń dínkù náà sínú ibùgbé ti ọ̀run. (Lúùkù 12:32; Jòh. 14:2, 3) Lọ́dún yìí, àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró pa pọ̀ pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ “àwọn àgùntàn mìíràn” tí ń pọ̀ sí i ṣáá yóò tún ní àǹfààní ti ṣíṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, ní April 11. (Jòh. 10:16; Ìṣí. 7:9, 10) A óò fún ìmọrírì wa lókun fún ìfẹ́ gíga lọ́lá ti Jèhófà ní rírán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá fún ire aráyé. A óò tẹnu mọ́ àpẹẹrẹ Jésù, ìfẹ́ rẹ̀, ìṣòtítọ́ rẹ̀ dójú ikú ní pípèsè ìràpadà, àti ṣíṣàkóso tí ó ń ṣàkóso nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run tí a ti gbé kalẹ̀, títí kan àwọn ìbùkún tí Ìjọba náà yóò mú wá fún aráyé. Ní tòótọ́, ó jẹ́ àkókò ìrántí kan!

3 Múra Sílẹ̀ Nísinsìnyí: Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa sakun láti mú kí àkókò Ìṣe Ìrántí yìí jẹ́ ti onídùnnú ńlá àti ti ikún-fún-ọpẹ́ níhà ọ̀dọ̀ wa àti níhà ọ̀dọ̀ àwọn tí yóò dara pọ̀ mọ́ wa. A lè múra ọkàn-àyà wa sílẹ̀ nípa kíka àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì lẹ́ẹ̀kan sí i nípa àwọn ọjọ́ díẹ̀ tí ó kẹ́yìn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣáájú ikú rẹ̀. Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa ní àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ṣáájú Ìṣe Ìrántí ni a lè yà sọ́tọ̀ láti ṣàtúnyẹ̀wò orí 112 sí 116 nínú ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ.

4 Àwọn mélòó ni o mọ̀ pé wọ́n lè wá sí Ìṣe Ìrántí bí o bá lo ìdánúṣe láti mú kí ìmọrírì wọn pọ̀ sí i fún ayẹyẹ yìí, bí o bá ké sí wọn, bí o bá sì mú kí wọ́n nímọ̀lára pé a óò fi ọ̀yàyà kí wọn káàbọ̀? Kọ orúkọ wọn nísinsìnyí, kí o sì ṣe ohun tí o bá lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fún wọn kí wọ́n lè wá. Lẹ́yìn náà, ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó láti dàgbà nípa tẹ̀mí nípa fífún wọn níṣìírí láti máa wá sí àwọn ìpàdé déédéé.

5 Ní àkókò Ìṣe Ìrántí, a óò ṣe àwọn ètò àkànṣe láti mú kí àǹfààní tí ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò ní láti wàásù pọ̀ sí i. Bí ìṣètò yíyẹ bá wà, ìwọ ha lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù April bí? ní oṣù May ńkọ́? Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti fi hàn pé a fi ìmọrírì rántí gbogbo ohun tí ìrúbọ Jésù túmọ̀ sí fún wa ni nípa sísọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run wa, Jèhófà, àti àwọn ìbùkún tí ìṣàkóso Ìjọba nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ yóò mú wá.—Sm. 79:13; 147:1.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́