ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/98 ojú ìwé 1
  • Ẹ̀yin Ọmọ—Ẹ̀yin Ni Ìdùnnú Wa!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀yin Ọmọ—Ẹ̀yin Ni Ìdùnnú Wa!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Gbé Àwọn Góńgó Tí Wàá Lépa ní Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn Tuntun Kalẹ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ẹ̀yin Èwe—Kí Ni Àwọn Góńgó Yín Nípa Tẹ̀mí?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Jẹ́ Kí Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tó O Ní Máa Múnú Rẹ Dùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 3/98 ojú ìwé 1

Ẹ̀yin Ọmọ—Ẹ̀yin Ni Ìdùnnú Wa!

1 Ẹ̀yin ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin, ẹ ha mọ̀ nípa àṣẹ Jèhófà pé kí ẹ máa lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ bí? (Diu. 31:12; Sm. 127:3) Inú wa mà máa ń dùn o bí ẹ bá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wa bí a ti ń jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀! Ẹ ń mú ọkàn-àyà wa yọ̀ nígbà tí ẹ bá jókòó jẹ́ẹ́ ní àwọn ìpàdé tí ẹ sì ń fetí sílẹ̀ dáadáa. Ó ń mú wa láyọ̀ ní pàtàkì nígbà tí ẹ bá gbìyànjú láti dáhùn ní àwọn ọ̀rọ̀ ti ara yín. Inú gbogbo ìjọ máa ń dùn nígbà tí ẹ bá ṣe àwọn apá tí a yàn fún yín nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, nígbà tí ẹ bá fi ìháragàgà dara pọ̀ mọ́ wa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, àti nígbà tí a bá gbọ́ pé ẹ fi ìgboyà jẹ́rìí fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ yín àti àwọn olùkọ́ yín.—Sm. 148:12, 13.

2 A fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé a ń fi yín yangàn nígbà tí a bá rí ànímọ́ rere yín, ìrísí mímọ́ tóní yín, ìwà mímọ́ yín, àti ọ̀wọ̀ tí ẹ ní fún àwọn àgbàlagbà. Ìdùnnú wa máa ń ga lọ́lá ní pàtàkì nígbà tí ẹ bá fi hàn pé ẹ ‘ń rántí Ẹlẹ́dàá yín Atóbilọ́lá’ nípa gbígbé àwọn góńgó ìṣàkóso Ọlọ́run kalẹ̀ fún ara yín.—Oníw. 12:1; Sm. 110:3.

3 Ẹ Sọ Àwọn Góńgó Yín fún Wa: Ọmọdékùnrin ọlọ́dún mẹ́jọ kan sọ fún alábòójútó àgbègbè kan pé: ‘Lákọ̀ọ́kọ́ ná, màá fẹ́ láti ṣe batisí, lẹ́yìn náà, màá fẹ́ láti sìn nínú ìjọ nípa ṣíṣèrànwọ́ níbi ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ àti bíbójútó gbohùngbohùn, nípa jíjẹ́ olùbójútó èrò, nípa ṣíṣèrànwọ́ nídìí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, nípa kíka ìwé ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àti ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Lẹ́yìn náà, màá fẹ́ láti jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí n sì di alàgbà. Màá tún fẹ́ láti jẹ́ aṣáájú ọ̀nà kí n sì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ aṣáájú ọ̀nà. Lẹ́yìn náà, màá fẹ́ láti lọ sí Bẹ́tẹ́lì, láti jẹ́ alábòójútó àyíká tàbí alábòójútó àgbègbè.’ Ẹ wo ìmọrírì àtàtà tí òun fi hàn fún àǹfààní sísin Ọlọ́run!

4 Bí ẹ ti ń tẹ̀ síwájú nípa ti ara àti nípa ti ẹ̀mí, a láyọ̀ láti rí yín tí ẹ ń lé àwọn góńgó yín bá. (Fi wé Lúùkù 2:52.) Lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún yín ń di akéde tí kò tíì ṣe batisí, lẹ́yìn náà ẹ sì ń tóótun fún batisí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́. Ìdùnnú wa ń pọ̀ sí i nígbà tí a bá tún rí yín tí ẹ ń nàgà fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, tí ẹ tilẹ̀ tún ń wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ní tòótọ́, ẹ̀yin ọmọ, ẹ̀yin ni ìdùnnú wa, ẹ sì jẹ́ àgbàyanu orísun ìyìn fún Baba wa ọ̀run. Ǹjẹ́ kí Jèhófà bù kún yín ní jìngbìnnì!—Òwe 23:24, 25.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́