Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún March
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 2
Orin 3
8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: “Ẹ Máa Ṣe Èyí ní Ìrántí Mi.” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà. Sọ̀rọ̀ ní ṣókí lórí ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 80 àti 81, tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì wíwá sí Ìṣe Ìrántí.
22 min: “Gbin Ìrètí Ìyè Àìnípẹ̀kun Sínú Àwọn Ẹlòmíràn.” Ìjíròrò àpilẹ̀kọ pẹ̀lú àwùjọ. Ṣàlàyé ní ṣókí nípa bí a ṣe lè lo àwọn ìbéèrè lọ́nà gbígbéṣẹ́ láti máa bá ìjíròrò nìṣó. Sọ àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ nípa àwọn ìbéèrè atọ́ka àti ìbéèrè èrò olúwarẹ̀ tí a lè lò nínú ìjíròrò kan. (Wo Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ojú ìwé 52 àti 53, ìpínrọ̀ 10 sí 12.) Jẹ́ kí akéde kan tí ó dáńgájíá ṣàṣefihàn ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ ní ìgbà àkọ́kọ́ pa pọ̀ pẹ̀lú ìpadàbẹ̀wò, kí ó fi bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan hàn.
Orin 88 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 9
Orin 60
8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ké sí gbogbo olùfìfẹ́hàn láti wá sí ọ̀rọ̀ àsọyé àkànṣe ní March 29. A pe àkọlé ọ̀rọ̀ àsọyé náà ní “Ìdí Tí O Fi Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé Bíbélì.”
15 min: Àwọn kókó ìtẹnumọ́ nínú Ìwé Pẹlẹbẹ Tuntun náà, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ nípa àwọn ìdí tí ó fi yẹ kí a ṣàgbéyẹ̀wò Bíbélì. A ṣe ìwé pẹlẹbẹ yìí láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ pé wọ́n lè jẹ́ ọ̀mọ̀wé gidigidi, ṣùgbọ́n tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Bíbélì. Dípò kí ìwé pẹlẹbẹ náà gbìyànjú láti mú un dá wọn lójú pé Ọlọ́run ni ó mí sí Bíbélì, ó jẹ́ kí àwọn òkodoro òtítọ́ sọ̀rọ̀ fúnra wọn. Ó yẹ kí a kà á, kí a sì ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, títí kan àwọn tí a ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́.
22 min: “Ṣé A Óò Ṣe É Lẹ́ẹ̀kan Sí I?” (Ìpínrọ̀ 1 sí 11) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Sọ àwọn kókó pàtàkì ìgbétáásì ọdún tó kọjá ti ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí a ṣe ròyìn rẹ̀ nínú ìwé 1998 Yearbook. Mẹ́nu kan iye àwọn tí ó ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nínú ìjọ ní àkókò yẹn. Jíròrò àwọn àǹfààní ojú ẹsẹ̀ tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ń rí láti inú ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà, sì fi hàn bí àfikún ìsapá yìí ṣe ń fi kún ìtẹ̀síwájú ìjọ. Sọ àwọn ìṣètò iṣẹ́ ìsìn tí a ń wéwèé nínú ìjọ fún oṣù April àti May láti ṣèrànwọ́ fún púpọ̀ sí i láti ṣe aṣáájú ọ̀nà. Àwọn akéde lè gba àwọn ìwé ìwọṣẹ́ lẹ́yìn ìpàdé.
Orin 195 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 16
Orin 43
8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: Àìní àdúgbò.
22 min: “Ṣé A Óò Ṣe É Lẹ́ẹ̀kan Sí I?” (Ìpínrọ̀ 12 sí 19) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí ìtóótun tí a fi hàn nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 113 àti 114. Ṣàlàyé bí ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ṣe ń múra ẹni sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà déédéé. Ké sí àwọn mélòó kan tí wọ́n ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lọ́dún tó kọjá láti sọ bí wọ́n ṣe ṣe ètò wọn láti dójú ìlà 60 wákàtí tí a béèrè fún. Èwo nínú àpẹẹrẹ ìṣètò tí ó wà ní ojú ìwé tí ó kẹ́yìn àkìbọnú yìí ni ó ṣiṣẹ́ fún wọn lọ́nà tí ó dára jù lọ? Bí àkókò bá ṣe wà tó, sọ àwọn ìrírí inú ìwé 1987 Yearbook, ojú ìwé 48 àti 49, 245 àti 246. Fún àwọn akéde níṣìírí láti gba ìwé ìwọṣẹ́ lẹ́yìn ìpàdé.
Orin 224 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 23
Orin 94
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Fún gbogbo ìjọ níṣìírí láti bẹ̀rẹ̀ sí ké sí àwọn olùfìfẹ́hàn sí Ìṣe Ìrántí ní April 11. Fi ẹ̀dà ìwé ìkésíni kan hàn, sì rọ gbogbo ìjọ láti gba àwọn ẹ̀dà kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pín wọn ní ọ̀sẹ̀ yìí. Kéde orúkọ gbogbo àwọn tí yóò ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù April. Ṣàlàyé pé kò tíì pẹ́ jù láti fi ìwé ìwọṣẹ́ sílẹ̀. Sọ gbogbo ìṣètò àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn tí a wéwèé fún oṣù April.
20 min: Múra Àwọn Ẹni Tuntun Sílẹ̀ fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá. Ọ̀rọ̀ àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Kí àwọn tí ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Ìmọ̀ ronú nípa mímúra àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn sílẹ̀ láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Tọ́ka sí ohun tí a sọ nínú ìwé Ìmọ̀, ojú ìwé 105 àti 106, ìpínrọ̀ 14, àti ojú ìwé 179, ìpínrọ̀ 20. Ṣàtúnyẹ̀wò ìlànà inú Ilé-Ìṣọ́nà, November 15, 1988, ojú ìwé 16 àti 17, ìpínrọ̀ 7 sí 10, fún àwọn ẹni tuntun láti di ẹni tí a kà sí akéde tí kò tíì ṣe batisí. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àbá inú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1996, ìpínrọ̀ 19, fún ríran àwọn akéde tuntun tí kò tíì ṣe batisí lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn.
15 min: Àpótí Ìbéèrè. Ìbéèrè àti ìdáhùn. Alàgbà ṣàtúnyẹ̀wò àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ inú ìwé Iṣetojọ Láti Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 130, ìpínrọ̀ 3 àti ojú ìwé 131, ìpínrọ̀ 1.
Orin 47 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 30
Orin 29
12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo ìjọ létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn fún oṣù March sílẹ̀. Fi àwọn ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ hàn, dábàá àwọn àpilẹ̀kọ tí o lè tẹnu mọ́ nígbà tí o bá ń fi wọ́n lọni, sì mẹ́nu kan àwọn kókó pàtó tí o lè sọ̀rọ̀ lé lórí. Ṣàyẹ̀wò “Àwọn Ìránnilétí Ìṣe Ìrántí,” kí o sì sọ ìṣètò tí a ti ṣe nínú ìjọ fún Ìṣe Ìrántí. Kí gbogbo àwùjọ parí ìwéwèé wọn láti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti wá. Rán gbogbo ìjọ létí láti rí i dájú pé wọ́n tẹ̀ lé ìṣètò Bíbélì kíkà fún Ìṣe Ìrántí fún April 6 sí 11, gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi hàn nínú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́.
13 min: “Ẹ̀yin Ọmọ—Ẹ̀yin Ni Ìdùnnú Wa!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Sọ ìrírí inú Ilé-Ìṣọ́nà, August 1, 1987, ojú ìwé 25.
20 min: Àwọn Ọ̀nà Láti Bá Àárẹ̀ Tẹ̀mí Jà. Alàgbà méjì jíròrò àpótí náà nínú Ilé-Ìṣọ́nà, May 15, 1986, ojú ìwé 19. Fún ọ̀kọ̀ọ̀kan “Awọn Ami-arun Àárẹ̀-líle,” fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé bí ẹnì kan ṣe lè jàǹfààní láti inú “Awọn Iranwọ-itilẹhin fun Ifarada” tí ó bára dọ́gba pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde méjì tí wọ́n sọ̀rọ̀ lórí bí fífi irú àwọn kókó bẹ́ẹ̀ sílò ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa bá a lọ láti ní okun nípa tẹ̀mí.
Orin 140 àti àdúrà ìparí.