Jíjẹ́rìí fún Àwọn Ènìyàn Láti Inú Gbogbo Èdè àti Ẹ̀sìn
1 Àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní fi ìtara jẹ́rìí fún àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ èdè mìíràn tí wọ́n sì ń ṣe onírúurú ẹ̀sìn. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, “nígbà tí ó fi máa di ọdún 100 ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé gbogbo ẹkùn tí ó bá Mẹditaréníà pààlà ni ó ní àwùjọ àwọn Kristẹni tí ń gbé nínú rẹ̀.”—Ìwé History of the Middle Ages.
2 Ní Nàìjíríà, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń sọ àwọn èdè tí ó yàtọ̀ sí Gẹ̀ẹ́sì. Ogunlọ́gọ̀ sì ń ṣe onírúurú ẹ̀sìn. Nítorí àwọn èdè àti ìsìn tí wọ́n jẹ́ onírúurú yìí, ó jẹ́ ìpèníjà gan-an láti mọ bí a ṣe lè bá gbogbo irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ jíròrò kí a sì jẹ́rìí fún wọn nígbà tí a bá bá wọn pàdé. Nítorí èyí, a lè ní ìpínlẹ̀ àwọn tí ń sọ èdè àjèjì ní àdúgbò wa. Báwo ni a ṣe lè pa àṣẹ Jésù mọ́ “láti wàásù fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná” fún àwọn ènìyàn gbogbo èdè àti ẹ̀sìn?—Ìṣe 10:42.
Jíjẹ́rìí fún Àwọn Ènìyàn Tí Ń Sọ Èdè Mìíràn
3 Bíborí Ìṣòro Èdè: Kò sí iyèméjì pé púpọ̀ ènìyàn tètè máa ń kẹ́kọ̀ọ́ tí ó sì máa ń yé wọn dáadáa nígbà tí a bá kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ní èdè ìbílẹ̀ tiwọn. “Nítorí ìhìn rere” àti kí wọ́n “lè di alájọpín nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn,” ọ̀pọ̀ arákùnrin àti arábìnrin ti kọ́ èdè mìíràn. (1 Kọ́r. 9:23) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé obìnrin kan tí ń sọ èdè China ti ń gba ìwé ìròyìn déédéé lọ́wọ́ arábìnrin kan tí ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, obìnrin náà kọ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a fi lọ̀ ọ́ títí di ìgbà tí arábìnrin mìíràn, tí ń kọ́ èdè China, fi ìwé kan lọ̀ ọ́ ní èdè yẹn. Ó fi ìmúratán tẹ́wọ́ gbà á àti ìkẹ́kọ̀ọ́. Ohun tí ó mú ìyàtọ̀ náà wá ni ìsapá arábìnrin kejì láti sọ ọ̀rọ̀ díẹ̀ ní èdè obìnrin náà.—Fi wé Ìṣe 22:2.
4 Fún ìdí rere ni Ilé-Ìṣọ́nà November 1, 1992, fi ṣe àlàyé yìí pé: “Kìí ṣe pe kíkọ́ èdè ajeji kan yoo mú ki agbara ero-ori awọn ọ̀dọ́ dagbasoke nikan ni ṣugbọn yoo tun mú ki wọn tubọ wulo fun eto-ajọ Jehofa.” Ọ̀pọ̀ lára àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aláápọn ti kíkọ́ èdè tuntun kan. Lọ́nà yìí, àwọn arákùnrin ti wúlò ní pàtàkì ní àwọn ìjọ tí a ti nílò wọn láti mú ipò iwájú. Bí o bá gbọ́ èdè mìíràn tàbí bí o bá fẹ́ láti kọ́ ọ, ó lè ṣeé ṣe fún ìwọ pẹ̀lú láti ṣèrànwọ́ fún ìjọ tàbí àwùjọ kan tí ń sọ èdè àjèjì.—Mát. 9:37, 38.
5 Arákùnrin kan ní Florida, U.S.A., tí ó ti kọ́ èdè Vietnam kí ó tó wá sínú òtítọ́ ń rí ìdùnnú ńlá nísinsìnyí nínú ṣíṣàjọpín ìhìn rere náà pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sọ èdè Vietnam. Láti túbọ̀ mú ara rẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti lo ìmọ̀ rẹ̀ nínú èdè yẹn fún jíjẹ́rìí, ó kó ìdílé rẹ̀ lọ sí ìgbèríko níbi tí àìní púpọ̀ wà nínú pápá àwọn ará Vietnam. Láti ìgbà tí ó ti kó lọ, ó ń ṣàṣeyọrí nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Vietnam.
6 Arábìnrin aṣáájú ọ̀nà kan ní California, U.S.A., pàdé ọ̀pọ̀ adití nínú ìpínlẹ̀ rẹ̀. Ó gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà láti rí ẹnì kan tí yóò kọ́ òun ní èdè àwọn adití kí òun lè kọ́ wọn ní òtítọ́. Lọ́jọ́ kan, nígbà tí ó ń rajà ní ilé ìtajà ńlá kan ní àdúgbò, ọ̀dọ́bìnrin adití kan tọ̀ ọ́ wá, ó kọ ìwé pélébé kan tí ó fi ń béèrè fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ láti bá òun wá ọjà kan. Lẹ́yìn tí ó ti ràn án lọ́wọ́ láti rí i, aṣáájú ọ̀nà náà kọ ìwé pélébé kan tí ń fi ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ hàn láti kọ́ èdè àwọn adití kí òun lè ran àwọn adití tí ń bẹ ní àgbègbè náà lọ́wọ́. Nígbà náà ni obìnrin adití náà kọ̀wé, ó béèrè pé: “Èé ṣe tí o fi fẹ́ ran àwọn adití lọ́wọ́?” Arábìnrin náà kọ̀wé padà pé: “Mo jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì fẹ́ ran àwọn adití lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye Bíbélì. Inú mi yóò dùn láti kọ́ ọ ní Bíbélì bí ìwọ yóò bá kọ́ mi ní èdè àwọn adití.” Arábìnrin náà sọ pé: “Ìdùnnú mi kọyọyọ nígbà tí ó sọ pé ‘Ó dára.’” Arábìnrin náà ń lọ sí ilé obìnrin náà ní gbogbo ìrọ̀lẹ́ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́fà. Ó kọ́ èdè àwọn adití, obìnrin adití náà sì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó sì ṣe batisí! Ìyẹn ṣẹlẹ̀ ní 30 ọdún sẹ́yìn, arábìnrin aṣáájú ọ̀nà náà ṣì ń jẹ́rìí fún àwọn adití, nísinsìnyí ó ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ tí ń lo èdè àwọn adití.
7 Bí èdè mìíràn bá yọ̀ mọ́ ọ lẹ́nu tí o sì ní ìfẹ́-ọkàn láti ṣí lọ sí ibi tí àìní ti pọ̀ ní pápá yẹn, tí ó sì ṣeé ṣe fún ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀, èé ṣe tí o kò fi jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú àwọn alàgbà nínú ìjọ rẹ. Bí wọ́n bá rò pé o tóótun láti ṣí lọ, béèrè lọ́wọ́ alábòójútó àyíká bí àgbègbè kan bá wà tí o ti lè sìn nítòsí. Bí kò bá sí, o lè kọ̀wé sí Society, ìyẹn bí àwọn alàgbà bá fi lẹ́tà tí ó sọ ojú ìwòye wọn nípa ìtóótun rẹ àti èdè tí o mọ̀ dáadáa ránṣẹ́ pẹ̀lú tìrẹ.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà ti August 15, 1988, ojú ìwé 21 sí 23.
8 Lílo Àwọn Ohun Èlò Tí A Pèsè: Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa wà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè Nàìjíríà àti ní àwọn èdè àjèjì. Yóò dára bí o bá ń kó àwọn ìwé àṣàrò kúkurú tàbí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè dání ní àwọn èdè tí àwọn ènìyàn ń sọ ní ìpínlẹ̀ rẹ. Bí ó bá hàn gbangba pé Gẹ̀ẹ́sì kì í ṣe èdè tí onítọ̀hún ń sọ, béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa èdè tí ó mọ̀ ọ́n kà. Èyí lè mú yíyàn rẹ pọ̀ sí i nípa ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí o lè fi lọni. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan tí ń sọ èdè Urdu lè ka èdè Lárúbáwá pẹ̀lú.
9 Àní bí o kò bá lè sọ èdè ẹni tí o bá pàdé nínú ìgbòkègbodò ìjẹ́rìí rẹ pàápàá, ó ṣì lè ṣeé ṣe fún ọ láti wàásù ìhìn rere náà fún un. Lọ́nà wo? Nípa lílo ìwé kékeré Good News for All Nations. Ó ní ìhìn iṣẹ́ ṣókí tí a tẹ̀ ní èdè 59 nínú. Gẹ́gẹ́ bí ìtọ́ni tí ó wà ní ojú ewé 2 ìwé kékeré náà ti ṣàlàyé, lẹ́yìn tí o bá ti mọ èdè onílé náà, jẹ́ kí ó ka ìsọfúnni tí a tẹ̀ sí ojú ewé tí ó bá a mu nínú ìwé kékeré náà. Lẹ́yìn tí ó bá ti kà á, fi ìtẹ̀jáde kan hàn án ní èdè rẹ̀. Bí o kò bá ní ọ̀kan, fi ìtẹ̀jáde náà hàn án ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Sọ fún un pé ìwọ yóò gbìyànjú láti mú ẹ̀dà kan padà wá ní èdè rẹ̀. Béèrè orúkọ rẹ̀, kí o sì kọ ọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú àdírẹ́sì rẹ̀. Bóyá o lè fi ìsọfúnni náà ránṣẹ́ sí ìjọ tàbí àwùjọ tí ó sún mọ́tòsí jù lọ tí ń sọ èdè yẹn. Bí kò bá sí ẹnì kankan tí ń sọ èdè náà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti tẹ́wọ́ gba ìpèníjà náà, bóyá kí o máa bá ẹni náà kẹ́kọ̀ọ́ pàápàá nípa fífojú bá a lọ nínú ìtẹ̀jáde ti Gẹ̀ẹ́sì.—1 Kọ́r. 9:19-23.
Jíjẹ́rìí fún Àwọn Ènìyàn Tí Kì Í Ṣe Ẹlẹ́sìn Kristẹni
10 Níní ìmọ̀ díẹ̀ nípa ipò àtilẹ̀wá ẹnì kan ní ti ìsìn ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́rìí nípa Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà tí ó gbéṣẹ́. Ìwé náà Mankind’s Search for God fún wa ní òye tí ó jinlẹ̀ nípa àwọn ẹ̀sìn kàǹkàkàǹkà lágbàáyé kí a lè ní òye tí ó pọ̀ tó nípa ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n ní ìmọ̀ òtítọ́.
11 Àpótí tí ó wà ní ojú ewé tí ó kẹ́yìn nínú àkìbọnú yìí fún wa ní àkọsílẹ̀ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa àwọn ìtẹ̀jáde tí ètò àjọ Jèhófà ti pèsè fún lílò wa láti jẹ́rìí fún àwọn ènìyàn tí kì í ṣe Kristẹni. Nípa kíka àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí, a óò mọ bí a ṣe lè mú ìhìn rere náà tọ àwọn ènìyàn lọ. Kí a má ṣe gbàgbé pé ìwé Reasoning jẹ́ ohun èlò tí ó wúlò. Ojú ewé 21 sí 24 ìwé yẹn pèsè àwọn àbá tí ó gbéṣẹ́ lórí bí a ṣe lè dá àwọn ẹlẹ́sìn Búdà, Híńdù, Júù, àti Mùsùlùmí lóhùn.
12 Ṣíṣọ́ra Nípa Ohun Tí Ìwọ Yóò Sọ: A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí a má ṣe ní èrò òdì nípa àwọn ẹlẹ́sìn kan nípa dídé ìparí èrò náà pé ìgbàgbọ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú tí àwọn mìíràn tí ó jẹ́ ẹlẹ́sìn yẹn. Dípò bẹ́ẹ̀, sakun láti mọ bí ẹni tí ìwọ ń bá sọ̀rọ̀ ṣe ń ronú. (Ìṣe 10:24-35) Salimoon tí ó jẹ́ Mùsùlùmí ní a fi ìgbàgbọ́ pé Kùránì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ dàgbà. Ṣùgbọ́n kò fi gbogbo ara tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ Mùsùlùmí pé Ọlọ́run aláàánú gbogbo yóò dá àwọn ènìyàn lóró nínú hẹ́ẹ̀lì tí ń jó rí. Lọ́jọ́ kan, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ké sí i wá sí ìpàdé. Kíá ni ó rí òtítọ́, ó sì ń sìn tayọ̀tayọ̀ gẹ́gẹ́ bí alàgbà nísinsìnyí nínú ìjọ Kristẹni.
13 Nígbà tí a bá ń jẹ́rìí fún àwọn tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn Kristẹni, ó yẹ kí a ṣọ́ra kí ọ̀nà ìyọsíni wa má bàa jẹ́ kí a pàdánù àǹfààní láti jíròrò ìhìn rere náà pẹ̀lú wọn. (Ìṣe 24:16) Àwọn ẹlẹ́sìn kan máa ń tètè bínú gan-an nípa ìgbìdánwò èyíkéyìí láti yí wọn padà kúrò nínú ìgbàgbọ́ wọn. Nítorí náà, wà lójúfò sí wíwá àwọn kókó ọ̀rọ̀ tí ẹ óò jọ fohùn ṣọ̀kan lé lórí kí o lè mú kí wọ́n wá mọ gbogbo òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn ẹni bí àgùntàn yóò dáhùn padà sí ìyọsíni onínúure, àti gbígbé òtítọ́ kalẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe kedere.
14 Ó tún ṣe pàtàkì pé kí a gbé àwọn ọ̀rọ̀ tí a óò sọ yẹ̀ wò, kí a má bàa mú kí àwọn ènìyàn yẹra fún ìhìn iṣẹ́ wa láìnídìí. Bí àpẹẹrẹ, bí o bá fi ara rẹ hàn lójú ẹsẹ̀ pé Kristẹni ni ọ́, ẹni tí ń fetí sí ọ lè wulẹ̀ rò pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù, èyí tí ó lè fa ìdènà. Ó tún lè ṣàǹfààní láti pe Bíbélì ní “Ìwé Mímọ́.”—Mát. 21:42.
15 Bí o bá bá ẹnì kan tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn Kristẹni pàdé tí o sì rò pé o kò gbára dì tó láti jẹ́rìí fún un lójú ẹsẹ̀, lo àǹfààní náà láti wulẹ̀ di ojúlùmọ̀ rẹ̀, fi ìwé àṣàrò kúkurú kan sílẹ̀, kí ẹ sì gba orúkọ ara yín. Lẹ́yìn náà, padà ní ọjọ́ kan tàbí méjì, lẹ́yìn tí o bá ti múra dáadáa láti jẹ́rìí fún un.—1 Tím. 4:16; 2 Tím. 3:17.
16 Jíjẹ́rìí fún Àwọn Ẹlẹ́sìn Búdà: (Wo àkòrí 6 nínú ìwé Mankind’s Search for God.) Ìgbàgbọ́ àwọn ẹlẹ́sìn Búdà yàtọ̀ gan-an láti ọ̀dọ̀ mẹ́ńbà ìsìn náà kan sí òmíràn. Dípò ṣíṣe alágbàwí wíwà Ẹlẹ́dàá tí ó jẹ́ ẹni gidi, àwọn ẹlẹ́sìn Búdà gbà pé ọkùnrin ará Íńdíà náà, Búdà Gautama, ti ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa, jẹ́ àwòkọ́ṣe pípé ní ti ìsìn. Nígbà tí Gautama kọ́kọ́ rí ọkùnrin aláìsàn kan, arúgbó kan, àti ọkùnrin kan tí ó ti kú, ó kérora nípa ìtumọ̀ ìgbésí ayé. Ó ṣe kàyéfì pé: ‘A ha bí ènìyàn kí ó wulẹ̀ jìyà, kí ó di arúgbó, kí ó sì kú bí?’ Dájúdájú, a lè dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn fún àwọn ẹlẹ́sìn Búdà aláìlábòsí tí ó fẹ́ mọ àwọn ìdáhùn náà.
17 Nígbà tí o bá ń bá àwọn ẹlẹ́sìn Búdà sọ̀rọ̀, sọ kìkì àwọn ìhìn iṣẹ́ tí ń múni fojú sọ́nà fún rere àti àwọn òtítọ́ tí ó ṣe kedere tí a rí nínú ìwé tí ó ga lọ́lá jù lọ nínú gbogbo àwọn ìwé mímọ́, Bíbélì. Bíi ti àwọn ènìyàn mìíràn tí ó pọ̀ jù lọ, àwọn ẹlẹ́sìn Búdà ní ọkàn-ìfẹ́ tí ó mú hánhán nínú àlàáfíà, ìwà rere, àti ìgbésí ayé ìdílé, lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n sì máa ń fayọ̀ tẹ́wọ́ gba jíjíròrò àwọn kókó ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Èyí lè ṣamọ̀nà sí títẹnumọ́ tí ìwọ yóò tẹnu mọ́ Ìjọba náà gẹ́gẹ́ bí ojútùú tòótọ́ sí àwọn ìṣòro aráyé.
18 Ní àwọn àgbègbè olú ìlú mélòó kan ní United States, ọ̀pọ̀ àwọn ará China tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀sìn Búdà àti àwọn àbá èrò orí ti Ìlà Oòrùn mìíràn ni wọ́n ti rọ́ wá. Ọ̀pọ̀ nínú wọn jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí ń lọ sí yunifásítì ní United States. Nígbà tí arábìnrin kan ní Montana rí ọkùnrin ọmọ ilẹ̀ China kan ní ilé ìtajà àwọn èèlò oúnjẹ, ó fún un ní ìwé àṣàrò kúkurú kan ní èdè rẹ̀, ó sì fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́. Ó sọ pé: “Ṣé Bíbélì Mímọ́ ni o ní lọ́kàn? Mo ti ń wá èyí kiri ní gbogbo ìgbésí ayé mi!” Ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀sẹ̀ yẹn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí gbogbo ìpàdé.
19 Fún ohun tí ó lé ní ẹ̀wádún, arábìnrin aṣáájú ọ̀nà kan ní Nevada ti ń fi òtítọ́ kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ilẹ̀ China. Nígbà tí ó ń wàásù ní ilé oníbùgbé mẹ́jọ tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí ń gbé, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó ran òun lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ibùgbé kọ̀ọ̀kan. Láàárín ọ̀sẹ̀ méjì ó ti ń bá akẹ́kọ̀ọ́ kan ó kéré tán ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ibùgbé kọ̀ọ̀kan. Ọ̀nà ìyọsíni kan tí ó rí pé ó máa ń kẹ́sẹ járí dáadáa fún òun ni sísọ pé òun ti rí àníyàn kan tí ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́—gbogbo wọn ń fẹ́ àlàáfíà àti ayọ̀. Lẹ́yìn náà, òun yóò béèrè bóyá ìyẹn jẹ́ àníyàn tiwọn pẹ̀lú. Wọ́n máa ń fohùn ṣọ̀kan. Ó ń darí àfiyèsí wọn sí ìwé pẹlẹbẹ Lasting Peace and Happiness—How to Find Them, èyí tí a pète fún àwọn ará China. Lẹ́yìn kíkẹ́kọ̀ọ́ nígbà márùn-ún péré, akẹ́kọ̀ọ́ kan sọ fún un pé òun ti ń wá òtítọ́ kiri fún ìgbà pípẹ́, òun sì ti rí i nísinsìnyí.
20 Jíjẹ́rìí fún Àwọn Ẹlẹ́sìn Híńdù: (Wo àkòrí 5 nínú ìwé Mankind’s Search for God.) Ẹ̀sìn Híńdù kò ní ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ kan pàtó. Àbá èrò orí wọn lọ́jú pọ̀ gidigidi. Àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù gbà gbọ́ pé ọlọ́run àwọn tí ó ṣe pàtàkì, Brahman, jẹ́ mẹ́talọ́kan (Brahma Ẹlẹ́dàá, Vishnu Olùdáàbòbò, àti Siva Olùpanirun). Ìgbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn ṣe pàtàkì nínú ẹ̀kọ́ wọn nípa àtúnwáyé, èyí tí ó máa ń jẹ́ kí àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù ní ojú ìwòye àyànmọ́. (Wo ìwé Reasoning, ojú ìwé 317 sí 321, àti Ilé Ìṣọ́, May 15, 1997, ojú ìwé 3 sí 8.) Ẹ̀sìn Híńdù ń fi ìráragba-nǹkan-sí kọ́ni, pé gbogbo ẹ̀sìn ń sinni lọ sí òtítọ́ kan náà.
21 Ọ̀nà tí a óò gbà jẹ́rìí fún ẹlẹ́sìn Híńdù kan ni láti ṣàlàyé ìrètí wa tí a gbé karí Bíbélì ti gbígbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn pípé àti àwọn ìdáhùn títẹ́ni lọ́rùn tí Bíbélì fúnni sí àwọn ìbéèrè pàtàkì tí ó dojú kọ gbogbo aráyé.
22 Jíjẹ́rìí fún Àwọn Ẹlẹ́sìn Júù: (Wo àkòrí 9 nínú ìwé Mankind’s Search for God.) Láìdàbí àwọn ẹ̀sìn mìíràn tí kì í ṣe ti Kristẹni, ẹ̀sìn àwọn Júù ni a gbé karí ọ̀rọ̀-ìtàn, a kò gbé e karí ìtàn àròsọ. Nípasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí a mí sí, ìsopọ̀ pàtàkì kan ni a pèsè nípa bí aráyé ṣe ń wá Ọlọ́run tòótọ́ kiri. Síbẹ̀, ní ìtakora pẹ̀lú ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí, lájorí ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn àwọn Júù òde òní ni ìgbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn ẹ̀dá ènìyàn. Kókó ìfohùnṣọ̀kan ni a lè gbé kalẹ̀ nípa sísọ pé àwa náà ń jọ́sìn Ọlọ́run Ábúráhámù àti nípa gbígbà pé a ń dojú kọ àwọn ìṣòro kan náà nínú ayé lónìí.
23 Bí o bá pàdé Júù kan tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, bíbéèrè tí o bá béèrè bóyá òun ti fìgbà gbogbo ronú bẹ́ẹ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tí yóò fà á mọ́ra jù lọ. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máà tí ì gbọ́ àlàyé tí ó tẹ́ni lọ́rùn rí nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà. Àwọn Júù aláìlábòsí ni a lè fún níṣìírí láti tún ṣàyẹ̀wò ohun tí a fi dá Jésù mọ̀ gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà, kì í ṣe nípasẹ̀ bí àwọn Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe fi í hàn lọ́nà òdì, ṣùgbọ́n lọ́nà tí àwọn Júù tí ó kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì gbà fi í hàn.
24 Jíjẹ́rìí fún Àwọn Mùsùlùmí: (Wo àkòrí 12 nínú ìwé Mankind’s Search for God.) Àwọn Mùsùlùmí jẹ́ ẹlẹ́sìn Ìsìláàmù (tàbí, ẹlẹ́sìn Mọ̀ọ́mọ́dù), èyí tí ó ní nínú, ìgbàgbọ́ nínú Álà gẹ́gẹ́ bí ọlọ́run àjúbàfún kan ṣoṣo tí wọ́n ní àti nínú Mọ̀ọ́mọ́dù (ọdún 570 sí 632 Sànmánì Tiwa) gẹ́gẹ́ bí wòlíì rẹ̀ tí ó kẹ́yìn tí ó sì ṣe pàtàkì jù lọ. Nítorí pé wọn kò gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ní ọmọ, àwọn Mùsùlùmí gbà pé Jésù Kristi jẹ́ wòlíì rírẹlẹ̀ kan fún Ọlọ́run, kò jù bẹ́ẹ̀ lọ. Kùránì, tí kò tí ì pé 1,400 ọdún, tọ́ka sí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Lédè Gíríìkì. Àwọn ìjọra púpọ̀ wà láàárín ẹ̀sìn Ìsìláàmù àti ti Kátólíìkì. Àwọn ẹ̀sìn méjèèjì ń kọ́ni ní àìleèkú ọkàn ẹ̀dá ènìyàn, ipò ìdánilóró fún ìgbà díẹ̀, àti wíwà hẹ́ẹ̀lì tí iná ti ń jó.
25 Kókó ìfohùnṣọ̀kan tí ó hàn kedere pé a ní, ni ìgbàgbọ́ wa pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ni ó wà àti pé òun ni ó mí sí Bíbélì. Ẹni tí ó bá fara balẹ̀ ka Kùránì yóò ti rí àwọn ìtọ́ka sí Tórà, Sáàmù, àti Ìhìn Rere gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, yóò sì ti kà á pé a ní láti gbà pé ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ kí a sì ṣègbọràn sí i. Nítorí náà, o lè fi kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwọ̀nyí lọ ẹni náà.
26 Ìgbékalẹ̀ yìí lè ṣiṣẹ́ fún ẹnì kan tí ó sọ pé òun jẹ́ Mùsùlùmí: “N kò tí ì bá Mùsùlùmí púpọ̀ sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n mo ti ka nǹkan kan nípa díẹ̀ lára ohun tí ẹ̀sìn rẹ fi ń kọ́ni nínú ìwé yìí. [Ṣí ìwé Reasoning sí ojú ewé 24.] Ó sọ pé ẹ gbà gbọ́ pé Jésù jẹ́ wòlíì ṣùgbọ́n pé Mọ̀ọ́mọ́dù ni wòlíì tí ó kẹ́yìn tí ó sì ṣe pàtàkì jù lọ. Ǹjẹ́ o gbà gbọ́ pẹ̀lú pé Mósè jẹ́ wòlíì tòótọ́? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ṣé kí n fi ohun tí Mósè kọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípa orúkọ Rẹ̀ hàn ọ́?” Lẹ́yìn náà, ka Ẹ́kísódù 6:2, 3. Nígbà ìpadàbẹ̀wò, o lè jíròrò ìsọ̀rí “Ọlọrun Kan, Isin Kan,” ní ojú ewé 14 nínú ìwé kékeré Akoko fun Ijuwọsilẹ-tẹriba Tootọ fun Ọlọrun.
27 Lónìí, ọ̀pọ̀ ń gbé ìgbésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Aísáyà 55:6, èyí tí ó kà pé: “Ẹ wá Jèhófà, nígbà tí ẹ lè rí i. Ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.” Èyí kan gbogbo àwọn olótìítọ́ inú, láìka èdè tí wọ́n ń sọ tàbí ipò àtilẹ̀wá wọn ní ti ìsìn sí. A lè ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà yóò bù kún àwọn ìsapá wa bí a ti ń sakun láti lọ kí a sì “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.”—Mát. 28:19.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ tí A Pète fún Àwọn tí Kì Í Ṣe Kristẹni
Àwọn Ẹlẹ́sìn Búdà
In Search of a Father (Ìwé kékeré)
“Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun” (Ìwé pẹlẹbẹ)
Àwọn Ará China
Lasting Peace and Happiness—How to Find Them (Ìwé pẹlẹbẹ)
Àwọn Ẹlẹ́sìn Híńdù
From Kurukshetra to Armageddon—And Your Survival (Ìwé kékeré)
Our Problems—Who Will Help Us Solve Them? (Ìwé pẹlẹbẹ)
The Path of Divine Truth Leading to Liberation (Ìwé kékeré)
Victory Over Death—Is It Possible for You? (Ìwé kékeré)
Why Should We Worship God in Love and Truth? (Ìwé pẹlẹbẹ)
Àwọn Júù
A Peaceful New World—Will It Come? (Ìwé àṣàrò kúkurú No. 17)
Jehovah’s Witnesses—What Do They Believe? (Ìwé àṣàrò kúkurú No. 18)
Will There Ever Be a World Without War? (Ìwé pẹlẹbẹ)
Àwọn Mùsùlùmí
Bí A Ṣe Lè Rí Ọ̀nà Sí Paradise (Ìwé àṣàrò kúkurú)
Akoko fun Ijuwọsilẹ-tẹriba Tootọ fun Ọlọrun (Ìwé kékeré)