Lo Ìwé Ìléwọ́ Lọ́nà Rere
1 Ìwé ìléwọ́ ìjọ wúlò fún sísọ àdírẹ́sì Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn àkókò gan-an tí a ń ṣe ìpàdé fún àwọn ènìyàn ní àdúgbò. Yóò dára láti fi ọ̀kan fún ẹnì kọ̀ọ̀kan tí o bá bá pàdé. Nítorí èyí, ó yẹ kí ìjọ kọ̀ọ̀kan ní ìwé ìléwọ́ tí ó pọ̀ tó lọ́wọ́. Ní ti àwọn ìjọ tí ó máa ń yí àkókò ìpàdé padà lọ́dọọdún, ní January, kí wọ́n máa béèrè fún ìwé ìléwọ́ tuntun ní October tí ó ṣáájú ìgbà náà lọ́dọọdún kí wọ́n lè máa ní èyí tí ó ní àkókò ìpàdé ti lọ́ọ́lọ́ọ́ nínú nígbà gbogbo. Fọ́ọ̀mù Handbill Request ni kí a lò fún ète yìí. Bí ẹ bá ti wá rí wọn gbà, báwo ni a ṣe lè lo ìwé ìléwọ́ lọ́nà tí ó ṣàǹfààní jù lọ?
2 Ọ̀pọ̀ àwọn akéde rí i pé fífún ẹnì kan ní ọ̀kan jẹ́ ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́ láti sọ ẹni tí àwọn jẹ́ kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀. Títọ́ka sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé tàbí ìhìn iṣẹ́ tí ó wà ní òdì-kejì lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìjíròrò nípa iṣẹ́ wa àti ète rẹ̀. Àwọn òbí lè mú kí ọmọ wọn kéékèèké kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ nípa jíjẹ́ kí wọ́n fi ìwé ìléwọ́ lọni ní ẹnu ọ̀nà. Kí àwọn akéde tí wọ́n máa ń nípìn-ín nínú kíkọ lẹ́tà láti jẹ́rìí máa fi ìwé ìléwọ́ kan sínú lẹ́tà wọn kí wọ́n sì ké sí ẹni náà láti wá sí àwọn ìpàdé. Bóyá a lè fi ìwé ìléwọ́ sílẹ̀ fún àwọn kò-sí-nílé, kìkì bí a bá lè rí i pé a fi wọ́n sábẹ́ ilẹ̀kùn, kí a má bàa rí wọn lóde rárá.
3 Ìwé ìléwọ́ ti wúlò gan-an ní dídarí àwọn aláìlábòsí ọkàn sínú òtítọ́. Ìrírí kan sọ nípa obìnrin kan tí ó ṣeé ṣe fún láti mú ìfẹ́-ọkàn tí ó ti ní tipẹ́tipẹ́ láti lóye Bíbélì ṣẹ, ọpẹ́lọpẹ́ ìwé ìléwọ́. Lẹ́yìn tí ó ti fi gbogbo òru gbàdúrà sí Ọlọ́run, tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan tẹ aago ilé rẹ̀ ní òwúrọ̀. Bí ó ṣe yọjú gba inú ihò ilẹ̀kùn rẹ̀, ó kígbe pé òun kò ní ṣílẹ̀kùn. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ti ìwé ìléwọ́ kan bọ abẹ́ ilẹ̀kùn rẹ̀. Ó kà pé: “Mọ Bíbélì Rẹ.” Ó rí i, ó sì ṣílẹ̀kùn. Ìkẹ́kọ̀ọ́ ni a bẹ̀rẹ̀ lójú ẹsẹ̀, ó sì ṣe batisí lẹ́yìn náà. Má ṣe fojú kéré agbára ẹ̀mí Ọlọ́run láé, ǹjẹ́ kí a máa lo ìwé ìléwọ́ déédéé lọ́nà rere bí a ṣe ń ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.