Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Ọjọ́ Àpéjọ Àkànṣe
‘Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo Nítorí Ìhìn Rere’ ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ tuntun fún ọjọ́ àpéjọ àkànṣe tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní March. (1 Kọ́r. 9:23) Ìhìn rere Ìjọba náà ni ìròyìn tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí a ń gbọ́ lónìí. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọrírì àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ tí a ní láti jẹ́ ẹni tí ń mú ìròyìn àgbàyanu yìí wá. Yóò tún fún wa ní ìgboyà láti máa bá a nìṣó ní pípolongo ìhín rere náà láìdábọ̀.—Ìṣe 5:42.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò fi hàn wá bí a ṣe lè lo ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí a ń rí gbà lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ kí a lè ṣàṣeparí ohun tí ó pọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. A óò gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn kan tí wọ́n ti ṣe àtúnṣe láti mú iṣẹ́ ìsìn wọn gbòòrò sí i, títí kan àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti mú ìhìn rere náà tẹ̀ síwájú.—Fi wé Fílípì 2:22.
Lájorí ọ̀rọ̀ àsọyé, tí olùbánisọ̀rọ̀ tí a óò gbà lálejò yóò sọ, yóò tẹnu mọ́ bí ó ṣe yẹ kí a máa bá a lọ láti “fi [ara wa] hàn ní ẹni tí ó yẹ kí a fi ìhìn rere sí ní ìkáwọ́.” (1 Tẹs. 2:4) A óò ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé bí a óò bá máa bá a lọ láti gbádùn àǹfààní ṣíṣàjọpín ìhìn rere náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti kúnjú àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè fún àti àwọn ìlànà rẹ̀ nínú ìrònú àti ìwà wa. A óò tún tẹnu mọ́ àwọn ìbùkún tí a ń rí gbà fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀.
Má ṣàìwá sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ pàtàkì yìí. Kí àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n fẹ́ láti ṣe batisí ní ọjọ́ àpéjọ àkànṣe fi tó alábòójútó olùṣalága létí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ké sí gbogbo àwọn tí o ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ láti wá. Kí a jẹ́ kí Jèhófà fún wa lókun láti ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí a sì tipa báyìí parí iṣẹ́ náà tí ó tóbi jù lọ kí Amágẹ́dọ́nì tó dé.