ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/98 ojú ìwé 8
  • Ní Ìdùnnú Nínú Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ní Ìdùnnú Nínú Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fi Òye Inú Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Dámọ̀ràn fún Lílò Lóde Ẹ̀rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ìmọ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ń Dáhùn Ọ̀pọ̀ Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àwọn Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí A Dábàá fún Lílò Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Pápá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 1/98 ojú ìwé 8

Ní Ìdùnnú Nínú Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná

1 Gbogbo wa ni a máa ń gbádùn ṣíṣe àwọn ohun tí a mọ̀ ọ́n ṣe dáradára. Máàkù 7:37 sọ pé àwọn ògìdìgbó polongo nípa Jésù pé: “Ó ti ṣe ohun gbogbo dáadáa.” Abájọ tí Jésù fi rí ìdùnnú nínú ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà! (Fi wé Orin Dá. 40:8.) Nípa ríronú nípa àwọn àbá tí ó tẹ̀ lé e yìí, àwa bákan náà yóò rí ayọ̀ bí a ti ń ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù “láti wàásù fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná.” (Ìṣe 10:42) Ní January, a óò máa fi ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí a tẹ̀ sóde ṣáájú 1985 tí ìjọ lè ní lọ́wọ́ tàbí ìwé Walaaye lọni. Báwo ni a ṣe lè lo àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí láti fi jẹ́rìí kúnnákúnná?

2 Níwọ̀n bí àwọn ènìyàn ti máa ń ṣàníyàn nípa àwọn ọ̀ràn ìlera, o lè sọ pé:

◼ “Láìka àṣeyọrí tí ó jọjú tí a ti ṣe ní pápá ìmọ̀ ìṣègùn sí, ìjìyà púpọ̀ wà nítorí àìsàn. Ní èrò tìrẹ, kí ló fà á tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Jésù Kristi sọ pé àjàkálẹ̀ àrùn yóò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tí yóò máa ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. (Lúùkù 21:11) Síbẹ̀, Bíbélì tún ṣàpèjúwe àkókò kan tí àìsàn kò ní sí mọ́. [Ka Aísáyà 33:24.] Kíyè sí bí ìwé yìí ṣe múni nírètí nínú ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti Bíbélì.” Fi àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá a mu hàn lákànṣe nínú ìwé tí o ń gbé jáde lákànṣe náà, kí o sì fi í lọni ní ẹ̀dínwó ₦40.

3 Nígbà tí o bá ń jẹ́rìí lọ́nà tí kò jẹ́ bí àṣà nítòsí àgbègbè tí a ti ń ṣe káràkátà, o lè kí ẹni náà kí o sì béèrè pé:

◼ “Lójú rẹ, ó ha dà bí pé àwọn nǹkan ń wọ́n sí i lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí débi pé ó ṣòro láti gbọ́ bùkátà bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] O ha rò pé àkókò èyíkéyìí tí a kò ní máa ráágó mọ́ yóò dé bí?” Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà, gbé àyọlò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó bá a mu jáde lákànṣe láti inú ìwé tí o ń fi lọni. Máa bá a nìṣó nípa sísọ pé: “Ìwé yìí fi hàn bí Ọlọ́run, nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀, yóò ṣe yanjú àwọn ìṣòro tí ó mú kí ìgbésí ayé ṣòro tó bẹ́ẹ̀ lónìí.” Fi ìwé náà lọni ní ẹ̀dínwó ₦40. O lè sọ bí o ṣe gbádùn ìjíròrò náà tó, kí o sì béèrè pé: “Ọ̀nà kankan ha wà tí a lè gbà máa bá ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ yí lọ ní àkókò míràn bí?” Ní ọ̀nà yí, yóò lè ṣeé ṣe fún ọ láti gba orúkọ ẹni náà àti àdírẹ́sì ilé rẹ̀.

4 O lè ní àǹfààní láti gbìyànjú ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ yí nípa àlàáfíà ayé, ní lílo ìwé “Walaaye”:

◼ “Ní èrò tìrẹ, kí ni ìdí tí ọwọ́ kò fi lè tẹ àlàáfíà ayé bọ̀rọ̀? [Jẹ́ kí ó fèsì, lẹ́yìn náà, fi àwòrán tí ó wà ní ojú ewé 20 àti 21 hàn án.] Àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ Bíbélì kan tí a ṣàpèjúwe nínú Ìṣípayá rèé. [Ka Ìṣípayá 12:7-9, 12 tààràtà láti inú ìpínrọ̀ 17. Lẹ́yìn náà, ka àkọlé tí ó bá àwòrán náà rìn.] Àìlálàáfíà ayé jẹ́ ọ̀kan lára àbáyọrí lílé tí a lé Èṣù sọ̀ kalẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé. Ìwé yìí dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè pàtàkì, inú mi sì dùn láti mú un wá fún ọ bí ìwọ yóò bá kà á.”—Láti rí ọ̀nà gbígbéṣẹ́ mìíràn láti fi ìwé Walaaye lọni, wo ojú ewé ẹ̀yìn ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1995, February 1995, September 1994, September 1993, àti August 1992.

5 Nígbà tí o bá ń pa dà sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n fi ìfẹ́ hàn, o lè sakun láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípa ṣíṣàmúlò ọ̀nà ìgbàyọsíni yìí bí ó ti yẹ:

◼ “Nígbà tí a jọ sọ̀rọ̀ kẹ́yìn, o sọ ohun kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra. [Mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ tí ẹni náà sọ.] Mo ti ń ronú nípa ìyẹn, èmi yóò sì fẹ́ láti ṣàjọpín àbájáde ìwádìí díẹ̀ tí mo ti ṣe lórí kókó ọ̀rọ̀ náà. [Ṣàjọpín ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó bá a mu.] A ń nawọ́ ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tí ó ti mú kí ó ṣeé ṣe fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn láti ṣàyẹ̀wò àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì ní sáà àkókò kúkúrú kan. Irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ lè fún ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ nínú ìmúṣẹ dídájú ti àwọn ìlérí Ọlọ́run lókun.” Tọ́ka sí àwọn ìbéèrè díẹ̀ tí a óò dáhùn. Bí ẹni náà bá kọ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣàlàyé pé a tún ní ètò ẹ̀kọ́ tí a mú yára kánkán lọ́nà àkànṣe tí ń gba kìkì ìṣẹ́jú 30 lọ́sẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ 16. Fi ìwé pẹlẹbẹ náà, Béèrè hàn, ṣí i sí ẹ̀kọ́ 1, kí o sì béèrè bí ó bá fẹ́ kí o ṣàṣefihàn ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́.

6 Rántí Láti Lo Àwọn Ìwé Ìléwọ́: O lè lò wọ́n lọ́nà gbígbéṣẹ́ nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ láti ru ìfẹ́ ọkàn sókè nínú àwọn ọ̀rọ̀ tẹ̀mí, o sì lè fi wọ́n sílẹ̀ bí a kò bá gba ìwé kankan. Ní ibi tí a bá ti fi ìfẹ́ hàn, lo ìhìn iṣẹ́ tí a tẹ̀ ní ojú ewé tí ó wà lẹ́yìn ìwé ìléwọ́ náà láti fún ẹni náà níṣìírí láti tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé kí ó sì wá sí àwọn ìpàdé wa.

7 Jẹ́ ọ̀jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì láyọ̀ nínú rẹ̀. Fiyè sí jíjẹ́rìí kúnnákúnná nígbà gbogbo kí o sì ní inú dídùn nínú ṣíṣe gbogbo onírúurú apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà dáradára.—1 Tím. 4:16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́