ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/98 ojú ìwé 7
  • Ṣíṣàìṣojúṣàájú Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣíṣàìṣojúṣàájú Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Wàásù fún Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Míì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Bí Onílé Bá Ń Sọ Èdè Tó Yàtọ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ǹjẹ́ Ò Ń Sọ “Èdè Mímọ́” Lọ́nà Tó Já Geere?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Bá A Ṣe Lè Kọ́kọ́ Wá Àwọn Èèyàn Ká Tó Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 1/98 ojú ìwé 7

Ṣíṣàìṣojúṣàájú Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa

1 “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú,” ni Pétérù sọ, ṣùgbọ́n “ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀ tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ni a ń ṣe lónìí pẹ̀lú ẹ̀kún rẹ́rẹ́ òye òtítọ́ tí a sọ ní kedere yẹn. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí a ṣe gbogbo ìsapá láti borí ìdènà èyíkéyìí tí yóò fawọ́ mímú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn sẹ́yìn.

2 Nígbà tí a bá ń wàásù láti ilé dé ilé ní àwọn agbègbè kan, kì í ṣe ohun àjèjì láti rí àwọn ènìyàn tí wọn kì í sọ èdè tí a ń lò nínú ìjọ wa, tí wọn kò sì lóye rẹ̀. Ìdènà èdè ń ṣèdíwọ́ fún àwọn kan láti má ṣe jàǹfààní ní kíkún nínú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà tí a ń wàásù rẹ̀. Lára àwọn wọ̀nyí ni àwọn adití wà, àwọn tí wọ́n ń báni sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ èdè adití. Kí ni a lè ṣe láti borí ìdènà èdè tí ń ṣèdíwọ́ fún wa láti mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ àwọn wọ̀nyí lọ́nà tí ó gbéṣẹ́?

3 Society ti fi ìpèsè fọ́ọ̀mù S-70a, Sign-Language Follow-up Slip, ránṣẹ́ sí gbogbo ìjọ ní Nàìjíríà. Ète ìwé pélébé yìí ni láti rí i dájú pé àwọn tí wọ́n ń lo èdè adití ni a fún ní àǹfààní láti gbọ́ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà ní èdè wọn.

4 Bí ìwọ kò bá lóye èdè adití tí o sì rí ẹnì kan nínú ìpínlẹ̀ yín tí ó jẹ́ adití, kí o kọ ọ̀rọ̀ kún ìwé pélébé náà ní ọ̀nà tí ó ṣeé kà. Èyí ni kí o ṣe àní bí ẹni náà kò bá tilẹ̀ fi ìfẹ́ hàn nínú òtítọ́ pàápàá. Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni yóò ṣeé ṣe fún ọ láti gba orúkọ ẹni náà, ṣùgbọ́n kọ àdírẹ́sì àti èdè tí ó gbọ́ sílẹ̀. O lè fi ìwé pélébé náà sínú àpótí ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Akọ̀wé yóò kó àwọn ìwé pélébé náà, yóò yẹ̀ wọ́n wò fún ìpépérépéré àti ìṣeékà, yóò sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Society tàbí sí ìjọ tí ó wà nítòsí jù lọ, tí a ti ń ṣògbufọ̀ èdè àwọn adití. Wọn yóò sakun láti yan ògbufọ̀ èdè àwọn adití kan láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ adití náà.

5 Bí kò bá sí aṣògbufọ̀ èdè adití tí ó sún mọ́ tòsí jù lọ láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ adití náà ńkọ́? Ní ọ̀nà yẹn, Society yóò ṣètò fún ìkọlẹ́tàránṣẹ́ sí adití náà, wọn yóò sì kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé ìtòlẹ́sẹẹsẹ orúkọ àwọn adití tí a ní. Òun lè wá kọ̀wé béèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì fún ìlò àwọn adití nípasẹ̀ ìjọ.

6 Ké sí wọn wá sí àwọn ìpàdé Kristẹni tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Ẹ máa gbapò fúnra yín láti jókòó ti àwọn adití. Ẹ máa ṣe àkọsílẹ̀ nígbà ìpàdé kí ẹ sì máa ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú adití tí ó jẹ́ olùfìfẹ́hàn. Ẹ ké sí wọn láti nípìn-ín nínú àwọn ìpàdé. Wọ́n lè kọ ọ̀rọ̀ ìdáhùn wọn lórí ìpínrọ̀ pàtó kí wọ́n sì jẹ́ kí ẹnì kan ka ìdáhùn wọn síta.

7 Kí tún ni àwọn alàgbà lè ṣe? Àwọn alàgbà lè yan ọ̀kan lára àwọn aṣáájú ọ̀nà tí ó túbọ̀ tóótun, tí ó ń fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ tìyárítìyárí láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ adití tí ó ń fi ìfẹ́ tí ó dára hàn. Bí adití náà bá jẹ́ ọ̀mọ̀wé, ó lè ṣeé ṣe láti kẹ́kọ̀ọ́, ní lílo ọ̀nà oníbébà-àti-ìkọ̀wé. Ó lè ṣeé ṣe fún àwọn kan láti ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ní lílo fídíò Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà. Àwọn mìíràn lè jàǹfààní láti inú kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹ́bẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!

8 Kí akéde kọ̀ọ̀kan wà lójúfò láti lo ìwé pélébé tí a fi ń ṣiṣẹ́ lórí ọkàn ìfẹ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti pọn dandan. Bí ìjọ kò bá ní ìpèsè fọ́ọmù S-70a lọ́wọ́, ìsọfúnni tí a béèrè fún ni a lè kọ sórí ìwé pélébé kan kí a sì fi í sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàpèjúwe lókè yí. Nípa lílo ìsapá tí a ṣe tọkàntọkàn láti mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn láìka èdè wọn sí, àwa yóò máa ṣàgbéyọ ìfẹ́ Ọlọ́run wa, Jèhófà, “ẹni tí ó jẹ́ ìfẹ́ inú rẹ̀ pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tím. 2:4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́