ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/98 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 1/98 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí a tẹ̀ sórí bébà tí ó máa ń di yẹ́lò tàbí tí ó máa ń di ràkọ̀ràkọ̀ tàbí èyíkéyìí tí a tẹ̀ ṣáájú 1985 ni a lè fi lọni ní ẹ̀dínwó ₦40. Bí ìjọ èyíkéyìí bá ní Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ lọ́wọ́, wọ́n lè fi ìtẹ̀jáde yìí lọni ní ẹ̀dínwó ₦40 pẹ̀lú. Àwọn ìwé olójú ewé 192 yòó kù tí a tẹ̀ jáde ṣáájú 1985 tí a tẹ̀ sórí bébà tí kì í ṣá tàbí tí kì í di ràkọ̀ràkọ̀ ni a kò gbọ́dọ̀ fi kún ìfilọni ẹlẹ́dìn-ínwó yìí. Ìfilọni àfidípò: Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia,” Isopọṣọkan ninu Ijọsin Ọlọrun Tootọ Kanṣoṣo Naa, Lilaaja Sinu Ilẹ-ayé Titun, True Peace and Security—How Can You Find It? ní ₦55, tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye (ẹ̀dà ńlá, ₦170; ẹ̀dà kékeré, ₦85). February: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Pọkàn pọ̀ sórí bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. April: Gbogbo èdè—Àsansílẹ̀-owó fún Ilé Ìṣọ́. ÀKÍYÈSÍ: Kí àwọn ìjọ tí yóò bá nílò àwọn ìwé ìgbétáásì tí a mẹ́nu kàn lókè yí béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.

◼ Gbogbo akéde tí ó ti ṣe batisí tí ó bá wà ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ January 5 ni a óò fún ní káàdì Advance Medical Directive/Release àti Identity Card (Káàdì Ìdánimọ̀) fún àwọn ọmọ wọn.

◼ Bẹ̀rẹ̀ ní February, tí kò sì ní kọjá March 1, ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni “Ìwọ Ha Ní Ojú Ìwòye Ọlọ́run Nípa Ìwàláàyè Bí?”

◼ Àsọyé àkànṣe fún gbogbo ènìyàn fún àkókò Ìṣe Ìrántí ọdún 1998 ni a óò sọ ní ọjọ́ Sunday, March 29. A óò pèsè ìlapa èrò. Àwọn ìjọ tí wọ́n bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká, tàbí ọjọ́ àpéjọ àkànṣe ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn yóò sọ àsọyé àkànṣe náà ní ọ̀sẹ̀ tí yóò tẹ̀ lé e. Kò sí ìjọ tí ó gbọ́dọ̀ sọ àsọyé àkànṣe náà ṣáájú March 29, 1998.

◼ Ó yẹ kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà mọ̀ pé àtúnṣe tí ó tẹ̀ lé e yìí pọn dandan nígbà tí ìjọ bá ń lọ sí àwọn àpéjọ: Nígbà tí a bá ṣètò fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ àpéjọ àkànṣe, ìjọ yóò ṣe àwọn ìpàdé tí wọ́n máa ń ṣe jálẹ̀ ọ̀sẹ̀, àyàfi ti pé wọ́n yóò wọ́gi lé Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Nígbà tí a bá ti ṣètò yín pé kí ẹ lọ sí àpéjọ àyíká, ìjọ yóò tún wọ́gí lé Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn; kìkì Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ nìkan ni ẹ óò ṣe nínú ìjọ ní ọ̀sẹ̀ yẹn.

◼ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti fọwọ́ sí i pé kí a ṣe àkànṣe ìgbétáásì kan láti mú ìwé Ayọ̀ Ìdílé dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbi gbogbo ní oṣù February. Kí a tún lo ẹ̀dà Jí! ti August 8, 1997, níbi tí ó bá ti wà. Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìgbétáásì yí, ní March 1998, ìjọ kọ̀ọ̀kan yóò gbé àkànṣe àwọn ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí ó dá lórí ìgbésí ayé ìdílé jáde lákànṣe. Kí alábòójútó olùṣalága ṣètò fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ọ̀rọ̀ àsọyé tí a óò lẹ̀ mọ́ ojú pátákó ìsọfúnni.

◼ Bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ May 4, 1998, tí yóò sì máá bá a lọ títí dé ọ̀sẹ̀ June 15, 1998, ìwé pẹlẹbẹ náà, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I? ni a óò máa kà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́