ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 9/15 ojú ìwé 3-7
  • Eeṣe Ti Awọn Eniyan Rere Fi Ń Jìyà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Eeṣe Ti Awọn Eniyan Rere Fi Ń Jìyà?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìjìyà Jobu
  • Kìí ṣe Ẹ̀bi Ọlọrun
  • Ati Ẹni Rere ati Ẹni Buburu Ń Jìyà
  • Idi Ti Awọn Eniyan Oniwa-bi-Ọlọrun Fi Ń Jìyà
  • Laipẹ—Ìjìyà Kì Yoo Si Mọ́!
  • Jóòbù Jẹ́ Oníwà Títọ́ ó Sì Ní Ìfaradà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìyà
    Jí!—2015
  • Jobu Lo Ìfaradà—Àwa Pẹ̀lú Lè Ṣe Bẹ́ẹ̀!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Jóòbù Gbé Orúkọ Jèhófà Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 9/15 ojú ìwé 3-7

Eeṣe Ti Awọn Eniyan Rere Fi Ń Jìyà?

ỌDUN naa ni 1914, ayé si ti kowọnu ogun. Lojiji, amodi typhus bẹ́ silẹ ni àgọ́ ẹ̀wọ̀n awọn jagunjagun ti a ríkó lakooko ogun ni Serbia. Ṣugbọn ibẹrẹ lasan ni iyẹn jẹ́. Àrùn abanilẹ́rù naa tankalẹ dé ọ̀dọ̀ awọn eniyan ilu o si ṣokunfa ikú 150,000 ni kiki oṣu mẹfa pere. Laaarin awọn ipo akoko ogun ati iyipada afọ̀tẹ̀ṣe ti o tẹ̀le ni Russia, million mẹta kú nipasẹ amodi typhus. Iwọ le pari ero si pe ọpọ awọn eniyan rere ati awọn mẹmba idile wọn ti ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ wà lara awọn ojiya ipalara naa.

Eyi wulẹ jẹ apẹẹrẹ kan nipa ọran ibanujẹ ẹ̀dá eniyan ni. Iwọ funraarẹ ti le ni iriri ìjìyà ti ń jẹyọ nigba ti ololufẹ kan ba ń jìyà lọwọ àrùn, ijamba, ati irú awọn àjálù kan tabi omiran. Boya, iwọ ni a daamu nigba ti irora àrùn alaiṣeewo kan ba ki aduroṣanṣan kan mọlẹ. Ó ṣeeṣe ki a ba ọ ninujẹ gidigidi nigba ti ẹni rere kan—boya ọkunrin oṣiṣẹẹkara onidiile kan—ba kú ninu ijamba kan. Ibanujẹ awọn ti ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ naa le mu ki ọkàn-aya rẹ gbọgbẹ́ fun wọn.

Ọpọ nimọlara pe ẹnikan ti ń ṣe rere ni a gbọdọ fi ominira kuro lọwọ ìjìyà san èrè fun. Awọn kan tilẹ ka ìjìyà si ohun ti o fihan pe ojiya ipalara naa jẹ oluṣebuburu. Eyi ni àròyé awọn ọkunrin mẹta ti wọn gbé ni nǹkan bii 3,600 ọdun sẹhin. Wọn gbé ni igba kan-naa pẹlu ọkunrin rere kan ti ń jẹ́ Jobu. Jẹ ki a pada si ọjọ́ wọn bi a ti bẹrẹ sii wá idahun kan si ibeere naa, Eeṣe ti awọn eniyan rere fi ń jìyà?

Ìjìyà Jobu

Nigba ti awọn mẹta ti a lero pe wọn jẹ́ ọ̀rẹ́ Jobu ṣebẹwo sọdọ rẹ̀, oun ń jìyà lọwọ irora ati àrùn lọna ti kò ṣeé ṣapejuwe. Ọ̀fọ̀ awọn ọmọ rẹ̀ mẹwaa ti ṣẹ̀ ẹ́ o si ti padanu gbogbo awọn ohun-ìní ti ara rẹ̀. Awọn eniyan ti wọn ti ń buyi fun Jobu wá koriira rẹ̀. Ani aya rẹ̀ pàápàá tilẹ kọ̀ ọ́ silẹ ti o si rọ̀ ọ́ lati bú Ọlọrun ki o si kú.—Jobu 1:1–2:13; 19:13-19.

Fun ọjọ meje ati òru meje, awọn alejo Jobu ń fi idakẹjẹ ṣakiyesi ìjìyà rẹ̀. Nigba naa ni ọ̀kan ninu wọn fi ẹsun iwa aiṣododo kàn án eyi ti a lero pe a ń fi ìyà rẹ̀ jẹ ẹ́. “Emi bẹ ọ ranti,” ni ọkunrin naa Elifasi wi: “Ta ni o ṣègbé ri laiṣẹ, tabi nibo ni a gbe ké olododo kuro rí? Ani bi emi ti ri rí pe: awọn ti ń ṣe itulẹ ẹ̀ṣẹ̀, ti wọn si fún irugbin iwa buburu, wọn a si ká eso rẹ̀ na. Nipa ifẹsi Ọlọrun wọn a ṣègbé, nipa eemi ibinu rẹ̀ wọn a parun.”—Jobu 4:7-9.

Nitori naa, Elifasi fi idaniloju sọ pe Ọlọrun ń fìyà jẹ Jobu nitori awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Lonii, pẹlu, awọn kan tọka pe awọn jamba jẹ àmúwá Ọlọrun ti a ṣe lati fìyà jẹ awọn eniyan nitori iwa-aitọ. Ṣugbọn kìí ṣe pe Jehofa ń fìyà jẹ Jobu nitori iṣe aiṣododo. A mọ eyi nitori pe Ọlọrun sọ fun Elifasi nikẹhin pe: “Mo binu si ọ ati si awọn ọ̀rẹ́ rẹ mejeeji, nitori pe ẹyin kò sọrọ niti emi, ohun ti o tọ́ bi Jobu iranṣẹ mi ti sọ.”—Jobu 42:7.

Kìí ṣe Ẹ̀bi Ọlọrun

Lonii, araadọta ọ̀kẹ́—ti o daju pe o ní ọpọlọpọ awọn eniyan rere ninu—ni wọn ń ṣíṣẹ̀ẹ́ ti wọn si wà ni bèbè ìfebipani. Awọn eniyan kan di ọlọ́kàn kikoro ti wọn si dẹbi fun Ọlọrun fun ìjìyà wọn. Ṣugbọn oun kò jẹbi fun ìyàn. Niti tootọ, oun ni Ẹni naa ti ń pese ounjẹ fun araye.—Orin Dafidi 65:9.

Imọtara-ẹni-nikan, iwọra, ati awọn okunfa miiran lati ọwọ́ eniyan le ṣediwọ fun mímú ki ounjẹ wà larọọwọto fun awọn ti ebi ń pa. Ogun jíjà wà lara awọn ohun ti ń ṣokunfa ìyàn. Fun apẹẹrẹ, iwe gbedegbẹyọ The World Book Encyclopedia wi pe: “Ogun le yọrisi ìyàn bi ọpọ awọn àgbẹ̀ ba fi oko wọn silẹ ti wọn si darapọ mọ awọn ẹgbẹ ologun. Ninu awọn ọran kan, ẹgbẹ-ọmọ-ogun kan ti dìídì dá ìyàn silẹ lati le febi pa ọ̀tá kan ki o baa le juwọsilẹ. Ẹgbẹ-ọmọ-ogun naa ba awọn ounjẹ ti a kojọ pamọ ati awọn ohun ọgbin ti o ṣẹṣẹ ń dagba jẹ́ wọn si ṣe isénà-mọ́ lati dá ipese ounjẹ ọ̀tá naa duro. Awọn ìsénà-mọ́ ń ṣediwọ fun ounjẹ ti a fi ranṣẹ lati maṣe de agbegbe Biafra lakooko Ogun Abẹle Nigeria (1967 si 1970). O yọrisi ìyàn, eyi ti o si ju million kan awọn ara Biafra ni o ṣeeṣe ki a fi ebi pa kú.”

Ni pataki ni awọn kan dẹbi fun Ọlọrun lọna aitọ lakooko Ogun Agbaye II, nigba ti ọpọ awọn eniyan rere jìyà ti wọn si kú. Sibẹ, awọn eniyan ń rú òfin Ọlọrun nipa kikoriira ati gbigbogun ti araawọn enikinni keji. Nigba ti a bi Jesu Kristi leere pe ewo ni “ekinni ninu gbogbo” òfin, ó dahun pe: “Ekinni ninu gbogbo òfin ni, Gbọ́, Israeli; Oluwa Ọlọrun wa Oluwa kan ni. Ki iwọ ki o fi gbogbo àyà rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo iyè rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, fẹ Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun rẹ: eyi ni òfin ekinni. Ekeji si dabi rẹ̀, fẹ́ ọmọnikeji rẹ bi araarẹ. Kò sì sí òfin miiran, ti o tobi ju iwọnyi lọ.”—Marku 12:28-31.

Nigba ti eniyan ba rú òfin Ọlọrun nipa lilọwọ ninu ipaniyan tìrìgàngàn, ǹjẹ́ ẹnikẹni ha le dẹbi fun Un lọna ti o tọ́ bi ìjìyà ba jẹ iyọrisi rẹ̀? Bi obi kan ba sọ fun awọn ọmọ rẹ̀ lati maṣe bá araawọn jà ti wọn kò si ka itọni rẹ̀ sí, oun ni o ha jẹbi bi wọn bá jìyà ifarapa bi? Obi naa kò ni ẹ̀bi gan-an bi Ọlọrun kò ti ni ẹ̀bi fun ìjìyà eniyan nigba ti awọn eniyan ba ṣaika awọn òfin atọrunwa si.

Bi o tilẹ jẹ pe ìjìyà le jẹyọ nigba ti a ba foju tin-in-rin awọn òfin Jehofa, Bibeli kò tọka pe ìjábá lapapọ jẹ amuwa Ọlọrun ti a wéwèé lati fìyàjẹ awọn ẹni buburu. Nigba ti awọn tọkọtaya akọkọ dẹ́ṣẹ̀, wọn padanu akanṣe ibukun ati idaabobo rẹ̀. Bi a ba yọwọ awọn ipo ninu eyi ti a ń dasi ọran latọrunwa lati ṣaṣepari awọn ète Jehofa, ohun ti o ti ṣẹlẹ si araye lati ọjọ dé ọjọ ni a ti dari nipasẹ ilana Iwe Mimọ yii: “Iré-ìje kìí ṣe ti ẹni ti o yára, bẹẹ ni ogun kìí ṣe ti alagbara, bẹẹ ni ounjẹ kìí ṣe ti ọlọgbọn, bẹẹ ni ọrọ̀ kìí ṣe ti ẹni òye, bẹẹ ni ojurere kìí ṣe ti ọlọgbọn-inu; ṣugbọn igba ati èèṣì ń ṣe si gbogbo wọn.”—Oniwasu 9:11.

Ati Ẹni Rere ati Ẹni Buburu Ń Jìyà

Niti gidi, ati ẹni rere ati ẹni buburu ń jìyà nitori ẹ̀ṣẹ̀ ati aipe ti a ti jogún. (Romu 5:12) Fun apẹẹrẹ, ati olododo ati ẹni buburu bakan-naa ń ni iriri àrùn aronilara. Kristian oluṣotitọ naa Timoteu jìyà lọwọ “ailera igbakugba.” (1 Timoteu 5:23) Nigba ti aposteli Paulu mẹnuba ‘ẹ̀gún inu ara’ tirẹ, oun le ti maa tọka si awọn ìjìyà ti ara kan. (2 Korinti 12:7-9) Ani fun awọn iranṣẹ rẹ̀ oluṣotitọ, Ọlọrun kò mú awọn ailera ti a jogun tabi agbara lati má lè gba àrùn duro kuro nisinsinyi.

Awọn eniyan oniwa-bi-Ọlọrun pẹlu le jìyà nitori lilo iṣediyele ti kò gbeṣẹ tabi kikuna lati fi itọni Iwe Mimọ si ilo ni awọn igba miiran. Lati ṣapejuwe: Ẹnikan ti o ṣaigbọran si Ọlọrun ti o si ṣegbeyawo pẹlu alaigbagbọ le jìyà awọn wahala inu ìdè igbeyawo ti oun ìbá ti yẹra fun. (Deuteronomi 7:3, 4; 1 Korinti 7:39) Bi Kristian kan kii ba jẹun daadaa ti kii ṣii ní isinmi ti o pọ̀ tó, oun le jìyà nitori bíba ilera rẹ̀ jẹ́.

Ìjìyà niti ero-imọlara le jẹ jade bi a ba juwọsilẹ fun ailera ti a si lọwọ ninu iwa-aitọ. Iwa-panṣaga Ọba Dafidi pẹlu Batṣeba mu ìjìyà nlanla wá fun un. (Orin Dafidi 51) Nigba ti o ń gbiyanju lati bo iwa-aitọ mọlẹ, oun jìyà ìrora-ọkàn jọjọ. Ó wi pe, “Nigba ti mo dákẹ́, egungun mi di gbígbó nitori igbe mi ni gbogbo ọjọ́. . . . Omi ara mi si dabi ọ̀dá-ẹ̀rùn.” (Orin Dafidi 32:3, 4) Ìkérora lori ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ dín agbara Dafidi kù gẹgẹ bi igi kan ti le padanu omi afúnni-ní-ìyè lakooko ọ̀gbẹlẹ̀ tabi ninu ooru gbígbẹ akoko ẹ̀rùn. Lọna ti o han gbangba oun jìyà niti ero-ori ati niti ara-ìyára. Ṣugbọn Orin Dafidi 32 fihàn pe a lè bọ́ lọwọ iru ìjìyà bẹẹ nipa fifi ti ẹnikan fi ironupiwada jẹwọ ẹ̀ṣẹ̀ ati gbigba idariji Ọlọrun.—Owe 28:13.

Awọn eniyan buburu sábà maa ń jìyà nitori lilepa ipa-ọna oniwakiwa, kìí ṣe gẹgẹ bi ìjìyà atọrunwa. Herodu Nla ni a fi àrùn bájà nitori awọn iṣẹ ibi. Ni awọn ọjọ rẹ̀ ti o kẹhin, Herodu “jìyà idaloro buburujai,” ni opitan Ju naa Josephus wi. “Ó ni ìfàsí-ọkàn buburujai lati họra bi elékùsá, awọn ìfun rẹ̀ kun fun ọgbẹ́-inu, awọn nǹkan ọmọkunrin rẹ̀ ń rà wọn si kun fun ìdin. Pàbó ni igbiyanju rẹ̀ lati tu araarẹ lara kuro lọwọ ìmípàkà ati gìrì rẹ̀ ninu omi lilọwọọwọ ni Callirrhoe jasi. . . . Herodu ń jìyà iru irora lile bẹẹ nisinsinyi debi pe o gbiyanju lati gún araarẹ lọ́bẹ, ṣugbọn ibatan rẹ̀ dá a lọwọ duro.”—Josephus: The Essential Writings, ti a tumọ ti a si tẹ̀ lati ọwọ Paul L. Maier.

Rírọ̀mọ́ ofin Ọlọrun ń pese awọn idaabobo kan lodisi iru awọn nǹkan bii àrùn ti ibalopọ takọtabo ń ta latare. Sibẹ, eeṣe ti awọn eniyan rere ti wọn ń wá ojurere rẹ̀ ṣe dabi ẹni ti o ń ní ju ipin tiwọn lọ ninu ìjìyà naa?

Idi Ti Awọn Eniyan Oniwa-bi-Ọlọrun Fi Ń Jìyà

Olori idi ti awọn eniyan oniwa-bi-Ọlọrun fi ń jìyà ni pe wọn jẹ olododo. Eyi ni a ṣapejuwe ninu ọ̀ràn Josẹfu ọmọkunrin baba-nla naa Jakọbu. Bi o tilẹ jẹ pe aya Potifari ń rọ Josefu leralera lati ni ibalopọ takọtabo pẹlu rẹ̀, oun beere pe: “Ǹjẹ́ emi o ha ti ṣe hu iwa buburu nla yii, ki emi si dẹ́ṣẹ̀ si Ọlọrun?” (Genesisi 39:9) Eyi jalẹ si ifinisẹwọn laitọ, Josefu si jìyà nitori pe oun jẹ́ olododo.

Ṣugbọn eeṣe ti Ọlọrun fi fayegba ki awọn iranṣẹ rẹ̀ olododo maa jìyà? Idahun naa sinmi lori ariyanjiyan kan ti angẹli ọlọtẹ naa Satani Eṣu gbé dide. Ariyanjiyan yii ní ninu iwatitọ si Ọlọrun. Bawo ni a ṣe mọ̀? Nitori pe eyi ni a fihàn ninu ọran ọkunrin olododo naa Jobu, ti a mẹnukan ni iṣaaju.

Ni ipade awọn angẹli ọmọkunrin Ọlọrun ni ọ̀run, Jehofa beere lọwọ Satani pe: “Iwọ ha kiyesi Jobu iranṣẹ mi, pe, kò si ekeji rẹ̀ ni ayé, ọkunrin tii ṣe oloootọ, ti o si duro ṣinṣin, ẹni ti o bẹru Ọlọrun, ti o si koriira iwa buburu?” Idahun Eṣu fihàn pe asọ̀ kan wa nipa boya awọn eniyan yoo pa iwatitọ si Jehofa mọ labẹ idanwo. Satani tẹnumọ ọn pe Jobu ń sin Ọlọrun nitori ibukun nipa ti ara ti o ń gbadun kìí ṣe lati inu ifẹ. Nigba naa ni Satani wi pe: “Ǹjẹ́ nawọ rẹ nisinsinyi, ki o si fi tọ́ ohun gbogbo ti [Jobu] ní; bi kì yoo si bọ́hùn ni oju rẹ.” Jehofa fesipada pe: “Kiyesi i, ohun gbogbo ti o ní ń bẹ ni ikawọ rẹ, kiki oun tikaraarẹ ni iwọ kò gbọdọ fi ọwọ rẹ kan!”—Jobu 1:6-12.

Laika ohun gbogbo ti Satani le ṣe si, Jobu di ipa-ọna òdodo mu ó si fihàn pe oun ṣiṣẹsin Jehofa lati inu ifẹ. Nitootọ, Jobu wi fun awọn olufisun rẹ̀ pe: “Ki a ma rii pe emi ń da yin ni àre, titi emi óò fi kú emi ki yoo ṣí ìwà otitọ mi kuro lọdọ mi.” (Jobu 27:5) Bẹẹni, iru awọn olupawatitọmọ bẹẹ ti sábà maa ń muratan lati jìyà nitori òdodo. (1 Peteru 4:14-16) Bibeli sọ fun wa nipa ọpọlọpọ ti wọn ti ni ifẹ alaiyẹsẹ fun Ọlọrun ti wọn si ti gbé igbesi-aye òdodo lati fi ọla fun un ki wọn si fi ijẹwọ Satani pe oun le yí gbogbo eniyan kuro lọdọ Jehofa hàn gẹgẹ bi eke. Olukuluku eniyan ti ń jìyà nitori pipa iwatitọ si Ọlọrun mọ́ le layọ pe oun ń fi Satani hàn gẹgẹ bi elékèé ti o si ń mú ọkàn Jehofa yọ̀.—Owe 27:11.

Ọlọrun kò ṣàìbìkítà nipa ìjìyà awọn iranṣẹ rẹ̀ oluṣotitọ. Olorin naa Dafidi wi pe: “Oluwa [“Jehofa,” NW] mú gbogbo awọn ti o ṣubu ró; o si gbé gbogbo awọn ti o tẹriba dide.” (Orin Dafidi 145:14) Awọn wọnni ti wọn ya araawọn si mimọ fun Jehofa lè ṣalaini okun ti ara-ẹni ti o pọ tó lati farada awọn ìjìyà igbesi-aye ati inunibini ti wọn ń ni iriri gẹgẹ bi eniyan rẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ń fun wọn lokun o si ń ràn wọn lọwọ o si ń fun wọn ni ọgbọ́n ti wọn nilo lati foriti gbogbo idanwo wọn. (Orin Dafidi 121:1-3; Jakọbu 1:5, 6) Bi awọn oninunibini ba pa diẹ ninu awọn iranṣẹ Jehofa olododo, wọn ni ireti ajinde ti Ọlọrun fifunni. (Johannu 5:28, 29; Iṣe 24:15) Ani de àyè yẹn, Ọlọrun le yi awọn iyọrisi ìjìyà eyikeyii tí awọn tí wọn nifẹẹ rẹ̀ là kọja pada. Ó mu ìjìyà Jobu wa si opin o si bukun fun ọkunrin aduroṣinṣin yẹn lọpọlọpọ. A si le ni idaniloju pe Jehofa kì yoo kọ awọn eniyan rẹ silẹ ni ọjọ wa.—Jobu 42:12-16; Orin Dafidi 94:14.

Laipẹ—Ìjìyà Kì Yoo Si Mọ́!

Wayi o, nigba naa, gbogbo eniyan ń ni iriri ìjìyà nitori aipe ti a jogun ati igbesi-aye laaarin eto awọn nǹkan buburu yii. Awọn eniyan oniwa-bi-Ọlọrun pẹlu le reti lati jìyà nitori pipa iwatitọ mọ si Jehofa. (2 Timoteu 3:12) Ṣugbọn wọn le layọ, nitori pe laipẹ Ọlọrun yoo fi opin si omije, iku, ọ̀fọ̀, ẹkún, ati irora. Nipa eyi aposteli Johannu kọwe pe:

“Mo si ri ọ̀run titun kan ati ayé titun kan: nitori pe ọ̀run ti iṣaaju ati ayé iṣaaju ti kọja lọ; òkun kò sì sí mọ́. Mo si ri ilu mimọ nì, Jerusalemu titun ń ti ọ̀run sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wá, ti a mura silẹ bi iyawo ti a ṣe lọṣọọ fun ọkọ rẹ̀. Mo si gbọ ohùn nla kan lati ori itẹ ni wá, ń wi pe, Kiyesi i, àgọ́ Ọlọrun wà pẹlu awọn eniyan, oun o si maa ba wọn gbé, wọn o si maa jẹ́ eniyan rẹ̀, ati Ọlọrun tikaraarẹ yoo wà pẹlu wọn, yoo si maa jẹ́ Ọlọrun wọn. Ọlọrun yoo si nu omije gbogbo nù kuro ni oju wọn; ki yoo si si iku mọ, tabi ọ̀fọ̀, tabi ẹkún, bẹẹ ni ki yoo si irora mọ: nitori pe ohun atijọ ti kọja lọ. Ẹni ti o jokoo lori itẹ nì si wi pe, Kiyesi i, mo sọ ohun gbogbo di ọ̀tun. Ó si wi fun mi pe, Kọwe rẹ̀: nitori ọ̀rọ̀ wọnyi ododo ati otitọ ni wọn.”—Ìfihàn 21:1-5.

Ni ọ̀nà ti o jọra, aposteli Peteru kede pe: “Gẹgẹ bi ileri rẹ̀ [Jehofa Ọlọrun], awa ń reti awọn ọ̀run titun ati ayé titun, ninu eyi ti ododo ń gbé.” (2 Peteru 3:13) Ẹ wo ireti nlanla ti o wà ni iwaju! Iwalaaye ninu paradise ilẹ̀-ayé le jẹ́ anfaani alayọ rẹ. (Luku 23:43) Nitori naa, maṣe jẹ ki ìjìyà ọjọ oni bà ọ́ nínú jẹ́. Kaka bẹẹ, wo ọjọ iwaju pẹlu ẹmi nǹkan-yoo-dara. Gbe ireti ati igbẹkẹle rẹ kárí-ayé titun Ọlọrun ti o ti sunmọtosi gan an. Lepa ipa-ọna kan ti o ṣetẹwọgba fun Jehofa Ọlọrun, iwọ yoo si le walaaye titilae ninu ayé kan ti o bọ́ lọwọ gbogbo ìjìyà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Bi o tilẹ jẹ pe Jobu jìyà, oun lepa ipa-ọna kan ti o ṣetẹwọgba fun Ọlọrun

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Iwọ le walaaye ninu ayé kan ti o bọ́ lọwọ gbogbo ìjìyà

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Collier’s Photographic History of the European War

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́