Jehofa Ń Dariji ní Ọ̀nà Pupọ Gan-an
“Jẹ ki eniyan buruku fi ọ̀nà rẹ̀ silẹ, ati apanilara eniyan awọn ero-inu rẹ̀; sì jẹ́ kí ó pada sọdọ Jehofa, . . . nitori ti oun yoo dariji ní ọ̀nà pupọ gan-an.”—ISAIAH 55:7, NW.
1. Pẹlu ki ni a fi bukun fun awọn ti wọn ri idariji Jehofa gbà nisinsinyi?
JEHOFA ń dariji awọn oniwa aitọ ti wọn ronupiwada ó si ń jẹ ki wọn gbadun alaafia ọkàn ninu paradise tẹmi nisinsinyi. Eyi ri bẹẹ nitori pe wọn dójú awọn ohun ti a beere fun wọnyi: “Ẹ wá Jehofa kínníkínní, ẹyin eniyan, nigba ti ẹ lè ri i. Ẹ képè é nigba ti ẹ̀rí fihàn pe o wà nitosi. Jẹ́ ki eniyan buruku fi ọ̀nà rẹ̀ silẹ, ati apanilara eniyan awọn ero-inu rẹ̀; sì jẹ́ ki o pada sọdọ Jehofa, ẹni ti yoo fi àánú hàn si i, ati sọdọ Ọlọrun wa, nitori ti oun yoo dariji ní ọ̀nà púpọ̀ gan-an.”—Isaiah 55:6, 7.
2. (a) Ki ni a ni lọkan nipa ‘wíwá Jehofa kínníkínní’ ati ‘pipada sọdọ rẹ̀,’ bi a ti mẹnukan an ni Isaiah 55:6, 7? (b) Eeṣe ti awọn igbekun ọmọ Ju ni Babiloni fi nilati pada sọdọ Jehofa, ki sì ni o ṣẹlẹ si awọn diẹ ninu wọn?
2 Lati “wá Jehofa kínníkínní” ki ó si ké pè é pẹlu itẹwọgba, eniyan buruku kan gbọdọ fi ọ̀nà ati ironu rẹ̀ eyikeyii lati ṣe ipalara fun awọn ẹlomiran silẹ. Aini naa lati “pada sọdọ Jehofa” fihàn pe eniyan buruku naa fi Ọlọrun silẹ, ẹni ti oun ti ni ibatan timọtimọ pẹlu rẹ̀ nigbakanri. Iyẹn jẹ bi ọ̀ràn ti ri pẹlu awọn olugbe Juda, awọn ti aiṣododo wọn si Ọlọrun nigbẹhin-gbẹhin ṣamọna si ìgbèkùn ni Babiloni. Awọn Ju ti a kó nígbèkùn nilati pada sọdọ Jehofa nipa rironupiwada awọn aṣiṣe ti o ti yọrisi ikolẹru wọn lọ si Babiloni ati isọdahoro 70 ọdun ti a sọtẹlẹ nipa ilẹ wọn. Ni 537 B.C.E., ilẹ yẹn ni àṣẹ́kù awọn Ju olubẹru-Ọlọrun ti a dasilẹ lati Babiloni nipa ofin ijọba tun bẹrẹ sii pada gbé. (Esra 1:1-8; Daniel 9:1-4) Awọn iyọrisi imupadabọsipo yẹn tobi tobẹẹ debi pe ilẹ Juda ni a fiwe Paradise ti Edeni.—Esekieli 36:33-36.
3. Bawo ni aṣẹku Israeli tẹmi ṣe ni iriri kan bii ti awọn igbekun olubẹru-Ọlọrun ti wọn pada si Juda?
3 Awọn Israeli tẹmi ti ni iriri kan bii ti awọn Ju olubẹru-Ọlọrun ti wọn pada si Juda lẹhin igbekun ni Babiloni. (Galatia 6:16) Aṣẹku awọn Israeli tẹmi ṣe iyipada awọn ọ̀nà ati awọn ironu wọn diẹ gẹrẹ lẹhin Ogun Agbaye I. Ọdun 1919 sàmì si opin igbekun wọn kuro ninu ojurere Ọlọrun lẹkun-unrẹrẹ ni ilẹ-akoso Babiloni Nla, ilẹ-ọba isin eke agbaye. Nitori pe wọn ronupiwada awọn ẹṣẹ ti o ni ninu ibẹru eniyan ati aigboṣaṣa ninu iṣẹ-isin Jehofa, oun da wọn silẹ lominira kuro lọwọ Babiloni Nla, o mu wọn pada bọ sinu ipo tẹmi wọn títọ́, o si bẹrẹ sii lò wọn lati waasu ihin-iṣẹ Ijọba naa. Paradise tẹmi kan ti gbilẹ laaarin awọn eniyan Ọlọrun lati igba naa, si ọla orukọ mimọ rẹ̀. (Isaiah 55:8–13) Nigba naa, ninu apẹẹrẹ iṣaaju ti igbaani ati amapẹẹrẹṣẹ ti ode-oni, a ni ẹ̀rí ti o daniloju pe awọn ibukun ń tẹle idariji atọrunwa ati pe Jehofa niti gidi ń dariji awọn ti wọn ronupiwada ni ọ̀nà púpọ̀ gan-an.
4. Ibẹru wo ni awọn iranṣẹ Jehofa diẹ ni?
4 Awọn iranṣẹ Jehofa ti ọjọ-oni nigba naa le ni igbẹkẹle ninu idariji rẹ̀. Sibẹ, awọn kan ninu wọn jẹ alainireti nipa awọn aṣiṣe kan ti o ti kọja, ti awọn imọlara ẹ̀bi si fẹrẹẹ bò wọn mọlẹ. Wọn kò ka araawọn yẹ ni ẹni tíí gbé ninu paradise tẹmi naa. Niti tootọ, awọn kan mikàn pe awọn ti dá ẹṣẹ ti kò ni idariji ti awọn kì yoo si ri idariji Jehofa gbà lae. Iyẹn ha le ṣeeṣe bi?
Awọn Ẹṣẹ kan Kò Ni Idariji
5. Eeṣe ti a fi le sọ pe awọn ẹṣẹ kan kò ni idariji?
5 Awọn ẹṣẹ kan kò ni idariji. Jesu Kristi wi pe: “Gbogbo iru ẹ̀ṣẹ̀-kẹ́ṣẹ̀ ati ọrọ-odi ni a o dariji eniyan, ṣugbọn ọrọ-odi si ẹmi mimọ, oun ni a kì yoo dariji eniyan.” (Matteu 12:31) Wayi o, nigba naa, ọrọ-odi si ẹmi mimọ Ọlọrun, tabi ipa agbekankanṣiṣẹ, ni a ki yoo dari rẹ̀ ji. Aposteli Paulu sọ̀rọ̀bá iru ẹṣẹ bẹẹ nigba ti o kọwe pe: “Nitori awọn ti a ti là loju lẹẹkan, . . . ti wọn si ti ṣubu kuro, kò lè ṣeeṣe lati sọ wọn di ọ̀tun si ironupiwada, nitori wọn tun kan Ọmọ Ọlọrun mọ́ [igi oró] si araawọn ni ọ̀tun, wọn si dojuti i ni gbangba.”—Heberu 6:4-6.
6. Ki ni o ń pinnu boya ẹṣẹ kan ni idariji tabi bẹẹkọ?
6 Kiki Ọlọrun nikan ni o mọ bi ẹnikan ba ti dẹṣẹ ti kò ni idariji naa. Bi o ti wu ki o ri, Paulu tan imọlẹ sori ọran yii nigba ti oun kọwe pe: “Bi awa ba mọọmọ dẹṣẹ lẹhin igba ti awa ba ti gba imọ otitọ kò tun si ẹbọ fun ẹṣẹ mọ́, bikoṣe ireti idajọ ti o banilẹru, ati ti ibinu ti o muna.” (Heberu 10:26, 27) Ẹnikan ti o jẹ́ aṣeyòówùú maa ń mọọmọ gbegbeesẹ, tabi jẹ “aṣetinu-ẹni lọna yíyigbì ati olóríkunkun.” (Webster’s New Collegiate Dictionary) Ẹnikẹni ti o ba ń ṣeyòówùú ti o si ń fi oríkunkun baa lọ lati dẹṣẹ lẹhin ti o ti mọ otitọ ni a kò dariji. Fun idi yii, kìí ṣe bi ẹṣẹ naa ti tobi to funraarẹ bikoṣe ipo ọkàn, iwọn mimọọmọ ti o wemọ ọn, ni o ń nipa lori boya ẹṣẹ naa ṣe e dari rẹ̀ jini tabi bẹẹkọ. Ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, ki ni o ṣeeṣe ki ọran naa jẹ nigba ti Kristian kan ti o dẹṣẹ ba ni idaamu gidigidi nipa iwa aitọ rẹ̀? Aniyan giga rẹ̀ ni o ṣeeṣe ki o fihàn pe oun, niti gidi, kò tii dẹṣẹ ti kò ni idariji.
Awọn Ẹ̀ṣẹ̀ Wọn Kò Ni Idariji
7. Eeṣe ti a fi le sọ pe diẹ ninu awọn alatako isin Jesu dẹṣẹ ti kò ni idariji?
7 Awọn olori isin Ju kan ti wọn tako Jesu dẹṣẹ amọọmọda, ti o si tipa bayii jẹ eyi ti kò ni idariji. Bi o tilẹ jẹ pe wọn ri ẹmi mimọ Ọlọrun lẹnu iṣẹ́ nipasẹ Jesu bi o ti ṣe rere ti o si ṣe awọn iṣẹ iyanu, awọn olori isin wọnyẹn ka agbara rẹ̀ si ti Beelsebubu, tabi Satani Eṣu. Wọn dẹṣẹ pẹlu ojú wọn ní yíyà silẹ ketekete si iṣiṣẹ ẹmi mimọ Ọlọrun ti kò ṣee sẹ́. Nipa bayi, wọn dẹṣẹ ti kò ni idariji, nitori Jesu wi pe: “Ẹnikẹni ti o ba ń sọrọ odi si ẹmi mimọ, a kì yoo dari rẹ̀ ji i ni ayé yii, ati ni ayé ti ń bọ̀.”—Matteu 12:22-32.
8. Eeṣe ti ẹṣẹ Judasi Iskariotu kò fi ni idariji?
8 Ẹṣẹ Judasi Iskariotu pẹlu kò ni idariji. Dídà ti o da Jesu jẹ fifi ifẹ-inu, ìmọọmọ tọ ipa-ọna agabagebe ati abosi jalẹjalẹ. Fun apẹẹrẹ, nigba ti Judasi ri Maria ti o ń fi òróró olowo iyebiye kun Jesu, o beere pe: “Eeṣe ti a kò ta ororo ikunra yii ni ọọdunrun owó-idẹ ki a si fifun awọn talaka?” Aposteli Johannu fikun un pe: “[Judasi] wi eyi, kìí ṣe nitori ti o náání awọn talaka, ṣugbọn nitori tii ṣe ole oun ni o si ni apo, a si maa gbé ohun ti a fi sinu rẹ̀.” Laipẹ lẹhin naa, Judasi da Jesu fun 30 owó fadaka. (Johannu 12:1-6; Matteu 26:6-16) Lotiitọ, Judasi bọkanjẹ o si ṣekupa araarẹ. (Matteu 27:1-5) Ṣugbọn a kò dariji i, niwọnbi ipa-ọna amọọmọṣe rẹ̀, ti o figba gbogbo jẹ́ ti onimọtara-ẹni-nikan ati iwa alareekereke rẹ̀ ti fi ẹṣẹ rẹ̀ lodisi ẹmi mimọ hàn. Ẹ wo bi o ti baa mu to ti Jesu fi nilati pe Judasi ni “ọmọ ègbé”!—Johannu 17:12; Marku 3:29; 14:21.
A Dárí Ẹṣẹ Wọn Jì
9. Eeṣe ti Ọlọrun fi dari ẹṣẹ Dafidi ni isopọ pẹlu Batṣeba jì?
9 Awọn ẹṣẹ amọọmọda wà ni iyatọ patapata ni ifiwera pẹlu aṣiṣe awọn wọnni ti Ọlọrun dariji. Wo Ọba Dafidi ti Israeli gẹgẹ bi apẹẹrẹ kan. Ó bá Batṣeba aya Uria, ṣe panṣaga, lẹhin naa ni ó mu ki Joabu dọgbọn fa iku Uria loju ogun. (2 Samueli 11:1-27) Eeṣe ti Ọlọrun fifi aanu hàn si Dafidi? Ni pataki nitori ti majẹmu Ijọba naa ati ni akoko kan-naa nitori ìláàánú ti Dafidi funraarẹ ati ojulowo ironupiwada rẹ̀ pẹlu.—1 Samueli 24:4-7; 2 Samueli 7:12; 12:13.
10. Bi o tilẹ jẹ pe Peteru dẹṣẹ lọna lilekoko, eeṣe ti Ọlọrun fi dariji í?
10 Bakan-naa, gbé ọran ti aposteli Peteru yẹwo. Ó dẹṣẹ lọna lilekoko nipa sísẹ́ Jesu leralera. Eeṣe ti Ọlọrun fi dariji Peteru? Laida bii Judasi Iskariotu, Peteru ti jẹ alailabosi ninu iṣẹ-isin Ọlọrun ati Kristi. Ẹṣẹ aposteli yii jẹ́ nitori ailera ẹran-ara, oun si ronupiwada niti tootọ ó si “sọkun kikoro.”—Matteu 26:69-75.
11. Bawo ni iwọ yoo ṣe tumọ “ironupiwada,” ki si ni ẹnikan nilati ṣe bi oun ba ronupiwada nitootọ?
11 Awọn apẹẹrẹ ti a mẹnukan ṣaaju fihàn pe ẹnikan ti o dẹṣẹ wiwuwo paapaa lè rí idariji Jehofa Ọlọrun gbà. Ṣugbọn iṣarasihuwa wo ni a beerefun ki a tó lè ri idariji gbà? Ironupiwada tootọ ṣe koko bi Ọlọrun ba nilati dariji Kristian kan. Lati ronupiwada tumọsi “lati yipada kuro ninu ẹṣẹ pẹlu ikẹdun fun awọn aṣiṣe ti o ti kọja” tabi “kábàámọ̀ tabi kẹ́dùn fun ohun ti ẹnikan ti ṣe tabi gbàgbé lati ṣe.” (Webster’s Third New International Dictionary) Ẹnikan ti o ronupiwada niti tootọ yoo fi ìbọkànjẹ́ hàn lori abuku, ibanujẹ, tabi awọn iṣoro eyikeyii ti ẹṣẹ rẹ̀ ti mu wa sori orukọ Jehofa ati eto-ajọ rẹ̀. Oniwa-aitọ ti o ronupiwada naa yoo tun so eso ti o wà ni ìdọ́gbarẹ́gí, ni ṣiṣe awọn iṣẹ ti o yẹ si ironupiwada. (Matteu 3:8; Iṣe 26:20) Fun apẹẹrẹ, bi oun ba ti lu ẹnikan ni jibiti, oun yoo gbé awọn igbesẹ ti o bọgbọnmu lati ṣe asanpada adanu naa. (Luku 19:8) Iru Kristian ti o ronupiwada bẹẹ ní awọn idi fifẹsẹmulẹ ti o ba Iwe Mimọ mu lati ni igbẹkẹle pe Jehofa yoo dariji ni ọ̀nà púpọ̀ gan-an. Ki ni awọn wọnyi?
Awọn Idi fun Igbẹkẹle Ninu Idariji Ọlọrun
12. Lori ipilẹ ki ni Orin Dafidi 25:11 fihàn pe eniyan ti o ronupiwada kan le gbadura fun idariji?
12 Oniwa aitọ ti o ronupiwada le fi igbẹkẹle gbadura fun idariji lori ipilẹ orukọ Jehofa. Dafidi bẹbẹ pe: “Nitori orukọ rẹ, Oluwa [“Jehofa,” NW], dari ẹṣẹ mi ji, nitori ti o tobi.” (Orin Dafidi 25:11) Iru adura bẹẹ, papọ pẹlu ironupiwada fun abuku eyikeyi ti oniwa aitọ naa ti muwa sori orukọ Ọlọrun, tun gbọdọ ṣiṣẹ gẹgẹ bi idiwọ fun ẹṣẹ wiwuwo ni ọjọ iwaju.
13. Ipa wo ni adura ń kó ninu idariji atọrunwa?
13 Jehofa Ọlọrun ń dahun awọn adura atọkanwa ti awọn iranṣẹ rẹ̀ ti wọn ṣe aṣiṣe ṣugbọn ti wọn jẹ́ onironupiwada. Fun apẹẹrẹ, Jehofa kò kọ eti ikún si Dafidi, ẹni ti o gbadura lati inu ọkan-aya wá lẹhin mimọ itobi awọn ẹṣẹ rẹ̀ ni isopọ pẹlu Batṣeba. Niti tootọ, awọn ọ̀rọ̀ Dafidi ni Orin 51 sọ ọpọ ero alaṣiṣe tí awọn imọlara gbé jade. Oun bẹbẹ pe: “Ọlọrun, ṣaanu fun mi, gẹgẹ bi iṣeun ifẹ rẹ: gẹgẹ bii ìrọ́nú ọpọ aanu rẹ, nu irekọja mi nù kuro. Wẹ mi ni awẹmọ kuro ninu aiṣedeedee mi, ki o si wẹ̀ mi nù kuro ninu ẹṣẹ mi. Ẹbọ Ọlọrun ni irobinujẹ ọkàn: irobinujẹ ati irora àyà, Ọlọrun, oun ni iwọ ki yoo gàn.”—Orin Dafidi 51:1, 2, 17.
14. Bawo ni Iwe Mimọ ṣe pese idaniloju lẹẹkansii pe Ọlọrun ń dariji awọn ti wọn ń fi igbagbọ hàn ninu ẹbọ irapada Jesu?
14 Ọlọrun ń dariji awọn wọnni ti wọn ń fi igbagbọ hàn ninu ẹbọ irapada Jesu. Paulu kọwe pe: “Ninu ẹni ti awa ni irapada wa nipa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, idariji ẹṣẹ wa, gẹgẹ bi ọ̀rọ̀ ore-ọfẹ rẹ̀.” (Efesu 1:7) Pẹlu itumọ pataki kan-naa, aposteli Johannu kọwe pe: “Ẹyin ọmọ mi, iwe nǹkan wọnyi ni mo kọ si yin, ki ẹ ma baa dẹṣẹ. Bi ẹnikẹni ba si dẹṣẹ, awa ni alagbawi lọdọ Baba, Jesu Kristi olododo: Oun si ni etutu fun ẹṣẹ wa: kii sii ṣe fun tiwa nikan, ṣugbọn fun ti gbogbo araye pẹlu.”—1 Johannu 2:1, 2.
15. Lati maa baa lọ ni gbigbadun aanu Ọlọrun, ki ni ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada gbọdọ ṣe?
15 Aanu Jehofa fun oniwa aitọ kan ti o ronupiwada ní ipilẹ fun igbẹkẹle pe a le dariji i. Nehemiah wi pe: “Iwọ ni Ọlọrun ti o mura lati dariji, oloore-ọfẹ, ati alaaanu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ.” (Nehemiah 9:17; fiwe Eksodu 34:6, 7.) Nitootọ, lati maa baa lọ ni gbigbadun aanu atọrunwa, ẹlẹṣẹ naa gbọdọ tiraka lati pa ofin Ọlọrun mọ. Gẹgẹ bi olorin naa ti sọ, “Jẹ ki ìrọ́nú aanu rẹ ki o tọ mi wá, ki emi ki o le yè: nitori ofin rẹ ni didun-inu mi. Ọpọ ni ìrọ́nú aanu rẹ, Oluwa [“Jehofa,” NW]: sọ mi di ààyè gẹgẹ bi idajọ rẹ.”—Orin Dafidi 119:77, 156.
16. Itunu wo ni o wà ninu otitọ naa pe Jehofa ń gba ti ipo ẹṣẹ wa rò?
16 Otitọ naa pe Jehofa gba ipo ẹṣẹ wa rò tun ń fun ẹlẹṣẹ kan ti o ti ronupiwada ni itunu ati idi lati gbadura pẹlu igbẹkẹle pe Ọlọrun yoo dariji i. (Orin Dafidi 51:5; Romu 5:12) Olorin naa Dafidi funni ni awọn imudaniloju ti ń tunilara nigba ti o kede pe: “Oun [Jehofa Ọlọrun] kìí ṣe si wa gẹgẹ bi ẹṣẹ wa; bẹẹ ni kii san án fun wa gẹgẹ bi aiṣedeedee wa. Nitori pe, bi ọ̀run ti ga si ilẹ, bẹẹ ni aanu rẹ̀ tobi si awọn ti o bẹru rẹ̀. Bi ila-oorun ti jinna si iwọ-oorun, bẹẹ ni o mu irekọja wa jinna kuro lọdọ wa. Bi baba tii ṣe ìyọ́nú si awọn ọmọ, bẹẹ ni Oluwa [“Jehofa,” NW] ń ṣe ìyọ̀nú si awọn ti o bẹru rẹ̀. Nitori ti o mọ ẹda wa; o ranti pe erupẹ ni wá.” (Orin Dafidi 103:10-14) Bẹẹni, Baba wa ọ̀run tilẹ tubọ kun fun aanu ati ìyọ̀nú ju obi kan ti o jẹ́ eniyan lọ.
17. Ipa wo ni akọsilẹ iṣẹ-isin oloootọ ti ẹnikan si Ọlọrun ni awọn ìgbà ti o ti kọja ní lori idariji?
17 Ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada le gbadura fun idariji pẹlu igbẹkẹle pe Jehofa kì yoo gbójúfo akọsilẹ iṣẹ-isin olódodo rẹ̀ ti o ti kọja dá. Kìí ṣe pe Nehemiah ń jirẹẹbẹ fun idariji ẹṣẹ rẹ̀, ṣugbọn oun wi pe: “Ranti mi, Ọlọrun mi, fun rere.” (Nehemiah 13:31) Kristian kan ti o ronupiwada lè ri itunu ninu awọn ọ̀rọ̀ naa: “Ọlọrun kìí ṣe alaiṣododo ti yoo fi gbagbe iṣẹ yin ati ifẹ ti ẹ̀yin fihàn si orukọ rẹ̀.”—Heberu 6:10.
Iranlọwọ Lati Ọ̀dọ̀ Awọn Agba Ọkunrin
18. Ki ni a nilati ṣe bi ẹṣẹ Kristian kan ba ti mu un ṣaarẹ nipa tẹmi?
18 Ki ni bi Kristian kan bá nimọlara aitootun lati duro ninu paradise tẹmi naa tabi ti kò le gbadura nitori pe ẹṣẹ rẹ̀ ti mu un ṣaisan nipa tẹmi? “Ki o pe awọn agba ìjọ, ki wọn si gbadura sori rẹ̀, ki wọn fi òróró kun un ni orukọ Oluwa [“Jehofa,” NW],” ni ọmọlẹhin naa Jakọbu kọwe. “Adura igbagbọ yoo si gba alaisan naa là, Oluwa yoo si gbe e dide; bi o ba si ṣe pe o ti dẹṣẹ, a o dariji i.” Bẹẹni, awọn alagba ijọ lọna ti o gbeṣẹ le gbadura pẹlu ki wọn sì fun onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn kan ti o ronupiwada ni ireti lati mu un larada si ilera tẹmi ti o dara.—Jakọbu 5:14-16.
19. Bi a ba ti yọ ẹnikan lẹ́gbẹ́, ki ni oun nilati ṣe ki o baa le di ẹni ti a dariji ti a si gbà sipopada?
19 Ani bi igbimọ idajọ ba tilẹ yọ ẹlẹṣẹ kan ti kò ronupiwada lẹ́gbẹ́, eyi kò tumọsi pe oun ti dẹṣẹ ti kò ni idariji. Bi o ti wu ki o ri, lati jẹ ẹni ti a dariji ti a si gbà sipopada, o gbọdọ fi tirẹlẹtirẹlẹ ṣegbọran si awọn òfin Ọlọrun, ki o mu eso ti o yẹ fun ironupiwada jade, ki o si kọwe si awọn alagba fun ìgbàsípò pada. Lẹhin ti a ti yọ alágbèrè kan kuro ninu ijọ ni Korinti igbaani, Paulu kọwe pe: “Ìyà yii ti ọpọlọpọ ti fi jẹ iru eniyan bẹẹ, o tó fun un. Kaka bẹẹ, ẹyin ìbá kuku dariji i, ki ẹ si tu u ninu, lọnakọna ki ọpọlọpọ ibanujẹ má baa bo iru eniyan bẹẹ mọlẹ. Nitori naa mo bẹ yin, ẹ fi ifẹ yin hàn daju si oluwarẹ.”—2 Korinti 2:6-8; 1 Korinti 5:1-13.
Ọlọrun Ń Funni Ni Okun
20, 21. Ki ni ó lè ran ẹnikan ti ń niriiri aniyan nipa boya ó ti dẹṣẹ ti kò ni idariji lọwọ?
20 Bi iru awọn ipo bii ailera tabi masunmawo ba ń fa aniyan nipa pe a ti dẹṣẹ kan ti kò ní idariji, nini isinmi ati oorun ti o pọ̀ tó le ṣeranwọ. Bi o ti wu ki o ri, ni pataki, ni iwọ nilati ranti awọn ọ̀rọ̀ Peteru pe: “Ẹ maa kó gbogbo aniyan yin le [Ọlọrun]; nitori oun ń ṣe itọju yin.” Ma si ṣe jẹ́ ki Satani kó irẹwẹsi ba ọ, nitori pe Peteru fikun un pe: “Ẹ maa wa ni airekọja, ẹ maa ṣọra; nitori Eṣu, ọ̀tá yin, bii kinniun ti ń ké ramuramu, o ń rìn kaakiri, o ń wa ẹni ti yoo pajẹ kiri: Ẹni ti ki ẹyin ki o kọ oju ija si pẹlu ‘iduroṣinṣin ninu igbagbọ, ki ẹyin ki o mọ pe ìyà kan-naa ni awọn ará yin ti ń bẹ ninu ayé ń jẹ. Ọlọrun oore-ọfẹ gbogbo, . . . nigba ti ẹyin ba ti jìyà diẹ, oun tikaraarẹ, yoo si ṣe yin ni aṣepe, yoo fi ẹsẹ yin mulẹ, yoo fun yin ni agbara, yoo fi idi yin kalẹ.”—1 Peteru 5:6-10.
21 Nitori naa ti o ba ni irobinujẹ ṣugbọn ti o ti ń bẹru pe o jẹbi ẹṣẹ ti kò ni idariji, ranti pe awọn ọ̀nà Ọlọrun jẹ ọgbọ́n, ododo, ati onifẹẹ. Nitori naa, gbadura si i ni igbagbọ. Maa baa lọ ni jijẹ ounjẹ tẹmi ti oun ń pese nipasẹ “ẹru oluṣotito ati ọlọgbọn-inu naa.” (Matteu 24:45-47) Maa darapọ pẹlu awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ ki o si maa ṣajọpin ninu iṣẹ-ojiṣẹ Kristian deedee. Eyi yoo fun igbagbọ rẹ lokun yoo si sọ ọ́ dominira kuro lọwọ ibẹru eyikeyii pe Ọlọrun lè má tii dárí ẹṣẹ rẹ̀ jì.
22. Ki ni a o gbeyẹwo tẹle e?
22 Awọn olùgbé paradise tẹmi naa le ri itunu ninu mímọ̀ pe Jehofa ń dariji ní ọ̀nà púpọ̀ gan-an. Sibẹ, iwalaaye wọn kò ṣaini awọn idanwo lonii. Boya wọn sorikọ nitori pe ololufẹ kan ti kú tabi ọ̀rẹ́ timọtimọ kan ń ṣaisan lilekoko. Bi a o ti rii, ninu eyi ati awọn ipo-ọran miiran, Jehofa ń ṣeranwọ o si ń darí awọn eniyan rẹ̀ nipasẹ ẹmi mimọ rẹ̀.
Ki Ni Idahun Rẹ?
◻ Ẹ̀rí wo ni o wà pe Jehofa ‘ń dariji ní ọ̀nà púpọ̀ gan-an’?
◻ Fun ẹṣẹ wo ni kò si idariji?
◻ Labẹ awọn ipo ayika wo ni a ti ń dari ẹṣẹ jini?
◻ Eeṣe ti awọn ẹlẹṣẹ ti wọn ronupiwada fi lè ni idaniloju ninu idariji Ọlọrun?
◻ Iranlọwọ wo ni o wà larọọwọto fun awọn oniwa aitọ ti wọn ronupiwada?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Iwọ ha mọ idi ti a fi dariji Dafidi ati Peteru ṣugbọn ti a kò ṣe bẹẹ fun Judasi Iskariotu bi?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Iranlọwọ nipasẹ awọn alagba ijọ le ṣe pupọ lati ran Kristian kan lọwọ nipa tẹmi