ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 7/15 ojú ìwé 16-20
  • Ǹjẹ́ o Rò Pé o Ti Ṣẹ̀ Sí Ẹ̀mí Mímọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ o Rò Pé o Ti Ṣẹ̀ Sí Ẹ̀mí Mímọ́?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Béèyàn Bá Ronú Pìwà Dà Yóò Rí Ìdáríjì
  • Àwọn Wọ̀nyí Ṣẹ̀ sí Ẹ̀mí Mímọ́
  • Àwọn Wọ̀nyí Kò Ṣẹ̀ sí Ẹ̀mí Mímọ́
  • Bí Ìbẹ̀rù Pé A Ti Ṣẹ̀ sí Ẹ̀mí Mímọ́ Ṣe Lè Dín Kù
  • Jehofa Ń Dariji ní Ọ̀nà Pupọ Gan-an
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀ṣẹ̀ kan Wà Tí Kò ní Ìdáríjì?
    Jí!—2003
  • Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀ Tí Kò Ní Ìdáríjì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Àánú Jehofa Ń Gbà Wá Là Kuro Ninu Ainireti
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 7/15 ojú ìwé 16-20

Ǹjẹ́ o Rò Pé o Ti Ṣẹ̀ Sí Ẹ̀mí Mímọ́?

“Ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tí ń fa ikú.”—1 JÒHÁNÙ 5:16.

1, 2. Báwo la ṣe mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kéèyàn ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́?

OLÙJỌSÌN Ọlọ́run ni obìnrin kan nílẹ̀ Jámánì, síbẹ̀ ó kọ̀wé pé: “Ìgbà gbogbo ni mò ń rò ó pé mo ti ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́.” Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe lóòótọ́ pé kí Kristẹni kan ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́ tí í ṣe agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run?

2 Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe kéèyàn ṣẹ̀ sí ẹ̀mí Jèhófà. Jésù Kristi sọ pé: “Gbogbo onírúurú ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀ òdì ni a óò dárí ji àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí ni a kì yóò dárí jini.” (Mátíù 12:31) Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Bí a bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà lẹ́yìn rírí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ gbà, kò tún sí ẹbọ kankan tí ó ṣẹ́ kù fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, bí kò ṣe ìfojúsọ́nà fún ìdájọ́ akúnfẹ́rù.” (Hébérù 10:26, 27) Àpọ́sítélì Jòhánù sì sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tí ń fa ikú wá báni ní tòótọ́.” (1 Jòhánù 5:16) Àmọ́, ṣé ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ ńlá ló máa fúnra rẹ̀ pinnu bóyá ẹ̀ṣẹ̀ òun jẹ́ ‘ẹ̀ṣẹ̀ tó ń fa ikú’ ni?

Béèyàn Bá Ronú Pìwà Dà Yóò Rí Ìdáríjì

3. Tínú èèyàn bá bà jẹ́ gan-an nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, ẹ̀rí kí ló ṣeé ṣe kí ìyẹn jẹ́?

3 Jèhófà gan-an ló ń ṣèdájọ́ àwọn tó bá dẹ́ṣẹ̀. Láìsí àní-àní, gbogbo wa pátá ni yóò jíhìn fún un, kì í sì í ṣe àìtọ́ rárá. (Jẹ́nẹ́sísì 18:25; Róòmù 14:12) Jèhófà ló ń pinnu bóyá ẹnì kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì, òun ló sì lè mú ẹ̀mí rẹ̀ kúrò lára ẹni. (Sáàmù 51:11) Àmọ́ ṣá o, tínú ẹnì kan bá bà jẹ́ gan-an nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, ó ṣeé ṣe kí ìyẹn jẹ́ ẹ̀rí pé onítọ̀hún ronú pìwà dà látọkànwá. Ṣùgbọ́n kí ni ojúlówó ìrònúpìwàdà?

4. (a) Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn ronú pìwà dà? (b) Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ Sáàmù 103:10-14 fi jẹ́ ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú gan-an?

4 Téèyàn bá ronú pìwà dà, ó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún ti yí èrò ọkàn rẹ̀ padà nípa irú ojú tó fi ń wo ẹ̀ṣẹ̀ tó dá tàbí ẹ̀ṣẹ̀ tó ń gbèrò àtidá. Ó túmọ̀ sí pé ó kẹ́dùn tàbí pé ó kábàámọ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ náà, ó sì ti jáwọ́ nínú rẹ̀. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé a ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá, ṣùgbọ́n tá a ti gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ, láti fi hàn pé a ronú pìwà dà lóòótọ́, ọ̀rọ̀ onísáàmù tó tẹ̀ lé e yìí lè jẹ́ ìtùnú fún wa. Ó ní: “Òun [Jèhófà] kì í ṣe sí wa àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa; bẹ́ẹ̀ ni òun kì í mú ohun tí ó yẹ wá wá sórí wa gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣìnà wa. Nítorí pé bí ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ ga lọ́lá sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Bí yíyọ oòrùn ti jìnnà réré sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ìrélànàkọjá wa jìnnà réré sí wa. Bí baba ti ń fi àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fi àánú hàn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.”—Sáàmù 103:10-14.

5, 6. Sọ kókó inú 1 Jòhánù 3:19-22, kó o sì sọ ohun tí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Jòhánù yẹn túmọ̀ sí.

5 Ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ ń tuni nínú bákan náà. Ó ní: “Nípa èyí ni àwa yóò mọ̀ pé a pilẹ̀ṣẹ̀ láti inú òtítọ́, a óò sì fún ọkàn-àyà wa ní ìdánilójú níwájú rẹ̀ ní ti ohun yòówù nínú èyí tí ọkàn-àyà wa ti lè dá wa lẹ́bi, nítorí Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo. Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, bí ọkàn-àyà wa kò bá dá wa lẹ́bi, a ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lọ́dọ̀ Ọlọ́run; ohun yòówù tí a bá sì béèrè ni a ń rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, nítorí a ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, a sì ń ṣe àwọn ohun tí ó dára lójú rẹ̀.”—1 Jòhánù 3:19-22.

6 A “mọ̀ pé a pilẹ̀ṣẹ̀ láti inú òtítọ́” nítorí pé a ní ìfẹ́ ará, a kò sì sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà. (Sáàmù 119:11) Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ọkàn wa ń dá wa lẹ́bi ṣáá nítorí nǹkan kan, ńṣe ni ká máa rántí pé “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” Jèhófà máa ń fi àánú hàn sí wa nítorí ó mọ̀ pé a ní “ìfẹ́ni ará tí kò ní àgàbàgebè,” ó mọ̀ pé à ń bá ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀yáàjà, ó sì mọ gbogbo ipá tá à ń sà láti lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (1 Pétérù 1:22) Ọkàn wa ‘kò ní dá wa lẹ́bi’ tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tá a ní ìfẹ́ ará, tá ò sì máa mọ̀ọ́mọ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀. Tá a bá ń gbàdúrà, àá ní “òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lọ́dọ̀ Ọlọ́run,” yóò sì gbọ́ àdúrà wa nítorí pé à ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.

Àwọn Wọ̀nyí Ṣẹ̀ sí Ẹ̀mí Mímọ́

7. Kí ló ń pinnu bóyá ẹ̀ṣẹ̀ kan máa ní ìdáríjì tàbí kò ní ní?

7 Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni kò ní ìdáríjì? Láti lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn èèyàn kan nínú Bíbélì. Ó yẹ kí èyí jẹ́ ìtùnú fún wa tá a bá ti ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wa àmọ́ tí ìbànújẹ́ ọkàn ṣì ń bá wa nítorí àwọn àṣìṣe ńlá tá a ṣe. A óò rí i pé irú ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn dá nìkan kọ́ ló ń pinnu bóyá Ọlọ́run máa dárí jì í tàbí kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó ń pinnu rẹ̀ ni ohun tó sún onítọ̀hún ṣe é, bí ọkàn rẹ̀ ṣe rí nípa ẹ̀ṣẹ̀ náà àti bí ẹ̀ṣẹ̀ náà ṣe jẹ́ àmọ̀ọ́mọ̀dá tó.

8. Báwo làwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù kan ní ọ̀rúndún kìíní ṣe ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́?

8 Ẹ̀ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́ làwọn aṣáájú ìsìn ọ̀rúndún kìíní dá bí wọ́n ṣe ń fi inú burúkú ta ko Jésù Kristi. Wọ́n rí i pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń ṣiṣẹ́ lára Jésù bó ṣe ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ tó ń gbé Jèhófà ga. Síbẹ̀, àwọn aṣáájú ìsìn tó jẹ́ ọ̀tá Kristi yìí sọ pé Sátánì Èṣù ló fún un lágbára tó ń lò. Ohun tí Jésù sì sọ ni pé ẹnikẹ́ni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́ dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì “nínú ètò àwọn nǹkan yìí tàbí nínú èyí tí ń bọ̀.”—Mátíù 12:22-32.

9. Kí ni ọ̀rọ̀ òdì, kí ni Jésù sì sọ nípa rẹ̀?

9 Ọ̀rọ̀ òdì jẹ́ ọ̀rọ̀ ìbanijẹ́, ọ̀rọ̀ tó ń ṣèpalára tàbí ọ̀rọ̀ àbùkù. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lẹ̀mí mímọ́ ti wá, tẹ́nikẹ́ni bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí rẹ̀ yìí, Ọlọ́run lonítọ̀hún ń sọ̀rọ̀ òdì sí yẹn. Ẹni tó bá sì ń forí kunkun bá a nìṣó láti sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kò lè rí ìdáríjì gbà. Ohun tí Jésù sọ nípa irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn tó mọ̀ọ́mọ̀ ń ta ko ohun tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń ṣe ni Jésù ń bá wí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹ̀mí Jèhófà ni Jésù ń lò, táwọn alátakò rẹ̀ sì wá ń sọ pé ẹ̀mí Èṣù ni, ọ̀rọ̀ òdì ni wọ́n ń sọ sí ẹ̀mí mímọ́ yẹn, èyí tí í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. Ìyẹn ni Jésù fi sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, kò ní ìdáríjì kankan títí láé, ṣùgbọ́n ó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ àìnípẹ̀kun.”—Máàkù 3:20-29.

10. Kí nìdí tí Jésù fi pe Júdásì ní “ọmọ ìparun”?

10 Tún wo ọ̀rọ̀ ti Júdásì Ísíkáríótù. Ó di aláìṣòótọ́ èèyàn, ó bẹ̀rẹ̀ sí í jí owó inú àpótí tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ rẹ̀. (Jòhánù 12:5, 6) Nígbà tó yá, Júdásì lọ bá àwọn olórí àwọn Júù gbìmọ̀ pọ̀, ó sì fi Jésù lé wọn lọ́wọ́ fún ọgbọ̀n owó fàdákà. Lóòótọ́, Júdásì kábàámọ̀ lẹ́yìn tó ti fi Jésù lé wọn lọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ tó mọ̀ọ́mọ̀ dá yìí. Nítorí náà, àjíǹde ò tọ́ sí Júdásì. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi pè é ní “ọmọ ìparun.”—Jòhánù 17:12; Mátíù 26:14-16.

Àwọn Wọ̀nyí Kò Ṣẹ̀ sí Ẹ̀mí Mímọ́

11-13. Báwo ni Dáfídì Ọba ṣe dẹ́ṣẹ̀ nínú ọ̀ràn ti Bátí-ṣébà, ìtùnú wo ni ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bójú tó ọ̀rọ̀ yẹn fúnni?

11 Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìbànújẹ́ ọkàn ṣì lè máa bá Kristẹni kan nítorí òfin Ọlọ́run tó ti rú sẹ́yìn kódà lẹ́yìn tó ti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, táwọn alàgbà ìjọ sì ti ràn án lọ́wọ́ láti mú kó tún ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. (Jákọ́bù 5:14) Tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ń ṣe wá, ó ṣeé ṣe kí àgbéyẹ̀wò ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa àwọn tí Ọlọ́run ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì ràn wá lọ́wọ́.

12 Dáfídì Ọba dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì nínú ọ̀ràn ti Bátí-ṣébà aya Ùráyà. Ó ṣẹlẹ̀ pé bí obìnrin arẹwà yìí ṣe ń wẹ̀, Dáfídì rí i láti òkè ilé rẹ̀, ó ní kí wọ́n lọ mú un wá sí ààfin òun, ó sì bá a ṣèṣekúṣe. Nígbà tó wá gbọ́ pé obìnrin náà lóyún, ó dá ọgbọ́n kan tí Ùráyà ọkọ obìnrin náà á fi lè bá a lò pọ̀ kí ìyẹn lè bo panṣágà tí wọ́n ṣe mọ́lẹ̀. Nígbà tí ìyẹn já sí pàbó, Dáfídì ta ọgbọ́n kan tí wọ́n fi pa Ùráyà lójú ogun. Lẹ́yìn náà, ó wá fi Bátí-ṣébà ṣaya, ìyẹn sì bí ọmọ kan fún un bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ náà kú.—2 Sámúẹ́lì 11:1-27.

13 Jèhófà ṣèdájọ́ ọ̀rọ̀ Dáfídì àti Bátí-ṣébà. Ó dárí ji Dáfídì, bóyá nítorí pé ó wo àwọn nǹkan kan mọ́ ọn lára, irú bí ẹ̀mí ìrònúpìwàdà rẹ̀ àti májẹ̀mú Ìjọba tó bá a dá. (2 Sámúẹ́lì 7:11-16; 12:7-14) Ó ní láti jẹ́ pé Bátí-ṣébà pẹ̀lú lẹ́mìí ìrònúpìwàdà, torí pé ó dẹni tí Ọlọ́run fún láǹfààní láti bí Sólómọ́nì tó di Ọba, àtọmọdọ́mọ rẹ̀ sì tún ni Jésù Kristi. (Mátíù 1:1, 6, 16) Tó bá jẹ́ pé a ti dẹ́ṣẹ̀, ó dára ká rántí pé Jèhófà máa ń kíyè sí ẹ̀mí ìrònúpìwàdà wa.

14. Báwo ni ọ̀ràn Mánásè Ọba ṣe jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe ń dárí jini tó?

14 A tún lè rí bí Jèhófà ṣe ń dárí jini tó nínú ọ̀ràn ti Mánásè ọba Júdà. Mánásè ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà. Ó gbé àwọn pẹpẹ kalẹ̀ fún Báálì, ó ń sin “gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run,” kódà ó tiẹ̀ mọ pẹpẹ àwọn òrìṣà sínú àgbàlá méjèèjì tó wà nínú tẹ́ńpìlì. Ó mú káwọn ọmọ rẹ̀ la iná kọjá, ó mú káwọn èèyàn máa bá ẹ̀mí èṣù lò, ó sì mú kí àwọn èèyàn Júdà àti Jerúsálẹ́mù “ṣe ohun tí ó burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà pa rẹ́ ráúráú kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” Àwọn wòlíì Ọlọ́run kìlọ̀ títí kò gbọ́. Nígbà tó ṣe, ọba Ásíríà mú Mánásè nígbèkùn. Mánásè wá ronú pìwà dà ní ìgbèkùn tó wà, ó sì ń fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà sí Ọlọ́run ṣáá. Ọlọ́run sì dárí jì í, ó mú kó padà sípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Jerúsálẹ́mù, tó fi wá dẹni tó ń gbé ìsìn mímọ́ ga.—2 Kíróníkà 33:2-17.

15. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pétérù, èyí tó jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń dárí jini “lọ́nà títóbi”?

15 Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pétérù dẹ́ṣẹ̀ ńlá, ó sẹ́ Jésù, ó lóun ò mọ̀ ọ́n rí. (Máàkù 14:30, 66-72) Ṣùgbọ́n Jèhófà dárí jí Pétérù “lọ́nà títóbi.” (Aísáyà 55:7) Kí nìdí? Ìdí ni pé ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn. (Lúùkù 22:62) Ẹ̀rí pé Ọlọ́run dárí jì í hàn kedere ní àádọ́ta ọjọ́ lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì. Lọ́jọ́ náà, Ọlọ́run fún Pétérù láǹfààní àrà ọ̀tọ̀, ó mú kó lè wàásù nípa Jésù láìṣojo. (Ìṣe 2:14-36) Ǹjẹ́ ó wá yẹ ká rò pé Ọlọ́run yìí kan náà kò ní dárí ji Kristẹni èyíkéyìí tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn lóde òní? Onísáàmù kọ ọ́ lórin pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró? Nítorí ìdáríjì tòótọ́ ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ, kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.”—Sáàmù 130:3, 4.

Bí Ìbẹ̀rù Pé A Ti Ṣẹ̀ sí Ẹ̀mí Mímọ́ Ṣe Lè Dín Kù

16. Kí la ní láti ṣe kí Ọlọ́run tó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wá?

16 Ó yẹ kí àwọn àpẹẹrẹ tá a mẹ́nu kàn yìí mú kí àníyàn wa nípa bóyá a ti ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́ dín kù. Àwọn àpẹẹrẹ yẹn jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà. Ṣùgbọ́n ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká fi taratara gbàdúrà sí Ọlọ́run. Tó bá jẹ́ pé a ti dẹ́ṣẹ̀, a lè bẹ Jèhófà pé kó dárí jì wá lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù àti lọ́lá àánú Jèhófà, àti pé kó wo ti àìpé tá a jogún mọ́ wa lára, kó sì rántí bá a ṣe ń fi ìṣòtítọ́ sìn ín látẹ̀yìnwá. Nígbà tá a sì ti mọ̀ pé Jèhófà máa ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn síni, a lè tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé yóò gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa.—Éfésù 1:7.

17. Téèyàn bá dẹ́ṣẹ̀ àmọ́ tó ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ kí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà lè padà bọ̀ sípò, kí ló ní láti ṣe?

17 Téèyàn bá dẹ́ṣẹ̀ àmọ́ tí kò lè gbàdúrà sí Ọlọ́run mọ́ torí pé ẹ̀ṣẹ̀ náà ti ba àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ńkọ́? Ohun tí ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù sọ pé kírú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe ni pé: “Kí ó pe àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì gbàdúrà lé e lórí, ní fífi òróró pa á ní orúkọ Jèhófà. Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì mú aláàárẹ̀ náà lára dá, Jèhófà yóò sì gbé e dìde. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí ó bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀, a óò dárí rẹ̀ jì í.”—Jákọ́bù 5:14, 15.

18. Bí wọ́n bá yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́, kí nìdí tíyẹn ò fi fi dandan túmọ̀ sí pé ẹ̀ṣẹ̀ onítọ̀hún ò ní ìdáríjì?

18 Kódà bí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan ò bá ronú pìwà dà nígbà tó dẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n sì yọ ọ́ lẹ́gbẹ́, ìyẹn ò fi dandan túmọ̀ sí pé ó ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì. Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa ẹni àmì òróró kan nínú ìjọ Kọ́ríńtì tó dẹ́ṣẹ̀ tí kò sì ronú pìwà dà ni pé: “Ìbáwí mímúná yìí tí ọ̀pọ̀ jù lọ fi fún un ti tó fún irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé, dípò èyí nísinsìnyí, kí ẹ fi inú rere dárí jì í, kí ẹ sì tù ú nínú, pé lọ́nà kan ṣáá, kí ìbànújẹ́ rẹ̀ tí ó pàpọ̀jù má bàa gbé irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ mì.” (2 Kọ́ríńtì 2:6-8; 1 Kọ́ríńtì 5:1-5) Àmọ́ tẹ́nì kan bá dẹ́ṣẹ̀, kí àjọṣe òun àti Jèhófà tó lè padà dán mọ́rán, ó ní láti kọ́kọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn alàgbà kí wọ́n lè fi Bíbélì ràn án lọ́wọ́, ó sì ní láti fẹ̀rí hàn pé òun ti ronú pìwà dà lóòótọ́, kó sì “mú àwọn èso tí ó yẹ ìrònúpìwàdà jáde.”—Lúùkù 3:8.

19. Kí ló máa jẹ́ ká lè máa bá a lọ láti jẹ́ “onílera nínú ìgbàgbọ́”?

19 Irú àwọn nǹkan wo ló lè mú kéèyàn máa rò pé òun ti ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́? Àìlera ara tàbí ṣíṣe òfíntótó ara ẹni lè wà lára ohun tó fà á. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí onítọ̀hún tẹra mọ́ àdúrà gbígbà kó sì túbọ̀ máa sinmi. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká má ṣe jẹ́ kí Sátánì bu ìrẹ̀wẹ̀sì lù wá láti mú wa ṣíwọ́ sísin Ọlọ́run. Níwọ̀n bí Jèhófà kò ti ní inú dídùn sí ikú èèyàn búburú, ó dájú pé kì í fẹ́ pàdánù èyíkéyìí lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Nítorí náà, tí ẹ̀rù bá ń bà wá pé a ti ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́, ńṣe ni ká máa bá a nìṣó ní kíka Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, pàápàá àwọn ibi tó ń tuni nínú gan-an bíi Sáàmù. Ká máa lọ sípàdé ìjọ déédéé ká sì máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Tá a bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyẹn, ìyẹn á jẹ́ ká di “onílera nínú ìgbàgbọ́,” a ó sì lè bọ̀ lọ́wọ́ àníyàn nípa bóyá a ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì.—Títù 2:2.

20. Àwọn nǹkan wo lèèyàn lè ronú lé tí yóò jẹ́ kó rí i pé òun ò ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́?

20 Bí ẹnì kan bá ń bẹ̀rù pé òun ti ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́, ó lè bi ara rẹ̀ pé: ‘Ǹjẹ́ mo sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́? Ǹjẹ́ mo ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ mi tọkàntọkàn? Ǹjẹ́ mo nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa ń dárí jini? Ṣé mo ti di apẹ̀yìndà tó kẹ̀yìn sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ ni?’ Àfàìmọ̀ lonítọ̀hún ò ní rí i pé òun ò sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni òun kò di apẹ̀yìndà. Yóò rí i pé òun ti ronú pìwà dà, òun ò sì ṣiyèméjì rárá pé Jèhófà máa ń dárí jini. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́ rárá.

21. Àwọn ìbéèrè wo ni àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí máa dáhùn?

21 Ìtura gbáà ló máa ń jẹ́ téèyàn bá mọ̀ dájú pé òun ò ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́! Ṣùgbọ́n a óò tún gbé ìbéèrè tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí. Bí àpẹẹrẹ, kálukú wa lè bi ara rẹ̀ pé: ‘Ǹjẹ́ ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí mi ní ti gidi? Ǹjẹ́ èso ẹ̀mí Ọlọ́run ń hàn kedere nígbèésí ayé mi?’

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ó ṣeé ṣe kéèyàn ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́?

• Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn ronú pìwà dà?

• Àwọn wo ló ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́ nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé?

• Báwo lèèyàn ṣe lè borí àníyàn pé òun ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn tó sọ pé ẹ̀mí èṣù ni Jésù fi ń ṣe iṣẹ́ ìyanu ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Lóòótọ́ Pétérù sẹ́ Jésù, àmọ́ kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì ló ṣẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́