Àánú Jehofa Ń Gbà Wá Là Kuro Ninu Ainireti
“Ọlọrun, ṣaanu fun mi, gẹgẹ bi iṣeun-ifẹ rẹ: gẹgẹ bi irọnu ọpọ aanu rẹ, nu irekọja mi nù kuro.”—ORIN DAFIDI 51:1.
1, 2. Bawo ni ẹṣẹ wiwuwo ṣe lè nipa lori ọ̀kan lara awọn iranṣẹ Jehofa?
OFIN Jehofa ni a kò lè ṣẹ̀sí laijiya. Ẹ wo bi iyẹn ti ṣe kedere tó bi awa bá dá awọn ẹṣẹ wiwuwo ribiribi kan lodisi Ọlọrun! Bi o tilẹ jẹ pe awa ti lè fi iṣotitọ ṣiṣẹsin Jehofa fun ọpọ ọdun, ṣíṣẹ̀ sí ofin rẹ̀ lè ṣokunfa aniyan ńláǹlà tabi ìkárísọ jijinlẹ. A lè nimọlara pe Jehofa ti fi wá silẹ ati pe awa kò yẹ ni ẹni tíí ṣiṣẹsin in mọ́. Ẹṣẹ wa lè dabi awọsanmọ titobi kan ti ń dí ìmọ́lẹ̀ ojurere Ọlọrun pa.
2 Ọba Dafidi ti Israeli igbaani bá araarẹ̀ ninu iru ipo bẹẹ rí. Bawo ni ipo yii ṣe gbèrú?
Ìṣisẹ̀gbé Lè Ṣamọna si Ẹṣẹ Buburu Lékenkà
3, 4. Ki ni o ṣẹlẹ si Ọba Dafidi ni ìgbà aásìkí?
3 Dafidi fẹran Ọlọrun ṣugbọn ó gbé ìgbésẹ̀ òdì ti ó ṣamọna si ẹṣẹ gbígbópọn. (Fiwe Galatia 6:1.) Eyi lè ṣẹlẹ si eniyan alaipe eyikeyii, ni pataki bi o bá ni àṣẹ lori awọn ẹlomiran. Gẹgẹ bi ọba alaasiki kan, Dafidi gbadun okiki ati agbara. Ta ni ó tó lati fọwọ́ pa idà rẹ̀ lójú? Awọn abarapá ọkunrin wà ní sẹpẹ́ fun un, awọn eniyan sì ń fi iharagaga ṣe ohun ti ó bá sọ fun wọn pe ki wọn ṣe. Sibẹ, Dafidi ṣàṣìṣe nipa fífẹ́ iyawo rẹpẹtẹ fun araarẹ̀ ati kíka awọn eniyan.—Deuteronomi 17:14-20; 1 Kronika 21:1.
4 Nigba ìláásìkí ohun ti ara yii, Dafidi dá awọn ẹṣẹ wiwuwo lodisi Ọlọrun ati eniyan. Họwu, ẹṣẹ kan ń sokunfa omiran bi fọ́rán òwú lilọpọmọra lara aṣọ kan ti Satani hun! Nigba ti awọn ọmọ Israeli bíi tirẹ̀ ń wọ̀jà pẹlu awọn ará Ammoni, lati ori òrùlé rẹ̀ Dafidi wo Batṣeba, aya Uriah rírẹwà, ti ń wẹ̀. Bi Uriah ti wà loju ogun, ọba mú ki wọ́n mu obinrin naa wọle wá sinu aafin oun ó sì dẹṣẹ panṣaga pẹlu rẹ̀. Ronuwoye ìjayà rẹ̀ nigba ti ó mọ̀ lẹhin naa pe ó ti lóyún! Dafidi ranṣẹ si Uriah, ni rireti pe yoo sùn pẹlu Batṣeba ni òru ọjọ naa ti yoo sì ka ọmọ naa sí tirẹ̀. Bi o tilẹ jẹ pe Dafidi mú ki a rọ ọ́ lọ́tí yó, Uriah kọ̀ lati sùn pẹlu rẹ̀. Bi o ti gbekuta nisinsinyi, Dafidi pàṣẹ ìkọ̀kọ̀ ranṣẹ si Joabu olori-ogun lati fi Uriah siwaju ìlà ogun nibi ti oun yoo ti kú dajudaju. Uriah ni a pa ni oju ogun, aya rẹ̀ opó pa sáà akoko ọ̀fọ̀ mọ́ bi o ti sábà maa ń rí, Dafidi sì fẹ́ ẹ ni aya ṣaaju ki awọn eniyan tó mọ̀ nipa oyún rẹ̀.—2 Samueli 11:1-27.
5. Ki ni ó wáyé lẹhin ti Dafidi dẹṣẹ pẹlu Batṣeba, ipa wo sì ni awọn ẹṣẹ rẹ̀ ní lori rẹ̀?
5 Nipasẹ wolii Natani, Ọlọrun tudii aṣiri ẹṣẹ Dafidi ó sì wi pe: “Emi ó jẹ́ ki ibi ki o dide si ọ lati inu ile rẹ wá.” Ni ibamu pẹlu eyi, ọmọ naa ti Batṣeba bí kú. (2 Samueli 12:1-23) Ọmọkunrin akọbi Dafidi, Amnoni, fipá bá arabinrin ọmọ baba rẹ̀ Tamari lòpọ̀ arakunrin rẹ̀ si ṣeku pa á. (2 Samueli 13:1-33) Absalomu ọmọkunrin ọba gbiyanju lati fipa gba ìtẹ́ laibofinmu ó sì kó itiju bá baba rẹ̀ nipa níní ibalopọ takọtabo pẹlu awọn àlè Dafidi. (2 Samueli 15:1–16:22) Ogun abẹ́lé pari pẹlu iku Absalomu ti o sì yọrisi ibanujẹ pupọ sii fun Dafidi. (2 Samueli 18:1-33) Bi o ti wu ki o ri, ẹṣẹ Dafidi rẹ̀ ẹ́ silẹ ó sì mú ki o mọ̀ nipa aini naa lati wà timọtimọ pẹlu Ọlọrun rẹ̀ oníyọ̀ọ́nú. Bi o bá ṣẹlẹ pe a ṣaṣiṣe, ẹ jẹ ki a fi tirẹlẹtirẹlẹ ronupiwada ki a sì sunmọ Jehofa timọtimọ.—Fiwe Jakọbu 4:8.
6. Eeṣe ti Ọba Dafidi fi jẹbi ni pataki?
6 Dafidi jẹbi ní pataki nitori pe oun jẹ oluṣakoso Israeli ti ó mọ Ofin Jehofa ní àmọ̀dunjú. (Deuteronomi 17:18-20) Oun kìí ṣe farao Egipti tabi ọba Babiloni kan ti ó ṣalaini iru ìmọ̀ bẹẹ ti ó sì lè maa ṣe awọn ohun ti Ọlọrun kò tẹwọgba ni aṣetunṣe. (Fiwe Efesu 2:12; 4:18.) Gẹgẹ bi mẹmba orilẹ-ede kan ti a yasimimọ fun Jehofa, Dafidi mọ̀ daju pe panṣaga ati ipaniyan jẹ́ ẹṣẹ biburu lékenkà. (Eksodu 20:13, 14) Awọn Kristian pẹlu mọ ofin Ọlọrun. Bi Dafidi, bi o ti wu ki o ri, diẹ ninu wọn ń rú u nitori ipo ẹṣẹ àjogúnbá, ailera eniyan, ati idẹwo ti a kò dènà rẹ̀. Bi iyẹn bá nilati ṣẹlẹ si enikẹni ninu wa, a kò nilati maa baa lọ ni wíwà ninu ipo kan ti a mu ṣokunkun biribiri ti ń sọ iriran tẹmi wa di bàìbàì ti ó sì bò wá loju ninu ainireti jijinlẹ.
Ìjẹ́wọ́ Ń Mú Itura Wá
7, 8. (a) Ki ni ó ṣẹlẹ si Dafidi nigba ti o gbiyanju lati bo ẹṣẹ rẹ̀ mọlẹ? (b) Eeṣe ti ẹnikan fi nilati jẹwọ ẹṣẹ rẹ̀ ki o sì kọ̀ ọ́ silẹ?
7 Bi a bá jẹbi ìtàpá si ofin Ọlọrun lọna ti o gbópọn, a lè ri pe ó ṣoro fun wa lati jẹ́wọ́ awọn ẹṣẹ wa, àní fun Jehofa paapaa. Ki ni ó lè ṣẹlẹ labẹ awọn ipo-ayika wọnni? Ninu Orin Dafidi 32, Dafidi jẹwọ pe: “Nigba ti mo dakẹ [dipo jijẹwọ], egungun mi di gbígbó nitori igbe mi ni gbogbo ọjọ. Nitori ni ọ̀sán ati ni òru, ọwọ rẹ [Jehofa] wuwo si mi lara: omi ara mi sì dabi ọ̀dá-ẹ̀ẹ̀rùn.” (Ẹsẹ 3, 4) Igbiyanju lati bo ẹṣẹ rẹ̀ ki ó sì tẹ ẹ̀rí-ọkàn ẹlẹ́bi-ẹ̀ṣẹ̀ rì mú ki Dafidi oníwàkiwà gbó. Idaamu dín okun ara rẹ̀ kù pupọpupọ tobẹẹ debi pe ó dabi igi ti ọ̀dá-ẹ̀ẹ̀rùn ti kọlu laisi ọ̀rinrin ti ń funni ni ìyè. Niti tootọ, oun ti lè niriiri iyọrisi buburu gbáà niti ero-ori ati ti ara-ìyára. Sibẹ naa, ó padanu ayọ rẹ̀. Bi ẹnikẹni ninu wa bá rí araawa ninu ipo ti o rí bakan naa, ki ni a nilati ṣe?
8 Ìjẹ́wọ́ fun Ọlọrun lè mú idariji ati itura wá. “Emi jẹ́wọ́ ẹṣẹ mi fun ọ, ati ẹṣẹ mi ni emi kò sì fi pamọ́,” ni Dafidi kọ lórin. “Emi wi pe, emi ó jẹ́wọ́ irekọja mi fun Oluwa: iwọ sì dari ẹbi ẹṣẹ mi jì.” (Orin Dafidi 32:5) Idaamu ha bá ọ nitori awọn ẹṣẹ kan ti o fi pamọ́ bi? Kò ha ní sàn julọ lati jẹ́wọ́ ki o sì fi i silẹ ki o baa lè rí àánú Ọlọrun gba bi? Eeṣe ti o kò késí awọn alagba ijọ ki o sì wá imularada tẹmi? (Owe 28:13; Jakọbu 5:13-20) Ẹmi onironupiwada rẹ ni a o mọ̀ daju, bi akoko sì ti ń lọ ayọ Kristian rẹ ni a o mu padabọsipo. “[Ayọ] ni fun awọn ti a dárí irekọja wọn jì, ti a bo ẹṣẹ wọn mọlẹ,” ni Dafidi sọ. “[Ayọ] ni fun ọkunrin naa ẹni ti Oluwa kò ka ẹṣẹ si lọ́rùn, ati ninu ẹmi ẹni ti ẹ̀tàn kò sí.”—Orin Dafidi 32:1, 2.
9. Ìgbà wo ni a ṣakojọ Orin Dafidi 51, eesitiṣe?
9 Dafidi ati Batṣeba jihin fun Jehofa Ọlọrun fun iwa-aitọ wọn. Bi o tilẹ jẹ pe à bá ti pa wọn fun ẹṣẹ wọn, Ọlọrun ṣaanu fun wọn. Ní pataki ni oun kún fun àánú si Dafidi nitori majẹmu Ijọba naa. (2 Samueli 7:11-16) Iṣarasihuwa onironupiwada Dafidi si ẹṣẹ rẹ̀ ti ó wémọ́ Batṣeba ni a rí ni Orin Dafidi 51. Orin ti ó wọnilọkan ṣinṣin yii ni ọba ti ń jiya ẹṣẹ naa kójọ lẹhin ti wolii Natani ta ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ jí si ìtóbi awọn ìrékọjá ofin atọrunwa rẹ̀. Ó gba igboya fun Natani lati mú awọn ẹṣẹ Dafidi wá si afiyesi rẹ̀, àní bi awọn Kristian alagba ti a yàn sipo ṣe gbọdọ jẹ́ onigboya ki wọn baa lè ṣe iru awọn nǹkan bẹẹ lonii. Dipo sísẹ́ ẹ̀sùn naa ki ó sì paṣẹ ifiya-iku-jẹni fun Natani, ọba naa fi tirẹlẹtirẹlẹ jẹ́wọ́. (2 Samueli 12:1-14) Orin Dafidi 51 fi ohun ti o sọ fun Ọlọrun ninu adura nipa awọn igbesẹ alaibọla funni rẹ̀ hàn ó sì yẹ fun ironujinlẹ ti o kun fun adura, ni pataki bi a bá ti ṣaṣiṣe ti a sì ń yánhànhàn fun àánú Jehofa.
A O Jihin fun Ọlọrun
10. Bawo ni Dafidi ṣe lè niriiri ìkọ́fẹpadà tẹmi?
10 Dafidi kò wá ọ̀nà lati ṣàwáwí fun ẹṣẹ rẹ̀ ṣugbọn ó bẹ̀bẹ̀ pe: “Ọlọrun, ṣaanu fun mi, gẹgẹ bi iṣeun-ifẹ rẹ: gẹgẹ bi irọnu ọpọ àánú rẹ, nu irekọja mi nù kuro.” (Orin Dafidi 51:1) Nipa ìrékọjá, Dafidi ti kọja ààlà Ofin Ọlọrun. Ireti wà fun imularada tẹmi rẹ̀, bi o ti wu ki o ri, bi Ọlọrun bá fi ojurere hàn sí i ni ibamu pẹlu iṣeun-ifẹ Rẹ̀, tabi ifẹ aduroṣinṣin rẹ̀. Ọpọ yanturu awọn àánú Ọlọrun nigba ti o ti kọja fún ọba ti o fi ironupiwada hàn naa ni idi fun igbagbọ pe Oluṣẹda rẹ̀ yoo nu awọn ìrékọjá rẹ̀ nù kuro.
11. Ki ni awọn ẹbọ Ọjọ Ètùtù damọran, ki sì ni a beere fun igbala lonii?
11 Nipasẹ ojiji alasọtẹlẹ ti awọn irubọ Ọjọ Ètùtù, Jehofa mú ki ó yéni pe oun ní ọ̀nà kan lati gba wẹ awọn ẹlẹṣẹ ti wọn ronupiwada kuro ninu ẹṣẹ wọn mọ́. A wá mọ̀ nisinsinyi pe àánú ati idariji rẹ̀ ni a mú gbooro dé ọ̀dọ̀ wa lori ipilẹ igbagbọ wa ninu ẹbọ irapada Jesu Kristi. Bi Dafidi bá lè ni igbẹkẹle ninu iṣeun-ifẹ ati àánú Jehofa, pẹlu kìkì iru ati ojiji ẹbọ yii lọ́kàn, meloomeloo ni awọn iranṣẹ Ọlọrun lode-oni ṣe nilati lo igbagbọ ninu irapada ti a pese fun igbala wọn!—Romu 5:8; Heberu 10:1.
12. Ki ni o tumọsi lati dẹṣẹ, bawo sì ni imọlara Dafidi ti ri nipa iwa-aitọ rẹ̀?
12 Ninu ọ̀rọ̀ ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ rẹ̀ niwaju Ọlọrun, Dafidi fikun un pe: “Wẹ̀ mi ní àwẹ̀mọ́ kuro ninu aiṣedeedee mi, ki o sì wẹ̀ mi nù kuro ninu ẹṣẹ mi. Nitori ti mo jẹwọ irekọja mi: nigba gbogbo ni ẹṣẹ mi sì ń bẹ niwaju mi.” (Orin Dafidi 51:2, 3) Lati ṣẹ̀ jẹ́ lati tàsé àmì nipa awọn ọpa-idiwọn Jehofa. Dafidi sì ti ṣe bẹẹ nitootọ. Sibẹ, oun kìí ṣe bi apànìyàn kan tabi panṣaga ọkunrin kan tí kò bikita nipa aṣiṣe rẹ̀, ti ó wulẹ banujẹ lori ijiya rẹ̀ tabi ṣiṣeeṣe naa lati kó èèràn aisan. Gẹgẹ bi olùfẹ́ Jehofa, Dafidi koriira ohun ti o jẹ́ ibi. (Orin Dafidi 97:10) Ẹṣẹ rẹ̀ fúnraarẹ̀ kó o niriira ó sì fẹ́ ki Ọlọrun wẹ oun nù kuro ninu rẹ̀ patapata. Dafidi mọ̀ nipa ìrékọjá rẹ̀ lẹkun-un-rẹrẹ ó sì kabaamọ lọna ti o jinlẹ debi pe oun ti jẹ́ ki ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ ti ó kun fun ẹṣẹ bori rẹ̀. Ẹṣẹ rẹ̀ wà niwaju rẹ̀ nigba gbogbo, nitori pe ẹ̀rí-ọkàn ẹlẹ́bi-ẹ̀ṣẹ̀ ti olùbẹ̀rù Ọlọrun kan ni ara kìí dẹ̀ titi di ìgbà ti ironupiwada, ijẹwọ, ati idariji Jehofa bá tó wà.
13. Eeṣe ti Dafidi fi nilati sọ pe oun ti dẹṣẹ si Ọlọrun nikanṣoṣo?
13 Ni jijẹwọgba ijihin rẹ̀ fun Jehofa, Dafidi sọ pe: “Iwọ, iwọ nikanṣoṣo ni mo ṣẹ̀ sí, ti mo ṣe buburu yii niwaju rẹ: ki a lè dá ọ láre, nigba ti iwọ ba ń sọrọ, ki ara rẹ ki o lè mọ́, nigba ti iwọ ba ń ṣe idajọ.” (Orin Dafidi 51:4) Dafidi ti rú awọn ofin Ọlọrun, ó ti ṣaibọla fun ipo ọba, oun sì ti “fi ààyè silẹ fun awọn ọ̀tá Oluwa lati sọ ọ̀rọ̀ òdì,” ní mimu ki O yẹ ni pípẹ̀gàn sí. (2 Samueli 12:14; Eksodu 20:13, 14, 17) Awọn igbesẹ Dafidi ti o kun fun ẹṣẹ tun jẹ́ láìfí si awujọ Israeli ati awọn mẹmba idile rẹ̀, gan-an gẹgẹ bi olùṣàìtọ́ kan ti o ti ṣe iribọmi lonii ṣe ń ṣokunfa ibanujẹ tabi idaamu ninu ijọ Kristian ati laaarin awọn ololufẹ. Bi o tilẹ jẹ pe ọba ti ó ronupiwada naa mọ̀ pe oun ti dẹṣẹ si iru eniyan ẹlẹgbẹ rẹ̀ bẹẹ bi Uriah, o mọ pe Jehofa ni oun jẹ ní gbèsè ijihin ti o ga jù. (Fiwe Genesisi 39:7-9.) Dafidi mọ̀ daju pe idajọ Jehofa yoo jẹ́ ododo. (Romu 3:4) Awọn Kristian ti wọn bá ti dẹ́ṣẹ̀ nilati ní oju-iwoye kan-naa.
Awọn Ipo Amọ́rànfúyẹ́
14. Awọn ipo amọ́rànfúyẹ́ wo ni Dafidi mẹnukan?
14 Bi o tilẹ jẹ pe Dafidi kò gbiyanju lati dá araarẹ̀ láre, ó sọ niti gidi pe: “Kiyesi i, ninu aiṣedeedee ni a gbé bí mi: ati ninu ẹṣẹ ni ìyá mi sì loyun mi.” (Orin Dafidi 51:5) Dafidi ni a bí ninu aiṣedeedee, ìyá rẹ̀ sì niriiri awọn irora ìbímọ nitori ipo-ẹṣẹ ti a jogunba. (Genesisi 3:16; Romu 5:12) Awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò tumọsi pe awọn ajọṣepọ inu igbeyawo, ìlóyún, ati ibimọ bibojumu jẹ́ ẹlẹṣẹ, niwọn bi o ti jẹ́ pe Ọlọrun pese fun igbeyawo ati ọmọ-bíbí; bẹẹ ni kìí ṣe pe Dafidi ń tọka si ẹṣẹ pato eyikeyii ti o jẹ ti ìyá rẹ̀. A loyun rẹ̀ ninu ẹṣẹ nitori pe awọn òbí rẹ̀ jẹ́ ẹlẹṣẹ bi gbogbo awọn eniyan alaipe.—Jobu 14:4.
15. Bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun lè gba ti awọn ipo amọ́rànfúyẹ́ rò, ki ni awa kò gbọdọ ṣe?
15 Bi a bá ti dẹṣẹ, a lè mẹnuba awọn ipo amọ́rànfúyẹ́ eyikeyii ti o ti lè dákún iwa-aitọ wa ninu adura si Ọlọrun. Ṣugbọn ẹ maṣe jẹ ki a yi inurere ailẹtọọsi Ọlọrun pada si àwáwí fun iwa ainijaanu tabi ki a lo ipo ẹṣẹ ti a jogunba gẹgẹ bi ìbòjú lẹhin eyi ti a gọ sí ki a má baa jihin fun ẹṣẹ wa. (Juda 3, 4) Dafidi tẹwọgba ijihin fun fífààyè gba awọn èrò ti kò mọ́ ati jijuwọsilẹ fun idẹwo. Ẹ jẹ ki a gbadura pe ki a má fi wá silẹ fun idẹwo ki a sì gbegbeesẹ ni ibamu pẹlu iru adura bẹẹ lẹhin naa.—Matteu 6:13.
Ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ fun Wíwẹ̀mọ́
16. Animọ wo ni Ọlọrun ni inudidun ninu rẹ̀, bawo sì ni iyẹn ṣe nilati nipa lori iwa wa?
16 Awọn eniyan lè farahan gẹgẹ bi ẹni rere ti o ni ifọkansin fun Ọlọrun, ṣugbọn oun ń wò rekọja ohun ti wọn jẹ́ lode ó sì ń rí ohun ti wọn jẹ́ ninu. Dafidi sọ pe: “Kiyesi i, iwọ [Jehofa] fẹ́ otitọ ni inu: ati niha ikọkọ ni iwọ o mú mi mọ ọgbọn.” (Orin Dafidi 51:6) Dafidi jẹbi èké ṣiṣe ati békebèke ninu fifọgbọndari iku Uriah ati gbigbiyanju lati fi otitọ bò nipa oyun Batṣeba. Sibẹ, oun mọ̀ pe Ọlọrun ni inudidun ninu iṣotitọ ati ijẹmimọ. Eyi nilati nipa lori iwa wa ni ọ̀nà rere, nitori pe Jehofa yoo dá wa lẹbi bi a bá jẹ́ oníbékebèke. (Owe 3:32) Dafidi tun mọ pe bi Ọlọrun yoo bá ‘mú oun mọ ọgbọn,’ gẹgẹ bi ọba kan ti o ronupiwada, oun yoo lè tẹle awọn ọpa-idiwọn atọrunwa ni iyoku igbesi-aye oun.
17. Ki ni ijẹpataki gbigbadura lati di ẹni ti a sọ di mímọ́ pẹlu ewe-hissopu?
17 Nitori pe olorin naa rí aini naa ti o ni fun iranlọwọ Ọlọrun ninu bibori awọn itẹsi ti ó kun fun ẹṣẹ, o jírẹ̀ẹ́bẹ̀ siwaju sii pe: “Fi ewe-hissopu fọ̀ mi, emi ó sì mọ́: wẹ̀ mi, emi ó sì fún ju ẹ̀gbọ̀n-òwú lọ.” (Orin Dafidi 51:7) Papọ pẹlu awọn nǹkan miiran, eweko hissopu (boya marjoram, tabi Origanum maru) ni a ń lò ninu ayẹyẹ iwẹnumọ fun awọn eniyan ti ẹ̀tẹ̀ ti mú ri. (Lefitiku 14:2-7) Nitori naa ó ṣe wẹku pe Dafidi nilati gbadura lati di ẹni ti a sọ di mímọ kuro ninu ẹṣẹ pẹlu hissopu. Èrò ijẹmimọ ni a tun sopọ pẹlu ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ rẹ̀ pe ki Jehofa wẹ oun nù ki oun baa lè di mímọ́ latokedelẹ, ki oun tilẹ funfun ju òjò dídì ti kò tii kó màjàlà tabi pantiri miiran mọra. (Isaiah 1:18) Bi ẹnikẹni ninu wa bá ń jiya irora ẹ̀rí-ọkàn lori awọn iwa-aitọ kan nisinsinyi, ẹ jẹ ki a ní igbagbọ pe bi a bá fi ironupiwada wá idariji Ọlọrun, oun lè sọ wa di mímọ́ ki o sì wẹ̀ wá nù lori ipilẹ ẹbọ irapada Jesu.
Ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ fun Imupadabọsipo
18. Ki ni ipo Dafidi ṣaaju ki o tó ronupiwada ati ki o tó jẹwọ, bawo sì ni ìmọ̀ nipa eyi ṣe lè ràn wá lọwọ lonii?
18 Kristian eyikeyii ti o bá ti jiya ẹ̀rí-ọkàn ẹlẹ́bi-ẹ̀ṣẹ̀ rí lè loye awọn ọ̀rọ̀ Dafidi pe: “Mú mi gbọ ayọ ati inu didun; ki awọn egungun ti iwọ [Jehofa] ti rún ki o lè maa yọ̀.” (Orin Dafidi 51:8) Ṣaaju ki Dafidi tó ronupiwada ki o sì jẹwọ awọn ẹṣẹ rẹ̀, ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ ti a dà laamu mú un wà ninu ipo ibanujẹ. Oun kò tilẹ rí inu didun ninu awọn orin ayọ-aṣeyọri ati yíyọ̀ ti awọn akọrin olóhùn-iyọ̀ ati awọn olorin amọṣẹ́dunjú gbekalẹ. Irora Dafidi ti o dẹṣẹ pọ̀ tobẹẹ nitori airojurere Ọlọrun debi pe oun dabi ọkunrin kan ti a ti fi irora fọ́ egungun rẹ̀. Ó yánhànhàn fun idariji, ìkọ́fẹpadà tẹmi, ati imupadabọsipo ayọ ti oun ti niriiri rẹ̀ ni iṣaaju. Oniwa-aitọ kan ti o ronupiwada lonii tun nilo idariji Jehofa ki o baa lè pada jere ayọ ti ó ni ṣaaju ki ó tó ṣe ohun kan ti ń fi ipo-ibatan rẹ̀ pẹlu Ọlọrun sinu ewu. Imupadabọsipo “ayọ ẹmi mímọ́” fun oluronupiwada kan fihàn pe Jehofa ti dariji i ó sì nifẹẹ rẹ̀. (1 Tessalonika 1:6) Ẹ wo iru itunu ti iyẹn ń mú wá!
19. Bawo ni imọlara Dafidi yoo ti ri bi Ọlọrun bá nu gbogbo aṣiṣe rẹ̀ nù kuro?
19 Dafidi gbadura siwaju sii pe: “Pa oju rẹ mọ́ kuro lara ẹṣẹ mi, ki iwọ ki o sì nu gbogbo aiṣedeedee mi nù kuro.” (Orin Dafidi 51:9) Jehofa ni a kò lè reti pe ki o foju rere wo ẹṣẹ. Fun idi yii, oun ni a beere lọwọ rẹ̀ pe ki o pa oju rẹ̀ mọ́ kuro lara awọn ẹṣẹ Dafidi. Ọba naa tun jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pe ki Ọlọrun nu gbogbo awọn aṣiṣe oun nù kuro, ki o pa gbogbo aiṣododo oun rẹ́. Kìkì bi Jehofa yoo bá ṣe iyẹn! Yoo gbé ẹmi Dafidi soke, yoo gbé ẹrù-ìnira ẹ̀rí-ọkàn ti a kó idaamu bá kuro, yoo sì jẹ ki ọba ti o ti ronupiwada nisinsinyi mọ̀ pe oun ni Ọlọrun rẹ̀ onifẹẹ ti dariji.
Bi Iwọ Bá Ti Dẹṣẹ Ńkọ́?
20. Ki ni a damọran fun Kristian eyikeyii ti o ti dẹṣẹ lọna wiwuwo ribiribi?
20 Orin Dafidi 51 fihàn pe eyikeyii ninu awọn iranṣẹ Jehofa ti o ti ṣeyasimimọ ti o bá ti dẹṣẹ lọna wiwuwo ṣugbọn ti o ronupiwada lè fi igboya beere pe ki o fi ojurere hàn si wọn ki o sì sọ wọn di mímọ́ kuro ninu ẹṣẹ wọn. Bi iwọ bá jẹ́ Kristian kan ti ó ti ṣàṣìṣe ni iru ọ̀nà bẹẹ, eeṣe ti o kò wá idariji Baba wa ọrun ninu adura onirẹlẹ? Mọ aini rẹ fun iranlọwọ Ọlọrun ni àmọ̀dájú ki o baa lè duro ni ẹni itẹwọgba ni iwaju rẹ̀, ki o sì beere pe ki ó mú ayọ rẹ iṣaaju padabọsipo. Awọn Kristian ti wọn ronupiwada lè fi igboya tọ Jehofa lọ ninu adura pẹlu iru awọn ibeere-ẹbẹ bẹẹ, nitori pe “yoo sì fi jì í ni ọpọlọpọ.” (Isaiah 55:7; Orin Dafidi 103:10-14) Dajudaju awọn alagba ijọ ni a nilati késí ki wọn baa lè pese itilẹhin tẹmi ti a nilo.—Jakọbu 5:13-15.
21. Ki ni awa yoo ṣayẹwo tẹle e?
21 Àánú Jehofa ń gba awọn eniyan rẹ̀ là kuro ninu ainireti nitootọ. Ṣugbọn ẹ jẹ ki a ṣayẹwo awọn ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ atọkanwa miiran ti Dafidi ti o ronupiwada ninu Orin Dafidi 51. Ikẹkọọ wa yoo fihàn pe Jehofa kò gan ọkàn ìròbìnújẹ́.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Ipa wo ni ẹṣẹ wiwuwo lè ní lori ọ̀kan lara awọn iranṣẹ Jehofa?
◻ Bawo ni a ṣe nipa lori Dafidi nigba ti o gbiyanju lati bo ẹṣẹ rẹ̀ mọlẹ?
◻ Eeṣe ti Dafidi fi sọ pe oun ti dẹṣẹ si Ọlọrun nikanṣoṣo?
◻ Bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun lè gba ti awọn ipo amọ́rànfúyẹ́ rò bi a bá dẹṣẹ, ki ni awa kò nilati ṣe?
◻ Ki ni Kristian kan nilati ṣe bi o bá ti dẹṣẹ lọna wiwuwo ribiribi?