ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 3/15 ojú ìwé 13-18
  • Jehofa Kò Gan Ọkàn Ìròbìnújẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa Kò Gan Ọkàn Ìròbìnújẹ́
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọkan-Aya Mimọgaara Ni A Nilo
  • Ẹmi Mimọ Ṣekoko
  • Ayọ Igbala
  • Kọ́ Awọn Olùrékọjá Ni Ki Ni?
  • Awọn Ẹbọ Ti O Ni Itẹwọgba Lọdọ Ọlọrun
  • Aniyan fun Ijọsin Mimọgaara
  • Jehofa Ń Gbọ́ Igbe Wa
  • Àánú Jehofa Ń Gbà Wá Là Kuro Ninu Ainireti
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìjẹ́wọ́ Tí Ń Yọrí sí Ìwòsàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Gbára Lé Ẹ̀mí Ọlọ́run Nígbà Tí Ipò Nǹkan Bá Yí Padà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Kí Lo Gbọ́dọ̀ Ṣe Tó O Bá Fẹ́ Kí Jèhófà Dárí Jì ẹ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 3/15 ojú ìwé 13-18

Jehofa Kò Gan Ọkàn Ìròbìnújẹ́

“Ẹbọ Ọlọrun ni irobinujẹ ọkàn: irobinujẹ ati irora àyà, Ọlọrun, ohun ni iwọ kì yoo gàn.”—ORIN DAFIDI 51:17.

1. Oju wo ni Jehofa fi ń wo awọn olujọsin rẹ̀ ti wọn dẹṣẹ wiwuwo ṣugbọn ti wọn ronupiwada?

JEHOFA lè “fi awọsanma bo ara rẹ̀, ki adura má lè là á kọja.” (Ẹkún Jeremiah 3:44) Ṣugbọn ó ń fẹ́ ki awọn eniyan rẹ̀ ní ọ̀nà àtidé ọ̀dọ̀ oun. Àní bi ọ̀kan lara awọn olujọsin rẹ̀ bá nilati ṣàṣìṣe lọna wiwuwo paapaa ṣugbọn ti ó ronupiwada, Baba wa ọrun ń ranti rere ti ẹni yẹn ti ṣe. Fun idi yii, aposteli Paulu lè sọ fun awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ pe: “Ọlọrun kìí ṣe alaiṣododo ti yoo fi gbagbe iṣẹ yin ati ifẹ ti ẹyin fihàn si orukọ rẹ̀.”—Heberu 6:10.

2, 3. Ki ni awọn Kristian alagba nilati gbeyẹwo ninu biba awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn ti ó ṣaṣiṣe lò?

2 Awọn Kristian alagba tun nilati gbé awọn ọdun iṣẹ-isin iṣotitọ ti onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn ti fifun Ọlọrun yẹwo. Eyi ní ninu iṣẹ-isin mímọ́ niha ọ̀dọ̀ awọn oluronupiwada ti wọn ti ṣi ẹsẹ gbé tabi ti wọn tilẹ ti dẹṣẹ lọna gbígbópọn paapaa. Awọn Kristian oluṣọ-agutan ń wá alaafia tẹmi ti gbogbo awọn wọnni ti wọn wà ninu agbo-agutan Ọlọrun.—Galatia 6:1, 2.

3 Oniwa-aitọ kan ti ó ronupiwada nilo àánú Jehofa. Sibẹ, pupọ sii ni a beere. Eyi ni a mú ṣe kedere nipasẹ awọn ọ̀rọ̀ Dafidi ni Orin Dafidi 51:10-19.

Ọkan-Aya Mimọgaara Ni A Nilo

4. Eeṣe ti Dafidi fi gbadura fun ọkan-aya mimọgaara ati ẹmi titun?

4 Bi Kristian oluṣeyasimimọ kan bá wà ninu ipo buburu nipa tẹmi nitori ẹṣẹ, ki ni oun lè nilo yatọ si àánú ati idariji Jehofa? Ó dara, Dafidi jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pe: “Dá àyà titun sinu mi, Ọlọrun; ki o sì tun ọkàn diduro-ṣinṣin ṣe sinu mi.” (Orin Dafidi 51:10) Lọna ti ó hàn gbangba, Dafidi bẹ ẹ̀bẹ̀ yii nitori ti ó mọ̀ pe ìtẹ̀sí fun ẹṣẹ biburu lékenkà ṣì wà ninu ọkan-aya oun sibẹ. Awa ti lè ṣailọwọ ninu iru ẹṣẹ ti ó ré Dafidi lọ ni isopọ pẹlu Batṣeba ati Uriah, ṣugbọn a nilo iranlọwọ Jehofa lati yẹra fun ṣiṣubu sinu idẹwo lati lọwọ ninu iwa ẹṣẹ ti o gbópọn. Fun idi yẹn, a lè nilo iranlọwọ Ọlọrun funraawa lati mú iru awọn ìtẹ̀sí ti ó kún fun ẹṣẹ bi ojukokoro ati ikoriira kuro ni ọkan-aya wa—awọn iwa-ọdaran ti wọn rí bakan naa pẹlu olè-jíjà ati ipaniyan.—Kolosse 3:5, 6; 1 Johannu 3:15.

5. (a) Ki ni ó tumọsi lati ní ọkan-aya mimọgaara? (b) Ki ni Dafidi fẹ́ nigba ti o beere fun ẹmi titun?

5 Jehofa beere pe ki awọn iranṣẹ rẹ̀ ní “àyà titun,” iyẹn ni, imọgaara isunniṣe tabi èrò. Ní mímọ̀ pe oun kòì tíì fi iru imọgaara bẹẹ hàn, Dafidi gbadura pe ki Ọlọrun fọ ọkan-aya oun mọ́ ki ó sì mú ki ó wà ni iṣọkan pẹlu awọn ọpa-idiwọn atọrunwa rẹ̀. Olorin naa tún fẹ́ ẹmi titun, ti ó duroṣinṣin, tabi itẹsi ero-ori. Ó nilo ẹmi ti yoo ràn án lọwọ lati dènà idẹwo ki o sì dìrọ̀ gbọnyingbọnyin mọ awọn ofin ati ilana Jehofa.

Ẹmi Mimọ Ṣekoko

6. Eeṣe ti Dafidi fi bẹbẹ pe ki Jehofa maṣe mú ẹmi mimọ rẹ̀ kuro lọdọ oun?

6 Nigba ti a bá wà ninu ainireti lori awọn aṣiṣe tabi iwa-aitọ wa, a lè nimọlara pe Ọlọrun ti fẹ́ pa wá tì sẹgbẹẹkan ki o sì fawọ ẹmi mimọ, tabi ipá agbékánkánṣiṣẹ́ rẹ̀ sẹhin kuro lọdọ wa. Dafidi nimọlara ni ọ̀nà yẹn, nitori ti ó bẹ Jehofa pe: “Maṣe ṣá mi tì kuro niwaju rẹ; ki o má sì ṣe gba ẹmi mimọ rẹ lọwọ mi.” (Orin Dafidi 51:11) Dafidi ti inu rẹ̀ bàjẹ́ ti ó sì rẹ̀wẹ̀sì nimọlara pe awọn ẹṣẹ oun ti sọ oun di alaiyẹ lati ṣiṣẹsin Jehofa. Lati di ẹni ti a gbá dànù kuro niwaju Ọlọrun yoo tumọsi lati padanu ojurere, ìtùnú, ati ibukun rẹ̀. Bi a bá nilati mú Dafidi padabọsipo nipa tẹmi, ó nilo ẹmi mimọ Jehofa. Ni jijẹki ó ràdọ̀ bo oun, ọba naa lè fi taduratadura wá itọsọna atọrunwa ki ó baa lè wu Jehofa, ó lè yẹra fun ẹṣẹ, ó sì lè fi ọgbọ́n ṣakoso. Ni mimọ awọn ẹṣẹ rẹ̀ daradara lodisi Olufunni ni ẹmi mimọ, Dafidi jírẹ̀ẹ́bẹ̀ lọna ti o ṣe wẹ́kú pe ki Jehofa maṣe gbà á kuro lọwọ oun.

7. Eeṣe ti a fi nilati gbadura fun ẹmi mimọ ki a sì ṣọra lati maṣe mú un banujẹ?

7 Awa ń kọ́? A nilati gbadura fun ẹmi mimọ a sì gbọdọ ṣọra lati maṣe mú un banujẹ nipa kikuna lati tẹle idari rẹ̀. (Luku 11:13; Efesu 4:30) Bi bẹẹ kọ́, awa lè padanu ẹmi naa a kò sì ní lè fi awọn iṣupọ-eso rẹ̀ ti Ọlọrun ń fifunni ti ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, iwapẹlẹ, iṣoore, igbagbọ, iwatutu, ati ikora-ẹni-nijaanu hàn. Jehofa Ọlọrun ní pataki yoo gba ẹmi mimọ rẹ̀ kuro lọwọ wa bi a bá ń baa lọ lati maa dẹṣẹ lodisi i laironupiwada.

Ayọ Igbala

8. Bi a bá ṣẹ̀ ṣugbọn ti a fẹ́ lati ni ayọ igbala, ki ni a nilati ní?

8 Ẹlẹṣẹ ti o ronupiwada ti o niriiri imupadabọsipo tẹmi lè yọ̀ lẹẹkan sii ninu ipese igbala ti Jehofa. Ni yíyánhànhàn fun eyi, Dafidi bẹ̀bẹ̀ lọdọ Ọlọrun pe: “Mú ayọ igbala rẹ pada tọ̀ mí wá; ki o sì fi [ẹmi imuratan, NW] rẹ gbé mi duro.” (Orin Dafidi 51:12) Ó ti jẹ agbayanu tó lati yọ̀ ninu ireti igbala ti o daniloju lati ọ̀dọ̀ Jehofa Ọlọrun! (Orin Dafidi 3:8) Lẹhin didẹṣẹ lodisi Ọlọrun, Dafidi wá ọ̀nà imupadabọsipo ayọ igbala lati ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ni awọn akoko ẹhinwa ìgbà naa, Jehofa pese ọ̀nà fun igbala nipasẹ ẹbọ irapada Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi. Bi awa gẹgẹ bi oluṣeyasimimọ iranṣẹ Ọlọrun bá ṣẹ̀ lọna gbígbópọn ṣugbọn ti a fẹ́ ki ayọ igbala di eyi ti a mupadabọsipo fun wa, a nilati ní iṣarasihuwa onironupiwada ki a baa lè yẹra fun ṣíṣẹ̀ si ẹmi mimọ.—Matteu 12:31, 32; Heberu 6:4-6.

9. Ki ni Dafidi ń beere fun nigba ti ó beere lọwọ Ọlọrun lati fi “ẹmi imuratan,” ti oun lẹhin?

9 Dafidi beere pe ki Jehofa fi “ẹmi imuratan,” ti oun lẹhin. Ni kedere, eyi tọka si, kìí ṣe mímúratán ti Ọlọrun muratan lati ṣeranlọwọ tabi si ẹmi mimọ rẹ̀, ṣugbọn si ìtẹ̀sí ero-ori ti ń sún Dafidi ṣiṣẹ. Dafidi fẹ́ ki Ọlọrun ti oun lẹhin nipa fifun oun ni ẹmi imuratan lati ṣe ohun ti ó tọ́ ki oun má sì ṣe ṣubu sinu ẹṣẹ lẹẹkan sii. Jehofa Ọlọrun ń ti awọn iranṣẹ rẹ̀ lẹhin lemọlemọ ó sì ń gbé awọn wọnni ti oniruuru idanwo ti tẹ̀ loriba soke. (Orin Dafidi 145:14) Ó ti tuni ninu tó lati mọ eyi, ni pataki bi a bá ti ṣàṣìṣe ṣugbọn ti a ti banujẹ gidigidi ti a sì fẹ́ lati fi iṣotitọ ṣiṣẹsin Jehofa titi laelae!

Kọ́ Awọn Olùrékọjá Ni Ki Ni?

10, 11. (a) Ki ni Dafidi lè fi kọ́ awọn olùrékọjá Israeli? (b) Dafidi lè kọ́ awọn ẹlẹṣẹ kìkì lẹhin ṣiṣe ki ni funraarẹ?

10 Bi Ọlọrun yoo bá yọnda rẹ̀, Dafidi fi aimọtara-ẹni-nikan fẹ́ lati ṣe ohun kan ti yoo fi imọriri rẹ̀ fun àánú Jehofa hàn ti yoo sì ran awọn ẹlomiran lọwọ. Pẹlu adura ti o fi ero-imọlara hàn eyi ti a dari si Jehofa, ọba ti o ronupiwada naa polongo tẹle e pe: “Nigba naa ni emi ó maa kọ́ awọn olùrékọjá ni ọ̀nà rẹ: awọn ẹlẹṣẹ yoo sì maa yipada si ọ.” (Orin Dafidi 51:13) Bawo ni Dafidi ẹlẹṣẹ ṣe lè kọ́ awọn olùrékọjá ni Ofin Ọlọrun? Ki ni oun lè sọ fun wọn? Rere wo sì ni eyi lè ṣaṣepari rẹ̀?

11 Nigba ti ó ń fi awọn ọ̀nà Jehofa han awọn ọmọ Israeli olùrékọjá pẹlu ireti yiyi wọn pada kuro ni ipa-ọna buburu, Dafidi lè fi bi ẹṣẹ ti buru tó hàn, ohun ti ironupiwada tumọsi, ati bi wọn ṣe lè rí àánú Ọlọrun gbà. Bi ó ti nimọlara irora airojurere Jehofa ati ẹ̀rí-ọkàn ẹlẹ́bi-ẹ̀ṣẹ̀, Dafidi laiṣiyemeji yoo jẹ́ olutọni ti o ní ìyọ́nú fun awọn ẹlẹṣẹ oluronupiwada, ti wọn ní irobinujẹ-ọkan. Dajudaju, oun lè lo apẹẹrẹ tirẹ̀ lati kọ́ awọn ẹlomiran kìkì lẹhin ti oun funraarẹ bá ti tẹwọgba awọn ilana Jehofa ti o sì ti rí idariji Rẹ̀ gbà, nitori pe awọn wọnni ti wọn bá ń kọ̀ lati juwọsilẹ fun awọn ohun abeere fun Ọlọrun kò ní ẹ̀tọ́ lati ‘maa sọ awọn ilana Ọlọrun.’—Orin Dafidi 50:16, 17.

12. Bawo ni Dafidi ṣe janfaani lati inu ìmọ̀ pe Ọlọrun ti dá oun nídè kuro ninu ẹbi ẹ̀jẹ̀?

12 Nipa títún èrò rẹ̀ sọ ni ọ̀nà miiran, Dafidi sọ pe: “Ọlọrun, gbà mi lọwọ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, iwọ Ọlọrun igbala mi: ahọ́n mi yoo sì maa kọrin òdodo rẹ kíkan.” (Orin Dafidi 51:14) Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ mú ìdálẹ́bi si iku wá pẹlu rẹ̀. (Genesisi 9:5, 6) Nitori naa ìmọ̀ naa pe Ọlọrun igbala rẹ̀ ti dá oun nídè kuro lọwọ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ni isopọ pẹlu Uriah yoo fun Dafidi ni alaafia ọkan-aya ati ero-inu. Ahọ́n rẹ̀ lè fi ayọ kọrin nigba naa nipa òdodo Ọlọrun, kìí ṣe ti tirẹ̀. (Oniwasu 7:20; Romu 3:10) Dafidi kò lè pa iwapalapala rẹ̀ rẹ́ tabi mú Uriah pada wa lati inu sàréè, àní gẹgẹ bi eniyan ode-oni kan kò ti lè mú iwa-mimọ ẹni ti oun ti yileropada-dẹṣẹ kan tabi ẹni kan ti oun ti ṣekúpa padabọsipo. Kò ha yẹ ki a ronu nipa iyẹn nigba ti a bá dán wa wò bi? A sì ti nilati mọriri àánú ti Jehofa fihàn sí wa ni òdodo tó! Nitootọ, imọriri nilati sún wa lati dari awọn ẹlomiran si Orí-ojúsun òdodo ati idariji yii.

13. Kìkì labẹ ipo ayika wo ni ẹlẹṣẹ kan lè fi ẹ̀tọ́ ṣí ètè rẹ̀ lati yin Jehofa?

13 Kò sí ẹlẹṣẹ kan ti o lè fi ẹ̀tọ́ ṣí ètè rẹ̀ lati yin Jehofa ayafi bi Ọlọrun bá fi àánú ṣí wọn, kí á wí bẹẹ, lati sọ awọn otitọ Rẹ̀. Nitori naa Dafidi kọrin pe: “Oluwa, iwọ ṣí mi ni ètè; ẹnu mi yoo sì maa fi iyin rẹ hàn.” (Orin Dafidi 51:15) Pẹlu ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ ti a mú fúyẹ́ nitori idariji Ọlọrun, Dafidi ni a o sún lati kọ́ awọn olùrékọjá ni awọn ọ̀nà Jehofa, ó sì lè gbé E ga ni fàlàlà. Gbogbo awọn ti a ti dari ẹṣẹ wọn jì bi a ti ṣe fun Dafidi nilati mọriri iṣeun-ifẹ Jehofa si wọn, ó sì yẹ ki wọn lo anfaani gbogbo akoko ti o bá ṣí silẹ lati polongo otitọ Ọlọrun ki wọn sì ‘sọ iyin rẹ̀ jade.’—Orin Dafidi 43:3.

Awọn Ẹbọ Ti O Ni Itẹwọgba Lọdọ Ọlọrun

14. (a) Awọn ẹbọ wo ni a beere fun ni ibamu pẹlu majẹmu Ofin? (b) Eeṣe ti yoo fi lodi lati ronu pe a lè san àsanpadà fun iwa-aitọ ti ń baa lọ nipa ṣiṣe awọn ohun rere kan?

14 Dafidi ti jere agbára-òye jijinlẹ ti ó mú ki ó sọ pe: “Nitori iwọ [Jehofa] kò fẹ́ ẹbọ, ti emi ìbá rú u: inu rẹ kò dùn si ọrẹ-ẹbọ sísun.” (Orin Dafidi 51:16) Majẹmu Ofin beere pe ki a fi ẹbọ ẹran fun Ọlọrun. Ṣugbọn awọn ẹṣẹ Dafidi ti panṣaga ati ipaniyan, ti o yẹ fun ijiya iku, ni a kò lè fi iru awọn ẹbọ bẹẹ dí. Bi kìí bá ṣe bẹẹ ni, oun kì bá tí háwọ́ lati fi awọn ẹbọ ẹran fun Jehofa. Laisi ironupiwada atọkanwa, awọn ẹbọ jẹ alainiyelori. Kì yoo tọna nigba naa lati ronu pe awa lè san àsanpadà fun iwa-aitọ ti ń baa lọ nipa ṣiṣe awọn ohun rere kan.

15. Ki ni iṣarasihuwa oluṣeyasimọ kan ti ó ní ọkàn ìròbìnújẹ́?

15 Dafidi fikun un pe: “Ẹbọ Ọlọrun ni irobinujẹ ọkàn: irobinujẹ ati irora àyà, Ọlọrun, oun ni iwọ kì yoo gàn.” (Orin Dafidi 51:17) Ninu ọ̀ràn ti ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada, ‘ẹbọ ti o ṣetẹwọgba fun Ọlọrun ni ìròbìnújẹ́ ọkàn.’ Iru ẹni bẹẹ kìí ní iṣarasihuwa aríjàgbàá. Ọkan-aya oluṣeyasimimọ kan ti ó ni ìròbìnújẹ́ ọkàn ni ó bàjẹ́ gidigidi lori ẹṣẹ rẹ̀, oun ni a rẹ̀sílẹ̀ nitori ti o nimọlara pe oun kò ni ojurere Ọlọrun, ó sì muratan lati ṣe ohunkohun lati tun jere ojurere atọrunwa pada. Kò sí ohun ti ó niyelori kan ti a lè fun Ọlọrun titi di ìgbà ti a bá ronupiwada kuro ninu awọn ẹṣẹ wa ti a sì fun un ni ọkan-aya wa ninu ifọkansin ti a yasọtọ gedegbe.—Nahumu 1:2.

16. Oju wo ni Ọlọrun fi ń wo ẹnikan ti a bà lọkan jẹ́ nitori ẹṣẹ rẹ̀?

16 Ọlọrun kò kọ ẹbọ kan bi iru eyi ti o jẹ ti ọkàn ìròbìnújẹ́ ti a nilara. Laika iṣoro eyikeyii ti a bá dojukọ gẹgẹ bi eniyan rẹ̀ sí, nigba naa, ẹ maṣe jẹ ki a juwọsilẹ fun ainireti. Bi a bá ti kọsẹ̀ ni ipa oju-ọna igbesi-aye ni awọn ọ̀nà kan ti ó mú ọkan-aya wa kigbe jade fun àánú atọrunwa, kò tíì bọ́ latokedelẹ. Àní bi a bá tilẹ ti dẹṣẹ wiwuwo ribiribi paapaa ṣugbọn ti a ronupiwada, Jehofa kò ní fi ibinu kọ ọkàn ìròbìnújẹ́ wa. Oun yoo dariji wa lori ipilẹ ẹbọ irapada Kristi yoo sì mú ojurere Rẹ̀ padabọsipo fun wa. (Isaiah 57:15; Heberu 4:16; 1 Johannu 2:1) Bii Dafidi, bi o ti wu ki o ri, adura wa nilati jẹ fun imupadabọsipo ojurere atọrunwa kìí sìí ṣe fun àjàbọ́ lọwọ ibawi tabi itọsọna ti a nilo. Ọlọrun dariji Dafidi, sibẹ ó tún fiya jẹ ẹ́.—2 Samueli 12:11-14.

Aniyan fun Ijọsin Mimọgaara

17. Yatọ si jíjírẹ̀ẹ́bẹ̀ fun idariji Ọlọrun, ki ni awọn ẹlẹṣẹ nilati ṣe?

17 Bi a bá ti dá ẹṣẹ gbígbópọn kan, laiṣe tabi-ṣugbọn eyi yoo da ọkàn wa láàmú gidigidi, ìròbìnújẹ́ àyà yoo sì sún wa lati jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fun idariji Ọlọrun. Sibẹ, ẹ jẹ ki a tun gbadura fun awọn ẹlomiran. Bi o tilẹ jẹ pe Dafidi wọna fun ṣiṣe ijọsin ti o ṣetẹwọgba fun Ọlọrun lẹẹkan sii, orin rẹ̀ kò fi imọtara-ẹni-nikan ṣalai niiṣe pẹlu awọn ẹlomiran. Ó ní ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ yii si Jehofa ninu: “Ṣe rere ni didun inu rẹ si Sioni: iwọ mọ odi Jerusalemu.”—Orin Dafidi 51:18.

18. Eeṣe ti Dafidi ti o ronupiwada fi gbadura fun Sioni?

18 Bẹẹni, Dafidi fojusọna fun imupadabọsipo rẹ̀ si ojurere atọrunwa. Bi o ti wu ki o ri, olorin onirẹlẹ naa ni ó tún gbadura pe ‘ninu idunnu inu rẹ̀ Ọlọrun yoo ṣe rere fun Sioni,’ olu-ilu Israeli, Jerusalemu, nibi ti Dafidi ti reti lati kọ́ tẹmpili Ọlọrun si. Awọn ẹṣẹ Dafidi ti o gbópọn ti halẹmọ gbogbo orilẹ-ede naa latokedelẹ, nitori pe gbogbo awọn eniyan naa ìbá ti jiya nitori iwa-aitọ ọba naa. (Fiwe 2 Samueli, ori 24.) Niti tootọ, awọn ẹṣẹ rẹ̀ mú ki “ogiri Jerusalemu” di ẹgẹrẹmìtì, debi pe a nilati tun wọn kọ́ nigba naa lọhun-un.

19. Bi a bá ti dẹṣẹ ṣugbọn ti a ti dariji wa, ki ni yoo jẹ́ ohun yiyẹ lati gbadura fun?

19 Bi a bá ti dẹṣẹ lọna wíwúwo ribiribi ṣugbọn ti a ti rí idariji Ọlọrun gbà, yoo yẹ lati gbadura pe ki o ṣatunṣe ibajẹ eyikeyii ti iwa wa bá ti fà lọna kan ṣáá. A ti lè mú ẹ̀gàn wá sori orukọ mimọ rẹ̀, a ti lè jin ijọ lẹsẹ, a sì ti lè mu ibanujẹ wá bá idile wa. Baba wa ọrun onifẹẹ lè mú ẹ̀gàn eyikeyii ti a mú wá sori orukọ rẹ̀ kuro, ó lè gbé ijọ ró nipasẹ ẹmi mimọ rẹ̀, ó sì lè tu ọkan-aya awọn ololufẹ wa ti wọn nifẹẹ rẹ̀ ti wọn sì ń ṣiṣẹsin in ninu. Yala ó wémọ́ ẹṣẹ tabi bẹẹkọ, dajudaju, isọdimimọ orukọ Jehofa ati iwalalaafia awọn eniyan rẹ̀ nilati maa figba gbogbo jẹ́ idaniyan wa.—Matteu 6:9.

20. Labẹ awọn ipo ayika wo ni Jehofa yoo ni inu didun ninu awọn ẹbọ ati ọrẹ-ẹbọ Israeli?

20 Bi Jehofa bá tún ogiri Sioni kọ́, ohun miiran wo ni yoo tún ṣẹlẹ? Dafidi kọrin pe: “Nigba naa ni inu rẹ [Jehofa] yoo dùn si ẹbọ òdodo; pẹlu ọrẹ-ẹbọ sísun ati ọtọtọ ọrẹ-ẹbọ sísun: nigba naa ni wọn ó fi akọ-maluu rubọ lori pẹpẹ rẹ.” (Orin Dafidi 51:19) Dafidi fi ifọkansi fẹ́ pe ki oun ati orilẹ-ede naa gbadun ojurere Jehofa ki wọn baa lè jọsin Rẹ̀ lọna ti o ṣetẹwọgba. Nigba naa ni Ọlọrun yoo ni inu didun si awọn ẹbọ sísun ati gbogbo ẹbọ wọn. Eyi yoo rí bẹẹ nitori pe iwọnyi yoo jẹ́ ẹbọ òdodo tí awọn oluṣeyasimimọ, olotiitọ-inu, ti wọn sì jẹ́ eniyan ti o ronupiwada ti ń gbadun ojurere Ọlọrun rú. Nitori imoore fun àánú Jehofa, lori pẹpẹ rẹ̀ ni wọn yoo ti fi akọ-maluu rubọ—awọn ẹbọ didara julọ ti ó sì gbooro julọ. Lonii, a ń bọla fun Jehofa nipa mimu ohun didara julọ ti a ní wá fun un. Awọn ẹbọ wa sì wémọ́ “ọmọ-maluu ètè wa,” awọn ẹbọ iyin si Ọlọrun wa alaaanu, Jehofa.—Hosea 14:2; Heberu 13:15.

Jehofa Ń Gbọ́ Igbe Wa

21, 22. Orin Dafidi 51 ní awọn ẹkọ wo ninu fun anfaani wa?

21 Adura atọkanwa Dafidi ti a kọ silẹ ni Orin Dafidi 51 fihàn wa pe a nilati fi ẹmi ironupiwada tootọ huwapada si ẹṣẹ wa. Orin yii tún ní awọn ẹkọ ti wọn ṣe ṣàkó ninu fun anfaani wa. Fun apẹẹrẹ, bi a bá dẹṣẹ sibẹ ti a ronupiwada, a lè ni igbẹkẹle ninu àánú Ọlọrun. Bi o ti wu ki o ri, ẹ jẹ ki a daniyan ni pataki nipa ẹ̀gàn eyikeyii ti a ti lè mú wá sori orukọ Jehofa. (Ẹsẹ 1-4) Bii Dafidi, a lè fi taratara bẹbẹ fun àánú lọdọ Baba wa ọrun lori ipilẹ ipo wa ti ó kun fun ẹṣẹ ti a jogunba. (Ẹsẹ 5) A nilati jẹ oloootọ, a sì gbọdọ beere fun ọgbọn lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun. (Ẹsẹ 6) Bi a bá ti dẹṣẹ, ó yẹ ki a jírẹ̀ẹ́bẹ̀ lọdọ Jehofa fun isọdimimọ, ọkan-aya mimọgaara, ati ẹmi ti o duroṣinṣin.—Ẹsẹ 7-10.

22 Lati inu Orin Dafidi 51 a tun lè rí i pe a kò nilati fààyè gba araawa lati di ẹni ti o jingiri sinu ẹṣẹ. Bi awa bá nilati ṣe bẹẹ, Jehofa yoo mú ẹmi mimọ rẹ̀, tabi ipá agbékánkánṣiṣẹ́ rẹ̀ kuro lọdọ wa. Pẹlu ẹmi Ọlọrun lori wa, bi o ti wu ki o ri, a lè fi ikẹsẹjari kọ́ awọn ẹlomiran ni awọn ọ̀nà rẹ̀. (Ẹsẹ 11-13) Bi a bá ṣaṣiṣe sibẹ ti a ronupiwada, Jehofa yoo yọnda fun wa lati maa baa lọ ni yiyin in nitori pe oun kò jẹ́ gan ọkàn ìròbìnújẹ́ ati eyi ti a nilara. (Ẹsẹ 14-17) Orin yii fihàn siwaju sii pe awọn adura wa kò nilati kó afiyesi jọ sori araawa nikan. Kaka bẹẹ, a nilati gbadura fun ibukun ati iwalalaafia gbogbo awọn wọnni ti wọn ń lọwọ ninu ijọsin mimọgaara ti Jehofa.—Ẹsẹ 18, 19.

23. Eeṣe ti Orin Dafidi 51 ṣe nilati sún wa lati jẹ́ onigboya ati ẹlẹmii nǹkan yoo dara?

23 Orin wiwọnilọkan ṣinṣin ti Dafidi yii nilati sún wa lati jẹ́ onigboya ati ẹlẹmii nǹkan yoo dara. Ó ràn wá lọwọ lati mọ̀ pe a kò nilati ronu pe gbogbo rẹ̀ ti bọ́ latokedelẹ àní bi a bá tilẹ kọsẹ̀ ninu ẹṣẹ. Eeṣe? Nitori pe bi a bá ronupiwada, àánú Jehofa lè gbà wá là kuro ninu ainireti. Bi a bá jẹ́ onirobinujẹ ti a sì fi gbogbo ọkàn ṣiṣẹsin fun Baba wa ọrun onifẹẹ, oun yoo gbọ́ igbe wa fun àánú. Ó sì ti tuni ninu tó lati mọ̀ pe Jehofa kìí gan ọkàn ìròbìnújẹ́!

Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?

◻ Eeṣe ti awọn Kristian fi nilo ọkan-aya mimọgaara ati ẹmi mimọ Ọlọrun?

◻ Ki ni oluronupiwada kan lè fi kọ́ awọn olùré ofin Jehofa kọjá?

◻ Oju wo ni Jehofa fi ń wo ọkan-aya ti o ni ìròbìnújẹ́ ti a sì nilara?

◻ Awọn ẹkọ wo ni a rí ninu Orin Dafidi 51?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Iwọ ha ń gbadura fun ẹmi mimọ ti o sì ń ṣọra lati maṣe mú un banujẹ bi?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Fi imọriri hàn fun inurere ailẹtọọsi Jehofa nipa pipolongo otitọ rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́