Araye Ha Nilo Messia kan Niti Gidi Bi?
“AYÉ NILO MESSIA KAN, NI IJOYE-OṢIṢẸ WÍ”
Àkọlé gàdàgbà yẹn farahan ninu iwe-irohin The Financial Post ti Toronto, Canada, ni 1980. Ijoye-oṣiṣẹ ti a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ni Aurelio Peccei, ààrẹ ati olùdásílẹ̀ ajọ ti ń ṣewadii ninu pápá ìmọ̀-ẹ̀kọ́ pupọ tí a ń pè ni Club of Rome. Gẹgẹ bi iwe-irohin Post ṣe sọ, Peccei gbagbọ pe “aṣaaju akonimọra kan—niti imọ-ijinlẹ, oṣelu, tabi ti isin—ni yoo jẹ́ igbala kanṣoṣo fun ayé kuro ninu làásìgbò ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ati ti ọrọ̀-ajé tí ń halẹ̀ lati pa ọ̀làjú run.” Kí ni èrò rẹ? Ayé yii ha wà ninu iru òbítíbiti ipo iṣoro mimuna bẹẹ debi pe araye nilo Messia kan bi? Gbé kìkì ọ̀kan ninu awọn iṣoro ti ayé yii ń dojukọ yẹwo—ebi.
OJU alawọ ilẹ meji, ti o ri kòǹgbà ń wò ọ́ roro lati inu aworan inu iwe-irohin tabi iwe-irohin atigbadegba kan. Wọn jẹ́ oju ọmọde kan, ọmọdebinrin kan ti kò tilẹ tíì tó ọmọ ọdun marun-un. Ṣugbọn awọn oju wọnyii kò dẹ́rìn-ín pa ọ́. Kò si ẹwà ìgbà ọmọde lara wọn, kò sí imọlara iyanu amunilayọ, kò sí ifọkantan alailepanilara. Dipo bẹẹ wọn kún fun irora onídààmú, ríroni fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, ebi biburu jai. Ebi ń pa ọmọ naa. Irora ati ebi ni gbogbo ohun ti ó tíì mọ̀ rí.
Boya, bii ọpọlọpọ, iwọ kò fẹ́ lati ronu lori iru aworan bẹẹ, nitori naa iwọ yára ṣí oju-iwe naa. Kìí ṣe pe iwọ kò bikita, ṣugbọn o ní imọlara idaamu nitori pe o fura pe ẹ̀pa kò bóró mọ́ fun ọmọdebinrin yii. Awọn apá ati ẹsẹ ti ó ti rù kan egungun ati ikùn rẹ̀ rogodo jẹ́ àmì pe ara rẹ̀ ti bẹrẹ sii jẹ araarẹ̀ run. Ni akoko ti o ń rí aworan rẹ̀, oun ni o ṣeeṣe ki ó ti kú. Eyi ti ó buru jù, iwọ mọ̀ pe ọ̀ràn tirẹ̀ kuro ni eyi ti ó ṣajeji patapata.
Àní bawo ni iṣoro naa ti gbooro tó gan-an? Ó dara, iwọ ha lè ronuwoye awọn ọmọ million 14 bi? Ọpọ julọ ninu wa kò lè ṣe bẹẹ; iye naa wulẹ ti ga ju eyi ti a lè foju inu wo lọ. Nigba naa, ronuwoye ibi pápá iṣere nla kan ti ó lè gba 40,000 eniyan. Nisinsinyi ronuwoye pé ó kún bamubamu fun awọn ọmọde—ni ìlà tẹle ìlà, ìpele tẹle ìpele, awọn oju ti ó lọ súà bi omi-òkun. Iyẹn paapaa ṣoro lati ronuwoye. Sibẹ, yoo gba 350 iru pápá iṣere ńlá bẹẹ ti ó kún fun awọn ọmọde lati fun wa ni million 14. Gẹgẹ bi UNICEF (Ajọ Owó Akanlo Iparapọ Orilẹ-ede fun Awọn Ọmọde) ti wí, iyẹn ni iye bibanininujẹ ninu awọn ọmọde ti wọn kò tii pe ọdun marun-un ti wọn ń kú lọdọọdun fun àìjẹunre-kánú ati awọn aisan ti ó rọrun lati dènà ni awọn ilẹ ti ó ṣẹṣẹ ń goke àgbà. Iyẹn parapọ jẹ́ iye ti ó fẹrẹẹ tó pápá iṣere bọọlu ńlá ti ó kún fun awọn ọmọde ti wọn ń kú lojoojumọ! Fi iye awọn agbalagba ti ebi ń pa kún eyi, iwọ yoo sì gba aropọ nǹkan bii billion kan awọn eniyan ti wọn kò ri ounjẹẹre-jẹ-kanu fun ìgbà pípẹ́ kárí-ayé.
Kí ni Ó Fa Gbogbo Ebi Yii?
Ni lọwọlọwọ planẹti yii ń mú ounjẹ pupọ sii jade ju eyi ti awọn eniyan ń jẹ nisinsinyi, ó sì ni agbara lati tubọ mú pupọ sii jade. Sibẹ, ni iṣẹju kọọkan, awọn ọmọde 26 ń kú nitori àìjẹunre-kánú ati aisan. Ni iṣẹju yẹn kan-naa, ayé ń ná nǹkan bii $2,000,000 lori imurasilẹ ogun. Iwọ ha lè ronuwoye ohun ti gbogbo owó yẹn—tabi ìdákan rẹ̀ lasan—lè ṣe fun awọn ọmọde 26 wọnyẹn.
Ni kedere, ebi tí ń pa ayé ni a kò wulẹ lè dẹ́bi rẹ̀ lé aisi ounjẹ tabi owó. Iṣoro naa lọ jinlẹ ju iyẹn lọ. Gẹgẹ bi Jorge E. Hardoy, ọjọgbọn ọmọ ilẹ Argentina kan, ṣe sọ ọ́, “ayé lodindi ní àìlágbára wiwapẹtiti lati ṣajọpin itura, agbara, akoko, awọn ohun àmúṣọrọ̀ ati ìmọ̀ pẹlu awọn wọnni ti wọn nilo awọn nǹkan wọnyi jù.” Bẹẹni, iṣoro naa sinmi le, kìí ṣe awọn ohun àmúṣọrọ̀ eniyan, ṣugbọn pẹlu eniyan fúnraarẹ̀. Iwọra ati imọtara-ẹni-nikan dabi eyi ti o jẹ́ ipá ajọbabori ninu awujọ eniyan. Ìdámárùn-ún ti wọn lọ́rọ̀ julọ ninu awọn olùgbé ilẹ̀-ayé ń fi nǹkan bi ìgbà 60 gbadun awọn ire ipese awọn iṣeto ju ti ìdámárùn-ún tí wọn tòṣì julọ.
Loootọ, awọn kan ń fi otitọ-inu gbiyanju lati wá ounjẹ fun awọn ti ebi ń pa, ṣugbọn ọpọ julọ ninu awọn isapa wọn ni awọn kókó abajọ ti o kọja agbara wọn ń sọ di alaigbeṣẹ. Ìyàn sábà maa ń pọ́n awọn orilẹ-ede ti ogun abẹ́lé tabi ọ̀tẹ̀ ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ loju, kò sì ṣàìwọ́pọ̀ fun awọn ọmọ ogun alatako lati dínà mọ́ awọn ipese itura alaafia ki o ma baa dé ọdọ awọn alaini. Awọn apa mejeeji ń bẹru pe nipa jijẹ ki ounjẹ dé ọdọ awọn ara-ilu ti ebi ń pa ni agbegbe awọn ọ̀tá, awọn yoo maa founjẹ bọ́ awọn ọ̀tá wọn. Awọn ijọba funraawọn kò kọja lilo ifebipani gẹgẹ bi ohun ìjà oṣelu.
Kò Ha Sí Ojútùú Ni Bi?
Lọna ti kò dunmọni-ninu, iṣoro fífebi pa araadọta-ọkẹ ni kìí ṣe kìkì yanpọnyanrin kanṣoṣo ti ń fiya jẹ eniyan ode-oni. Iparun ati dída majele si agbegbe-ayika lọna pupọ rẹpẹtẹ, iyọnu ogun ṣiṣe lemọlemọ ti ń pa araadọta-ọkẹ ẹmi run, iwa-ọdaran oniwa-ipa ti ń tankalẹ eyi ti ń da ẹ̀rù ati ainigbẹkẹle silẹ nibi gbogbo, ati ipo iwarere ti ó figba gbogbo ń buru sii ṣáá eyi ti o jọ bii pe ó jẹ́ gbongbo ọpọlọpọ awọn iṣoro wọnyi—gbogbo awọn yanpọnyanrin agbaye wọnyi fọwọsowọpọ, gẹgẹ bi a ṣe lè sọ pe ó rí, wọn sì jẹrii si otitọ ti kò ṣee jáníkoro kan-naa—eniyan kò lè dari araarẹ pẹlu aṣeyọrisirere.
Kò sí iyemeji pe idi niyẹn ti ọpọlọpọ fi sọretinu nipa rírí ojútùú si awọn iṣoro ayé. Awọn miiran nimọlara gẹgẹ bi Aurelio Peccei, ọmọwe ọmọ ilẹ Italy ti a mẹnukan ni ibẹrẹ ti ṣe. Bi ojútùú kan bá nilati wà, wọn ronu pe, ó gbọdọ wá lati orisun ara-ọtọ kan—boya eyi ti o jú ti eniyan lọ paapaa. Nipa bayii èrò nipa messia ní ifanilọkanmọra alagbara. Ṣugbọn ó ha jẹ́ otitọ gidi lati nireti ninu messia kan bi? Tabi iru ireti kan bẹẹ ha wulẹ jẹ́ àlá kan ti kò lè ṣẹ bi?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Fọto ẹhin-iwe: Òkè: Fọto U.S. Naval Observatory; Ìsàlẹ̀: Fọto NASA
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Fọto WHO lati ọwọ P. Almasy
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
Fọto WHO lati ọwọ P. Almasy
Fọto U.S. Navy