ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 12/8 ojú ìwé 3-5
  • Wíwá Ojútùú Kiri

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwá Ojútùú Kiri
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé “Ọ̀rọ̀ Àpárá Tí Ń Pani Lẹ́kún” Ni Gbogbo Rẹ̀?
  • Kíkẹ́ Lọmọ
    Jí!—2000
  • Láti Inú Òógùn Àwọn Ọmọdé
    Jí!—1999
  • Dídáàbòbo Ìlera Àwọn Ọmọ
    Jí!—1997
  • Ìṣòro náà Kárí Ayé
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 12/8 ojú ìwé 3-5

Wíwá Ojútùú Kiri

LÁTI ìgbà tí wọ́n ti dá àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ ló ti nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀ràn tó bá ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọdé àti ìṣòro wọn. Lópin ọdún 1946, ó ṣètò ohun tí wọ́n ń pè ní Owó Àkànlò Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Ọ̀ràn Pàjáwìrì Àwọn Ọmọdé Jákèjádò Ayé (UNICEF) gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà pàjáwìrì láti máa fi bójú tó àwọn ọmọdé ní àwọn àgbègbè tí ogun ti ṣọṣẹ́.

Ní ọdún 1953, wọ́n sọ ètò owó àkànlò yìí di àjọ tí yóò máa wà títí lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti wá mọ̀ ọ́n sí Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé, ìkékúrú orúkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, ìyẹn UNICEF, ni wọ́n ṣì ń lò fún un. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ti lé ní àádọ́ta ọdún báyìí tí àjọ UNICEF ti ń pèsè oúnjẹ, aṣọ, àti ìtọ́jú lọ́nà ti ìṣègùn fún àwọn ọmọdé jákèjádò ayé, wọ́n sì ti ń gbìyànjú láti bójú tó ohun tí àwọn ọmọdé ṣaláìní lápapọ̀.

Wọ́n fún àìní àwọn ọmọdé ní àfiyèsí púpọ̀ gan-an ní ọdún 1959 nígbà tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe Ìkéde Ẹ̀tọ́ Ọmọdé. (Wo àpótí ní ojú ewé 5.) Wọ́n nírètí pé ìwé náà yóò mú kí ìṣòro àwọn ọmọdé gba àwọn èèyàn lọ́kàn, kí wọ́n sì lè wá nǹkan ṣe sí i nípa fífún àwọn ará ìlú níṣìírí láti ṣèrànwọ́ nípa nínáwó nára.

Ìwé ọdọọdún 1980 Year Book ti Collier sọ pé, ṣùgbọ́n “ogún ọdún lẹ́yìn náà, èyí tó pọ̀ jù lọ lára bílíọ̀nù kan ààbọ̀ ọmọdé tó wà lágbàáyé ni kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn ‘àwọn ẹ̀tọ́’ wọ̀nyí—àgàgà àwọn tó ní í ṣe pẹ̀lú oúnjẹ tí ń ṣara lóore, ìlera, àti níní àwọn ohun amáyédẹrùn.” Nítorí náà, níwọ̀n bí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti rí i pé ó yẹ kí òun yanjú ìṣòro àwọn ọmọdé àti pé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tó kéde pé òun yóò ṣe, ó wá pe ọdún 1979 ní Ọdún Àwọn Ọmọdé ní Àgbáyé. Àwọn ìjọba, àwọn aráàlú, àwọn ẹlẹ́sìn, àti àwùjọ àwọn afẹ́dàáfẹ́re jákèjádò ayé kò jáfara láti ṣètìlẹ́yìn fún wíwá ojútùú sí ìṣòro àwọn ọmọdé.

Ṣé “Ọ̀rọ̀ Àpárá Tí Ń Pani Lẹ́kún” Ni Gbogbo Rẹ̀?

Ó dùn wá láti sọ pé ìròyìn kan tí àjọ UNICEF gbé jáde fi hàn pé ọwọ́ ìyà ò tán lára àwọn ọmọdé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà láàárín Ọdún Àwọn Ọmọdé ní Àgbáyé. Lópin ọdún náà, nǹkan bí igba mílíọ̀nù lára wọn ni kò jẹunre kánú, àti pé ìdajì lára àwọn mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó kú nígbà tí wọn kò tíì pé ọmọ ọdún márùn-ún ni àìjẹunkánú pa. Lára ọgọ́rùn-ún ọmọdé táwọn èèyàn bí láàárín ìṣẹ́jú kọ̀ọ̀kan ní ọdún yẹn ní àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn, mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lára wọn ló kú kí wọ́n tó pé ọmọ ọdún kan. Kò ní tó ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn tí yóò kàwé jáde ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Nígbà tí ìwé ìròyìn Indian Express ń sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn àjọ UNICEF náà, ọ̀rọ̀ olóòtú inú rẹ̀ kédàárò pé ńṣe ni Ọdún Àwọn Ọmọdé wá yọrí sí “ọ̀rọ̀ àpárá tí ń pani lẹ́kún.”

Àwọn èèyàn kan ti rí i tẹ́lẹ̀ pé ìjákulẹ̀ náà ń bọ̀. Fún àpẹẹrẹ, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yẹn gan-an ni Fabrizio Dentice ti sọ nínú ìwé ìròyìn L’Espresso pé: “Ohun tí wọ́n pè ní Ọdún Àwọn Ọmọdé kò lè yanjú ìṣòro tó wà nílẹ̀ yìí rárá.” Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà gbé ìgbésí ayé lónìí ló sọ wá dà bí a ṣe dà, ìyẹn gan-an sì ni ohun tó yẹ ká yí padà.”

Bí wọ́n ti ń wá ojútùú kiri sí ìṣòro tí àwọn ọmọdé ní, wọ́n ṣe ìpàdé àgbáyé kan ní orílé-iṣẹ́ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní oṣù September 1990. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpàdé tó tóbi jù lọ tí àwọn aṣáájú lágbàáyé tíì ṣe nínú ìtàn ẹ̀dá. Ó lé ní àádọ́rin àwọn aṣáájú nínú ìjọba tó wà níbi ìpàdé náà. Ìpàdé náà jẹ́ àfikún sí Àdéhùn Nípa Ẹ̀tọ́ Ọmọdé, èyí tí wọ́n fọwọ́ sí ní November 20, 1989, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lò ó ní September 2, 1990. Nígbà tó fi máa di òpin oṣù yẹn, orílẹ̀-èdè mọ́kàndínlógójì ti fọwọ́ sí àdéhùn náà.

Láìpẹ́ yìí, àjọ UNICEF sọ pé: “Àdéhùn náà ti yára di àdéhùn lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tó ṣètẹ́wọ́gbà jù lọ, ó sì ń fún àwọn ọmọdé jákèjádò ayé ní ìṣírí.” Ní ti gidi, nígbà tó fi máa di oṣù November 1999, igba ó dín mẹ́sàn-án orílẹ̀-èdè ti tẹ́wọ́ gba Àdéhùn náà. Àjọ UNICEF yangàn pé: “Ní àwọn ẹ̀wádún tó tẹ̀ lé ìgbà táa ti fọwọ́ sí Àdéhùn Nípa Ẹ̀tọ́ Ọmọdé, a ṣe àwọn àṣeyọrí púpọ̀ gan-an ju ti ìgbàkigbà mìíràn tí a lè fi wéra nínú ìtàn ẹ̀dá lórí mímọ ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé kí a sì dáàbò bò ó.”

Láìka àwọn ìlọsíwájú yìí sí, Ààrẹ Johannes Rau ti orílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé: “Ó bani nínú jẹ́ pé ní àkókò tiwa yìí, ńṣe ni wọ́n ṣì ń rán wa létí pé àwọn ọmọdé ní ẹ̀tọ́.” Tàbí kí wọ́n ṣì tún máa rán wa létí pé wọ́n ṣì ní àwọn ìṣòro tó le koko! Àjọ UNICEF alára jẹ́wọ́ ní oṣù November 1999 pe, “àwọn ṣì ní ohun púpọ̀ láti ṣe,” ó sì ṣàlàyé pé: “Jákèjádò ayé, nǹkan bí àwọn ọmọdé tí iye wọ́n tó mílíọ̀nù méjìlá, tí wọn kò tíì pé ọmọ ọdún márùn-ún ló ń kú lọ́dọọdún, àwọn ohun tí a lè dènà rẹ̀ ló sì ń pa èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn. Nǹkan bí àádóje mílíọ̀nù ọmọdé ni kò lọ sí ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà . . . Nǹkan bí ọgọ́jọ mílíọ̀nù ọmọdé ni kò rí oúnjẹ jẹ tàbí kí wọ́n má jẹun kánú. . . . Ọ̀pọ̀ ọmọdé tí àwọn òbí wọn kò fẹ́ mọ́ ló ń ráre ní àwọn ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ aláìlóbìí àti àwọn ibùdó mìíràn. Wọn kò láǹfààní àtilọ sí ilé ìwé, wọn ò sì rí ìtọ́jú yíyẹ gbà. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń fìyà jẹ àwọn ọmọdé wọ̀nyí. Nǹkan bí àádọ́ta lé rúgba mílíọ̀nù àwọn ọmọdé làwọn èèyàn ń kó ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ àṣekúdórógbó.” Wọ́n tún mẹ́nu kan ọ̀ràn ẹgbẹ̀ta mílíọ̀nù ọmọdé tí òṣì paraku ń ta àti àwọn mílíọ̀nù mẹ́tàlá tí àrùn éèdì á ti pa ọ̀kan lára àwọn òbí wọn nígbà tó bá fi máa di òpin ọdún 2000.

Ó jọ pé ọwọ́ àwọn aṣíwájú tí wọ́n jẹ́ olóṣèlú kò tíì ba ojútùú tó tẹ́rùn sí àwọn ìṣòro wọ̀nyí. Síbẹ̀ ìṣòro àwọn ọmọdé kò mọ sí àwọn ilẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà nìkan. Ní àwọn orílẹ̀-èdè apá Ìwọ̀ Oòrùn ayé, àìmọye ọmọ ni oríṣi ìyà míì ń jẹ.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

“Ó bani nínú jẹ́ pé ní àkókò tiwa yìí, ńṣe ni wọ́n ṣì ń rán wa létí pé àwọn ọmọdé ní ẹ̀tọ́”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọdé tí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ṣe:

● Ẹ̀tọ́ láti ní orúkọ àti ìlú ìbílẹ̀.

● Ẹ̀tọ́ sí ìfararora, ìfẹ́, àti òye àti ohun ìní ti ara.

● Ẹ̀tọ́ sí oúnjẹ tó gbámúṣé, ilé, àti àbójútó ìlera.

● Ẹ̀tọ́ sí ìtọ́jú àkànṣe bí ó bá jẹ́ abirùn, yálà ní ìrísí, ní ọpọlọ, tàbí tí kò lè bẹ́gbẹ́ ṣe.

● Ẹ̀tọ́ sí wíwà lára àwọn tí a óò kọ́kọ́ dáàbò bò tí a óò sì ràn lọ́wọ́ nínú ipòkípò.

● Ẹ̀tọ́ láti rí ìdáàbòbò kúrò lọ́wọ́ gbogbo oríṣi ìwà àìnáání, ìwà òǹrorò, àti ìrẹ́nijẹ.

● Ẹ̀tọ́ sí àǹfààní kíkún fún eré ṣíṣe àti eré ìnàjú àti àǹfààní ọgbọọgba sí ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tí a mú lọ́ràn-anyàn, kí ọmọ náà lè lo agbára òye rẹ̀, kó sì di ẹni tó wúlò láwùjọ.

● Ẹ̀tọ́ láti mú gbogbo ẹ̀bùn àbínibí dàgbà ní àyíká tó lómìnira àti iyì.

● Ẹ̀tọ́ sí títọ́ ọ dàgbà láyìíká tí ẹ̀mí òye, àmúmọ́ra, ìbádọ́rẹ̀ẹ́ láàárín àwọn èèyàn, ẹ̀mí àlàáfíà, àti ẹ̀mí ará jákèjádò ayé wà.

● Ẹ̀tọ́ láti gbádùn àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí láìka ẹ̀yà, àwọ̀, ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ̀sìn, èrò onítọ̀hún nípa ìṣèlú tàbí àwọn èrò mìíràn, orírun rẹ̀, àti dúkìá, ìbí, tàbí àwọn ipò mìíràn sí.

[Credit Line]

A gbé àkópọ̀ yìí karí Everyman’s United Nations

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

UN PHOTO 148038/Jean Pierre Laffont

Fọ́tò UN

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

Àwọn fọ́tò tó wà lójú ewé 4 àti 5 Giacomo Pirozzi/Panos Pictures

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́