Dídáàbòbo Ìlera Àwọn Ọmọ
ÌRÒYÌN lọ́ọ́lọ́ọ́ kan tí Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé (UNICEF) gbé jáde nínú ìwé náà, The Progress of Nations, fi bí ipò ìlera àwọn ọmọdé ti sunwọ̀n sí i gan-an ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè hàn. Nípasẹ̀ ìsapá àjùmọ̀ṣe ti àwọn ìjọba àti àwọn àjọ àgbáyé, iye àwọn ọmọ tí ń kú láìtí ì pé ọmọ ọdún márùn-ún ti dín kù ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan. Síbẹ̀síbẹ̀, ìwé The Progress of Nations tún fi hàn pé lọ́dọọdún, a lè máa dá ẹ̀mí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọdé sí ní lílo ohun rírọrùn, tí kò sì wọ́n, pàápàá jù lọ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Àwọn òbí ní àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí àti ní àwọn ibòmíràn lè rí i pé àwọn àbá tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí wúlò.
Ìfọ́mọlọ́mú. Ìròyìn náà gbani nímọ̀ràn pé: “Ìfọ́mọlọ́mú ni ìbẹ̀rẹ̀ rírọrùn jù lọ sípa ìlera pípé àti ìjẹunrekánú.” Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) ti sọ, “a lè máa gba ẹ̀mí àwọn ọmọ ọwọ́ tí iye wọn lé ní mílíọ̀nù kan là lọ́dọọdún bí a bá ń fún gbogbo àwọn ọmọ ọwọ́ ní ọmú nìkan fún nǹkan bí oṣù mẹ́fà àkọ́kọ́.” Níwọ̀n bí àwọn ilé ìwòsàn àti àwọn ẹ̀ka ìtọ́jú aboyún ti ń fi àpẹẹrẹ gbígbámúṣé lélẹ̀, àjọ UNICEF àti àjọ WHO ń ṣagbátẹrù “fífún ilé ìwòsàn lẹ́bùn ṣíṣètìlẹ́yìn fún ire ọmọ ọwọ́.” Ète wọ́n jẹ́ láti fún àwọn ilé ìwòsàn ní ìsúnniṣe láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ìyá ọlọ́mọ tuntun, kí wọ́n sì fún wọn ní àmọ̀ràn yíyẹ nípa ìfọ́mọlọ́mú.
Ìmọ́tótó àti omi mímọ́tónítóní . Ìròyìn náà sọ pé: “A lè dín ìwọ̀n àrùn kù kíákíá nípasẹ̀ omi dídára, nípa yíyàgbẹ́ sínú ṣáláńgá, nípa fífọ ọwọ́ kí a tó fọwọ́ kan oúnjẹ, àti nípa gbígbọ́únjẹ àti kíkó o síbi tí ó láàbò.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ọ̀pọ̀ àdúgbò, ó béèrè fún ìsapá púpọ̀ kí a tó lè rí omi mímọ́tónítóní, ó ṣe pàtàkì gidigidi fún ìlera ọmọdé àti tí ìdílé.
Ìjẹunrekánú. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ti sọ, àfikún fítámì A lè ṣèdíwọ́ fún ikú àwọn ọmọdé tí iye wọ́n tó mílíọ̀nù mẹ́ta lọ́dọọdún. Ó sọ pé, ojútùú sí ìṣòro náà wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ó sì rọrùn láti rí i gbà, a sì lè ṣe èyí nípa mímú oúnjẹ sunwọ̀n sí i, mímú kí oúnjẹ túbọ̀ léròjà nínú, tàbí pípín oògùn fítámì A oníhóró. Pípín oògùn fítámì A oníhóró tí owó rẹ̀ jẹ́ sẹ́ǹtì méjì fún àwọn ọmọdé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ti ń fẹ̀rí hàn pé ó gbéṣẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí àìnító ìwọ̀n fítámì A ti wọ́pọ̀. A tún dábàá àwọn oúnjẹ bí ìbẹ́pẹ, máńgòrò, kárọ́ọ̀tì, ewébẹ̀ títutù yọ̀yọ̀, àti ẹyin.
Ìtọ́jú Àtẹnujẹ fún Ìdápadà Omi Ara. Àjọ UNICEF sọ pé, a lè dènà ikú ìdajì lára iye àwọn ọmọdé tí àrùn ìgbẹ́ gbuuru ń pa nípasẹ̀ àpòpọ̀ omi mímọ́tónítóní, iyọ̀, àti ṣúgà tàbí ìrẹsì lílọ̀, tí kò wọ́n, tí ó sì rọrùn láti ṣe.a Àwọn òbí tún gbọ́dọ̀ máa fún ọmọ náà ní oúnjẹ. Ní báyìí ná, a ti ń fi èyí gba ẹ̀mí tí a fojú díwọ̀n iye rẹ̀ sí mílíọ̀nù kan là lọ́dọọdún.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni síwájú sí i lórí dídáàbòbo ìlera àwọn ọmọ rẹ, jọ̀wọ́ wo Jí!, April 8, 1995, ojú ìwé 3 sí 14.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 11]
WHO